Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jésù—Báwo Ló Ṣe Gbé Ìgbé Ayé Rẹ̀?

Jésù—Báwo Ló Ṣe Gbé Ìgbé Ayé Rẹ̀?

“Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.”—JÒHÁNÙ 4:34.

OHUN tó ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù sọ̀rọ̀ tó wà lókè yìí fi ọ̀pọ̀ nǹkan hàn nípa ohun tó gbájú mọ́ ní ìgbésí ayé rẹ̀. Àtàárọ̀ ni Jésù àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ti ń rìn gba àwọn orí òkè tó wà ní àgbègbè Samáríà kọjá. (Jòhánù 4:6) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù rò pé níbi tọ́jọ́ dé yìí, ebi á ti máa pa á, nítorí náà, wọ́n ní kó wá jẹun. (Jòhánù 4:31-33) Nínú ìdáhùn tí Jésù fún wọn, ó jẹ́ kí wọ́n mọ ohun tí òun fẹ́ fi ìgbésí ayé òun ṣe. Ṣíṣe iṣẹ́ Ọlọ́run ṣe pàtàkì lójú rẹ̀ ju oúnjẹ lọ. Nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe Jésù, ó gbé ìgbé ayé rẹ̀ lọ́nà tó bá ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kó ṣe mu. Ọ̀nà wo ló gbà ṣe é?

Ó ń wàásù, ó sì ń kọ́ni nípa Ìjọba Ọlọ́run

Bíbélì ṣàlàyé iṣẹ́ tí Jésù fi ìgbésí ayé rẹ̀ ṣe, ó ní: “Ó lọ yí ká jákèjádò Gálílì, ó ń kọ́ni . . . ó sì ń wàásù ìhìn rere ìjọba náà.” (Mátíù 4:23) Yàtọ̀ sí pé Jésù wàásù tàbí polongo Ìjọba Ọlọ́run fún àwọn èèyàn, ó tún kọ́ wọn, ìyẹn ni pé, ó fún wọn ní ìtọ́ni, ó ṣàlàyé nǹkan fún wọn, ó sì bá wọn fèrò wérò kó lè mú kí nǹkan dá wọ́n lójú. Ìjọba Ọlọ́run ni ẹ̀kọ́ Jésù dá lé.

Ní gbogbo àkókò tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ó kọ́ àwọn tó ń gbọ́rọ̀ rẹ̀ ní ohun tí Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ àti ohun tí yóò ṣe. Kíyè sí àwọn òtítọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí nípa Ìjọba Ọlọ́run àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó jẹ́ ká mọ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa rẹ̀.

  • Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba ọ̀run, Jésù sì ni Jèhófà yàn láti jẹ́ Ọba ìjọba náà.—MÁTÍÙ 4:17; JÒHÁNÙ 18:36.

  • Ìjọba náà yóò ya orúkọ Ọlọ́run sí mímọ́, yóò sì mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé bíi ti ọ̀run.—MÁTÍÙ 6:9, 10.

  • Lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, gbogbo ayé yóò di Párádísè.—LÚÙKÙ 23:42, 43.

  • Ìjọba Ọlọ́run yóò dé láìpẹ́, á sì ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́ fún aráyé. *MÁTÍÙ 24:3, 7-12.

Ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu

“Olùkọ́” ni wọ́n mọ Jésù sí jù lọ. (Jòhánù 13:13) Àmọ́, ó tún ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu lákòókò iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ tó ṣe fún ọdún mẹ́ta àti ààbọ̀. Àwọn iṣẹ́ náà jẹ́ ká mọ ohun méjì nípa Jésù. Àkọ́kọ́, wọ́n jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ló rán an lóòótọ́. (Mátíù 11:2-6) Èkejì, wọ́n ṣe àfihàn ohun tí Jésù tó jẹ́ Ọba Ìjọba Ọlọ́run máa ṣe lọ́nà tó gbòòrò lọ́jọ́ iwájú. Kíyè sí díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe.

Fojú inú wo bí ayé ṣe máa rí lábẹ́ ìṣàkóso irú Ọba alágbára yẹn!

Ó fi ànímọ́ Jèhófà Ọlọ́run hàn

Nígbà tó bá kan ọ̀ràn kíkọ́ àwọn èèyàn nípa Jèhófà, kò sí ẹni tó kúnjú ìwọ̀n bí Ọmọ Ọlọ́run, ẹni tá a mọ̀ sí Jésù Kristi. Gẹ́gẹ́ bí “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá,” Jésù tí gbé lọ́dọ̀ Jèhófà ní ọ̀run ju ẹ̀dá ẹ̀mí èyíkéyìí lọ. (Kólósè 1:15) Ronú nípa àǹfààní tí Jésù ní láti mọ èrò Bàbá rẹ̀, láti mọ ohun tó fẹ́, kó sì mọ àwọn ìlànà àtàwọn ọ̀nà rẹ̀.

Ìdí nìyẹn tí Jésù fi sọ pé: “Kò sì sí ẹni tí ó mọ ẹni tí Ọmọ jẹ́ bí kò ṣe Baba; ẹni tí Baba sì jẹ́, kò sí ẹni tí ó mọ̀ bí kò ṣe Ọmọ, àti ẹni tí Ọmọ bá fẹ́ láti ṣí i payá fún.” (Lúùkù 10:22) Nígbà tí Jésù wà láyé gẹ́gẹ́ bí èèyàn, tọkàntọkàn ló fi sọ irú ẹni tí Bàbá rẹ̀ jẹ́, ó sì ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìtara. Jésù sọ̀rọ̀, ó sì kọ́ni lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó rántí gbogbo ohun tí ó mọ̀ nígbà tó ń gbé lọ́run lọ́dọ̀ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, ó sì fi wọ́n sílò.—Jòhánù 8:28.

Ohun tí Jésù ṣe láti jẹ́ ká mọ irú ẹni tí Bàbá rẹ̀ jẹ́ ni a lè fi wé ohun tí ẹ̀rọ tó ń pín agbára iná mànàmáná, ìyẹn tiransifọ́mà, máa ń ṣe. Ẹ̀rọ yìí máa ń gba agbára iná mànàmáná tó kàmàmà sára, á wá pín in sí kéékèèké, èyí tí á ṣeé lò fún àwọn èèyàn. Bákan náà, nígbà tí Jésù wà láyé, ó fi àwọn ohun tó ti kọ́ ní ọ̀run nípa Bàbá rẹ̀ kọ́ àwọn ẹ̀dá èèyàn lọ́nà tó máa tètè yé wọn, tí wọ́n á sì lè fi í sílò.

Ṣàgbéyẹ̀wò ọ̀nà pàtàkì méjì tí Jésù gbà jẹ́ ká mọ Bàbá rẹ̀.

  • Nígbà tí Jésù ń kọ́ni, ó jẹ́ ká mọ òtítọ́ nípa Jèhófà, ìyẹn ohun tí orúkọ rẹ̀ túmọ̀ sí, ohun tó fẹ́ ṣe fún aráyé àtàwọn ọ̀nà rẹ̀.—JÒHÁNÙ 3:16; 17:6, 26.

  • Nípa ohun tí Jésù ṣe, ó jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ ọ̀nà tó dára tí ànímọ́ Jèhófà pín sí. Jésù fi ànímọ́ Bàbá rẹ̀ hàn láìkù síbì kan débi tó fi sọ pé: ‘Tó o bá fẹ́ mọ bí Bàbá mi ṣe rí, ìwọ sáà wò mí.’—JÒHÁNÙ 5:19; 14:9.

Ọ̀nà tí Jésù gbà gbé ìgbé ayé rẹ̀ ṣàrà ọ̀tọ̀, ó sì wú wa lórí gan-an. Àǹfààní tá a máa jẹ nínú rẹ̀ á kàmàmà tá a bá ṣàgbéyẹ̀wò ìdí tí Jésù fi kú, tá a sì fi ohun tá a bá kọ́ ṣèwà hù.

^ Láti kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i nípa Ìjọba Ọlọ́run àti bí a ṣe mọ̀ pé yóò dé láìpẹ́, ka orí 8, ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? tó ní àkòrí náà, “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run,” àti orí 9, tó sọ pé, “Ṣé ‘Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn’ La Wà Yìí?” Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.