Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àsọtẹ́lẹ̀ 1. Ìsẹ̀lẹ̀

Àsọtẹ́lẹ̀ 1. Ìsẹ̀lẹ̀

Àsọtẹ́lẹ̀ 1. Ìsẹ̀lẹ̀

“Ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà yóò sì wà.”—LÚÙKÙ 21:11.

● Wọ́n yọ Winnie ọmọ ọdún kan àtoṣù mẹ́rin lábẹ́ àwókù ilé ní orílẹ̀-èdè Haiti. Àwùjọ oníròyìn fún ilé iṣẹ́ tẹlifíṣọ̀n tí wọ́n ń gbé ìròyìn nípa àjálù náà gbọ́ nígbà tó ń kérora lábẹ́ àwókù ilé náà. Ọmọbìnrin yìí kò kú nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀, ìyẹn ìmìtìtì ilẹ̀ yìí wáyé, àmọ́ àwọn òbí rẹ̀ kú.

KÍ NI Ẹ̀RÍ FI HÀN? Nígbà tí ìsẹ̀lẹ̀ tó lágbára gan-an [ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ 7.0] wáyé ní orílẹ̀-èdè Haiti ní January ọdún 2010, èèyàn tó ju ọ̀kẹ́ márùndínlógún [300,000] ló kú. Àwọn èèyàn mílíọ̀nù kan àti ọ̀kẹ́ márùndínlógún [1,300,000] ni wọ́n sì di aláìnílé lójú ẹsẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé, ìsẹ̀lẹ̀ tó wáyé ní orílẹ̀-èdè Haiti lágbára gan-an, síbẹ̀ kì í ṣe ibẹ̀ nìkan ni irú rẹ̀ ti wáyé. Ó kéré tán, ìmìtìtì ilẹ̀ méjìdínlógún tó lágbára ló wáyé kárí ayé láti oṣù April ọdún 2009 sí oṣù April ọdún 2010.

ÀTAKÒ TÁWỌN ÈÈYÀN Ń ṢE Kì í ṣe pé ìsẹ̀lẹ̀, ìyẹn ìmìtìtì ilẹ̀ tó pọ̀ ju ti tẹ́lẹ̀ ń wáyé, àmọ́ ìtẹ̀síwájú tó bá ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ló jẹ́ kí àwa èèyàn òde òní máa gbọ́ nípa àwọn ìmìtìtì ilẹ̀ tó ń wáyé ju àwọn èèyàn ayé àtijọ́ lọ.

ṢÉ ÀTAKÒ YÌÍ LẸ́SẸ̀ NÍLẸ̀? Ṣàgbéyẹ̀wò kókó yìí: Bíbélì kò sọ ní pàtó iye ìsẹ̀lẹ̀, ìyẹn ìmìtìtì ilẹ̀ tó máa wáyé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Àmọ́, ó sọ pé ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà” máa wáyé “láti ibì kan dé ibòmíràn,” èyí sì mú kí wọ́n jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ohun tó gbàfiyèsí tó máa wáyé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí.—Máàkù 13:8; Lúùkù 21:11.

KÍ NI ÈRÒ RẸ? Ṣé ìsẹ̀lẹ̀ tí Bíbélì sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ là ń rí lónìí?

Kì í ṣe ìsẹ̀lẹ̀ nìkan ló jẹ́ ẹ̀rí tó fi hàn pé à ń gbé láwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Àmọ́, ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ń ṣẹ. Ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò ìkejì.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

“Àwa [onímọ̀ nípa ìmìtìtì ilẹ̀] ń pè wọ́n ní ìsẹ̀lẹ̀ ńláǹlà. Àmọ́, àwọn èèyàn ń pè wọ́n ní àjálù tó burú jáì.”—KEN HUDNUT, U.S. GEOLOGICAL SURVEY.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

© William Daniels/Panos Pictures