Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Èèyàn Àlàáfíà Gbèjà Orúkọ Rere Wọn

Àwọn Èèyàn Àlàáfíà Gbèjà Orúkọ Rere Wọn

ÀKÍYÈSÍ FÚN ÀWỌN OLÙGBÉ ILẸ̀ RỌ́ṢÍÀ: Tí wọ́n bá tẹ ohun tá a fẹ́ sọ yìí jáde, ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn tó ń gbé ní ilẹ̀ tó lé ní igba àti ọgbọ̀n [230] ló máa mọ̀ nípa bí ilẹ̀ Rọ́ṣíà kò ṣe fàyè gba òmìnira ìjọsìn. Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ ni ìwé ìròyìn tí wọ́n ń túmọ̀ sí èdè tó pọ̀ jù lọ tí wọ́n sì ń pín káàkiri jù lọ láyé. A máa túmọ̀ àpilẹ̀kọ yìí sí èdè ọgọ́sàn-án ó lé mẹ́jọ[188]. Ẹ̀dà tó lé ní ogójì mílíọ̀nù [40,000,000] la máa tẹ̀ jáde. Àwọn aláṣẹ kan lè máà fẹ́ kí gbogbo ayé mọ̀ nípa ohun tó n ṣẹlẹ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Rọ́ṣíà. Àmọ́ ọ̀rọ̀ Jésù ló máa ṣẹ, ó ní: “Kò sí ohun kan tí a rọra fi pa mọ́ tí a kì yóò ṣí payá, àti àṣírí tí kì yóò di mímọ̀.”—LÚÙKÙ 12:2.

NÍ December ọdún 2009 àti January ọdún 2010, méjì lára àwọn ilé ẹjọ́ gíga jù lọ nílẹ̀ Rọ́ṣíà kéde pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ agbawèrèmẹ́sìn. Irú nǹkan yìí ti ṣẹlẹ̀ rí. Nígbà tí ìjọba Soviets ń ṣàkóso ilẹ̀ Rọ́ṣíà, wọ́n fẹ̀sùn èké kan ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé ọ̀tá orílẹ̀-èdè náà ni wọ́n. Wọ́n kó wọn lọ sí ìgbèkùn, ẹ̀wọ̀n àti àwọn àgọ́ tí wọ́n ti ń fi àwọn èèyàn ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó. Wọ́n dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sílẹ̀ nígbà tí ìjọba yẹn forí ṣánpọ́n. Ìjọba tuntun wá kéde pé èèyàn rere ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. * Àmọ́ ní báyìí, àwọn èèyàn kan tún fẹ́ ba àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórúkọ jẹ́.

Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2009, àwọn aláṣẹ gbẹ́sẹ̀ lé òmìnira ẹ̀sìn tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní. Ní oṣù February nìkan, àwọn amòfin ṣe ìwádìí tó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún lọ káàkiri ilẹ̀ Rọ́ṣíà. Kí nìdí tí wọ́n fi ṣe àwọn ìwádìí náà? Ó jẹ́ nítorí kí wọ́n lè rí ẹ̀rí ohun táwọn èèyàn sọ pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti rú òfin. Ní àwọn oṣù tó tẹ̀ lé e, àwọn ọlọ́pàá lọ gbéjà ko àwọn èèyàn àlàáfíà níbi tí wọ́n ti ń ṣe ìpàdé ẹ̀sìn ní àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti nínú àwọn ilé àdáni. Wọ́n fipá gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àtàwọn ohun ìní wọn. Àwọn aláṣẹ tún ní kí àwọn agbẹjọ́rò ilẹ̀ òkèèrè tó wá gbèjà àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi orílẹ̀-èdè náà sílẹ̀ ní tipátipá, pé wọ́n kò gbọ́dọ̀ pa dà wá mọ́.

Ní October 5, ọdún 2009, àwọn ọlọ́pàá aṣọ́bodè gba ẹrù ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ibodè tó wà nítòsí ìlú St. Petersburg. Orílẹ̀-èdè Jámánì ni wọ́n ti tẹ àwọn ìwé náà, wọ́n sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí ọ̀pọ̀ ìjọ ní Rọ́ṣíà. Àwọn àkànṣe aṣọ́bodè tí wọ́n máa ń ṣàyẹ̀wò àwọn ẹrù òfin tó léwu ṣàyẹ̀wò ẹrù ìwé náà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ìwé kan látọ̀dọ̀ ìjọba sọ pé, ẹrù náà “lè ní àwọn ìwé tó máa dá yánpọnyánrin sílẹ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn.”

Kò pẹ́ tí ìhalẹ̀mọ́ni yìí fi burú sí i. Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà àti ní Altay Republic (apá kan Rọ́ṣíà) sọ pé àwọn kan lára ìtẹ̀jáde àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, títí kan ìwé ìròyìn tí ò ń kà yìí jẹ́ ti àwọn agbawèrèmẹ́sìn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn, àwọn orílẹ̀-èdè ayé dá sí ọ̀ràn náà, àmọ́ ilé ẹjọ́ náà kò yí ọ̀ràn náà pa dà! Ìdájọ́ náà kò yí padà, ìyẹn sì sọ kíkó àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọ orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà àti pínpín wọn di ohun tí kò bófin mu.

Kí ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ṣe sí bí wọ́n ṣe fẹ́ bà wọ́n lórúkọ jẹ́ yìí àti bí wọ́n ṣe fẹ́ gbẹ́sẹ̀ lé iṣẹ́ wọn? Kí ni ìdájọ́ tí Ilé Ẹjọ́ ṣe yìí máa ṣe fún òmìnira ìsìn àwọn olùgbé Rọ́ṣíà?

Ohun Tí Wọ́n Ṣe sí Ìhalẹ̀mọ́ni Tó Ń Pọ̀ Sí I Yìí

Lọ́jọ́ Friday, February 26, ọdún 2010, nǹkan bí ọ̀kẹ́ mẹ́jọ [160,000] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jákèjádò ilẹ̀ Rọ́ṣíà bẹ̀rẹ̀ sí í pín mílíọ̀nù méjìlá àkànṣe ìwé àṣàrò kúkúrú tó ṣàlàyé ohun tójú àwọn Ẹlẹ́rìí ń rí, wọ́n pe àkòrí rẹ̀ ní Could It Happen Again? A Question for the Citizens of Russia. Bí àpẹẹrẹ, ní ìlú Usol’ye-Sibirskoye tó wà ní Siberia, nǹkan bí irínwó [400] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà péjọ sí òpópónà ní aago márùn-ún ààbọ̀ ìdájí. Àwọn kan lára wọn sì jẹ́ àwọn tí wọ́n kó wá sí ìgbèkùn ní Siberia lọ́dún 1951 nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Wọ́n sì fara da òtútù yìnyín tó lágbára gan-an (tó jẹ́ ìwọ̀n -40°C.) nígbà tí wọ́n pín ọ̀kẹ́ kan [20,000] ìwé àṣàrò kúkúrú tí wọ́n ní kí wọ́n pín.

Nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa ìpolongo ọlọ́jọ́ mẹ́ta náà, wọ́n bá àwọn oníròyìn ṣèpàdé ní ìlú Moscow, tó jẹ́ olú ìlú Rọ́ṣíà. Lára àwọn tí wọ́n pè kó wá sọ̀rọ̀ níbẹ̀ ni Ọ̀gbẹ́ni Lev Levinson tó jẹ́, ọ̀jọ̀gbọ́n láti Àjọ tó ń rí sí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn. Ó sọ ní ṣókí nípa ìwà ìkà àti inúnibíni tí wọ́n ṣe sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà Ìjọba Násì àti ìjọba Soviet Union, ó sì sọ nípa bí ìjọba ṣe dá wọn sílẹ̀. Ó tún sọ pé: “Gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn tí wọ́n ṣenúnibíni sí nígbà ìjọba Soviet ni Ààrẹ Yeltsin pàṣẹ pé kí wọ́n dá láre. Kí wọ́n sì dá gbogbo nǹkan tí wọ́n pàdánù pa dà fún wọn. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò ní ohun ìní kan pàtó nígbà ìjọba Soviet Union, àmọ́, wọ́n jèrè orúkọ rere wọn pa dà.”

Wọ́n tún ti ń halẹ̀ láti ba orúkọ rere yìí jẹ́ o! Ọ̀gbẹ́ni Levinson sọ pé, “Nínú orílẹ̀-èdè kan náà tó kábàámọ̀ ohun tó ṣe sáwọn èèyàn yìí nígbà kan rí, ni wọ́n tún ti ń ṣe inúnibíni sáwọn èèyàn yìí láìnídìí.”

Ìpolongo Náà Wọ Àwọn Èèyàn Lọ́kàn

Ǹjẹ́ ìpolongo ìwé àṣàrò kúkúrú náà ṣe ohun tí wọ́n fẹ́ kó ṣe? Ọ̀gbẹ́ni Levinson sọ pé: “Nígbà tí mò ń bọ̀ wá sí ìpàdé [àwọn oníròyìn] yìí, mo rí àwọn kan láàárín ìlú tí wọ́n ń ka ìwé àṣàrò kúkúrú tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pín jákèjádò ilẹ̀ Rọ́ṣíà lónìí. . . . Àwọn èèyàn jókòó wọ́n ń ka ìwé náà, wọ́n sì ń fiyè sí ohun tí wọ́n ń kà.” * Bí àpẹẹrẹ, kíyè sí àwọn ìrírí tó tẹ̀ lé yìí.

Ìyá àgbà kan tó ń gbé lágbègbè táwọn Mùsùlùmí pọ̀ sí ní àárín gbùngbùn ilẹ̀ Rọ́ṣíà gba ìwé àṣàrò kúkúrú náà, ó sì béèrè ohun tó wà fún. Nígbà tí wọ́n sọ fún pé, ìwé yìí ṣàlàyé ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti òmìnira nílẹ̀ Rọ́ṣíà, ó lọgun pé: “Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, àwọn kan pe àfiyèsí sí ọ̀rọ̀ yìí! Èyí fi hàn pé, ilẹ̀ Rọ́ṣíà ti pa dà sí àkókò ìjọba Soviet Union. Ẹ ṣeun gan-an ni. Iṣẹ́ lẹ ṣe!”

Obìnrin kan ní Chelyabinsk tí wọ́n fún ní ìwé àṣàrò kúkúrú sọ pé: “Mo ti gba ìwé yìí, mo sì ti kà á. Mo wà lẹ́yìn yín gbágbáágbá. Mi ò tíì rí àwọn ẹlẹ́sìn míì tí wọ́n lè gbèjà ìgbàgbọ́ wọn lọ́nà tó wà létòletò báyìí. Ìmúra yín wù mí, gbogbo ìgbà lẹ sì máa ń fọgbọ́n ṣe nǹkan. Ó dájú pé, ohun tẹ́ ẹ gbà gbọ́ dá a yín lójú. Lójú tèmi, Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”

Ní ìlú St. Petersburg, wọ́n béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin kan tó lóun tí gba ìwé àṣàrò kúkúrú náà bóyá ó nífẹ̀ẹ́ sí ohun tó kà. Ó ní, “Bẹ́ẹ̀ ni. Nígbà tí mò ń kà á, ńṣe ni ara mi ń bù máṣọ, mo sì sunkún. Àwọn aláṣẹ fipá mú màmá mi àgbà pé kó máa ṣe ohun tí àwọn fẹ́ [nígbà ìjọba Soviet] ó sì sọ ọ̀pọ̀ nǹkan fún mi nípa àwọn tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n pẹ̀lú rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ló jẹ́ ọ̀daràn, ṣùgbọ́n, àwọn kan tún wà tí wọn kò ṣe nǹkan kan àmọ́ tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn. Mo rò pé, ó yẹ kí gbogbo èèyàn mọ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ náà, nítorí náà, ohun tó tọ́ lẹ̀ ń ṣe.”

Kí Ló Lè Ṣẹlẹ̀ Nílẹ̀ Rọ́ṣíà Lọ́jọ́ Iwájú?

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọrírì òmìnira tí wọ́n gbádùn fún ogún ọdún sẹ́yìn nílẹ̀ Rọ́ṣíà. Síbẹ̀, wọ́n mọ̀ pé ìgbàkigbà ni wọ́n lè gbẹ́sẹ̀ lé òmìnira náà. Ohun tó bá ṣẹlẹ̀ ló máa pinnu bóyá ìbanilórúkọjẹ́ tí wọ́n ń ṣe sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yìí jẹ́ àmì pé ilẹ̀ Rọ́ṣíà tún ti fẹ́ pa dà sí àkókò ìfìyàjẹni míì.

Àmọ́ ṣá o, ohun yòówù tí ì bá ṣẹlẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti pinnu pé àwọn á máa bá a nìṣó láti máa wàásù ọ̀rọ̀ nípa àlàáfíà àti ìrètí tó wà nínú Bíbélì. Ìwé àṣàrò kúkúrú tí wọ́n pín lákànṣe náà ṣàkópọ̀ ìpinnu wọn pé: “Ìfipá-múni yìí kò ní yọrí sí rere. A kò ní jáwọ́ nínú fífi ọgbọ́n àti ọ̀wọ̀ sọ̀rọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run àti Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀. (1 Pétérù 3:15) A kò jáwọ́ nígbà tí ìjọba Násì hùwà òǹrorò sí wa, a kò jáwọ́ nígbà tí orílẹ̀-èdè wa fipá mú wa pé ká ṣe ohun tí àwọn fẹ́, a kò sì ní jáwọ́ nísinsìnyí.—Ìṣe 4:18-20.”

^ Wo àpótí náà,  “Ìwé Ẹ̀rí Ìdáláre.”

^ Ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Moscow ti bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé àṣàrò kúkúrú náà ní wákàtí mélòó kan ṣáájú ìpàdé náà.