Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Mo Ti Rí Ọ̀pọ̀ Ohun Rere

Mo Ti Rí Ọ̀pọ̀ Ohun Rere

Mo Ti Rí Ọ̀pọ̀ Ohun Rere

Gẹ́gẹ́ bí Arthur Bonno ṣe sọ ọ́

ỌDÚN 1951 ni ọ̀rọ̀ yìí wáyé. Ó ṣẹlẹ̀ pé èmi àti ìyàwó mi, Edith, wà ní àpéjọ àgbègbè kan níbi tí wọ́n ti ṣèfilọ̀ pé wọ́n máa ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì.

Mo fìtara sọ pé: “Jẹ́ ká lọ gbọ́ ohun tí wọ́n máa sọ.”

Ìyàwó mi dáhùn pé: “Baálé mi, irú wa kọ́ ni wọ́n ń wá níbẹ̀!”

Mo fèsì pé: “Ṣebí ká kàn lọ gbọ́ ohun tí wọ́n fẹ́ sọ ni.”

A lọ síbẹ̀, wọ́n sì pín fọ́ọ̀mù Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì lé wa lọ́wọ́ lẹ́yìn ìpàdé náà.

Mo sọ fún ìyàwó mi pé: “Jẹ́ ká kọ ọ̀rọ̀ sínú fọ́ọ̀mù náà.”

Ìyàwó mi wá sọ pé: “Kí la ti máa ṣe ti ìdílé wa sí?”

Ní nǹkan bí ọdún kan àtààbọ̀ lẹ́yìn àpéjọ àgbègbè náà, a lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì wọ́n sì ní ká lọ máa sìn ní orílẹ̀-èdè Ecuador tó wà ní Amẹ́ríkà ti Gúúsù.

Ó ṣeé ṣe kẹ́ ẹ ti kíyè sí irú èèyàn tí mo jẹ́ nínú ìjíròrò tó wáyé láàárín èmi àti ìyàwó mi ní àpéjọ àgbègbè yẹn. Mo mọ bá a ṣe ń rọni láti ṣe nǹkan, mo sì gbà pé kò sí ohun tí kò ṣeé ṣe béèyàn bá ti pinnu láti ṣe nǹkan náà. Àmọ́, èèyàn jẹ́jẹ́ ni ìyàwó mi ó sì mọ̀wọ̀n ara rẹ̀. Nígbà tó ń gbé ní ìlú kékeré kan tó ń jẹ́ Elizabeth, ní ìpínlẹ̀ Pennsylvania lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, kì í fi bẹ́ẹ̀ rìn jìnnà sílé kò sì tíì bá ẹni tó wá láti orílẹ̀-èdè míì pàdé rí. Torí náà, ó ṣòro fún un láti fi ìdílé rẹ̀ sílẹ̀. Síbẹ̀, ó fara mọ́ ọn tọkàntọkàn pé ká lọ sìn ní ilẹ̀ òkèèrè. Ọdún 1954 la dé sí orílẹ̀-èdè Ecuador, láti ìgbà náà wá la sì ti ń sìn níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì. Láàárín àwọn ọdún tá a ti lò níbí, a ti rí ọ̀pọ̀ ohun rere. Ṣé wàá fẹ́ ká sọ díẹ̀ fún ẹ lára àwọn ohun rere náà?

Mo Rántí Àwọn Nǹkan Tó Fún Mi Láyọ̀

Olú ìlú orílẹ̀-èdè náà, Quito, ni wọ́n kọ́kọ́ yàn wá sí. Ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìlú tó wà lórí Òkè Andes, ó sì ga tó ẹgbẹ̀rún mẹ́sàn-án [9,000] ẹsẹ̀ bàtà. Ìlú Guayaquil tó wà ní etíkun la ti gbéra. A wọ ọkọ̀ ojú irin àti ọkọ̀ akẹ́rù, ó sì gbà wá ní ọjọ́ méjì ká tó dé ibẹ̀. Bẹ́ẹ̀ sì rèé o, kò ju ìrìn ọgbọ̀n ìṣẹ́jú lọ báyìí béèyàn bá wọ ọkọ̀ òfuurufú! Mánigbàgbé ni ọdún mẹ́rin tá a fi sìn ní ìlú Quito yìí jẹ́ fún wa. Lẹ́yìn náà, ní ọdún 1958, ohun rere mìíràn tún wáyé: Wọ́n ní ká máa sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká.

Nígbà yẹn, àyíká kékeré méjì péré ló wà ní gbogbo orílẹ̀-èdè náà. Torí náà, ní àfikún sí bíbẹ àwọn ìjọ wò, à ń fi ọ̀pọ̀ ọ̀sẹ̀ wàásù lọ́dọọdún ní àwọn ìlú kéékèèké tó wà ládùúgbò náà àmọ́ tí kò sí Ẹlẹ́rìí kankan tó ń gbé níbẹ̀. Ilé tá a máa ń dé sí láwọn abúlé wọ̀nyẹn sábà máa ń ní àwọn yàrá kékeré tí kò ní wíńdò tàbí ohunkóhun mìíràn yàtọ̀ sí bẹ́ẹ̀dì. A kó àwọn ohun tá a máa ń lò sínú àpótí onígi kan tá a máa ń gbé dání. Lára wọn ni ohun ìdáná tó ń lo epo, páànù, abọ́, bàsíà ìfabọ́, aṣọ ibùsùn, àpò ẹ̀fọn, aṣọ, ìwé ìròyìn ògbólógbòó àtàwọn nǹkan míì. Ńṣe la máa ń fi àwọn ìwé ìròyìn náà dí ojú ihò ara ògiri, kó lè ṣòro díẹ̀ fáwọn eku láti gba ibẹ̀ wọlé.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn iyàrá náà ṣókùnkùn tí wọ́n sì dọ̀tí, ìyẹn ò ní ká gbàgbé àwọn ìjíròrò tá a máa ń ní ní alaalẹ́ tá a bá jókòó sórí bẹ́ẹ̀dì wa tá a sì ń jẹ ìwọ̀nba oúnjẹ tá a sè lórí ohun ìdáná wa tó ń lo epo. Torí pé mo jẹ́ oníwàdùwàdù, èyí máa ń mú kí n sọ̀rọ̀ kí n tó ronú. Nígbà míì, ìyàwó mi máa ń lo irú àkókò tára àwa méjèèjì balẹ̀ yẹn láti sọ fún mi bí mo ṣe lè máa fi ọgbọ́n sọ̀rọ̀ lọ́nà tó sàn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ bí mo bá ń bá àwọn ará tá a lọ bẹ̀ wò sọ̀rọ̀. Mo máa ń tẹ́tí sí i, èyí sì mú kí ìbẹ̀wò mi túbọ̀ máa tu àwọn ará lára. Bákan náà, bí mo bá sọ̀rọ̀ tí kò dáa nípa ẹnì kan láìronú jinlẹ̀, ìyàwó mi kò ní dá sí mi. Nípa bẹ́ẹ̀, mo kọ́ láti máa sọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró nípa àwọn arákùnrin àti arábìnrin mi. Àmọ́ ṣá o, ohun tí ìjíròrò wa ní alaalẹ́ sábà máa ń dá lé ni àwọn kókó tá a bá kà nínú àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ àtàwọn ìrírí tá a bá rí nínú iṣẹ́ ìsìn pápá ní ọjọ́ yẹn. A sì ní ọ̀pọ̀ ìrírí tó ń múni lórí yá!

Bá A Ṣe Wá Carlos Kàn

Ní ìlú Jipijapa, ní ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Ecuador, wọ́n fún wa ní orúkọ olùfìfẹ́hàn kan. A kò mọ̀ ju Carlos Mejía tó jẹ́ orúkọ rẹ̀ lọ. A kò mọ àdírẹ́sì ibi tó ń gbé. Nígbà tá a kúrò ní ilé tá a háyà ní òwúrọ̀ ọjọ́ yẹn, a kò mọ ibi tó yẹ ká wá a sí, ńṣe la kàn ń gba ibi tá a bá ṣáà ti rí lọ. Ọ̀pọ̀ ibi tó rí gbágungbàgun lójú pópó tí òjò ńlá tó rọ̀ mọ́jú ti mú kó kún fún ẹrẹ̀ là ń pẹ́ sílẹ̀. Èmi wà níwájú, ìyàwó mi sì ń bọ̀ lẹ́yìn, àfi bó ṣe lọgun lójijì pé, “Arthur!” Mo yí pa dà bìrí mo sì rí pé ìyàwó mi ti rì sínú ẹrẹ̀, ẹrẹ̀ náà sì ti mù ún dé orúnkún. Ọ̀rọ̀ burúkú tòun tẹ̀rín ni ohun tó ṣẹlẹ̀ náà, àmọ́ mo gbé ẹ̀rín náà mì nígbà tí mo rí bí omijé ṣe lé ròrò ní ojú rẹ̀.

Mo fà á yọ kúrò nínú ẹrẹ̀ náà, àmọ́ bàtà rẹ̀ há sínú ẹrẹ̀. Ọmọdékùnrin àti ọmọdébìnrin kan ń wò wá, torí náà mo sọ́ fún wọn pe, “Màá fún yín ní owó tẹ́ ẹ bá lè yọ bàtà yẹn kúrò nínú ẹrẹ̀.” Ní kíá mọ́sá, wọ́n ti yọ bàtà náà jáde. Àmọ́, ó wá ku ibi tí ìyàwó mi ti máa rí omi ṣan ẹrẹ̀ tó wà lára rẹ̀ kúrò. Màmá àwọn ọmọ náà ń wo gbogbo ohun tó ń ṣẹlẹ̀, ó sì ní ká máa bọ̀ nílé òun. Ìgbà tá a débẹ̀, ó bá ìyàwó mi fọ ẹsẹ̀ rẹ̀ àwọn ọmọ rẹ̀ sì bá wa fọ bàtà tí wọ́n yọ nínú ẹrẹ̀ náà. Ká tó kúrò níbẹ̀, ohun rere kan ṣẹlẹ̀. Mo béèrè lọ́wọ́ obìnrin náà bóyá ó mọ ibi tá a ti lè rí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Carlos Mejía. Pẹ̀lú ìyàlẹ́nu, ó sọ pé, “Ọkọ mi ló ń jẹ́ bẹ́ẹ̀.” Kò pẹ́ tá a bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé náà sì ṣèrìbọmi lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Carlos, ìyàwó rẹ̀ àti méjì lára àwọn ọmọ wọn di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe.

A Rìnrìn Àjò Tó Nira Ṣùgbọ́n A Gbádùn Ìwà Ọ̀làwọ́ Tó Mọ́kàn Yọ̀

Ìpèníjà ló jẹ́ fún wa láti máa ti ibì kan lọ sí ibòmíì lẹ́nu iṣẹ́ àyíká. A máa ń wọ bọ́ọ̀sì, ọkọ̀ ojú irin, ọkọ̀ akẹ́rù, ọkọ̀ òbèlè àtàwọn ọkọ̀ òfuurufú kéékèèké. Nígbà kan, John McLenachan, tó sìn gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àgbègbè, àti ìyàwó rẹ̀, Dorothy, bá wa lọ sóde ẹ̀rí ní abúlé àwọn apẹja nítòsí ààlà orílẹ̀-èdè Kòlóńbíà. Ọkọ̀ òbèlè tó ń lo ẹ́ńjìnnì la wọ̀. Àwọn ẹja ekurá tó tóbi tó ọkọ̀ òbèlè náà ń lúwẹ̀ẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́ wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹni tó nírìírí ló ń tukọ̀ náà, síbẹ̀ ẹ̀rù bà á nígbà tó rí bí àwọn ẹja náà ṣe tóbi tó, ó sì yára tu ọkọ̀ náà sún mọ́ èbúté.

Àwọn ìṣòro tá a rí lẹ́nu iṣẹ́ àyíká kò já mọ́ nǹkan kan tá a bá fi wé àwọn àǹfààní tá a rí níbẹ̀. A mọ ọ̀pọ̀ àwọn ará tí wọ́n ṣe ohun tó jọjú, tí wọ́n sì hùwà ọ̀làwọ́ sí wa. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn ìdílé tá a máa ń dé bá lálejò máa ń rọ̀ wá pé ká jẹun lẹ́ẹ̀mẹ́ta lóòjọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo péré làwọn máa jẹun. Tàbí kẹ̀ kí wọ́n ní ká sun orí ibùsùn kan ṣoṣo tí wọ́n ní, àwọn á sì sùn sí ilẹ̀. Ìyàwó mi sábà máa ń sọ pé, “Àwọn arákùnrin àti arábìnrin ọ̀wọ́n yìí máa ń rán mi létí bó ṣe jẹ́ pé ìwọ̀nba ohun díẹ̀ la nílò láyé yìí.”

“A Kò Fẹ́ Láti Fà Sẹ́yìn”

Ní ọdún 1960, ohun rere mìíràn ṣẹlẹ̀ sí wa. Wọ́n ní ká wá máa sìn ní ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní orílẹ̀-èdè Guayaquil. Èmi wà nídìí iṣẹ́ àbójútó, Edith sì wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nínú ìjọ kan tó wà nítòsí ẹ̀ka ọ́fíìsì náà. Iṣẹ́ ọ́fíìsì ò bá mi lára mu torí náà ó ṣe mí bíi pé mi ò tóótun, àmọ́ gẹ́gẹ́ bí Hébérù 13:21 ṣe sọ, Ọlọ́run ń fun wa ní “ohun rere gbogbo . . . láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀.” Ní ọdún méjì lẹ́yìn náà, wọ́n pè mí sí Gílíádì fún ètò ẹ̀kọ́ olóṣù-mẹ́wàá kan tó wáyé ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn, New York. Nígbà yẹn, wọn kì í jẹ́ káwọn ìyàwó bá àwọn ọkọ wọn wá sí ilé ẹ̀kọ́ náà. Wọ́n kọ lẹ́tà kan sí ìyàwó mi láti Brooklyn. Wọ́n ní kó rò ó dáadáa bóyá ó máa lè fi ọkọ rẹ̀ sílẹ̀ fún oṣù mẹ́wàá tàbí kò ní lè ṣe bẹ́ẹ̀.

Ìyàwó mi fèsì pé: “Ó dá mi lójú pé èyí jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó máa nira fún mi láti ṣe, ṣùgbọ́n a mọ̀ dájú pé Jèhófà máa bá wa gbé ìṣòro èyíkéyìí tó bá yọjú. . . . A kò fẹ́ láti fà sẹ́yìn bí a bá fi àǹfààní èyíkéyìí lọ̀ wá tàbí bí a bá fún wa ní àǹfààní èyíkéyìí tó máa mú ká túbọ̀ tóótun láti ṣe àwọn ojúṣe tá a gbé lé wa lọ́wọ́.” Ní gbogbo àkókò tí mo lò ní Brooklyn, ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ ni mò ń rí lẹ́tà gbà látọ̀dọ̀ ìyàwó mi.

Sísìn Pẹ̀lú Àwọn Olùjọsìn Ẹlẹgbẹ́ Wa Tí Wọ́n Jẹ́ Olóòótọ́

Nítorí àìlera, èmi àti ìyàwó mi pa dà sí Quito lọ́dún 1966, a sì ń bá iṣẹ́ míṣọ́nnárì wa nìṣó pẹ̀lú àwọn arákùnrin àti arábìnrin tó wà ní àdúgbò náà. Àpẹẹrẹ àtàtà làwọn ará wọ̀nyẹn jẹ́ ní ti pípa ìwà títọ́ mọ́!

Arábìnrin olùṣòtítọ́ kan ní ọkọ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́, ìgbà gbogbo sì ni ọkọ rẹ̀ yìí máa ń lù ú. Lọ́jọ́ kan, ní agogo mẹ́fà òwúrọ̀, ẹnì kan pè wá láti sọ pé ọkọ rẹ̀ tún ti nà án. Mo sáré lọ sí ilé arábìnrin náà. Nígbà tí mo débẹ̀, ohun tí mo rí yà mí lẹ́nu. Orí bẹ́ẹ̀dì ló wà, ara ẹ̀ wú kódokòdo ó sì dáranjẹ̀. Igi búrọ́ọ̀ṣì tí wọ́n fi ń gbálẹ̀ ni ọkọ rẹ̀ fi lù ú títí tí igi náà fi ṣẹ́ sí méjì. Ó ṣe díẹ̀ lọ́jọ́ yẹn kí èmi àti ọkùnrin yìí tó fojú kanra, mo sì sọ fún un pé ńṣe ló fi egungun ọkùnrin yan obìnrin yẹn jẹ. Ó tọrọ àforíjì lọ́pọ̀ ìgbà.

Ní nǹkan bí ọdún mẹ́fà lẹ́yìn náà, ara mi ti yá dáadáa a sì pa dà sẹ́nu iṣẹ́ àyíká. Ìlú Ibarra wà lára àyíká tí à ń bẹ̀ wò. Nígbà tá a ṣèbẹ̀wò sí ìlú yẹn ní àárín ọdún 1957 sí ọdún 1959 àwọn Ẹlẹ́rìí méjì péré ni wọ́n wà níbẹ̀, míṣọ́nnárì kan àti arákùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ìlú náà. Torí náà, ara wa ti wà lọ́nà láti rí àwọn ẹni tuntun tí wọ́n ti dara pọ̀ mọ́ ìjọ náà.

Ní ìpàdé tá a kọ́kọ́ ṣe níbẹ̀, Arákùnrin Rodrigo Vaca dúró sórí pèpéle ó sì darí apá ìpàdé tó jẹ́ ìjíròrò pẹ̀lú àwùjọ. Nígbàkigbà tó bá béèrè ìbéèrè, dípò kí àwọn tó wà ní àwùjọ nawọ́, ńṣe ni wọ́n á máa sọ pé “Yo, yo!” (“Èmi, èmi!”). Ẹnu ya èmi àti Edith, a sì wojú ara wa. A ronú pé, ‘Kí ló ń ṣẹlẹ̀ yìí kẹ̀?’ Lẹ́yìn náà la wá mọ̀ pé afọ́jú ni Arákùnrin Vaca, àmọ́ ó dá ohùn ẹnì kọ̀ọ̀kan tó wà nínú àwùjọ mọ̀ bó bá gbọ́ ọ. Dájúdájú, ó jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn tó mọ àwọn àgùntàn rẹ̀ dáadáa! Èyí mú ká rántí ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nínú Jòhánù 10:3, 4, 14 nípa bí Olùṣọ́ Àgùntàn Àtàtà àti àwọn àgùntàn rẹ̀ ṣe mọ ara wọn dáadáa. Ní báyìí, ìjọ mẹ́fà tó ń sọ èdè Sípáníìṣì ló wà ní Ibarra, ìjọ kan tó ń sọ èdè Quechua àti ọ̀kan tó ń sọ èdè àwọn adití. Arákùnrin Vaca ń fi ìṣòtítọ́ sìn nìṣó gẹ́gẹ́ bí alàgbà àti aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. *

A Kún fún Ọpẹ́ Torí Oore Jèhófà

Lọ́dún 1974, Jèhófà tún nawọ́ oore rẹ̀ sí wa lọ́nà mìíràn, nígbà tí wọ́n ní ká máa pa dà bọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì. Wọ́n tún fi mí sídìí iṣẹ́ àbójútó, lẹ́yìn náà ni wọ́n sọ mí di ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka. Ilé ìgbọ́únjẹ ni Edith ti kọ́kọ́ ṣiṣẹ́, lẹ́yìn náà ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ ní ọ́fíìsì, ibẹ̀ ló ṣì wà gẹ́gẹ́ bí akọ̀wé tó ń bójú tó lẹ́tà.

Jálẹ̀ àwọn ọdún wọ̀nyí, a ti láyọ̀ láti kí ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn míṣọ́nnárì tó ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Èkọ́ Gílíádì káàbọ̀, bí wọ́n ti ń sọ ìjọ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n bá ti sìn di èyí tó dàgbà nípa tẹ̀mí tó sì ní ìtara. Àwa náà tún máa ń rí ìṣírí gbà látọ̀dọ̀ ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n wá láti orílẹ̀-èdè tó ju ọgbọ̀n lọ kí wọ́n lè sìn ní orílẹ̀-èdè yìí. Ẹ̀mí ìfara-ẹni-rúbọ wọn mà wú wa lórí gan-an ni o! Àwọn kan ta ilé àti okòwò wọn kí wọ́n lè wá sìn lórílẹ̀-èdè yìí, torí pé a nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Wọ́n ra àwọn ohun ìrìnnà kí wọ́n lè máa fi wàásù láwọn agbègbè àdádó, wọ́n dá àwọn ìjọ tuntun sílẹ̀, wọ́n sì kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba. Ọ̀pọ̀ àwọn arábìnrin tí kò tíì lọ́kọ ti òkè òkun wá láti wá ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà níbí. Ìtara wọ́n pọ̀, wọ́n sì ṣe gudugudu méje!

Dájúdájú, mo ti rí ọ̀pọ̀ ohun rere ní gbogbo ọdún tí mo ti fi ń sin Ọlọ́run. Èyí tó ga jù lọ nínú wọn ni àjọṣe tí mo ní pẹ̀lú Jèhófà. Bákan náà, mo dúpẹ́ pé Jèhófà fún mi ní “olùrànlọ́wọ́ kan.” (Jẹ́n. 2:18) Bí mo bá bojú wẹ̀yìn tí mo sì rántí pé ó ti lé ní ọdún mọ́kàndínláàádọ́rin [69] tá a ti jọ ń gbé gẹ́gẹ́ bíi tọkọtaya, ìwé Òwe 18:22 á wá sí mi lọ́kàn. Ó sọ pé: “Ẹnì kan ha ti rí aya rere bí? Ẹni náà ti rí ohun rere.” Ìbágbé èmi àti Edith tù mí lára gan-an ni. Ó ti ràn mí lọ́wọ́ ní ọ̀pọ̀ ọ̀nà. Ó tún jẹ́ ọmọ ọ̀wọ́n fún màmá rẹ̀. Látìgbà tá a ti dé sí orílẹ̀-èdè Ecuador ni ìyàwó mi ti máa ń fi lẹ́tà ránṣẹ́ sí màmá rẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ títí di ọdún 1990 nígbà tí màmá rẹ̀ kú ní ẹni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́rùn-ún [97].

Mo ti pé ọmọ àádọ́rùn-ún [90] ọdún báyìí, ìyàwó mi sì jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kàndínláàádọ́rùn-ún [89]. A mọyì àǹfààní tá a ní láti ran èèyàn tó tó àádọ́rin [70] lọ́wọ́ láti mọ Jèhófà, èyí sì máa ń fún wa láyọ̀ tó pọ̀. A tún máa ń láyọ̀ gan-an pé a gba fọ́ọ̀mù tá a fi béèrè fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ní ọgọ́ta [60] ọdún sẹ́yìn. Ìpinnu yẹn mú kí ìgbésí ayé wa kún fún ọ̀pọ̀ ohun rere.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Vaca wà nínú Jí! August 8, 1986.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Àwa àtàwọn míṣọ́nnárì tá a jọ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì lọ́dún 1958 rèé ní Pápá Ìṣeré Yankee ní ìlú New York

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

A lọ bẹ ìdílé Ẹlẹ́rìí kan wò nígbà tá a wà lẹ́nu iṣẹ́ àyíká lọ́dún 1959

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 32]

Àwa rèé ní ẹ̀ka ọ́fíìsì ti ìlú Ecuador, lọ́dún 2002