Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jésù—Kí Nìdí Tó Fi Kú?

Jésù—Kí Nìdí Tó Fi Kú?

‘Ọmọ ènìyàn wá kí ó lè fi ẹ̀mí rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn.’—MÁÀKÙ 10:45.

JÉSÙ mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀. Ó mọ̀ pé ìgbésí ayé òun kò ní rọrùn. Ó mọ̀ pé wọ́n máa dá ẹ̀mí òun légbodò tí òun bá ti lé lẹ́ni ọgbọ̀n ọdún, ó sì ti múra tán láti kú.

Bíbélì sọ pé ikú Jésù ṣe pàtàkì gan-an. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé nǹkan bí ìgbà márùndínlọ́gọ́sàn-án [175] ni Bíbélì mẹ́nu kan ikú Jésù ní tààràtà nínu Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, tàbí Májẹ̀mú Tuntun. Àmọ́, kí nìdí tí Jésù fi ní láti jìyà, kó sì kú? A ní láti mọ ìdí náà, nítorí ikú Jésù lè nípa rere lórí ìgbésí ayé wa.

Ohun tí Jésù ń retí

Ní àwọn ìgbà mélòó kan ní ọdún tí Jésù lò kẹ́yìn ìgbésí ayé rẹ̀, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nípa ìyà àti ikú tó ń dúró de òun. Nígbà tó ń lọ sí Jerúsálẹ́mù láti ṣe Ìrékọjá tó kẹ́yìn, ó sọ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá pé: “A ó sì fa Ọmọ ènìyàn lé àwọn olórí àlùfáà àti àwọn akọ̀wé òfin lọ́wọ́, wọn yóò sì dá a lẹ́bi ikú, wọn yóò sì fà á lé àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè lọ́wọ́, wọn yóò sì fi í ṣe yẹ̀yẹ́, wọn yóò sì tutọ́ sí i lára, wọn yóò sì nà án lọ́rẹ́, wọn yóò sì pa á.” * (Máàkù 10:33, 34) Kí nìdí tí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Jésù fi dá a lójú tó bẹ́ẹ̀?

Jésù mọ ọ̀pọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tó sọ nípa bí òun ṣe máa kú. (Lúùkù 18:31-33) Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ náà àtàwọn ẹsẹ Bíbélì tó ṣàlàyé bí wọ́n ṣe ṣẹ.

Mèsáyà máa di ẹni tí wọ́n . . .

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí àtàwọn míì ṣẹ sí Jésù lára. Kò sí bí òun fúnra rẹ̀ ṣe lè mú káwọn nǹkan yẹn ṣẹ sí òun lára. Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yìí ṣe ṣẹ sí Jésù lára jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run ló rán an lóòótọ́. *

Àmọ́ ṣá o, kí nìdí tí Jésù fi ní láti jìyà kó sì kú?

Jésù kú kí ó lè yanjú àwọn ọ̀ràn pàtàkì kan

Jésù mọ àwọn ọ̀ràn pàtàkì kan tó kan gbogbo ẹ̀dá èèyàn àtàwọn áńgẹ́lì, èyí tó wáyé ní ọgbà Édẹ́nì. Ipa tí áńgẹ́lì ọlọ̀tẹ̀ kan ní lórí Ádámù àti Éfà mú kí wọ́n ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ìwà ọ̀tẹ̀ tí tọkọtaya yìí hù fi èrò wọn hàn pé, Ọlọ́run kò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ láyé àtọ̀run tàbí pé ọ̀nà tó ń gbà ṣàkóso kò dára. Ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá tún gbé èrò míì jáde, pé bóyá ni ẹ̀dá èèyàn èyíkéyìí lè jẹ́ olóòótọ́ sí Ọlọ́run lójú ìdánwò.—Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6; Job 2:1-5.

Jésù fúnni ní ìdáhùn tó dára jù lọ lórí ọ̀ràn méjì náà, ìyẹn ipò ọba aláṣẹ Jèhófà àti ìṣòtítọ́ èèyàn. Jésù tipasẹ̀ ìgbọràn tó ṣe délẹ̀délẹ̀ “títí dé ikú, . . . lórí òpó igi oró,” fi hàn pé òun fara mọ́ ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. (Fílípì 2:8) Jésù tún fi hàn pé èèyàn pípé lè jẹ́ olóòótọ́ délẹ̀délẹ̀ sí Jèhófà láìka àdánwò tó le jù lọ sí.

Jésù kú kí ó lè ra aráyé pa dà

Wòlíì Aísáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé, ìyà àti ikú Mèsáyà máa pèsè ètùtù fún ẹ̀ṣẹ̀ aráyé. (Aísáyà 53:5, 10) Jésù lóye èyí, ó sì fínnúfíndọ̀ fi “ọkàn rẹ̀ fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Ikú ìrúbọ tí Jésù kú ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún àwa èèyàn aláìpé láti lè ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, kí á sì bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ikú Jésù ṣí àǹfààní sílẹ̀ fún wa láti gba ohun tí Ádámù àti Éfà sọ nù pa dà, ìyẹn ìrètí láti wà láàyè títí láé nínú ipò pípé lórí ilẹ̀ ayé. *Ìṣípayá 21:3, 4.

Ohun tí o lè ṣe

Nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí, a ti ṣàyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa ibi tí Jésù ti wá, bí ó ṣe gbé ìgbé ayé rẹ̀ àti ìdí tó fi kú. Yàtọ̀ sí pé mímọ àwọn òtítọ́ yìí nípa Jésù lè mú gbogbo àṣìlóye nípa Jésù kúrò, ó tún lè jẹ́ ká lóye àwọn ohun míì pẹ̀lú. Tá a bá fi àwọn òtítọ́ náà ṣèwà hù, ìbùkún tó máa jẹ́ tiwa ni, ìgbésí ayé tó dára nísinsìnyí àti ìyè àìnípẹ̀kun lọ́jọ́ iwájú. Bíbélì sọ ohun tó yẹ ká ṣe tá a bá fẹ́ ní irú ìbùkún yẹn.

  • Kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i nípa Jésù Kristi àti ipa tó kó nínú mímú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ.—JÒHÁNÙ 17:3.

  • Lo ìgbàgbọ́ nínú Jésù nípa fífi hàn nínú ìgbésí ayé rẹ pé o gbà pé Jésù ni Olùgbàlà rẹ.—JÒHÁNÙ 3:36; ÌṢE 5:31.

Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti mọ púpọ̀ sí i nípa Jésù Kristi, ‘Ọmọ bíbí kan ṣoṣo’ Ọlọ́run, ipasẹ̀ ẹni tá a lè rí ẹ̀bùn “ìyè àìnípẹ̀kun” gbà.—Jòhánù 3:16.

^ Jésù sábà máa ń pe ara rẹ̀ ní “Ọmọ ènìyàn.” (Mátíù 8:20) Ọ̀rọ̀ yìí fi hàn pé yàtọ̀ sí pé Jésù jẹ́ èèyàn, ó tún fi hàn pé òun ni “ọmọ ènìyàn” tí Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀.—Dáníẹ́lì 7:13, 14.

^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ sí Jésù lára, ka àkòrí náà, “Jésù Kristi Ni Mèsáyà Tí Ọlọ́run Ṣèlérí” nínú àfikún tó wà ní apá ìparí ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa bí ikú ìrúbọ tí Jésù kú ti ṣeyebíye tó, ka orí 5 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Ìràpadà—Ẹ̀bùn Tó Ṣeyebíye Jù Lọ Tí Ọlọ́run Fúnni.”