Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Má Ṣe Kọ Àwọn Tẹ́ Ẹ Jọ Jẹ́ Onígbàgbọ́ Sílẹ̀ Láé

Má Ṣe Kọ Àwọn Tẹ́ Ẹ Jọ Jẹ́ Onígbàgbọ́ Sílẹ̀ Láé

Má Ṣe Kọ Àwọn Tẹ́ Ẹ Jọ Jẹ́ Onígbàgbọ́ Sílẹ̀ Láé

JAROSŁAW àti ìyàwó rẹ̀ Beata * sọ pé: “Fún ọdún mẹ́wàá gbáko ni okòwò wa fi gbà wá lọ́kàn, a sì ń gbé ìgbé ayé yọ̀tọ̀mì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú òtítọ́ ni wọ́n ti tọ́ wa dàgbà, a ti ṣáko lọ jìnnà, àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà sì ti jó rẹ̀yìn débi pé ó ṣòro fún wa láti pa dà sínú òtítọ́.”

Arákùnrin míì, Marek, rántí ohun tó ṣẹlẹ̀, ó sọ pé: “Nítorí àwọn ìyípadà tó wáyé láwùjọ àti nínú ètò òṣèlú lórílẹ̀-èdè Poland, léraléra ni iṣẹ́ ń bọ́ lọ́wọ́ mi. Èyí kó ìdààmú bá mi. Ẹ̀rù sì bà mí láti dá iléeṣẹ́ tèmi sílẹ̀ torí pé mi ò fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ìṣòwò. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, mo dágbá lé e láti dá ọ̀kan sílẹ̀, èrò mi ni pé iṣẹ́ náà máa túbọ̀ ràn mí lọ́wọ́ láti gbọ́ bùkátà ìdílé mi, kò sì ní jẹ́ kí àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà yingin. Àmọ́ kò pẹ́ tí mo fi rí i pé ọ̀rọ̀ náà ò rí bí mo ṣe rò ó.”

Nínú ayé tí àtijẹ àtimu ti ń le sí i lójoojúmọ́ yìí, tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò sì rí iṣẹ́ ṣe, àwọn kan má ń wá ọ̀nà àbáyọ lójú méjèèjì, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ ṣe àwọn ìpinnu tí kò mọ́gbọ́n dání. Àwọn arákùnrin kan ti gbà láti máa ṣe àlékún iṣẹ́, láti wá iṣẹ́ kún iṣẹ́ tàbí kí wọ́n dá iṣẹ́ tara wọn sílẹ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ní ìrírí nípa iṣẹ́ náà. Wọ́n lérò pé àfikún owó tó ń wọlé fún àwọn máa ran ìdílé àwọn lọ́wọ́ kò sì ní pa àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Ọlọ́run lára. Síbẹ̀, béèyàn bá tiẹ̀ ní èrò rere lọ́kàn, àwọn ipò àìròtẹ́lẹ̀ àti ọrọ̀ ajé tí kò fara rọ lè ba ìwéwèé téèyàn ṣe jẹ́. Nítorí èyí, àwọn kan ti kó sínú pàkúté ìwọra, ìlépa ọ̀rọ̀ sì ti nípa búburú lórí iṣẹ́ ìsìn wọn sí Ọlọ́run.—Oníw. 9:11, 12.

Ìlépa àwọn nǹkan ti ayé ti gba àwọn arákùnrin àti àwọn arábìnrin kan lọ́kàn débi pé wọn kò ní àkókò fún ìdákẹ́kọ̀ọ́, ìpàdé tàbí iṣẹ́ ìwàásù mọ́. Torí pé wọn kò kíyè sára èyí ti ṣàkóbá fún ìjọsìn wọn àti àjọṣe tí wọ́n ní pẹ̀lú Jèhófà. Wọ́n tún lè pa àjọṣe pàtàkì mìíràn tì, ìyẹn ni àjọṣe tó wà láàárín wọn àti ‘àwọn tó bá wọn tan nínú ìgbàgbọ́.’ (Gál. 6:10) Díẹ̀díẹ̀ ni àwọn kan fà sẹ́yìn kúrò láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará Kristẹni. Ẹ jẹ́ ká fara balẹ̀ gbé apá yìí yẹ̀ wò.

Ojúṣe Wa sí Àwọn Tá A Jọ Jẹ́ Onígbàgbọ́

Ọ̀pọ̀ ọ̀nà ló wà tí gbogbo àwa ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin lè gbà fi ìyọ́nú hàn sí ara wa. (Róòmù 13:8) Nínú ìjọ tó o wà, ó ti ṣeé ṣe kó o rí ‘ẹni tí ìṣẹ́ ń ṣẹ́ tó ń kígbe fún ìrànlọ́wọ́.’ (Jóòbù 29:12) Àwọn kan lè ṣàìní ohun ìgbẹ́mìíró. Àpọ́sítélì Jòhánù rán wa létí àǹfààní tó ṣí sílẹ̀ fún wa bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀. Ó sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ní àlùmọ́ọ́nì ayé yìí fún ìtìlẹyìn ìgbésí ayé, tí ó sì rí i tí arákùnrin rẹ̀ ṣe aláìní, síbẹ̀ tí ó sé ilẹ̀kùn ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ rẹ̀ mọ́ ọn, lọ́nà wo ni ìfẹ́ fún Ọlọ́run fi dúró nínú rẹ̀?”—1 Jòh. 3:17.

Bó o bá jẹ́ ẹni tó lawọ́, ó ṣeé ṣe kó o ti ran àwọn tó ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́. Síbẹ̀, ìfẹ́ tá a ní sí ẹgbẹ́ àwọn ará kò mọ sórí àwọn ohun tara tá a lè fi ràn wọ́n lọ́wọ́. Àwọn kan lè máa kígbe fún ìrànlọ́wọ́ torí pé wọ́n dá wà tàbí torí pé wọ́n rẹ̀wẹ̀sì. Wọ́n lè máa rò pé àwọn kò yẹ lẹ́ni táá máa sin Jèhófà, àìsàn líle koko lè máa ṣe wọ́n tàbí kí èèyàn wọn kan kú. Ọ̀nà kan tá a lè gbà ràn wọ́n lọ́wọ́ ni pé ká tẹ́tí sí wọn ká sì máa bá wọn sọ̀rọ̀, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé à ń gba tiwọn rò àti pé àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ wá lógún. (1 Tẹs. 5:14) Èyí máa ń túbọ̀ mú kí okùn ìfẹ́ tá a ní sí àwọn ará wa yi.

Ó sì tún ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn olùṣọ́ àgùntàn tẹ̀mí ló máa wà nípò jù lọ láti tẹ́tí sí wọn lọ́nà tó fi hàn pé wọ́n gba tiwọn rò, tí wọ́n á fi hàn pé àwọn lóye wọn, tí wọ́n á sì fìfẹ́ lo Ìwé Mímọ́ láti gbà wọ́n nímọ̀ràn. (Ìṣe 20:28) Lọ́nà yẹn, àwọn alábòójútó ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, tó ní “ìfẹ́ni oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́” fún àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin.—1 Tẹs. 2:7, 8.

Àmọ́, bí Kristẹni kan bá ṣáko lọ kúrò nínú agbo, ojúṣe tó ní láti máa bójú tó àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni ńkọ́? Àwọn tó jẹ́ alábòójútó pàápàá lè kó sínú ọ̀fìn ìlépa ọrọ̀ àlùmọ́nì. Bí Kristẹni kan bá wá kó sínú irú ọ̀fìn bẹ́ẹ̀ ńkọ́?

Àníyàn Ìgbésí Ayé Di Ẹrù Pa Wọ́n

Bá a ṣe sọ ṣáájú, ńṣe ni ṣíṣe làálàá torí àtiwá jíjẹ mímu fún ìdílé máa ń mú kéèyàn ṣàníyàn kì í sì í jẹ́ kéèyàn fi ọwọ́ tó tọ́ mú àwọn ìlànà Ọlọ́run. (Mát. 13:22) Marek, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ lẹ́ẹ̀kan ṣàlàyé pé: “Nígbà tí okòwò mi dẹnu kọlẹ̀, mo pinnu pé màá lọ sókè òkun láti lọ wá iṣẹ́ olówó gọbọi. Mi ò lò ju oṣù mẹ́ta lọ, lẹ́yìn náà mo tún lọ lo oṣù mẹ́ta míì, bí mo sì ṣe máa ń ṣe nìyẹn. Àmọ́ bí mo bá ti dé kì í pẹ́ tí màá tún fi pa dà lọ. Èyí kó ìdààmú ọkàn bá ìyàwó mi tí kì í ṣe Kristẹni.”

Kì í ṣe ìdílé nìkan ló fara gbá a. Marek ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Yàtọ̀ sí wákàtí gígùn tí mo fi ń ṣiṣẹ́ lábẹ́ ooru gbígbóná janjan, ọ̀rọ̀ táwọn èèyànkéèyàn tí wọ́n fẹ́ láti máa mú àwọn ẹlòmíì sìn ń sọ máa ń ta sí mi létí. Ìwà ọmọ ìta ni wọ́n ń hù. Ọ̀rọ̀ náà tojú sú mi, kò sì sí ohun tí mo lè ṣe nípa rẹ̀. Ó tiẹ̀ wá burú débi pé mi ò rí àkókò fi tọ́jú ara mi, torí náà mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì pé bóyá ni màá lè wúlò fáwọn míì.”

Ó yẹ kí àbájáde ìpinnu tí Marek ṣe yìí mú ká sinmẹ̀dọ̀ ká sì ronú. Bó bá tiẹ̀ dà bíi pé wíwá iṣẹ́ lọ sókè òkun máa yanjú ìṣòro ìgbọ́bùkátà, ṣé kò ní dá àwọn ìṣòro míì sílẹ̀? Bí àpẹẹrẹ, kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí àjọṣe ìdílé pẹ̀lú Ọlọ́run, ta ni yóò sì jẹ́ agbọ̀ràndùn fún ìdílé? Ṣé wíwá iṣẹ́ lọ sókè òkun lè yọrí sí fífi ìjọ Ọlọ́run sílẹ̀? Ǹjẹ́ kò ní gba àǹfààní tá a ní láti máa ṣe iṣẹ́ ìránṣẹ́ fún àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ mọ́ wa lọ́wọ́?—1 Tím. 3:2-5.

Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó o mọ̀ pé kò dìgbà téèyàn bá kúrò lórílẹ̀-èdè rẹ̀ láti lọ ṣiṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè míì kí iṣẹ́ tó máa gba àkókò rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ. Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jarosław àti Beata. Ó sọ pé: “Wẹ́rẹ́ báyìí náà ni gbogbo rẹ̀ bẹ̀rẹ̀. A ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó tán ni, a wá ṣí ṣọ́ọ̀bù kékeré kan síbi tí ọjà ti tà dáadáa ká lè máa ta hot dog, ìyẹn ohun jíjẹ tí wọ́n máa ń fi ẹran ṣe. Torí èrè gọbọi tá à ń rí nídìí òwò náà, a mú kó gbòòrò sí i. Àmọ́, ó gba gbogbo àkókò wa, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í pa ìpàdé ìjọ jẹ. Kò pẹ́ kò jìnnà, mo fi iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sílẹ̀ mi ò sì lè sìn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ mọ́. Èrè tá à ń rí níbẹ̀ mú orí wa wu gan-an, torí náà a ṣí ilé ìtajà ńlá a sì dòwò pọ̀ pẹ̀lú ẹnì kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Láìpẹ́, mo bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sí òkè òkun láti tọwọ́ bọ àwọn ìwé àdéhùn ìṣòwò tó tó ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù dọ́là. Agbára káká ni mo fi máa ń wà nílé, èmi, ìyàwó mi àti ọmọbìnrin wa sì di àjèjì síra wa. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, òwò tó búrẹ́kẹ́ náà gbà wá lọ́kàn débi tá a fi ṣíwọ́ láti máa sin Jèhófà. Látìgbà tá a sì ti fi ìjọ sílẹ̀, a kò rí tàwọn ara wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin rò mọ́.”

Ẹ̀kọ́ wo lèyí fi kọ́ wa? Bí Kristẹni kan bá fẹ́ láti fi gbogbo ohun rere inú ayé tẹ́ ara rẹ̀ lọ́run, ó lè jìn sínú ọ̀fìn kó má sì bìkítà mọ́, kódà ó lè pàdánù “ẹ̀wù àwọ̀lékè rẹ̀,” ìyẹn àmì tá a fi ń dá wa mọ̀ gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni. (Ìṣí. 16:15) Ìyẹn lè mú ká má wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn arákùnrin wa tó yẹ ká máa ràn lọ́wọ́.

Gbé Ọ̀rọ̀ Ara Rẹ Yẹ̀ Wò

Ó ṣeé ṣe ká ronú pé, ‘ìyẹn ò jẹ́ ṣẹlẹ̀ sí mi.’ Síbẹ̀, ó dára kí gbogbo wa ronú jinlẹ̀ lórí ohun náà gan-an tó yẹ ká kà sí kòṣeémáàní nígbèésí ayé wa. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “A kò mú nǹkan kan wá sínú ayé, bẹ́ẹ̀ ni a kò sì lè mú ohunkóhun jáde. Nítorí náà, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” (1 Tím. 6:7, 8) Òótọ́ ni pé iye tó ń náni láti gbé lórílẹ̀-èdè kan yàtọ̀ sí iye tó ń náni láti gbé lórílẹ̀-èdè míì. Owó tá a lè rò pé kò tó nǹkan lórílẹ̀-èdè tó ti gòkè àgbà lè jẹ́ owó gọbọi lọ́pọ̀ ilẹ̀ míì.

Bó ti wù kí nǹkan rí níbi tá à ń gbé, ó dára ká ronú lórí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ tẹ̀ lé e. Ó ní: “Àwọn tí ó pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń ṣubú sínú ìdẹwò àti ìdẹkùn àti ọ̀pọ̀ ìfẹ́-ọkàn tí í ṣe ti òpònú, tí ó sì ń ṣeni lọ́ṣẹ́, èyí tí ń ri ènìyàn sínú ìparun àti ègbé.” (1 Tím. 6:9) Ibi tó fara sin ni ìdẹkùn máa ń wà, kó lè mú ẹran lójijì. Kí la lè ṣe tí a kò fi ní í kó sínú ìdẹkùn ‘ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́’?

Bá a bá ń pinnu àwọn nǹkan tá a máa fi sí ipò iwájú, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti ní àkókò púpọ̀ sí i fún àwọn ohun tó ní í ṣe pẹ̀lú Ìjọba Ọlọ́run tó fi mọ́ ìdákẹ́kọ̀ọ́. Bí Kristẹni kan bá sì ń gbàdúrà kó tó kẹ́kọ̀ọ́, èyí á ràn án lọ́wọ́ láti di ẹni tó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá” láti ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́.—2 Tím. 2:15; 3:17.

Láàárín ìwọ̀nba ọdún mélòó kan, ó ṣeé ṣe fún àwọn alàgbà onífẹ̀ẹ́ láti gbé Jarosław ró àti láti fún un ní ìṣírí. Èyí mú kó ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà. Ó sọ pé: “Nínú ìjíròrò kan tó yí mi lérò pa dà, àwọn alàgbà fa àpẹẹrẹ yọ nínú Ìwé Mímọ́ nípa ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ tó sì fẹ́ láti wà láàyè títí láé àmọ́ tí kò fẹ́ láti fi ọrọ̀ rẹ̀ sílẹ̀. Lẹ́yìn náà ni wọ́n fi ọgbọ́n béèrè bóyá ìsọfúnni náà bá ipò mi mu. Ìgbà yẹn ni ọpọlọ mi tó ṣí!”—Òwe 11:28; Máàkù 10:17-22.

Jarosław gbé ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ yẹ̀ wò, ó sì pinnu láti jáwọ́ nínú òwò tó ti búrẹ́kẹ́ náà. Láàárín ọdún méjì, àjọṣe òun àti ìdílé rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà tún ti dán mọ́rán sí i. Ó ti ń sin àwọn arákùnrin rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan nínú àwọn alàgbà báyìí. Jarosław sọ pé: “Bí àwọn ará bá ranrí mọ́ ìṣòwò débi pé wọ́n pa àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run tì, mo máa ń lo àpẹẹrẹ tèmi láti jẹ́ kí wọ́n rí i pé kò bọ́gbọ́n mu pé kí wọ́n fi àìdọ́gba dà pọ̀ pẹ̀lú àwọn aláìgbàgbọ́. Kò rọrùn láti mójú kúrò lára àwọn àǹfààní tó lè mówó wọlé, kò sì rọrùn láti má ṣe fàyè gba ìwà àìṣòótọ́.”—2 Kọ́r. 6:14.

Marek pẹ̀lú kẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó le. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé iṣẹ́ tó ń mú owó gidi wọlé tó lọ ṣe lókè òkun mú kí ìdílé rẹ̀ túbọ̀ rí owó gbọ́ bùkátà, èyí ṣàkóbá fún àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà àti àwọn arákùnrin rẹ̀. Nígbà tó yá, ó ṣe àtúntò ohun tó fi sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ó sọ pé: “Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá, ńṣe ni ọ̀ràn mi dà bíi ti Bárúkù ìgbàanì tó ‘ń wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ.’ Níkẹyìn, mo gbàdúrà sí Jèhófà, mo sọ àwọn àníyàn mi di mímọ̀ fún un, mo sì nímọ̀lára báyìí pé mo ti jèrè okun tẹ̀mí mi pa dà.” (Jer. 45:1-5) Ní báyìí, Marek ti ń fẹ́ láti tẹ́wọ́ gba “iṣẹ́ àtàtà” gẹ́gẹ́ bí alábòójútó nínú ìjọ.—1 Tím. 3:1.

Ìkìlọ̀ tí Marek fún àwọn tó ṣeé ṣe kí wọ́n máa gbèrò láti lọ sí òkè òkun láti wá iṣẹ́ táá máa mówó tabua wọlé rèé: “Bẹ́ ẹ bá wà lókè òkun, ó rọrùn láti kó sínú páńpẹ́ ayé búburú yìí. Bí ẹ kò bá lóye èdè tí wọ́n ń sọ níbẹ̀ dáadáa, ó máa ṣòro fún yín láti máa ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ẹ lè kó owó pa dà wálé, àmọ́ ó máa pẹ́ kí ọgbẹ́ tẹ̀mí tẹ́ ẹ gbà sára tó san.”

Bí a kò bá jẹ́ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ wa gba àkókò tó yẹ ká fi ṣe ojúṣe wa fún àwọn ará wa, a máa múnú Jèhófà dùn. A sì máa fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀, èyí tó máa mú kí àwọn míì ṣe ìpinnu tó mọ́gbọ́n dání. Àwọn tí àníyàn ìgbésí ayé ti di ẹrù pa nílò ìtìlẹ́yìn, àánú àti àpẹẹrẹ rere àwọn arákùnrin àti arábìnrin wọn. Àwọn alàgbà ìjọ àtàwọn míì tó dàgbà nípa tẹ̀mí lè ran àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ lọ́wọ́ láti wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì kí wọ́n má sì ṣe jẹ́ kí àwọn àníyàn ìgbésí ayé di ẹrù pa wọ́n.—Héb. 13:7.

Ǹjẹ́ kí a má ṣe jẹ́ kí iṣẹ́ wa gbà wá lọ́kàn débi tá a fi máa pa àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ wa tì. (Fílí. 1:10) Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká “ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run” bá a ti ń fi àwọn ohun tó jẹ mọ́ ire Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wa.—Lúùkù 12:21.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ṣé iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ rẹ máa ń dí ẹ lọ́wọ́ láti lọ sí ìpàdé?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ṣé o mọyì àǹfààní tó o ní láti ran àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ ará lọ́wọ́?