Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ibi tí Wọ́n Ti Ń Fi Iná Dáni Lóró Ni Gẹ̀hẹ́nà?

Ṣé Ibi tí Wọ́n Ti Ń Fi Iná Dáni Lóró Ni Gẹ̀hẹ́nà?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Ṣé Ibi tí Wọ́n Ti Ń Fi Iná Dáni Lóró Ni Gẹ̀hẹ́nà?

▪ Nínú ìwé Ìhìn Rere, Jésù kìlọ̀ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n kíyè sára kí wọ́n má bàa gba ìdájọ́ Gẹ̀hẹ́nà. Kò sí àní-àní pé Jésù fẹ́ kí wọ́n fọwọ́ pàtàkì mú ìkìlọ̀ yìí. Àmọ́, ṣé ìdálóró títí láé nínú iná ọ̀run àpáàdì ni Jésù ní lọ́kàn?—Mátíù 5:22.

Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ wo ọ̀rọ̀ náà fúnra rẹ̀. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, Geʹen·na ní ìtumọ̀ kan náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Hébérù náà, geh Hin·nomʹ, tó túmọ̀ sí “àfonífojì Hínómù,” tàbí àpèjá rẹ̀ tó ń jẹ́ geh veneh-Hin·nomʹ, ìyẹn “àfonífojì àwọn ọmọ Hínómù.” (Jóṣúà 15:8; 2 Àwọn Ọba 23:10) Ibí yìí la mọ̀ sí Wadi er-Rababi lóde òní, àfonífojì tó jìn gan-an ni, kò sì fẹ̀, ó wà ní àárín gúúsù àti gúúsù ìwọ̀ oòrùn ìlú Jerúsálẹ́mù.

Nígbà ayé àwọn ọba Júdà, láti ọgọ́rùn-ún ọdún kẹjọ ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n ti ń lo ibí yìí fún ààtò ìbọ̀rìṣà, títí kan fífi ọmọ rúbọ nínú iná. (2 Kíróníkà 28:1-3; 33:1-6) Wòlíì Jeremáyà sọ tẹ́lẹ̀ pé, àfonífojì kan náà yìí ni àwọn ará Bábílónì ti máa pa àwọn ará Júdà, ìyẹn sì jẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run nítorí ìwà ibi wọn. *Jeremáyà 7:30-33; 19:6, 7.

Gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé Júù tó ń jẹ́ David Kimhi ti sọ (nǹkan bí ọdún 1160 sí nǹkan bí ọdún 1235 Sànmánì Kristẹni), nígbà tó yá, wọ́n sọ àfonífojì yìí di ibi táwọn olùgbé Jerúsálẹ́mù ń da ilẹ̀ sí. Ibẹ̀ sì wá di ibi tí iná ti ń jó ní gbogbo ìgbà láti sun ìdọ̀tí. Ohunkóhun tí wọ́n bá jù sí ibí yìí ló máa jóná pátápátá di eérú.

Ọ̀pọ̀ àwọn tó túmọ̀ Bíbélì ló ṣe ohun tó wù wọ́n tí wọ́n sì túmọ̀ Geʹen·na sí “iná ọrun apadi.” (Mátíù 5:22, Bibeli Mimọ) Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe bẹ́ẹ̀? Ìgbàgbọ́ àwọn abọ̀rìṣà ni pé iná máa jó àwọn èèyàn burúkú lẹ́yìn tí wọ́n bá ti kú, ìdí nìyẹn táwọn atúmọ̀ Bíbélì yẹn fi sọ pé iná tó máa jó àwọn èèyàn burúkú yẹn ni iná tó ń jó nínú àfonífojì tó wà lóde ìlú Jerúsálẹ́mù. Àmọ́, Jésù kò ní i lọ́kàn pé Gẹ̀hẹ́nà jẹ́ ibi ìdálóró.

Jésù mọ̀ pé, nǹkan burúkú pátápátá ló jẹ́ lójú Jèhófà Bàbá rẹ̀ ọ̀run pé wọ́n ń sun àwọn èèyàn láàyè. Nígbà tí Ọlọ́run ń sọ̀rọ̀ nípa ohun táwọn èèyàn ń lo Gẹ̀hẹ́nà fún ní ìgbà ayé wòlíì Jeremáyà, ó ní: “Wọ́n . . . ti kọ́ àwọn ibi gíga Tófétì, èyí tí ó wà ní àfonífojì ọmọ Hínómù, láti sun àwọn ọmọkùnrin wọn àti àwọn ọmọbìnrin wọn nínú iná, ohun tí èmi kò pa láṣẹ tí kò sì wá sínú ọkàn-àyà mi.” (Jeremáyà 7:31) Síwájú sí i, èrò pé à ń dá òkú lóró ta ko ìwà onífẹ̀ẹ́ tí Ọlọ́run ní àti ẹ̀kọ́ Bíbélì tó ṣe kedere pé àwọn òkú “kò mọ nǹkan kan rárá.”—Oníwàásù 9:5, 10.

Jésù lo ọ̀rọ̀ náà, “Gẹ̀hẹ́nà” láti ṣàpẹẹrẹ ìparun yán-ányán-án tó máa jẹ́ àbájáde ìdájọ́ mímúná látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nítorí náà, ọ̀rọ̀ náà, “Gẹ̀hẹ́nà” ní ìtumọ̀ tó jọ “adágún iná” tí ìwé Ìṣípayá sọ. Àwọn méjèèjì ló ṣàpẹẹrẹ ìparun títí láé, nínú èyí tí èèyàn kò ti ní ní àjíǹde.—Lúùkù 12:4, 5; Ìṣípayá 20:14, 15.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Nígbà tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà New Catholic Encyclopedia ń sọ̀rọ̀ nípa àsọtẹ́lẹ̀ yìí, ó ní: “Nígbà ìparun Jerúsálẹ́mù, ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé ìlú yìí ló máa kú, inú àfonífojì yìí ni wọ́n máa da òkú wọn sí, wọn kò ní sin wọ́n, ibẹ̀ ni wọ́n máa jẹrà sí tàbí kí iná sun wọ́n.”