Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ìwà Ọ̀daràn wo ni Bárábà hù?

Ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ló mẹ́nu kan Bárábà, ìyẹn ọkùnrin tí Pọ́ńtù Pílátù tó ń ṣojú fún ilẹ̀ Róòmù dá sílẹ̀ dípò Jésù. Wọ́n pe Bárábà ní “ẹlẹ́wọ̀n olókìkí burúkú” àti “ọlọ́ṣà.” (Mátíù 27:16; Jòhánù 18:40) Ó wà ní àtìmọ́lé lábẹ́ àṣẹ Róòmù ní Jerúsálẹ́mù “pẹ̀lú àwọn adìtẹ̀ sí ìjọba, àwọn tí wọ́n ṣìkà pànìyàn nínú ìdìtẹ̀ wọn sí ìjọba.”—Máàkù 15:7.

Kò sí ẹ̀rí kankan nínú àkọsílẹ̀ ìtàn ayé tó sọ nípa ìwà ọ̀daràn tí Bárábà hù, àmọ́ nítorí pé wọ́n kà á mọ́ àwọn adìtẹ̀ sí ìjọba, èyí ti mú kí àwọn ọ̀mọ̀wé kan sọ pé, ó wà lára àwọn tó fẹ́ dojú ìjọba dé ní Ísírẹ́lì ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Òpìtàn Flavius Josephus kọ̀wé pé àwọn ọ̀daràn kan ni wọ́n jẹ́ òléwájú nínú jíjà fún àwọn ará ìlú ní àkókò yẹn. Àwọn ọ̀daràn yìí sọ pé ẹ̀tọ́ àwọn àgbẹ̀ Júù tí wọ́n jẹ́ mẹ̀kúnnù tí wọ́n ń pọ́n lójú làwọn ń jà fún. Ọ̀tẹ̀ tí àwọn ọ̀daràn yìí dá sílẹ̀, nítorí àìṣẹ̀tọ́ tí wọ́n sọ pé àwọn ará Róòmù àtàwọn abẹnugan Júù ń ṣe, wá gbilẹ̀ gan-an nígbà tó máa fi di ìdajì ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni. Nígbà tó yá, àwọn ọ̀daràn yìí ló pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ ogun Júù tí wọ́n lé àwọn ará Róòmù kúrò ní Jùdíà ní ọdún 66 Sànmánì Kristẹni.

Ìwé atúmọ̀ èdè Bíbélì, ìyẹn The Anchor Bible Dictionary sọ pé, “Ó ṣeé ṣe kí Bárábà jẹ́ ọ̀kan lára àwùjọ àwọn ọlọ́ṣà tó wà ní ìgbèríko. Àwùjọ àwọn ọlọ́ṣà yìí sábà máa ń jẹ́ àwọn èèyàn gbáàtúù tí wọ́n ń han àwọn tó nílé iṣẹ́ ńlá léèmọ̀ ní Ísírẹ́lì, tí wọ́n sì ń dá wàhálà sílẹ̀ fún ìjọba Róòmù.”

Nígbà tí ìjọba Róòmù ń ṣàkóso, irú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wo ni wọ́n lè torí rẹ̀ pààyàn bí wọ́n ṣe pa Jésù?

Ọ̀nà tí àwọn ará Róòmù máa ń gbà fìyà jẹ àwọn tó fẹ́ dojú ìjọba dé àtàwọn ọ̀daràn míì ni pé, wọ́n á kàn wọ́n mọ igi, wọ́n á sì fi wọ́n sílẹ̀ kí wọ́n kú. Ọ̀nà ìfìyà jẹni yìí ni wọ́n kà sí èyí tó burú jù lọ láti gbà pa èèyàn.

Ìwé kan tó sọ nípa àkókò Jésù, ìyẹn Palestine in the Time of Jesus, sọ nípa bí wọ́n ṣe ń kan èèyàn mọ́gi, ó ní, “Gbogbo èèyàn ló máa rí i, ó ń buni kù, ó sì kún fún ìrora, wọ́n máa ń kan èèyàn mọ́gi láti dẹ́rù ba ẹni tó bá fẹ́ ta ko òfin.” Ọ̀kan lára àwọn òǹkọ̀wé ní Róòmù láyé àtijọ́ sọ pé bí wọ́n ṣe ń pa àwọn arúfin, ó ní: “Ọ̀nà táwọn èèyàn máa ń pọ̀ sí jù lọ ni wọ́n ti máa ń ṣe é, kí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn lè rí i, kí ẹ̀rù lè bà wọ́n gidigidi.”

Gẹ́gẹ́ bí Òpìtàn Josephus ti sọ, àwọn ọmọ ogun Titus mú ọkùnrin kan nígbà tí wọ́n yí Jerúsálẹ́mù ká lọ́dún 70 Sànmánì Kristẹni, wọ́n sì pa á lọ́nà yìí níwájú odi ìlú kí wọ́n lè dẹ́rù bá àwọn ará ìlú náà tó fẹ́ ṣe àtakò. Nígbà tí wọ́n ṣẹ́gun ìlú náà níkẹyìn, ọ̀pọ̀ èèyàn ni wọ́n pa lọ́nà kan náà nípa kíkàn wọ́n mọ́gi.

Ìgbà tí iye èèyàn tí wọ́n pa lọ́nà yìí tíì pọ̀ jù lọ nínú ìtàn ayé ni ìgbà tí ìdìtẹ̀ tí ọ̀gbẹ́ni Spartacus ṣe aṣáájú rẹ̀ (láti ọdún 73 sí 71 ṣáájú Sànmánì Kristẹni) fẹ́ dópin, wọ́n pa ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] èèyàn, ìyẹn àwọn tó ń ja ìjà àjàkú akátá àtàwọn ẹrú lójú ọ̀nà Capua sí Róòmù.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

“Fún wa ní Bárábà,” látọwọ́ Charles Muller, ọdún 1878