Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Máa Ṣe Ìpinnu Tó Máa Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga

Ẹ Máa Ṣe Ìpinnu Tó Máa Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga

Ẹ Máa Ṣe Ìpinnu Tó Máa Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga

“Afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—ÒWE 14:15.

1, 2. (a) Kí ló yẹ kó jẹ wá lógún jù lọ nínú gbogbo ìpinnu tá a bá ń ṣe? (b) Àwọn ìbéèrè wo la máa gbé yẹ̀ wò?

 ILẸ̀ ọjọ́ kan ò lè mọ́ ká má ṣe àìmọye wọn. Èyí tó pọ̀ jù lára wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ nípa lórí wa. Àmọ́ àwọn kan máa ń ní ipa tó lágbára lórí ọ̀nà tá a gbà ń gbé ìgbé ayé wa. Kí ni àwọn nǹkan náà? Àwọn ìpinnu tá à ń ṣe ni. Nínú gbogbo ìpinnu ńlá tàbí ìpinnu kékeré tá à ń ṣe, olórí àníyàn wa ni pé kí àwọn ìpinnu náà lè máa gbé orúkọ Ọlọ́run ga.—Ka 1 Kọ́ríńtì 10:31.

2 Ṣé ó máa ń rọrùn fún ẹ láti ṣe ìpinnu àbí ó máa ń ṣòro? Bá a bá fẹ́ tẹ̀ síwájú láti di Kristẹni tó dàgbà nípa tẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ mọ bá a ṣe lè máa fi ìyàtọ̀ sáàárín ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́, ká má sì máa gbé ìpinnu wa karí ohun táwọn ẹlòmíì gbà gbọ́, bí kò ṣe ohun tó dá àwa fúnra wa lójú. (Róòmù 12:1, 2; Héb. 5:14) Kí ni àwọn ìdí pàtàkì míì tó fi yẹ ká mọ béèyàn ṣe ń ṣe àwọn ìpinnu tó dára? Kí nìdí tó fi máa ń ṣòro nígbà míì láti ṣe ìpinnu? Àwọn ìgbésẹ̀ wo la sì lè gbé kí àwọn ìpinnu wa lè máa gbé orúkọ Ọlọ́run ga?

Kí Tiẹ̀ Nìdí Tá A Fi Ń Ṣe Ìpinnu?

3. Kí ni a kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kó dí ìpinnu tá a bá fẹ́ ṣe lọ́wọ́?

3 Bí a kò bá lè dá ìpinnu ṣe lórí àwọn ọ̀ràn tó jẹ mọ́ ìlànà Bíbélì, àwọn ọmọléèwé wa tàbí àwọn tá a jọ jẹ́ òṣìṣẹ́ lè rò pé ohun tá a gbà gbọ́ kò dá wa lójú àti pé a lè tètè tẹ̀ síbi táwọn ẹlòmíì bá tẹ̀ sí. Wọ́n lè purọ́, kí wọ́n rẹ́ni jẹ tàbí kí wọ́n jí nǹkan, lẹ́yìn náà kí wọ́n wá gbìyànjú láti mú ká “tẹ̀ lé ogunlọ́gọ̀” nípa dídara pọ̀ mọ́ wọn tàbí nípa bíbá wọn bo ìwà ibi náà mọ́lẹ̀. (Ẹ́kís. 23:2) Àmọ́, ẹni tó bá mọ bí òun ṣe lè ṣe ìpinnu tó máa gbé orúkọ Ọlọ́run ga kò ní jẹ́ kí ìbẹ̀rù tàbí rírí ojúure àwọn ẹlòmíì mú òun ṣe ohun tó ta ko ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ tá a ti fi Bíbélì kọ́.—Róòmù 13:5.

4. Kí ló lè mú kí àwọn míì fẹ́ láti ṣe ìpinnu fún wa?

4 Kì í ṣe gbogbo àwọn tó bá ń fẹ́ láti ṣe ìpinnu fún wa ló fẹ́ ṣèpalára fún wa. Àwọn ọ̀rẹ́ tí wọ́n ní èrò rere lọ́kàn lè fi dandan lé e pé ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn àwọn. Bó bá jẹ́ ibòmíràn là ń gbé, ó ṣeé ṣe kí ọ̀ràn wa máa jẹ àwọn ẹbí wa tá a fi sílẹ̀ nílé lógún kí wọ́n sì fẹ́ láti máa bá wa dá sí ṣíṣe àwọn ìpinnu pàtàkì tó bá yẹ ká ṣe. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa gbígba ìtọ́jú lọ́dọ̀ dókítà. Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé kò dára láti gba ẹ̀jẹ̀ sára tàbí kéèyàn lò ó lọ́nà míì tí kò bá òfin Ọlọ́run mu. (Ìṣe 15:28, 29) Àmọ́ ṣá o, àwọn ọ̀ràn míì nípa ìtọ́jú ìlera wà tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe kedere èyí tó máa béèrè pé kí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa dá ṣe ìpinnu lórí irú ìtọ́jú tó máa gbà tàbí èyí tí kò ní gbà. * Àwọn ìbátan wa lè rò pé èrò tiwọn nípa àwọn ọ̀ràn wọ̀nyí ló tọ̀nà. Síbẹ̀, bí Kristẹni kọ̀ọ̀kan tó ti ṣe ìyàsímímọ́ tó sì ti ṣèrìbọmi bá ń ṣe ìpinnu lórí irú àwọn ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, òun ló máa ru “ẹrù ti ara rẹ̀.” (Gál. 6:4, 5) Ohun tó jẹ wá lógún jù lọ ni pé ká ní ẹ̀rí ọkàn rere níwájú Ọlọ́run, kì í ṣe pé ká máa wá ìtẹ́wọ́gbà àwọn èèyàn.—1 Tím. 1:5.

5. Kí la lè ṣe kí ọkọ̀ ìgbàgbọ́ wa má bàa rì?

5 Ó léwu gan-an kéèyàn jẹ́ ẹni tí kò lè dá ṣe ìpinnu. Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn Jésù sọ pé ẹni tí kò lè ṣe ìpinnu jẹ́ “aláìdúrósójúkan ní gbogbo ọ̀nà rẹ̀.” (Ják. 1:8) Bíi ti ọkùnrin kan tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi tí kò ní ìtọ́kọ̀ láàárín omi òkun tó ń ru gùdù, ńṣe ni èrò ẹ̀dá tí kò dúró sójú kan á máa gbé ẹni tí kò lè ṣe ìpinnu káàkiri. Ẹ sì wá wo bó ṣe máa rọrùn tó fún ọkọ̀ ìgbàgbọ́ irú ẹni bẹ́ẹ̀ láti rì, lẹ́yìn náà kó wá máa dá àwọn ẹlòmíì lẹ́bi nítorí ipò búburú tó bá ara rẹ̀! (1 Tím. 1:19) Kí la lè ṣe tí irú èyí kò fi ní ṣẹlẹ̀ sí wa? A gbọ́dọ̀ “fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.” (Ka Kólósè 2:6, 7.) Ká bàa lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, a gbọ́dọ̀ máa ṣe àwọn ìpinnu tó máa fi hàn pé a ní ìgbàgbọ́ nínú Ọ̀rọ̀ tó ní ìmísí Ọlọ́run. (2 Tím. 3:14-17) Àmọ́, kí ló lè mú ká má lè ṣe àwọn ìpinnu tó dára?

Ìdí Tó Fi Lè Ṣòro Láti Ṣe Àwọn Ìpinnu

6. Báwo ni ìbẹ̀rù ṣe lè nípa lórí wa?

6 A lè máà fẹ́ ṣe ìpinnu rárá bí ẹ̀rù bá ń bà wá pé a lè ṣe ìpinnu tí kò tọ́, pé ìpinnu wa lè kùnà tàbí pé àwọn míì lè máa rò pé òmùgọ̀ ni wá. Kò burú kéèyàn ṣàníyàn pé òun kò fẹ́ ṣi ìpinnu ṣe. Kò sẹ́ni tó fẹ́ ṣe ìpinnu tí kò dára, èyí tó máa dá wàhálà sílẹ̀ tó sì lè mú ìtìjú wá. Síbẹ̀, ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè dín ìbẹ̀rù tá a ní kù. Ní àwọn ọ̀nà wo? Ní ti pé ìgbà gbogbo ni ìfẹ́ tá a ní sí Ọlọ́run á mú ká máa yẹ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àtàwọn ìtẹ̀jáde tá a gbé karí Bíbélì wò kó tó di pé a ṣe àwọn ìpinnu pàtàkì. Nípa báyìí, a máa dín àwọn àṣìṣe tá à ń ṣe kù. Kí nìdí? Ìdí ni pé Bíbélì lè “fún àwọn aláìní ìrírí ní ìfọgbọ́nhùwà” kó sì “fún ọ̀dọ́kùnrin ní ìmọ̀ àti agbára láti ronú.”—Òwe 1:4.

7. Kí la lè rí kọ́ látinú àpẹẹrẹ Dáfídì Ọba?

7 Ṣé gbogbo ìgbà ni a óò máa ṣe ìpinnu tó tọ́? Rárá o. Gbogbo wa là ń ṣe àṣìṣe. (Róòmù 3:23) Bí àpẹẹrẹ, Dáfídì Ọba jẹ́ ọlọgbọ́n àti olùṣòtítọ́. Síbẹ̀, àwọn ìgbà kan wà tó ṣe àwọn ìpinnu tí kò tọ́, èyí tó fi fa ìjìyà wá sórí ara rẹ̀ àti sórí àwọn míì. (2 Sám. 12:9-12) Síbẹ̀, Dáfídì kò jẹ́ kí àwọn àṣìṣe rẹ̀ dí i lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tí inú Ọlọ́run dùn sí. (1 Ọba 15:4, 5) Àwa náà lè ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́ láìka àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn sí bá a bá rántí, bíi ti Dáfídì, pé Jèhófà máa gbójú fo àwọn àṣìṣe wa tó sì máa dárí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa jì wá. Jèhófà á máa bá a nìṣó láti ṣètìlẹ́yìn fún àwọn tó bá fẹ́ràn rẹ̀ tí wọ́n sì ń ṣègbọràn sí i.—Sm. 51:1-4, 7-10.

8. Kí la rí kọ́ látinú ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìgbéyàwó?

8 A lè dín àníyàn tá a máa ń ṣe lórí ọ̀ràn ìpinnu ṣíṣe kù. Báwo? Bá a bá gbà pé nígbà míì kì í ṣe ọ̀nà kan la lè gbà ṣe ìpinnu tó tọ́. Ṣe àgbéyẹ̀wò ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ nípa ìgbéyàwó. Ọlọ́run mí sí i láti kọ̀wé pé: “Bí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun ń hùwà lọ́nà àìbẹ́tọ̀ọ́mu sí ipò wúńdíá òun, bí onítọ̀hún bá ti ré kọjá ìgbà ìtànná òdòdó èwe, tí èyí sì jẹ́ ọ̀nà tí ó yẹ kí ó gbà ṣẹlẹ̀, kí ó ṣe ohun tí ó fẹ́; kò dẹ́ṣẹ̀. Kí wọ́n gbéyàwó. Ṣùgbọ́n bí ẹnikẹ́ni bá ti pinnu tán nínú ọkàn-àyà rẹ̀, tí kò ní àìgbọ́dọ̀máṣe kankan, ṣùgbọ́n tí ó ní ọlá àṣẹ lórí ohun tí ó fẹ́, tí ó sì ti ṣe ìpinnu yìí nínú ọkàn-àyà ara rẹ̀, láti pa ipò wúńdíá tirẹ̀ mọ́, òun yóò ṣe dáadáa.” (1 Kọ́r. 7:36-38) Pọ́ọ̀lù dámọ̀ràn pé ohun tó dáa jù ni kéèyàn wà láìní ọkọ tàbí aya, àmọ́ kò sọ pé yíyàn kan ṣoṣo tó tọ̀nà nìyẹn.

9. Ṣó yẹ kí ojú tí àwọn míì fi ń wo ìpinnu tá a bá ṣe jẹ wá lógún? Ṣàlàyé.

9 Ṣó yẹ kí ojú tí àwọn míì fi ń wo ìpinnu tá a bá ṣe jẹ wá lógún? Bẹ́ẹ̀ ni, bó tiẹ̀ jẹ́ níwọ̀nba. Ronú lórí ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa jíjẹ oúnjẹ tó ṣeé ṣe kí wọ́n ti fi rúbọ sí òrìṣà. Ó gbà pé ìpinnu téèyàn ṣe lè má burú, àmọ́ irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ lè ṣàkóbá fún ẹni tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ jẹ́ aláìlera. Kí ni Pọ́ọ̀lù wá pinnu láti ṣe? Ó sọ pé: “Bí oúnjẹ bá mú arákùnrin mi kọsẹ̀, dájúdájú, èmi kì yóò tún jẹ ẹran láé, kí n má bàa mú arákùnrin mi kọsẹ̀.” (1 Kọ́r. 8:4-13) Ó yẹ kí àwa pẹ̀lú máa ronú lórí bí ìpinnu wa ṣe máa nípa lórí ẹ̀rí ọkàn àwọn míì. Àmọ́ ṣá o, ohun tó yẹ kó jẹ wá lógún jù lọ ni ipa tí yíyàn tá a bá ṣe máa ní lórí àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà. (Ka Róòmù 14:1-4.) Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìpinnu tó máa gbé orúkọ Ọlọ́run ga?

Àwọn Ohun Mẹ́fà Tó Máa Mú Ká Lè Ṣe Ìpinnu Tó Dára

10, 11. (a) Kí ni kò ní jẹ́ ká máa hùwà ìkùgbù nínú ìdílé? (b) Kí ló yẹ kí àwọn alàgbà fi sọ́kàn bí wọ́n bá ń ṣe ìpinnu tó máa nípa lórí ìjọ?

10 Ṣọ́ra fún ìwà ìkùgbù. Ká tó yàn láti ṣe ohun kan, ó yẹ ká bi ara wa pé, ‘Ṣé ojúṣe mi ni láti ṣe ìpinnu yìí?’ Sólómọ́nì Ọba kọ̀wé pé: “Ìkùgbù ha ti dé bí? Nígbà náà, àbùkù yóò dé; ṣùgbọ́n ọgbọ́n wà pẹ̀lú àwọn amẹ̀tọ́mọ̀wà.”—Òwe 11:2.

11 Òótọ́ ni pé àwọn òbí lè jẹ́ káwọn ọmọ wọ́n ṣe àwọn ìpinnu kan, àmọ́ kò yẹ káwọn ọmọ kàn máa dá irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ ṣe fúnra wọn. (Kól. 3:20) Àwọn aya àti àwọn ìyá náà ní àṣẹ tiwọn nínú ìdílé, àmọ́ ó dára kí wọ́n mọyì ipò orí àwọn ọkọ wọn. (Òwe 1:8; 31:10-18; Éfé. 5:23) Bákan náà, ó yẹ kí àwọn ọkọ mọ̀ pé àṣẹ àwọn ní ààlà àti pé abẹ́ Kristi làwọn pẹ̀lú wà. (1 Kọ́r. 11:3) Àwọn alàgbà máa ń ṣe ìpinnu tó nípa lórí ìjọ. Àmọ́, wọ́n ń rí i dájú pé àwọn kò “ré kọjá àwọn ohun tí a ti kọ̀wé rẹ̀” nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (1 Kọ́r. 4:6) Wọ́n tún máa ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí wọ́n bá rí gbà látọ̀dọ̀ ẹrú olóòótọ́ náà lójú méjèèjì. (Mát. 24:45-47) A lè gba ara wa lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ àníyàn àti ẹ̀dùn ọkàn bá a bá mọ̀wọ̀n ara wa tí a sì ń ṣe ìpinnu kìkì nígbà tí wọ́n bá fún wa ní àṣẹ láti ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀.

12. (a) Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣe ìwádìí? (b) Ṣàlàyé bí ẹnì kan ṣe lè ṣe irú ìwádìí bẹ́ẹ̀.

12 Máa ṣe ìwádìí. Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Àwọn ìwéwèé ẹni aláápọn máa ń yọrí sí àǹfààní, ṣùgbọ́n ó dájú pé àìní ni olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń kánjú forí lé.” (Òwe 21:5) Bí àpẹẹrẹ, ṣé ò ń gbé okòwò kan yẹ̀ wò? Má ṣe jẹ́ kí ara yá ẹ bọ́ sódì. Rí i pé o mọ gbogbo ohun tó yẹ kó o mọ̀ nípa rẹ̀, gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn tó bá mọ̀ nípa irú nǹkan bẹ́ẹ̀, kó o sì pinnu àwọn ìlànà Bíbélì tó o gbọ́dọ̀ fi sílò ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀ràn náà. (Òwe 20:18) Kí ìwádìí rẹ bàa lè múná dóko, pín ohun tó o máa wádìí nípa rẹ̀ sí ọ̀nà méjì, kí ọ̀kan dá lórí àwọn àǹfààní tó wà nínú okòwò náà, kí èkejì sì dá lórí ibi tí okòwò náà kù díẹ̀ káàtó sí. Kó o tó ṣe ìpinnu, “gbéṣirò lé ìnáwó náà.” (Lúùkù 14:28) Má ṣe ronú lórí owó tó máa wọlé fún ẹ nìkan, ṣùgbọ́n tún ronú lórí ipa tí ìpinnu tó o bá ṣe máa ní lórí àjọṣe rẹ pẹ̀lú Jèhófà. Ó máa ń gba àkókò àti ìsapá kéèyàn tó lè ṣe ìwádìí. Àmọ́, ìwádìí tó o bá ṣe ni kò ní jẹ́ kó o kánjú ṣe ìpinnu tó máa kó ìdààmú bá ẹ.

13. (a) Kí ni Jákọ́bù 1:5 mú kó dá wa lójú? (b) Báwo ni gbígbàdúrà fún ọgbọ́n ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

13 Gbàdúrà fún ọgbọ́n. Tá a bá fẹ́ ṣe àwọn ìpinnu, àyàfi tá a bá bẹ Ọlọ́run pé kó ràn wá lọ́wọ́ ni àwọn ìpinnu náà tó lè gbé orúkọ rẹ̀ ga. Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn kọ̀wé pé: “Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ṣaláìní ọgbọ́n, kí ó máa bá a nìṣó ní bíbéèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run, nítorí òun a máa fi fún gbogbo ènìyàn pẹ̀lú ìwà ọ̀làwọ́ àti láìsí gíganni; a ó sì fi í fún un.” (Ják. 1:5) Kò sí ìtìjú níbẹ̀ tá a bá gbà pé a nílò ọgbọ́n Ọlọ́run ká tó lè ṣèpinnu. (Òwe 3:5, 6) Ó ṣe tán, bá a bá gbára lé òye tiwa fúnra wa ìyẹn lè tètè kó wa ṣìnà. Bá a bá gbàdúrà fún ọgbọ́n tá a sì ṣàwárí àwọn ìlànà tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a ó tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí ẹ̀mí mímọ́ ràn wá lọ́wọ́ ká lè fòye mọ ohun tó wà lọ́kàn wa gan-an tá a fi fẹ́ ṣe àwọn ohun kan.—Héb. 4:12; ka Jákọ́bù 1:22-25.

14. Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa fi nǹkan falẹ̀?

14 Ṣe ìpinnu. Má ṣe fi ìkánjú ṣe ìpinnu kó o tó ṣe ìwádìí àti kó o tó gbàdúrà fún ọgbọ́n. Ọlọgbọ́n èèyàn máa ń wá àkókò láti fi “ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Òwe 14:15) Ní ọwọ́ mìíràn ẹ̀wẹ̀, má ṣe máa fi nǹkan falẹ̀. Ẹni tó ń fi nǹkan falẹ̀ lè máa ṣe àwáwí tí kò mọ́gbọ́n dání nípa ìdí tí kò fi ṣe ohun kan. (Òwe 22:13) Síbẹ̀, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣì máa ṣe ìpinnu, ó kàn jẹ́ pé àwọn ẹlòmíì ló máa pinnu fún wọn.

15, 16. Kí ló wé mọ́ ṣíṣe ohun tá a pinnu?

15 Ṣe ohun tó o ti pinnu. Gbogbo ìsapá tá a ti ṣe kó tó di pé a ṣe ìpinnu tó dára lè já sí pàbó bá a bá gbé ìpinnu náà tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan tá ò sì ṣiṣẹ́ takuntakun láti ṣe ohun tá a pinnu náà. Sólómọ́nì kọ̀wé pé: “Gbogbo ohun tí ọwọ́ rẹ bá rí láti ṣe, fi agbára rẹ ṣe é.” (Oníw. 9:10) Ká bàa lè kẹ́sẹ járí, a gbọ́dọ̀ múra tán láti ṣe ohun tó bá gbà ká lè ṣe ohun tá a pinnu. Bí àpẹẹrẹ, akéde ìjọ kan lè pinnu láti ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà. Ṣó máa kẹ́sẹ járí? Ó ṣeé ṣe kó kẹ́sẹ járí bí kò bá jẹ́ kí iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ àti eré ìtura tán òun ní okun kó sì gba àkókò tó yẹ kí òun máa fi wàásù mọ́ òun lọ́wọ́.

16 Àwọn ìpinnu tó dára jù lọ kì í sábàá rọrùn láti ṣiṣẹ́ lé lórí. Kí nìdí? Ìdí ni pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòh. 5:19) A ní gídígbò lòdì sí “àwọn olùṣàkóso ayé òkùnkùn yìí, lòdì sí àwọn agbo ọmọ ogun ẹ̀mí burúkú ní àwọn ibi ọ̀run.” (Éfé. 6:12) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Júúdà ọmọ ẹ̀yìn Jésù fi hàn pé àwọn tó bá pinnu láti bọlá fún Ọlọ́run ní ìjà tí wọ́n ní láti jà.—1 Tím. 6:12; Júúdà 3.

17. Ní ti àwọn ìpinnu tí à ń ṣe, kí ni Jèhófà ń retí lọ́dọ̀ wa?

17 Gbé ìpinnu náà yẹ̀ wò kó o sì ṣe àtúnṣe tó bá yẹ. Kì í ṣe gbogbo ìpinnu ló máa ń yọrí sí bá a ṣe fẹ́. “Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” máa ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa. (Oníw. 9:11) Síbẹ̀ náà, Jèhófà retí pé ká tẹra mọ́ ṣíṣe àwọn ohun kan tá a ti pinnu bí a bá tilẹ̀ dojú kọ àdánwò. Bí ẹnì kan bá pinnu láti ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà tàbí tó jẹ́ ẹ̀jẹ́ ìgbéyàwó, irú ìpinnu bẹ́ẹ̀ kì í ṣeé yí pa dà. Ọlọ́run retí pé ká máa gbé ní ìbámu pẹ̀lú irú ìpinnu bẹ́ẹ̀. (Ka Sáàmù 15:1, 2, 4.) Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ ìpinnu ló wà tí kì í ṣe ìpinnu tó lágbára. Ọlọgbọ́n èèyàn máa ń gbé ìpinnu tó ti ṣe yẹ̀ wò láti ìgbà dé ìgbà. Bó bá gba pé kó tún ìpinnu kan ṣe tàbí kó tiẹ̀ yí i pa dà, kò ní jẹ́ kí ìgbéraga tàbí orí kunkun dí òun lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀. (Òwe 16:18) Ohun tó kà sí pàtàkì jù lọ ni bí ọ̀nà tó ń gbà gbé ìgbé ayé rẹ̀ á ṣe máa gbé orúkọ Ọlọ́run ga.

Kọ́ Àwọn Míì Kí Wọ́n Lè Ṣèpinnu Tó Máa Gbé Orúkọ Ọlọ́run Ga

18. Báwo ni àwọn òbí ṣe lè kọ́ àwọn ọmọ wọn kí wọ́n lè máa ṣe ìpinnu tó dára?

18 Ọ̀pọ̀ nǹkan làwọn òbí lè ṣe láti mú kí àwọn ọmọ wọn mọ bí wọ́n ṣe lè ṣe àwọn ìpinnu tó máa gbé orúkọ Ọlọ́run ga. Fífi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀nà tó dára jù lọ táwọn òbí lè gbà kọ́ wọn. (Lúùkù 6:40) Àwọn òbí lè wá àkókò tó bá yẹ láti ṣàlàyé fáwọn ọmọ wọn, àwọn ìgbésẹ̀ táwọn fúnra wọn gbé kó tó di pé wọ́n ṣe àwọn ìpinnu kan. Wọ́n tún lè jẹ́ káwọn ọmọ dá àwọn ìpinnu kan ṣe, kí wọ́n wá yìn wọ́n bí ìpinnu náà bá yọrí sí rere. Àmọ́ bí ọmọ kan bá ṣe ìpinnu tí kò dára ńkọ́? Ó lè kọ́kọ́ ṣe òbí bíi pé kó gba ọmọ náà sílẹ̀ lọ́wọ́ àbájáde búburú tí ìpinnu rẹ̀ mú wá, àmọ́ ṣíṣe bẹ́ẹ̀ kò ní ran ọmọ náà lọ́wọ́. Bí àpẹẹrẹ, òbí lè jẹ́ kí ọmọ rẹ̀ gba ìwé àṣẹ ọkọ̀ wíwà. Ká wá sọ pé ọmọ náà rú òfin ìrìnnà tí wọ́n sì ní kó sanwó ìtanràn ńkọ́? Òbí ọmọ náà lè bá a san owó náà. Àmọ́, bí ọmọ náà bá ní láti ṣiṣẹ́ kó lè san owó ìtanràn náà, ó ṣeé ṣe kí ìyẹn jẹ́ kó mọ̀ pé òun á máa jíhìn fún àwọn nǹkan tí òun bá ṣe.—Róòmù 13:4.

19. Kí ló yẹ ká kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa, báwo la sì ṣe lè kọ́ wọn?

19 Jésù sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa kọ́ àwọn ẹlòmíì. (Mát. 28:20) Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a lè fi kọ́ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wa ni bí wọ́n ṣe lè máa ṣe ìpinnu tó dára. Ká bàa lè kọ́ wọn lọ́nà tó gbéṣẹ́ a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra kó má lọ jẹ́ pé àwa la ó máa sọ ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe fún wọn. Ó sàn ká kọ́ wọn bí wọ́n ṣe lè máa ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì kí àwọn fúnra wọn lè máa pinnu ohun tí wọ́n máa ṣe. Ó ṣe tán, “olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.” (Róòmù 14:12) Torí náà, ìdí tó pọn dandan wà tí gbogbo wa fi ní láti máa ṣe àwọn ìpinnu tó ń gbé orúkọ Ọlọ́run ga.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Bó o bá fẹ́ mọ ohun tá a sọ nípa kókó yìí, wo àkìbọnú náà, “Ojú Wo Ló Yẹ Kí N Fi Wo Àwọn Oògùn Tó Ní Èròjà Ẹ̀jẹ̀ Nínú, Kí Ló sì Yẹ Kí N Ṣe Báwọn Dókítà Bá Fẹ́ Fi Ẹ̀jẹ̀ Mi Tọ́jú Mi Lọ́nà Èyíkéyìí?” nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa, December 2006, ojú ìwé 3 sí 6.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí nìdí tó fi yẹ ká kọ́ béèyàn ṣe ń ṣe ìpinnu?

• Ipa wo ni ìbẹ̀rù lè ní lórí wa, báwo la sì ṣe lè borí àwọn ìbẹ̀rù wa?

• Kí ni àwọn ohun mẹ́fà tá a lè ṣe kí àwọn ìpinnu wa lè máa gbé orúkọ Ọlọ́run ga?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Àwọn Ohun Tó Máa Mú Ká Lè Ṣe Ìpinnu Tó Dára

1 Ṣọ́ra fún Ìwà Ìkùgbù

2 Máa Ṣe Ìwádìí

3 Gbàdúrà fún Ọgbọ́n

4 Ṣe Ìpinnu

5 Ṣe Ohun Tó O Ti Pinnu

6 Gbé Ìpinnu Náà Yẹ̀ Wò Kó O sì Ṣe Àtúnṣe Tó Bá Yẹ

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ẹni tí kò lè dá ṣe ìpinnu dà bí ọkùnrin kan tó wà nínú ọkọ̀ ojú omi tí kò ní ìtọ́kọ̀ láàárín omi òkun tó ń ru gùdù