Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Ibi àti Ìjìyà?

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Ibi àti Ìjìyà?

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìwà Ibi àti Ìjìyà?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a béèrè àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa ṣe kàyéfì nípa wọn, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí ohun tí àwọn ìdáhùn náà jẹ́.

1. Báwo ni ìwà ibi ṣe bẹ̀rẹ̀?

Ìwà ibi bẹ̀rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé nígbà tí Sátánì pa irọ́ àkọ́kọ́. Ẹni ibi kọ́ ni áńgẹ́lì tó di Sátánì nígbà tí Ọlọ́run dá a. Áńgẹ́lì pípé ni, àmọ́ kò “dúró ṣinṣin nínú òtítọ́.” (Jòhánù 8:44) Ó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ ìjọsìn tó jẹ́ ti Ọlọ́run nìkan. Sátánì purọ́ fún Éfà, obìnrin àkọ́kọ́, ó sì yí i lérò pa dà láti ṣègbọràn sí òun dípò Ọlọ́run. Ádámù dara pọ̀ mọ́ Éfà láti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run. Ohun tí Ádámù ṣe yìí yọrí sí ìjìyà àti ikú.—Ka Jẹ́nẹ́sísì 3:1-6, 17-19.

Nígbà tí Sátánì sọ pé kí Éfà ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run, ńṣe ló ń ṣọ̀tẹ̀ sí ipò Ọlọ́run gẹ́gẹ́ ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Ọ̀pọ̀ jù lọ aráyé ti dara pọ̀ mọ́ Sátánì, wọn kò sì gbà kí Ọlọ́run jẹ́ Olùṣàkóso wọn. Sátánì tipa báyìí di “olùṣàkóso ayé.”—Ka Jòhánù 14:30; Ìṣípayá 12:9.

2. Ǹjẹ́ àwọn nǹkan tí Ọlọ́run dá ní àbùkù?

Ọlọ́run dá èèyàn àti áńgẹ́lì, wọ́n sì lè pa àwọn àṣẹ Ọlọ́run mọ́ délẹ̀délẹ̀. (Diutarónómì 32:5) Ọlọ́run dá àwa èèyàn pẹ̀lú òmìnira láti yan ohun rere tàbí ohun búburú. Òmìnira yẹn fún wa láǹfààní láti fi ìfẹ́ tá a ní fún Ọlọ́run hàn.—Ka Jákọ́bù 1:13-15; 1 Jòhánù 5:3.

3. Kí nìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà?

Fún àkókò kan, Jèhófà ti fàyè gba ọ̀tẹ̀ tí wọ́n ṣe sí ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. Kí nìdí tó fi fàyè gbà á? Ìdí ni pé, ó fẹ́ fi hàn pé ìsapá èyíkéyìí láti ṣàkóso láìsí ọwọ́ òun níbẹ̀ kò lè ṣe aráyé láǹfààní. (Jeremáyà 10:23) Ó sì ti hàn kedere pé òótọ́ lọ̀rọ̀ yẹn lẹ́yìn ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́fà tí ẹ̀dá èèyàn ti wà. Àwọn alákòóso èèyàn ti kùnà láti mú ogun, ìwà ọ̀daràn, àìṣẹ̀tọ́ àti àrùn kúrò.—Ka Oníwàásù 7:29; 8:9; Róòmù 9:17.

Àmọ́ ṣá o, àwọn tó gbà pé kí Ọlọ́run jẹ́ Olùṣàkóso wọn ti ṣe ara wọn láǹfààní. (Aísáyà 48:17, 18) Láìpẹ́, Jèhófà máa pa gbogbo ìjọba àwọn èèyàn run. Àwọn èèyàn tó gbà kí Ọlọ́run máa ṣàkóso àwọn ni á máa gbé lórí ilẹ̀ ayé.—Aísáyà 2:3, 4; 11:9; ka Dáníẹ́lì 2:44.

4. Àǹfààní wo ni sùúrù Ọlọ́run fún wa?

Sátánì sọ pé àwọn èèyàn kò ní ṣègbọràn sí Ọlọ́run tọkàntọkàn. Sùúrù Ọlọ́run fún gbogbo wa láǹfààní láti fi hàn bóyá ìṣàkóso Ọlọ́run la fara mọ́ tàbí ìṣàkóso èèyàn. Ọ̀nà tí a ń gbà gbé ìgbé ayé wa ló ń fi ohun tí a fẹ́ hàn.—Ka Jóòbù 1:8-11; Òwe 27:11.

5. Báwo la ṣe ń fi hàn pé Ọlọ́run ni Olùṣàkóso wa?

À ń fi hàn pé Ọlọ́run ni Olùṣàkóso wa tí a bá wá ìjọsìn tòótọ́ tó bá Bíbélì mu, tí a sì ń ṣe é. (Jòhánù 4:23) Ohun míì ni pé, bíi ti Jésù, a kò ní lọ́wọ́ nínú ìṣèlú àti ogun.—Ka Jòhánù 17:14.

Sátánì ń lo agbára rẹ̀ láti gbé ìṣekúṣe àtàwọn ìwàkiwà lárugẹ. Àmọ́, tí a bá kọ̀ láti lọ́wọ́ nínu irú àwọn ìwà bẹ́ẹ̀, àwọn kan lára àwọn ọ̀rẹ́ àti ẹbí wa lè máa fi wá ṣe yẹ̀yẹ́ tàbí kí wọ́n máa ta kò wá. (1 Pétérù 4:3, 4) Tóò, ó kù sí wa lọ́wọ́ láti yan èyí tá a máa ṣe. Ṣé àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run ni a óò máa bá rìn? Ṣé a ó ṣègbọràn sí àwọn òfin rẹ̀ onífẹ̀ẹ́ tó sì bọ́gbọ́n mu? Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe là ń fi hàn pé irọ́ ni Sátánì pa nígbà tó sọ pé kò sí ẹni tó lè ṣe ohun tí Ọlọ́run fẹ́.—Ka 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10; 15:33.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 11 ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Ádámù yan ohun tó burú

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ohun tí a bá yàn ló máa fi hàn pé a fẹ́ kí Ọlọ́run jẹ́ Olùṣàkóso wa