Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

KÍ LÓ mú kí ọkùnrin kan tí kò nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn àmọ́ tó fẹ́ràn orin rọ́ọ̀kì kọ́ láti nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn kó sì ràn wọ́n lọ́wọ́? Kí ló mú kí ọkùnrin kan ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò jáwọ́ nínú ìṣekúṣe? Kí ló mú kí ọkùnrin kan tó jẹ́ òléwájú nínú ìdíje eré kẹ̀kẹ́ nílẹ̀ Japan jáwọ́ nínú fífi kẹ̀kẹ́ díje tórí pé ó fẹ́ sin Ọlọ́run? Gbọ́ ohun tí wọ́n sọ.

“Ewèlè ni mí, mo jọra mi lójú, mo sì jẹ́ oníjàgídíjàgan.”—DENNIS O’BEIRNE

ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1958

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: ENGLAND

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: MI Ò FẸ́RÀN ÀWỌN ÈÈYÀN ÀMỌ́ MO FẸ́RÀN ORIN RỌ́Ọ̀KÌ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Ọmọ orílẹ̀-èdè Ireland làwọn èèyàn bàbá mi, ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Kátólíìkì ti ilẹ̀ Ireland ni wọ́n sì fi tọ́ mi dàgbà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi fúnra mi ni mo máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì, àmọ́ kì í wù mí láti lọ. Síbẹ̀, mò ń fẹ́ láti mọ àwọn nǹkan nípa Ọlọ́run. Mo máa ń gba Àdúrà Olúwa déédéé, mo sì rántí bí mo ṣe máa ń sùn sórí ibùsùn mi lálẹ́ tí màá máa ro ohun tí àdúrà náà túmọ̀ sí. Mo máa ń pín àdúrà náà sí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, mo sì máa ń gbìyànjú láti mọ ohun tí apá kọ̀ọ̀kan túmọ̀ sí.

Mi ò tíì pé ọmọ ogún ọdún tí mo ti dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ẹgbẹ́ Rastafarian. Mo tún fẹ́ràn ẹgbẹ́ òṣèlú tó ń ta ko ìjọba Násì. Àmọ́ mo ki ara bọ ìwà ọ̀tẹ̀ tí àwọn tó fẹ́ràn orin rọ́ọ̀kì ń gbé lárugẹ. Mò ń lo oògùn olóró, ní pàtàkì igbó, mò sì máa ń mu ún lójoojúmọ́. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà “kò kàn mí,” mò ń mutí lámujù, mò ń fi ẹ̀mí mi wewu, mi ò sì bìkítà fún àwọn èèyàn. Mi ò nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, mi ò kì í bá ẹnì kankan sọ̀rọ̀ àyàfi tí mo bá rí i pé ó pọn dandan. Mi ò kìí jẹ́ káwọn èèyàn yà mí ní fọ́tò pàápàá. Tí mo bá wo àwọn nǹkan tí mo ti ṣe sẹ́yìn, mo rí i pé, ewèlè ni mí, mo jọra mi lójú, mo sì jẹ́ oníjàgídíjàgan. Àwọn tó sún mọ́ mi nìkan ni mo máa ń ṣe inúure sí tí mo sì máa ń fún ní nǹkan.

Nígbà tí mo ti fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọmọ ogún ọdún, mo fẹ́ láti mọ ohun tó wà nínú Bíbélì. Nígbà tí ọ̀rẹ́ mi kan tó ń ta oògùn olóró wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ló ti ń ka Bíbélì, àwa méjèèjì sì jọ sọ̀rọ̀ fún àkókò tó gùn nípa ẹ̀sìn, Ṣọ́ọ̀ṣì àti ipa tí Sátánì ń kó nínú ayé. Mo ra Bíbélì kan, mo sì ń kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀ fúnra mi. Èmi àti ọ̀rẹ́ mi yìí máa ń ka àwọn apá kan nínú Bíbélì, a ó sì wá jọ jíròrò ohun tá a ti kọ́, a ó sì wá mọ ohun tó jẹ́ òótọ́. À ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù.

Díẹ̀ lára àwọn òótọ́ tá a mọ̀ rèé lẹ́yìn tá a ti ka Bíbélì: pé à ń gbé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn; pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba Ọlọ́run; pé wọn kò gbọ́dọ̀ jẹ́ apá kan ayé yìí, títí kan òṣèlú rẹ̀ àti pé Bíbélì fún wa láwọn ìlànà tó gbéṣẹ́ nípa ìwà híhù. Ó wá yé wa kedere pé, òtítọ́ lọ́rọ̀ Bíbélì àti pé ìsìn tòótọ́ kan gbọ́dọ̀ wà. Àmọ́ ẹ̀sìn wo ni? A ronú nípa àwọn ṣọ́ọ̀ṣì tó lókìkí àtàwọn afẹfẹyẹ̀yẹ̀ tí wọ́n máa ń ṣe títí kan bí wọ́n ṣe ń lọ́wọ́ nínú òṣèlú, a sì wá rí i pé Jésù kò ṣe bẹ́ẹ̀. A mọ̀ pé, Ọlọ́run kò lo àwọn ṣọ́ọ̀ṣì olókìkí yẹn, nítorí náà, a pinnu láti lọ wo nǹkan táwọn ẹ̀sìn tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ gbajúmọ̀ ń ṣe.

A máa ń lọ bá àwọn ẹlẹ́sìn tí kò fí bẹ́ẹ̀ gbajúmọ̀ yìí, a sì máa ń bi wọ́n ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè. A mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbéèrè kọ̀ọ̀kan tí à ń bi wọ́n, nítorí náà, a fẹ́ mọ̀ bóyá ìdáhùn wọn máa bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mu. Lẹ́yìn tá a bá ti kúrò lọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn yìí, mo máa ń gbàdúrà sí Ọlọ́run pé, ‘Tó bá jẹ́ àwọn tá a kúrò lọ́dọ̀ wọn yìí ló ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́, jọ̀wọ́ jẹ́ kó wù mí láti tún pa dà lọ sọ́dọ̀ wọn.’ Àmọ́ lẹ́yìn àwọn oṣù mélòó kan tá a ti ń lọ sọ́dọ̀ àwọn ẹlẹ́sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, mi ò tíì rí ẹ̀sìn èyíkéyìí tó fi Bíbélì dáhùn ìbéèrè wa, kò sì sí èyíkéyìí lára wọn tó wù mí láti tún pa dà lọ sọ́dọ̀ wọn.

Níkẹyìn, èmi àti ọ̀rẹ́ mi pàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A bi wọ́n ní ìbéèrè kan náà tá a máa ń bi àwọn ẹlẹ́sìn, wọ́n sì fi Bíbélì dáhùn ìbéèrè wa. Ohun tí wọ́n sọ bá ohun tá a ti kọ́ nínú Bíbélì mu. Nítorí náà, a bi wọ́n ní àwọn ìbéèrè tí a kò tíì rí ìdáhùn wọn nínú Bíbélì, bí àpẹẹrẹ, èrò Ọlọ́run nípa oògùn olóró, sìgá àti igbó mímú. Wọ́n tún fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáhùn ìyẹn náà. Nítorí náà, a gbà láti lọ sí ìpàdé tí wọ́n máa ń ṣe nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba.

Kò rọrùn fún mi rárá láti lọ sí ìpàdé. Mi ò nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn nítorí náà, kò bá mi lára mu rárá nígbà táwọn èèyàn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ tí wọ́n sì múra dáadáa yìí wá kí mi. Mo tiẹ̀ rò ó lọ́kàn mi pé àwọn kan lára àwọn tó ń kí mi kò ní èrò tó dáa nípa mi, mi ò sì fẹ́ lọ sí ìpàdé náà mọ́. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ìṣe mi, mo gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kó wù mí láti pa dà lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn yìí tó bá jẹ́ pé àwọn ló ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́, ó sì wá wù mí gan-an láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Mo mọ̀ pé ó yẹ kí n jáwọ́ nínú lílo oògùn olóró, ó sì ṣeé ṣe fún mi láti jáwọ́ pẹ̀lú ìrọ̀rùn. Sìgá ló ṣòro jù fún mi láti fi sílẹ̀. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni mo gbìyànjú láti jáwọ́, àmọ́ kò ṣeé ṣe. Nígbà tí mo gbọ́ pé kò nira fún àwọn kan láti fi sìgá sílẹ̀, pé wọ́n kàn sọ ọ́ nù ni, tí wọn kò sì mu ún mọ́, mo bá Jèhófà sọ̀rọ̀ nípa ọ̀ràn náà. Nígbà tó yá, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà mo fi sìgá mímu sílẹ̀. Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé, ó yẹ kí èèyàn máa sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára ẹni fún Jèhófà nínú àdúrà kí èèyàn má sì fi nǹkan kan pa mọ́.

Àyípadà ńlá míì tí mo ṣe nígbèésí ayé ni ti aṣọ àti ìmúra mi. Nígbà tí mo kọ́kọ́ lọ sí ìpàdé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, mo ṣe irun mi, ó dúró ṣánṣán mo sì fi oríṣiríṣi àwọ̀ pa á láró. Nígbà tó yá, mo pa á láró sí àwọ̀ olómi ọsàn. Mo wọ ṣòkòtò jín-ǹ-sì àti jákẹ́ẹ̀tì tí wọ́n fi awọ ṣe, oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ amóríwú ló sì wà lára jákẹ́ẹ̀tì náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fèrò wérò pẹ̀lú mi tìfẹ́tìfẹ́ nípa ọ̀ràn yìí, síbẹ̀ mo gbà pé kò sídìí kankan fún mi láti ṣe àyípadà. Àmọ́ níkẹyìn, mo ronú lórí ohun tó wà nínú ìwé 1 Jòhánù 2:15-17 tó sọ pé: “Ẹ má ṣe máa nífẹ̀ẹ́ yálà ayé tàbí àwọn ohun tí ń bẹ nínú ayé. Bí ẹnikẹ́ni bá nífẹ̀ẹ́ ayé, ìfẹ́ fún Baba kò sí nínú rẹ̀.” Mo wá rí i pé lóòótọ́ ni ìrísí mi ń fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ ayé yìí, tí mo bá sì fẹ́ fi hàn pé mo nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, mo ní láti ṣe àtúnṣe. Ohun tí mo sì ṣe nìyẹn.

Nígbà tó yá, mo wá rí i pé kì í ṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló kàn ń fẹ́ kí n máa wá sí àwọn ìpàdé Kristẹni. Ìwé Hébérù 10:24, 25 jẹ́ kó yé mi pé, ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí n ṣe nìyẹn. Nígbà tí mo ti ń lọ sí gbogbo ìpàdé, tí mo ti wá mọ àwọn èèyàn náà dáadáa, mo pinnu láti ya ara mi sí mímọ́ fún Jèhófà, mo sì ṣe ìrìbọmi.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Inú mi máa ń dùn gan-an fún bí Jèhófà ṣe fún wa láǹfààní láti ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú òun. Àánú àti ìyọ́nú rẹ̀ mú kó wù mí láti fara wé e, kí n sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí àwòfiṣàpẹẹrẹ nígbèésí ayé mi. (1 Pétérù 2:21) Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ pé, bí mo ṣe ń sapá láti ní àwọn ìwà tó yẹ Kristẹni, mo ṣì lè ní ohun táwọn èèyàn á fi máa dámi mọ̀. Mo ti sapá gan-an láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, kí n sì bìkítà nípa wọn. Mò ń sapá láti máa hùwà bíi ti Kristi nínú ọ̀nà tí mo gbà ń hùwà sí ìyàwó mi àti ọmọkùnrin wa. Mo sì ń bìkítà fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Títẹ̀ lé Kristi ti jẹ́ kí n di ẹni iyì, tó ní ọ̀wọ̀ ara ẹni, ó sì ti ṣeé ṣe fún mi láti máa fi ìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn.

“Wọ́n bọ̀wọ̀ fún mí.”—GUADALUPE VILLARREAL

ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1964

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: MẸ́SÍKÒ

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ONÍṢEKÚṢE

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Àwa méje làwọn òbí mi bí, ìlú Hermosillo tó jẹ́ olú ìlú ìpínlẹ̀ Sonora, ní orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò ni wọ́n ti tọ́ wa dàgbà, tálákà paraku ni àwọn tó ń gbé lágbègbè náà. Bàbá mi kú nígbà tí mo ṣì kéré, nítorí náà, màmá mi ní láti wá iṣẹ́ kan ṣe kó lè máa gbọ́ bùkátà wa. Ẹsẹ̀ lásán ni mo máa ń fi rìn, nítorí pé a ò lówó láti ra bàtà. Nígbà tí mo ṣì kéré ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ kí n lè ṣèrànwọ́ fún ìdílé wa. Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn ìdílé, ojú kan ni gbogbo wa jọ ń gbé.

Lọ́pọ̀ ìgbà lóòjọ́, màmá mi kì í sí nítòsí láti dáàbò bò wá. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́fà, mo kó sọ́wọ́ ọmọkùnrin ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kan tó ń bá mi lọ̀pọ̀. Ìṣekúṣe yìí ń bá a nìṣó fún ìgbà pípẹ́. Àbájáde èyí ni pé, ọ̀ràn ìbálòpọ̀ tojú sú mi, mi ò sì mọ ohun tó yẹ kí n ṣe. Èrò mi ni pé, kò burú kí ọkàn ọkùnrin máa fà sí ọkùnrin bíi tiẹ̀ fún ìbálòpọ̀. Nígbà tí mo fọ̀ràn náà lọ àwọn dókítà àti àwọn àlùfáà pé kí wọ́n ràn mí lọ́wọ́, wọ́n fi dá mi lójú pé mi ò ní ìṣòro, pé kò sí ohun tó burú níbẹ̀.

Nígbà tí mo wà ní ọmọ ọdún mẹ́rìnlá, mo pinnu láti fi ara mi han gbogbo èèyàn pé ọkùnrin tó ń bá ọkùnrin lòpọ̀ ni mí. Mò ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ fún ọdún mọ́kànlá, mo sì gbé pẹ̀lú onírúurú ọkùnrin láwọn àkókò yẹn. Nígbà tó yá, mo lọ kọ́ iṣẹ́ aṣerunlóge, mo sì ṣí ṣọ́ọ̀bù ìṣerunlóge. Síbẹ̀ náà, mi ò láyọ̀. Ìyà ń jẹ mí, mo sì ń rí ìjákulẹ̀. Ọkàn mi ń sọ fún pé ohun tí mò ń ṣe kò dára. Mo wá ń bi ara mi pé, ‘Ǹjẹ́ àwọn èèyàn rere àtàwọn èèyàn iyì kankan wà báyìí?’

Mo ronú nípa ẹ̀gbọ́n mi obìnrin. Ó ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, níkẹyìn, ó sì ṣèrìbọmi. Ó máa ń sọ ohun tó kọ́ fún mi, àmọ́ mi ò kì í fetí sí i. Síbẹ̀, mo fẹ́ràn ìgbésí ayé tó ń gbé àti bí àárín òun àti ọkọ rẹ̀ ṣe rí. Mo rí i pé òun àti ọkọ rẹ̀ fẹ́ràn ara wọn lóòótọ́, wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fún ara wọn. Wọ́n ń hùwà tó dáa sí ara wọn. Nígbà tó yá, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lákọ̀ọ́kọ́, mò kàn máa ń fetí sílẹ̀ ni, àmọ́ mi ò fi taratara ṣe é. Nígbà tó yá, nǹkan yí pa dà.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní kí n wá sí ọ̀kan lára ìpàdé wọn, mo sì lọ. Nǹkan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ni mo rí níbẹ̀. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun táwọn èèyàn máa ń ṣe sí mi nìyẹn. Wọ́n kí mi tọ̀wọ̀tọ̀wọ̀, wọ́n sì bọ̀wọ̀ fún mi. Orí mi wú gan-an.

Èrò tí mo ní nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà túbọ̀ dára sí i nígbà tí mo lọ sí àpéjọ tí wọ́n ṣe. Mo kíyè sí pé nígbà tí wọ́n tiẹ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ pàápàá, ńṣe làwọn èèyàn yìí dà bí ọmọ ìyá mi, ìfẹ́ àtọkànwá ni wọ́n ní. Mo wá bi ara mi pé, àbí àwùjọ àwọn èèyàn yìí ni àwọn èèyàn rere àtàwọn èèyàn iyì tí mo ti ń wá tipẹ́? Ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tó wà láàárín wọn àti bí wọ́n ṣe máa ń fi Bíbélì dáhùn gbogbo ìbéèrè jọ mí lójú púpọ̀. Mo wá rí i pé, Bíbélì ló mú kí ìgbésí ayé wọn dára. Ó sì tún yé mi pé, tí mo bá fẹ́ di ara wọn, mo ní láti ṣe ọ̀pọ̀ ìyípadà nígbèésí ayé mi.

Kódà, mo ní láti ṣe àtúnṣe pátápátá sí ọ̀nà ìgbésí ayé mi, nítorí pé bí obìnrin ni mo ṣe máa ń ṣe. Mo ní láti ṣàtúnṣe sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi, àwọn àṣà àti ìṣe tó ti mọ́ mi lára, aṣọ tí mò ń wọ̀, irun mi àti àwọn ọ̀rẹ́ tí mò ń bá rìn. Àwọn ọ̀rẹ́ mi tẹ́lẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í fi mí ṣe yẹ̀yẹ́, pé: “Kí ni gbogbo èyí tó o kó ara rẹ sí yìí? Ó ti dáa bó o ṣe wà tẹ́lẹ̀. Má kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́. Kí lo tún ń wá?” Àmọ́, ohun tó ṣòro fún mi jù lọ láti fi sílẹ̀ ni ìṣekúṣe tó ti mọ́ mi lára.

Síbẹ̀, mo mọ̀ pé ó ṣeé ṣe láti ṣàtúnṣe tó kàmàmà nígbèésí ayé ẹni nítorí ohun tí Bíbélì sọ nínú ìwé 1 Kọ́ríńtì 6:9-11 ti wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ó ní: “Kínla! Ẹ kò ha mọ̀ pé àwọn aláìṣòdodo kì yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a má ṣì yín lọ́nà. Kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí a pa mọ́ fún àwọn ète tí ó lòdì sí ti ẹ̀dá, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀ . . . ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. Síbẹ̀, ohun tí àwọn kan lára yín ti jẹ́ rí nìyẹn. Ṣùgbọ́n a ti wẹ̀ yín mọ́.” Jèhófà ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láyé ìgbà yẹn láti ṣe àtúnṣe, ó sì ran èmi náà lọ́wọ́. Ó gba ọdún mélòó kan àti ọ̀pọ̀ ìsapá kí n tó ṣe àtúnṣe, àmọ́ ìtọ́sọ́nà látọ̀dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti ìfẹ́ tí wọ́n fi hàn sí mi ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Lónìí, ìgbésí ayé tó yẹ ọmọlúwàbí ni mò ń gbé. Mo ti gbéyàwó, èmi àti ìyàwó mi sì ń kọ́ ọmọkùnrin wa láti máa gbé ìgbésí ayé tó bá àwọn ìlànà Bíbélì mu. Mo ti jáwọ́ pátápátá nínú ìwà tí mò ń hù tẹ́lẹ̀, mo sì ń gbádùn àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run àtàwọn àǹfààní iṣẹ́ ìsìn. Mò ń sìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú ìjọ, ó sì ti ṣeé ṣe fún mi láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn àyípadà tí mo ṣe nígbèésí ayé mi mú inú màmá mi dùn débi tó fi gbà láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì ti di Kristẹni tó ti ṣèrìbọmi. Àbúrò mi obìnrin tí òun náà ń gbé ìgbésí ayé oníṣekúṣe tẹ́lẹ̀ ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Àwọn tó mọ̀ mí tẹ́lẹ̀ pàápàá gbà pé ní báyìí, ìgbésí ayé mi ti yí pa dà sí rere. Mo sì mọ ohun tó mú kí àwọn àyípadà náà ṣeé ṣe. Ní àkókò kan sẹ́yìn, mo wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ àwọn agbani-nímọ̀ràn, àmọ́ ìmọ̀ràn burúkú ni wọ́n fún mi. Ṣùgbọ́n, Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ lóòótọ́. Bí mo tilẹ̀ ń rò pé mi ò yẹ lẹ́ni tó lè rojú rere rẹ̀, ó kíyè sí mi, ó sì fi ìfẹ́ àti sùúrù bójú tó mi. Mímọ̀ tí mo mọ̀ pé Ọlọ́run àgbàyanu, tó jẹ́ onílàákàyè, tó sì nífẹ̀ẹ́ ti kíyè sí mi, tó sì fẹ́ kí n gbé ìgbésí ayé tó dáa ló mú kí gbogbo àtúnṣe náà ṣeé ṣe.

“Mi ò ní ìtẹ́lọ́rùn, mo dá nìkan wà, inú mi kò sì dùn.”—KAZUHIRO KUNIMOCHI

ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1951

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: JAPAN

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: AFIKẸ̀KẸ́ DÍJE TÓ MÁA Ń FẸ́ IPÒ IWÁJÚ

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Èbúté ìlú Shizuoka lórílẹ̀-èdè Japan, ni wọ́n bí mi sí, àgbègbè yìí máa ń dákẹ́ rọ́rọ́, inú ilé kékeré kan sì ni ìdílé wa tá a jẹ́ ẹni mẹ́jọ ń gbé. Bàbá mi ní ṣọ́ọ̀bù kan níbi tó ti ń ta kẹ̀kẹ́ tó sì ń tún kẹ̀kẹ́ ṣe. Látìgbà tí mo ti wà ní kékeré, ni bàbá mi tí máa ń mú mi lọ síbi tí wọ́n ti ń fi kẹ̀kẹ́ díje, bàbá mi sì mú kí n nífẹ̀ẹ́ eré yìí. Bàbá mi wá ń ṣètò bí mo ṣe máa di ògbóǹkangí nínú àwọn tó ń fi kẹ̀kẹ́ díje. Kò pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ ilé ẹ̀kọ́ girama ni bàbá mi bẹ̀rẹ̀ sí í dámi lẹ́kọ̀ọ́ kẹ̀kẹ́ gígùn kíkankíkan. Nígbà tí mo wà ní apá kejì ilé ẹ̀kọ́ girama mo jáwé olúborí léraléra fún ọdún mẹ́ta nínú ìdíje eré kẹ̀kẹ́ ọdọọdún ti orílẹ̀-èdè wa. Wọ́n ní kí n wá kàwé ní yunifásítì, àmọ́ mi ò lọ, kàkà bẹ́ẹ̀ mo pinnu láti lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí wọ́n ti ń kọ́ fífi kẹ̀kẹ́ díje. Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mọ́kàndínlógún [19], mo ti di ògbóǹkangí afikẹ̀kẹ́ díje.

Lákòókò yẹn, ohun tó wà lórí ẹ̀mí mi ni pé, mo fẹ́ di òléwájú nínú ìdíje eré kẹ̀kẹ́ lórílẹ̀-èdè Japan. Nítorí náà, mo pinnu láti wá owó rẹpẹtẹ kí n bàa lè pèsè ààbò fún ìdílé mi, kí a sì máa gbé ìgbé ayé ìrọ̀rùn. Mo tẹra mọ́ ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Tí mo bá ní ìrẹ̀wẹ̀sì nítorí ìnira ìdálẹ́kọ̀ọ́ tàbí nítorí apá kan tí kò rọrùn nínú ìdíje eré kẹ̀kẹ́, màá sọ fún ara mi pé, wọ́n ti sọ pé iṣẹ́ yìí ni mo máa ṣe láyé mi, nítorí náà ohun tó bá gbà ni màá fún un! Mo sì ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í jèrè iṣẹ́ àṣekára mi. Lọ́dún àkọ́kọ́, èmi ni mó gba ipò kìíní nínú ìdíje kan tí wọ́n ṣe fún àwọn ẹni tuntun tó ń fi kẹ̀kẹ́ díje. Lọ́dún kejì, mó kúnjú ìwọ̀n láti kópa nínú ìdíje tí wọ́n fẹ́ fi mọ òléwájú nínú àwọn àfikẹ̀kẹ́ díje nílẹ̀ Japan. Ìgbà mẹ́fà ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sì ni mo gba ipò kejì nínú ìdíje yẹn.

Nítorí pé mo wà lára àwọn òléwájú tó máa ń gba ẹ̀bùn nígbà ìdíje eré kẹ̀kẹ́, àwọn èèyàn wá mọ̀ mí sí ẹlẹ́sẹ̀ agbára ilẹ̀ Tokai, ìyẹn àgbègbè kan lórílẹ̀-èdè Japan. Gbogbo ìgbà ni mo máa ń fẹ́ ipò iwájú. Nígbà tó yá, àwọn èèyàn bẹ̀rẹ̀ sí í bẹ̀rù mi, nítorí pé mi ò láàánú èèyàn tí ìdíje bá ti bẹ̀rẹ̀. Owó tó ń wọlé fún mi pọ̀, mo sì rí i pé mo lè ra ohunkóhun tó bá ti wù mí. Mo ra ilé kan tó ní yàrá eré ìdárayá àtàwọn ẹ̀rọ eré ìdárayá tó dára jù lọ. Mo ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ ilẹ̀ òkèèrè, owó rẹ̀ sì fẹ́ẹ̀ẹ́ tó iye owó ilé kan. Nítorí kí ọkàn mi lè balẹ̀ lọ́jọ́ ọ̀la, mo bẹ̀rẹ̀ sí í kó owó sórí dúkìá ilé àti ilẹ̀ àti sórí ìdókòwò.

Síbẹ̀, mi ò ní ìtẹ́lọ́rùn, mo dá nìkan wà, inú mi kò sì dùn. Mo ti gbéyàwó, mo sì ti bímọ nígbà yẹn, àmọ́, mi ò kì í ní sùúrù pẹ̀lú ìdílé mi. Mo máa ń bínú sódì sí ìyàwó àtàwọn ọmọ mi nítorí àwọn ohun tí kò tó nǹkan. Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi ìbẹ̀rù ṣàkíyèsí ojú mi láti mọ bóyá mo tún ti ń bínú.

Àmọ́ nígbà tó yá, ìyàwó mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìyẹn sì mú ọ̀pọ̀ àyípadà wá. Ó sọ fún mi pé òun fẹ́ lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, nítorí náà, mo pinnu pé gbogbo ìdílé wa ló máa lọ. Mo ṣì lè rántí alẹ́ ọjọ́ kan tí alàgbà kan wá sí ilé wa, tó sì bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ohun tí mo kọ́ wọ̀ mí lọ́kàn ṣinṣin.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Mi ò lè gbàgbé bí ìwé Éfésù 5:5 ṣe wọ̀ mí lọ́kàn nígbà tí mo kà á. Ó ní: “Kò sí àgbèrè kankan tàbí aláìmọ́ tàbí oníwọra—èyí tí ó túmọ̀ sí jíjẹ́ abọ̀rìṣà—tí ó ní ogún èyíkéyìí nínú ìjọba Kristi àti ti Ọlọ́run.” Mo rí i pé, ìdíje eré kẹ̀kẹ́ jẹ mọ́ tẹ́tẹ́ títa, eré yìí sì ń mú kéèyàn ní ìwọra. Ẹ̀rí-ọkàn wá bẹ̀rẹ̀ sí í dà mí láàmú. Mo gbà pé, tí mo bá fẹ́ rí ojú rere Jèhófà Ọlọ́run, mo ní láti fi ìdíje eré kẹ̀kẹ́ sílẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe ìpinnu tó rọrùn fún mi láti ṣe.

Mo ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ìdíje ọdún yẹn ni, ọdún yẹn ni ohun tí mo ṣe wú mi lórí jù lọ, mo sì ń fẹ́ púpọ̀ sí i. Àmọ́, mo rí i pé ẹ̀kọ́ Bíbélì tí mò ń kọ́ jẹ́ kí n ní àlàáfíà, kí n ní ìbàlẹ̀ ọkàn, ìyẹn sì yàtọ̀ pátápátá sí ẹ̀mí tó ń mú kí n borí nínú ìdíje eré kẹ̀kẹ́! Ìgbà mẹ́ta péré ni mo kópa nínú ìdíje eré kẹ̀kẹ́ lẹ́yìn ìgbà tí mo bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ nínú ọkàn mi lọ́hùn-ún, kò tíì wù mí láti jáwọ́ nínú ìdíje eré kẹ̀kẹ́. Ìrònú kọ́kọ́ bá mi nípa bí màá ṣe gbọ́ bùkátà ìdílé mi. Mi ò kọ́kọ́ mọ ohun tí ǹ bá ṣe, nítorí iwájú ò ṣeé lọ, ẹ̀yìn ò ṣeé pa dà sí, àwọn ẹbí mi tún bẹ̀rẹ̀ sí í dàmí láàmù gan-an nítorí ìgbàgbọ́ tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ gbà. Ọ̀rọ̀ náà ba bàbá mi nínú jẹ́ gan-an. Nǹkan dojú rú fún mi, ìdààmú mi wá pọ̀ sí i, àìsàn ọgbẹ́ inú sì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe mi.

Ohun tó ràn mí lọ́wọ́ láti la àkókò líle koko yẹn já ni pé, mò ń bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mi nìṣó, mò sì ń lọ sí ìpàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bí àkókò ṣe ń lọ, ìgbàgbọ́ mi lágbára sí i. Mo bẹ Jèhófà pé kó gbọ́ àdúrà mi, kó sì jẹ́ kí n mọ̀ pé òun ń gbọ́ àdúrà mi. Nígbà tí ìyàwó mi fi dá mi lójú pé, kò dìgbà tí òun bá gbé inú ilé ńlá kí òun tó lè láyọ̀, ará túbọ̀ tù mí. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, mo tẹ̀ síwájú.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ Jésù tó wà nínú ìwé Mátíù 6:33. Ó ní: “Ẹ máa bá a nìṣó, nígbà náà, ní wíwá ìjọba náà àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.” Kò sí ìgbà tí a kò ní “nǹkan mìíràn” tí Jésù sọ, ìyẹn àwọn ohun kòṣeémáàní tá a nílò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé owó tó ń wọlé fún mi kéré gan-an, ìyẹn ìdá kan péré nínú ìdá ọgbọ̀n iye tí mò ń rí nínú ìdíje eré kẹ̀kẹ́, síbẹ̀ kò sí ohun tí èmi àti ìdílé mi ṣaláìní láti ogún ọdún sẹ́yìn.

Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn tí mi ò ní tẹ́lẹ̀ ni mo máa ń ní nígbà tí mo bá ń ṣiṣẹ́ tàbí tí mò ń jọ́sìn pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá lọ. Ìgbésí ayé ìdílé mi pẹ̀lú tí dára sí i. Àwọn ọmọkùnrin mi mẹ́tẹ̀ẹ̀ta àtàwọn ìyàwó wọn ti di olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà.