Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Tó Dára Jù Ń Bọ̀ Lọ́jọ́ Iwájú!

Ohun Tó Dára Jù Ń Bọ̀ Lọ́jọ́ Iwájú!

Ohun Tó Dára Jù Ń Bọ̀ Lọ́jọ́ Iwájú!

“Àti pé ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—SÁÀMÙ 37:10, 11.

ṢÉ O fẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà lókè yìí ṣẹ? Ó dájú pé wàá fẹ́ kó rí bẹ́ẹ̀. Àwọn ìdí tó lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ wà pé ó máa tó ṣẹ.

Àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí sọ nípa àwọn kan lára àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì tó fi hàn kedere pé “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” la wà yìí. (2 Tímótì 3:1-5) Ọlọ́run mí sí àwọn tó kọ Bíbélì láti sọ àsọtẹ́lẹ̀ àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn kí á bàa lè ní ìrètí. (Róòmù 15:4) Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ yẹn ṣe ń ṣẹ fi hàn pé àwọn ìṣòro tí à ń dojú kọ nísinsìnyí yóò dópin láìpẹ́.

Kí ló máa wáyé lẹ́yìn àwọn ọjọ́ ìkẹyìn? Ìjọba Ọlọ́run máa ṣàkóso gbogbo aráyé. (Mátíù 6:9) Wo ohun tí Bíbélì sọ nípa bí ipò ayé ṣe máa rí nígbà yẹn:

Kò ní sí ebi mọ́. “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Sáàmù 72:16.

Kò ní sí àrùn mọ́. “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.

Ilẹ̀ ayé máa di ọ̀tun. “Aginjù àti ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí sáfúrónì.”—Aísáyà 35:1.

Èyí jẹ́ díẹ̀ lára àsọtẹ́lẹ̀ amóríyá tí Bíbélì sọ, tí yóò ṣẹ láìpẹ́. O kò ṣe ní kí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ìdí tó fi dá wọn lójú hàn ẹ́ pé ohun tó dára jù ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú.