Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ni Jésù Kristi?

Ta Ni Jésù Kristi?

“Wàyí o, nígbà tí ó wọ Jerúsálẹ́mù, arukutu sọ ní gbogbo ìlú ńlá náà, wọ́n ń sọ pé: ‘Ta ni èyí?’ Àwọn ogunlọ́gọ̀ náà ń sọ ṣáá pé: ‘Èyí ni wòlíì náà Jésù, láti Násárétì ti Gálílì!’” —MÁTÍÙ 21:10, 11.

KÍ NÌDÍ tí arukutu fi sọ nígbà tí Jésù Kristi * dé sí Jerúsálẹ́mù ní ìgbà ìrúwé ọdún 33 Sànmánì Kristẹni yẹn? Ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà ní ìlú yẹn ló ti gbọ́ nípa Jésù àtàwọn ohun àrà ọ̀tọ̀ tó gbé ṣe. Wọ́n sì ń sọ nípa Jésù fún àwọn èèyàn. (Jòhánù 12:17-19) Síbẹ̀, àwọn èèyàn náà kò mọ̀ pé ọkùnrin tó wà láàárín wọn yìí máa nípa lórí aráyé fún ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún títí dé ọjọ́ wa!

Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan nípa bí Jésù ṣe nípa lórí aráyé lọ́nà tó gbòòrò gan-an.

  • Ọdún tí wọ́n sọ pé wọ́n bí Jésù ni wọ́n fi ń ka kàlẹ́ńdà táwọn èèyàn sábà ń lò lóde òní níbi púpọ̀ láyé.

  • Nǹkan bíi bílíọ̀nù méjì àwọn èèyàn, ìyẹn nǹkan bí ìdá kan nínú ìdá mẹ́ta àwọn èèyàn tó ń gbé ayé ló sọ pé àwọn jẹ́ Kristẹni.

  • Àwọn Mùsùlùmí tó wà láyé lé ní bílíọ̀nù kan, wọ́n ń kọni pé Jésù jẹ́ “wòlíì tó tóbi ju Ábúráhámù, Nóà àti Mósè lọ.”

  • Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tí Jésù sọ là ń lò ní onírúurú ọ̀nà nínú ọ̀rọ̀ tá à ń sọ lójoojúmọ́. Lára wọn rèé:

    ‘Ohun tí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá ń ṣe, kí ọwọ́ òsì má mọ̀.MÁTÍÙ 6:3.

    ‘Ẹ fi ohun ti Késárì fún Késárì.’MÁTÍÙ 22:21.

    ‘Ẹnì kan kò lè sin ọ̀gá méjì.’MÁTÍÙ 6:24.

    ‘Ẹ jẹ́ kí bẹ́ẹ̀ ni yin jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni, kí bẹ́ẹ̀ kọ́ yín sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ kọ́.’MÁTÍÙ 5:37.

    ‘Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn èèyàn ṣe sí yín, ni kí ẹ máa ṣe sí wọn.’MÁTÍÙ 7:12.

    ‘Aláàánú ará Samáríà.’LÚÙKÙ 10:33.

Kò sí àní-àní pé Jésù ti nípa lórí aráyé. Síbẹ̀, oríṣiríṣi èrò àti ìgbàgbọ́ ni àwọn èèyàn ní nípa Jésù níbi gbogbo. Nítorí náà, o lè máa ṣe kàyéfì pé, ‘Ta ni Jésù Kristi?’ Bíbélì nìkan ṣoṣo ló sọ fún wa nípa ibi tí Jésù ti wá, bó ṣe gbé ìgbé ayé rẹ̀ àti ìdí tó fi kú. Tó o bá mọ àwọn òtítọ́ yìí nípa Jésù, èyí lè nípa rere lórí ìgbésí ayé rẹ nísinsìnyí àti lọ́jọ́ iwájú.

^ “Jésù,” ni orúkọ wòlíì náà tó wá láti Násárétì, orúkọ náà túmọ̀ sí “Jèhófà Ni Ìgbàlà.” Orúkọ oyè náà “Kristi” túmọ̀ sí “Ẹni Àmì Òróró,” ìyẹn sì túmọ̀ sí pé Ọlọ́run fòróró yan Jésù sí ipò pàtàkì kan.