Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bá A Ṣe Lè Fi Ọwọ́ Pàtàkì Mú Iṣẹ́ Ìsìn Wa sí Jèhófà

Bá A Ṣe Lè Fi Ọwọ́ Pàtàkì Mú Iṣẹ́ Ìsìn Wa sí Jèhófà

Bá A Ṣe Lè Fi Ọwọ́ Pàtàkì Mú Iṣẹ́ Ìsìn Wa sí Jèhófà

“Ohun yòówù tí ó jẹ́ ti ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì, . . . ẹ máa bá a lọ ní gbígba nǹkan wọ̀nyí rò.”—FÍLÍ. 4:8.

1, 2. Kí ló fà á tí ọ̀pọ̀ èèyàn kò fi fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbé ayé wọn, àwọn ìbéèrè wo ló sì yẹ ká bi ara wa?

 ÀKÓKÒ tá à ń gbé yìí jẹ́ àkókò tí ìṣòro àti làásìgbò tí a kò tíì rí irú rẹ̀ rí ń fojú aráyé rí màbo. Agbára káká sì ni àwọn tí kò ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà fi lè kojú “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” yìí. (2 Tím. 3:1-5) Wọ́n máa ń sa gbogbo ipá wọn lójoojúmọ́ bóyá wọ́n á jẹ́ rí ọ̀nà àbáyọ, àmọ́ òtúbáńtẹ́ ni gbogbo rẹ̀ máa ń já sí. Kí ìbànújẹ́ má bàa dorí wọn kodò torí bí ipò nǹkan ṣe ń lọ, ńṣe ni ọ̀pọ̀ lára wọn ń lọ́wọ́ nínú onírúurú eré ìnàjú tí wọ́n lè fi pa ìrònú rẹ́.

2 Àwọn èèyàn sábà máa ń fi gbígbádùn ara wọn sí ipò àkọ́kọ́ torí kí wọ́n lè kojú másùnmáwo inú ayé. Bí àwọn Kristẹni kò bá ṣọ́ra, àwọn pẹ̀lú lè bẹ̀rẹ̀ sí í gbé irú ìgbé ayé bẹ́ẹ̀. Báwo la ò ṣe ní fàyè gba irú ìgbésí ayé bẹ́ẹ̀? Ṣó máa gba pé ká máa fi ìgbádùn du ara wa ní gbogbo ìgbà? Báwo la ò ṣe ní jẹ́ kí adùn gba ojúṣe wa mọ́ wa lọ́wọ́? Àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ wo ló yẹ kó máa ṣamọ̀nà wa débi pé bí a bá tilẹ̀ fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn wa sí Ọlọ́run, a kò ní le koko mọ́ ara wa jù?

Bá A Ṣe Lè Gbájú Mọ́ Ohun Tó Ṣe Pàtàkì Jù Nínú Ayé Tó Nífẹ̀ẹ́ Fàájì

3, 4. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe mú ká rí ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìsìn wa?

3 Òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro ni pé ayé yìí ka ‘ìfẹ́ adùn’ sí ohun tó ṣe pàtàkì, èyí tí kò sì yẹ kó rí bẹ́ẹ̀. (2 Tím. 3:4) Bí a bá ń fi ojú tí ayé fi ń wo adùn wò ó, ó lè ṣàkóbá fún àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. (Òwe 21:17) Torí náà, nínú lẹ́tà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ sí Tímótì àti Títù, ó rí i pé ó yẹ kí òun fún wọn ní ìmọ̀ràn pé kí wọ́n fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìsìn wọn. Bí a bá fi àwọn ìlànà inú ìmọ̀ràn yẹn sílò, kò ní jẹ́ ká dà bí àwọn èèyàn ayé tí wọn kò fi ọwọ́ pàtàkì mú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbé ayé wọn.—Ka 1 Tímótì 2:1, 2; Títù 2:2-8.

4 Ohun tí Sólómọ́nì sọ ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn jẹ́ ká mọyì àǹfààní tó wà nínú fífi adùn du ara ẹni nígbà míì kéèyàn lè pọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó ṣe pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé. (Oníw. 3:4; 7:2-4) Níwọ̀n bí ìwàláàyè ẹ̀dá ti kúrú, a gbọ́dọ̀ “tiraka tokuntokun” ká bàa lè rí ìgbàlà. (Lúùkù 13:24) Torí náà, a gbọ́dọ̀ máa bá a nìṣó láti gba gbogbo nǹkan tí ó jẹ́ ti “ìdàníyàn ṣíṣe pàtàkì” rò. (Fílí. 4:8, 9) Ìyẹn túmọ̀ sí pé a gbọ́dọ̀ máa gbé gbogbo apá ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni yẹ̀ wò tìṣọ́ratìṣọ́ra.

5. Apá wo ló yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú nínú ìgbésí ayé wa?

5 Bí àpẹẹrẹ, àwọn Kristẹni máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jèhófà àti Jésù nípa fífi ọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe wọn láti jẹ́ òṣìṣẹ́ kára. (Jòh. 5:17) Nítorí èyí, àwọn èèyàn sábà máa ń yìn wọ́n torí pé wọ́n kì í ṣe ọ̀lẹ nídìí iṣẹ́, wọ́n sì ṣeé fọkàn tán. Àwọn tó jẹ́ olórí ìdílé lára wọn tiẹ̀ máa ń wá bí wọ́n á ṣe ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè gbọ́ bùkátà ìdílé wọn. Ó ṣe tán bí ẹnì kan kò bá pèsè fún ìdílé rẹ̀ ṣe ni ká kúkú sọ pé ó ti “sẹ́ Jèhófà”!—1 Tím. 5:8, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW.

Bá A Ṣe Lè Fi Ọwọ́ Pàtàkì Mú Ìjọsìn Wa Tá A Ó sì Máa Láyọ̀

6. Báwo la ṣe mọ̀ pé a gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn wa sí Jèhófà?

6 Jèhófà kò fọwọ́ yọ̀bọ́kẹ́ mú ìjọsìn tòótọ́ rí. Bí àpẹẹrẹ, lábẹ́ Òfin Mósè, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jìyà àbájáde búburú nígbà tí wọ́n yà bàrà kúrò nínú ìjọsìn Jèhófà. (Jóṣ. 23:12, 13) Ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Kristẹni, ó pọn dandan pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi jà fitafita kí ẹ̀kọ́ tí ń ṣini lọ́nà àti ìwà békebèke má bàa wọnú ìjọsìn tòótọ́. (2 Jòh. 7-11; Ìṣí. 2:14-16) Lónìí, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń bá a nìṣó láti máa fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn wọn.—1 Tím. 6:20.

7. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe ń múra sílẹ̀ kó tó lọ wàásù fáwọn ẹlòmíì?

7 Iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe máa ń fúnni láyọ̀. Àmọ́, kí ayọ̀ wa má bàa pẹ̀dín lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù náà, a gbọ́dọ̀ máa ronú jinlẹ̀ lórí ọ̀nà tá a gbà ń ṣe é, ká sì máa múra sílẹ̀ kó tó di pé a lọ sóde ẹ̀rí. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé bó ṣe máa ń gba tàwọn èèyàn tó kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ rò. Ó kọ̀wé pé: “Mo ti di ohun gbogbo fún ènìyàn gbogbo, kí n lè rí i dájú pé mo gba àwọn kan là. Ṣùgbọ́n mo ń ṣe ohun gbogbo nítorí ìhìn rere, kí n lè di alájọpín nínú rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.” (1 Kọ́r. 9:22, 23) Inú Pọ́ọ̀lù máa ń dùn bó ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run, ó sì máa ń ronú jinlẹ̀ lórí bó ṣe lè sọ̀rọ̀ tó máa ran olúkúlùkù àwọn tó ń wàásù fún lọ́wọ́. Torí náà, ó ṣeé ṣe fún un láti fún wọn ní ìṣírí tí ìyẹn sì mú kí wọ́n fẹ́ láti sin Jèhófà.

8. (a) Kí ló yẹ kó jẹ́ ìṣarasíhùwà wa sí àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa? (b) Báwo ní dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lè fi kún ayọ̀ tá à ń rí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù?

8 Báwo ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ Pọ́ọ̀lù ti ṣe pàtàkì tó lójú rẹ̀? Ó múra tán láti “sìnrú” fún Jèhófà àti fún àwọn tó bá máa tẹ́tí sí ìhìn rere tó ń wàásù rẹ̀ fún wọn. (Róòmù 12:11; 1 Kọ́r. 9:19) Bá a bá ń kọ́ àwọn èèyàn ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, yálà nígbà ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, nígbà ìpàdé ìjọ tàbí nígbà Ìjọsìn Ìdílé, ǹjẹ́ à ń ro ohun tó jẹ́ ojúṣe wa lọ́dọ̀ àwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ mọ́ ọn? A lè máa ronú pé dídarí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì déédéé jẹ́ ẹrù tó máa pọ̀ jù fún wa láti gbé. Òótọ́ ni pé ó sábà máa ń gba pé ká wá àkókò látinú àwọn ìlépa tara ẹni ká sì fi irú àkókò bẹ́ẹ̀ ran àwọn míì lọ́wọ́. Àmọ́, ṣé kì í ṣe ohun tí Jésù náà ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó sọ pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ”? (Ìṣe 20:35) Bí àwa fúnra wa bá ń kọ́ àwọn èèyàn ní ọ̀nà tí wọ́n fi lè rí ìgbàlà, a máa ní ayọ̀ tó pọ̀ ju èyí tá a lè rí nínú ìgbòkègbodò èyíkéyìí mìíràn lọ.

9, 10. (a) Bá a bá fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìsìn wa, ǹjẹ́ ìyẹn túmọ̀ sí pé a kò gbọ́dọ̀ sinmi ká sì wá àkókò láti bá àwọn èèyàn ṣeré? Ṣàlàyé. (b) Kí ló máa mú kí alàgbà kan mọ bá a ṣe ń fúnni níṣìírí kó sì ṣeé sún mọ́?

9 Bá a bá fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìsìn wa, ìyẹn ò túmọ̀ sí pé a kò lè ní àkókò ìsinmi tá a lè fi bá àwọn èèyàn ṣeré tó gbádùn mọ́ni. Jésù fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún wa, ó wá àkókò láti kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́, ó sinmi, ó sì tún ní àjọṣe tí ń gbéni ró pẹ̀lú àwọn míì. (Lúùkù 5:27-29; Jòh. 12:1, 2) Pé a fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìsìn wa kò túmọ̀ sí pé kí ojú wa máa le koko ní gbogbo ìgbà. Bí Jésù bá jẹ́ òǹrorò, tó sì máa ń fi ọwọ́ líle mú nǹkan, ó dájú pé ńṣe làwọn èèyàn á máa sá fún un. Ṣùgbọ́n ó máa ń tu àwọn ọmọdé pàápàá lára láti wà pẹ̀lú rẹ̀. (Máàkù 10:13-16) Báwo la ṣe lè ṣe lè máa wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì bíi ti Jésù?

10 Nígbà tí arákùnrin kan ń sọ̀rọ̀ nípa alàgbà kan, ó sọ pé, “Kì í gba gbẹ̀rẹ́ fún ara rẹ̀, àmọ́ kì í retí ohun tó pọ̀ jù látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíì.” Ṣé bí ìwọ náà ṣe rí nìyẹn? Kò dára ká máa retí pé káwọn míì ṣe kọjá ohun tí agbára wọn gbé. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ máa ń ṣe dáadáa bí àfojúsùn tí àwọn òbí ní fún wọn kò bá pọ̀ jù tí wọ́n sì ń ran àwọn ọmọ lọ́wọ́ láti lé àfojúsùn náà bá. Bákan náà, àwọn alàgbà lè fún olúkúlùkù ará nínú ìjọ ní ìṣírí kí wọ́n lè dàgbà nípa tẹ̀mí kí wọ́n sì fún wọn ní ìtọ́ni pàtó nípa ohun tí wọ́n lè ṣe. Síwájú sí i, bí alàgbà kan kò bá ro ara rẹ̀ ju bó ṣe yẹ lọ, ìṣesí rẹ̀ kò ní lé àwọn ará sá, á sì ṣeé sún mọ́. (Róòmù 12:3) Arábìnrin kan sọ pé: “Kì í wù mí kí alàgbà sọ gbogbo nǹkan di eré. Àmọ́ tó bá tún wá jẹ́ pé gbogbo ìgbà ló ń fọwọ́ líle mú nǹkan, ó máa ṣòroó sún mọ́.” Arábìnrin míì sọ pé ó máa ń ṣe òun bíi pé àwọn alàgbà kan “máa ń máyà jáni torí pé wọ́n ti máa ń le koko jù.” Àwọn alàgbà kò ní fẹ́ kí ayọ̀ tó yẹ kí gbogbo àwọn onígbàgbọ́ máa ní bí wọ́n ti ń sin Jèhófà, “Ọlọ́run aláyọ̀,” pẹ̀dín.—1 Tím. 1:11.

Gbígba Àǹfààní Iṣẹ́ Ìsìn Nínú Ìjọ

11. Kí ló túmọ̀ sí láti máa “nàgà” nínú ìjọ?

11 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń fún àwọn ọkùnrin tó wà nínú ìjọ ní ìṣírí pé kí wọ́n sakun láti kúnjú ìwọ̀n fún gbígba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn tó pọ̀ sí i, kì í ṣe pé ó ń gba ẹnikẹ́ni níyànjú láti máa wá ipò ọlá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó kọ̀wé pé: “Bí ọkùnrin èyíkéyìí bá ń nàgà fún ipò iṣẹ́ alábòójútó, iṣẹ́ àtàtà ni ó ń fẹ́.” (1 Tím. 3:1, 4) ‘Nínàgà’ túmọ̀ sí pé kó máa wu àwọn Kristẹni ọkùnrin láti ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè ní àwọn ànímọ́ yíyẹ nípa tẹ̀mí tó máa mú kí wọ́n lè sin àwọn arákùnrin wọn. Ó kéré tán, bó bá ti tó ọdún kan tí arákùnrin kan ti ṣèrìbọmi tó sì jẹ́ pé, dé ìwọ̀n tí ẹnikẹ́ni kò lè kọminú sí, ó dójú ìlà àwọn ohun tí Ìwé Mímọ́ béèrè fún kéèyàn tó lè di ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú 1 Tímótì 3:8-13, a lè dábàá rẹ̀ fún ìyànsípò. Kíyè sí i pé ẹsẹ 8 sọ lọ́nà tó ṣe kedere pé: “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ ní láti ní ìwà àgbà.”

12, 13. Ṣàlàyé bí àwọn arákùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́ ṣe lè nàgà fún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ.

12 Ṣé ọ̀dọ́kùnrin tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ọmọ ogún ọdún, tó ní ìwà àgbà, tó sì ti ṣèrìbọmi ni ẹ́? Onírúurú ọ̀nà ló wà tó o lè gbà nàgà. Ọ̀nà kan ni pé kó o túbọ̀ máa lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ṣé ẹni tó fẹ́ràn láti máa bá àwọn tí ọjọ́ orí wọn yàtọ̀ síra ṣiṣẹ́ lóde ẹ̀rí ni ẹ́? Ṣé ò ń wá ẹni tó o lè máa bá ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Bó o bá ń lo àwọn àbá tí ètò Ọlọ́run ń fún wa láwọn ìpàdé ìjọ láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wàá mú ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ sunwọ̀n sí i. Síwájú sí i, wàá mọ bó o ṣe lè máa ní ìgbatẹnirò fún ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ nípa àwọn ọ̀nà Jèhófà. Bí ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ bá ṣe ń rí i pé ó yẹ kí òun máa ṣe àwọn ìyípadà, ìwọ náà á mọ bó ṣe yẹ kó o máa fi sùúrù àti ọgbọ́n ràn án lọ́wọ́ láti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì sílò.

13 Ẹ̀yin ọkùnrin tẹ́ ẹ jẹ́ ọ̀dọ́ lè mú kí àwọn alàgbà máa rí yín lò nínú ìjọ, kẹ́ ẹ máa ṣe ìrànlọ́wọ́ èyíkéyìí tẹ́ ẹ bá lè ṣe fún wọn. Ẹ tún lè fi hàn pé ìrísí Gbọ̀ngàn Ìjọba jẹ yín lógún nípa mímú kí ó wà ní mímọ́ tónítóní. Bí ẹ bá ń ṣèrànlọ́wọ́ ní ọ̀nà èyíkéyìí débi tí ẹ bá lè ṣe é dé, ẹ̀mí ìmúratán tẹ́ ẹ ní yẹn máa fi hàn pé ẹ fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ yín. Bíi ti Tímótì, ẹ lè kọ́ bẹ́ ẹ ṣe lè máa fi òótọ́ inú bójú tó àwọn ohun tí ìjọ ṣaláìní.—Ka Fílípì  2:19-22.

14. Báwo la ṣe lè “dán” àwọn arákùnrin tó jẹ́ ọ̀dọ́ “wò ní ti bí wọn ti yẹ sí” kí wọ́n lè sìn nínú ìjọ?

14 Ẹ̀yin alàgbà, ẹ wà lójúfò láti máa yanṣẹ́ fún àwọn ọ̀dọ́kùnrin tí wọ́n ń tiraka láti “sá fún àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn” tí wọ́n sì ń lépa “òdodo, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, àlàáfíà” pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ànímọ́ rere míì. (2 Tím. 2:22) Bẹ́ ẹ bá ń yan iṣẹ́ fún wọn láti ṣe nínú ìjọ, ẹ lè tipa bẹ́ẹ̀ “dán” wọn “wò ní ti bí wọn ti yẹ sí” láti gba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ, kí “ìlọsíwájú” wọn sì lè tipa bẹ́ẹ̀ “fara hàn kedere fún gbogbo ènìyàn.”—1 Tím. 3:10; 4:15.

Bó O Ṣe Lè Fi Ọwọ́ Pàtàkì Mú Iṣẹ́ Ìsìn Ọlọ́run Nínú Ìjọ àti Nínú Ìdílé

15. Ní ìbámu pẹ̀lú ohun tó wà nínú 1 Tímótì 5:1, 2, báwo ni ojú tá a fi ń wo àwọn èèyàn ṣe lè fi hàn pé a jẹ́ oníwà àgbà?

15 A tún lè fi hàn pé a jẹ́ oníwà àgbà tá a bá ń bọlá fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa. Nínú ìmọ̀ràn tí Pọ́ọ̀lù fún Tímótì, ó sọ̀rọ̀ nípa ìdí tó fi yẹ kí ojú tá a fi ń wo àwọn ẹlòmíì fi hàn pé à ń bọ̀wọ̀ fún wọn. (Ka 1 Tímótì 5:1, 2.) Èyí tiẹ̀ tún wá ṣe pàtàkì bí ẹni tí nǹkan jọ dà wá pọ̀ kì í bá ṣe ọkọ tàbí ìyàwó wa. Àpẹẹrẹ tí Jóòbù fi lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ ká máa bọlá fún àwọn obìnrin, pàápàá jù lọ bó ṣe bọlá fún ìyàwó rẹ̀, tó ohun tó yẹ ká fara wé. Ó sapá gidigidi láti má ṣe wo obìnrin mìíràn pẹ̀lú èrò láti bá a ṣèṣekúṣe lọ́kàn. (Jóòbù 31:1) Bá a bá ka àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin sí ẹni àpọ́nlé, a kò ní máa bá wọn tage, a kò sì ní í ṣe ohunkóhun tí kò ní jẹ́ kí ọkàn wọn balẹ̀ bí wọ́n bá wà ní sàkáání wa. Ó tiẹ̀ tún wá ṣe pàtàkì pé kí àwọn méjì tó ń fẹ́ra sọ́nà, tí wọ́n ní in lọ́kàn láti ṣègbéyàwó máa bọlá fún ara wọn. Kristẹni tó ní ìwà àgbà kò jẹ́ fi ẹ̀tàn bá ọkùnrin tàbí obìnrin míì lò.—Òwe 12:22.

16. Sọ ìyàtọ̀ tó wà nínú ojú táwọn kan nínú ayé fi ń wo ojúṣe ọkọ àti bàbá pẹ̀lú bí Bíbélì ṣe ṣàlàyé rẹ̀.

16 A tún gbọ́dọ̀ kíyè sára ká lè máa fi ọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ nínú ìdílé. Ńṣe ni ayé Sátánì ń fi àwọn ọkọ àti baba ṣẹ̀sín nípa mímú kó jọ pé ojúṣe wọn nínú ìdílé kò já mọ́ nǹkan kan. Àwọn ohun tí wọ́n ń gbé jáde lórí tẹlifíṣọ̀n, eré orí ìtàgé, orin àtàwọn eré ìnàjú ń tẹ àwọn olórí ìdílé mẹ́rẹ̀ ó sì ń tàbùkù sí àṣẹ tí Ọlọ́run gbé lé wọn lọ́wọ́. Àmọ́, nínú Ìwé Mímọ́, a yan ọkọ láti jẹ́ “orí aya rẹ̀,” èyí tó fi hàn pé iṣẹ́ ńlá ló já lé àwọn ọkọ léjìká.—Éfé. 5:23; 1 Kọ́r. 11:3.

17. Ṣàlàyé bí kíkópa nínú Ìjọsìn Ìdílé ṣe lè fi hàn pé a fọwọ́ pàtàkì mú ojúṣe wa.

17 Ọkọ kan lè máa pèsè ohun tí ìdílé rẹ̀ nílò nípa tara. Àmọ́ bí kì í bá tọ́ wọn sọ́nà nípa tẹ̀mí, a jẹ́ pé kò fi hàn pé òun jẹ́ ọlọ́gbọ́n àti olóye. (Diu. 6:6, 7) Torí náà, 1 Tímótì 3:4 sọ pé bí o bá jẹ́ olórí ìdílé tó o sì ń nàgà fun àfikún àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ, o gbọ́dọ̀ jẹ́ ọkùnrin tó “ń ṣe àbójútó agbo ilé tirẹ̀ lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, tí ó ní àwọn ọmọ tí wọ́n ní ìtẹríba pẹ̀lú gbogbo ìwà àgbà.” Látàrí èyí, bi ara rẹ pé, ‘Nínú ìdílé mi, ǹjẹ́ mo máa ń ya àkókò sọ́tọ̀ déédéé fún Ìjọsìn Ìdílé?’ Àfi bí àwọn arábìnrin wa kan bá bẹ àwọn ọkọ wọn ní wọ́n tó máa ń mú ipò iwájú nípa tẹ̀mí. Ọkọ kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ fi ọwọ́ tó ṣe pàtàkì mú bó ṣe ń wo ojúṣe tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́. Àmọ́ ṣá o, ìyàwó tó jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ máa kọ́wọ́ ti Ìjọsìn Ìdílé kó sì máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ọkọ rẹ̀ kó lè kẹ́sẹ járí.

18. Báwo ní àwọn ọmọ ṣe lè jẹ́ ẹni tó ní ìwà àgbà?

18 Ìwé Mímọ́ tún gba àwọn ọmọ níyànjú láti pa ọkàn pọ̀ sórí àwọn ohun tó ṣe pàtàkì nínú ìgbésí ayé wọn. (Oníw. 12:1) Kò sí ohun tó burú nínú pé kí àwọn ọ̀dọ́ kọ́ láti ṣiṣẹ́ kára, kí wọ́n máa ṣe àwọn iṣẹ́ ilé tó bá ọjọ́ orí wọn mu àti èyí tí wọ́n lágbára láti ṣe. (Ìdárò 3:27) Nígbà tí Dáfídì Ọba ṣì wà ní ọ̀dọ́, ó kọ́ bó ṣe lè jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn rere. Ó di akọrin ó sì tún mọ bá a ṣe ń kó orin jọ. Àwọn ohun tó mọ̀ yẹn sì gbé e dé iwájú olùṣàkóso Ísírẹ́lì láti lọ ṣèránṣẹ́ fún un. (1 Sám. 16:11, 12, 18-21) Kò sí iyè méjì pé Dáfídì máa ń ṣeré nígbà tó wà ní ọ̀dọ́, àmọ́ ó tún kọ́ ọ̀pọ̀ ohun tó wúlò, èyí tó lò lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn láti yin Jèhófà. Òye tó ní gẹ́gẹ́ bí olùṣọ́ àgùntàn mú kó lè fi sùúrù darí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ẹ̀yin ọ̀dọ́, àwọn ohun tó wúlò wo lẹ̀ ń kọ́, èyí tẹ́ ẹ máa lè fi sin Ẹlẹ́dàá yín tó sì máa jẹ́ kẹ́ ẹ lè bójú tó ojúṣe yín lọ́jọ́ iwájú?

Bẹ́ Ẹ Ṣe Lè Máa Wà ní Ìwọ̀ntúnwọ̀nsì

19, 20. Kó o lè wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì nínú ọ̀nà tó o gbà ń gbé ìgbé ayé rẹ àti nínú ìjọsìn rẹ, kí lo ti pinnu láti ṣe?

19 Gbogbo wa lè sapá láti wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, ká má sì máa ro ara wa ju bó ṣe yẹ lọ. A kò ní fẹ́ láti di “olódodo àṣelékè.” (Oníw. 7:16) Bí ipò kan tó lè mú ká fara ya bá tiẹ̀ wáyé nínú ilé, níbi iṣẹ́ tàbí nígbà tí nǹkan bá jọ da àwa àti àwọn ará wa lọ́kùnrin àti lóbìnrin pọ̀, wíwulẹ̀ sọ ohun kan tó pani lẹ́rìn-ín lè mú kí ara tu gbogbo ẹni tí ọ̀ràn kàn. Àwọn tó jẹ́ ara ìdílé kan náà tún ní láti ṣọ́ra kí wọ́n má lọ máa ṣe àríwísí débi tí ìyẹn á fi ba àlàáfíà àti ìtura tó yẹ kó wà nínú ilé jẹ́. Nínú ìjọ, ó yẹ kí gbogbo wa máa yá mọ́ra kó sì máa wù wá láti wà pẹ̀lú ara wa, kí ìjíròrò wa àti ọ̀nà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wa máa gbéni ró kó sì máa nípa rere lórí àwọn tó ń gbọ́ wa.— 2 Kọ́r. 13:10; Éfé. 4:29.

20 À ń gbé nínú ayé kan tí kò ka Jèhófà tàbí àwọn òfin rẹ̀ sí pàtàkì. Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, ohun tó jẹ àwọn èèyàn Jèhófà lógún ni bí wọ́n á ṣe máa ṣègbọràn sí Ọlọ́run tí wọ́n á sì jẹ́ adúróṣinṣin. Ó ń múni lọ́kàn yọ̀ láti jẹ́ ara ògìdìgbó èèyàn tó ń sin Jèhófà “pẹ̀lú gbogbo ìwà àgbà”! Ǹjẹ́ kí gbogbo wa pinnu láti fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn wa àti ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbé ayé wa.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni kò ní jẹ́ ká dà bí àwọn èèyàn ayé tí wọn kò fi ọwọ́ pàtàkì mú ọ̀nà tí wọ́n ń gbà gbé ìgbé ayé wọn?

• Báwo la ṣe lè fi ọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa síbẹ̀ ká máa láyọ̀?

• Báwo ni ojú tá a fi ń wo gbígba àǹfààní iṣẹ́ ìsìn nínú ìjọ ṣe lè fi hàn bóyá a fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́ ìsìn wa tàbí a kò fọwọ́ pàtàkì mú un?

• Ṣàlàyé ìdí tí bíbọlá fún àwọn ará àtàwọn tó jẹ́ ara ìdílé wa fi ṣe pàtàkì.

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ọkọ gbọ́dọ̀ máa pèsè nípa tara àti nípa tẹ̀mí fún ìdílé rẹ̀