Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Ń Dún Bí Orin Aládùn Kan

Ó Ń Dún Bí Orin Aládùn Kan

Lẹ́tà Láti Orílẹ̀-èdè Madagásíkà

Ó Ń Dún Bí Orin Aládùn Kan

ÈMI àti ọkọ mi gbéra ìrìn-àjo, à ń lọ sí orílẹ̀-èdè Madagásíkà níbi tí wọ́n ní ká ti lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì. A dágbére fún àwọn èèyàn wa, a ṣọkàn gírí, a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pé yóò sì ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí níbi tó rán wa lọ.

A kò lè gbàgbé ìpàdé àkọ́kọ́ tá a ṣe níbi tí wọ́n rán wa lọ. Ńṣe ló dà bíi pé arákùnrin tó darí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ lọ́jọ́ yẹn ń darí ẹgbẹ́ akọrin kan. A kò mọ nǹkan kan nípa èdè náà rárá débi pé, ńṣe ni ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn sọ ń dún bí orin aládùn létí wa. Ó máa pẹ́ gan-an ká tó lè sọ pé a lóye ohun tí àwọn èèyàn ń sọ.

Lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tí mo lóye ìbéèrè tí kò sí nínú ìwé tí ẹni tó ń darí ìpàdé béèrè, ńṣe ni mo dáhùn ìbéèrè náà lójijì, ohùn mi sì lọ sókè. Àwọn tó jókòó sítòsí mi gbọ́, ńṣe ni mo fọwọ́ bo ẹnu mi káwọn èèyàn má bàa gbọ́ ẹ̀rín mi. Ojú tì mí, àmọ́ inú mi dùn nítorí pé mo lóye ohun tí wọ́n sọ!

Dípò kí n máa kọ́ àwọn èèyàn bí wọ́n ṣe máa wàásù, mo wá di ẹni tí wọ́n ń kọ́. Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin fi ìfẹ́ kọ́ mi bí mo ṣe lè wàásù lọ́nà tó máa yé àwọn èèyàn, wọ́n kọ́ mi ní ọ̀rọ̀ tí mo máa sọ àti ẹsẹ Bíbélì tí mo máa kà.

Mo rántí ọjọ́ kan tí mò ń wàásù, ọmọ kan bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo, ó sì ń pè mí ní, “Vazaha! Vazaha!” Ohun tí wọ́n sábà máa ń pe “àjèjì” nìyẹn ní èdè Malagásì. Ńṣe la tẹsẹ̀ mọ́ ìrìn kí àwọn ọmọ yòókù tó gbọ́, tí àwọn náà á sì máa pè wá bẹ́ẹ̀. Nígbà tó yá, ọmọkùnrin kan ní kí ọmọ tó ń pariwo náà dákẹ́. Ó sọ fún ọmọ náà pé, “Obìnrin yìí kì í ṣe àjèjì, ó lè sọ èdè wa!” Arábìnrin tá a jọ jáde ló sọ ìtúmọ̀ ọ̀rọ̀ náà fún mi, nítorí pé ẹnu wọ́n ti yá jù fún mi láti lóye ohun tí wọ́n ń sọ. Síbẹ̀, inú mi dùn pé mo ti ń tẹ̀ síwájú. Nígbà tó yá, orílẹ̀-èdè Madagásíkà bẹ̀rẹ̀ sí í mọ́ wa lára.

Nígbà tó bá ṣe mí bíi pé mo dánìkan wà, inú mi máa ń dùn gan-an bí àwọn ọmọ kékeré ṣe máa ń jẹ́ kí n mọ̀ pé àwọn fẹ́ràn mi bó tilẹ̀ jẹ́ pé mi ò lè sọ èdè wọn dáadáa, wọ́n máa ń di ọwọ́ mi mú, ó sì ju ìgbà kan lọ tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀. Ìbùkún látọ̀dọ̀ Jèhófà làwọn ọmọ kéékèèké tó wà nínú ìjọ wa jẹ́. Arábìnrin kékeré kan tó ń jẹ́, Hasina, ló máa ń bá mi túmọ̀ ohun tí mo bá sọ. Tí ẹnì kankan kò bá tiẹ̀ lóye mi, ó jọ pé ọmọbìnrin yìí lóye mi. Ó sì sábà máa ń ràn mí lọ́wọ́ nígbà tí mo bá ń bá àwọn ọ̀rẹ́ mi tó wà nínú ìjọ sọ̀rọ̀, ó máa ń bá mi ṣàlàyé ohun tí mo fẹ́ sọ gan-an.

Inú ìjọ tí wọ́n ò ní pẹ́ yọ ìjọ tuntun lára rẹ̀ ni èmi àti ọkọ mi wà. Èyí sì gba pé kí àwọn tó ń bá àwọn kan ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tẹ́lẹ̀ gbé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà fún àwọn ẹlòmíì, ìdí ni pé àgbègbè tí ìjọ tuntun náà wà ni àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ń gbé. Arábìnrin kan ní kí n máa bá òun ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ọ̀kan lára àwọn tó ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àyà mi já, mo sì sọ fún un pé mi ò tíì lè ṣe é, àmọ́ ó gbà mí níyànjú pé kí n ṣe é. Ó fi dá mi lójú pé, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, mo lè ṣe é. Ó fìfẹ́ àti ohùn jẹ́jẹ́ bá mi sọ̀rọ̀, èdè tó rọrùn gan-an ló sì lò, ó ní, kò ní pẹ́ mọ́ tí màá fi lè máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ bí mo ṣe fẹ́. Ọ̀rọ̀ yẹn fún mi níṣìírí gan-an ni.

Látìgbà yẹn, akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà ti tẹ̀ síwájú gan-an. Lọ́jọ́ kan tí mo wà ní ìta, mo gbọ́ tí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà pe orúkọ mi. Òun àti ọkọ rẹ̀ ń lọ forúkọ ìgbéyàwó wọn sílẹ̀ lọ́dọ̀ ìjọba. Ọkọ rẹ̀ náà ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àwọn méjèèjì ń sapá láti tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run, títí kan pé kí wọ́n lè ṣe ìrìbọmi. Èyí mú inú mi dùn gan-an, bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo mọ̀ pé Jèhófà ló ń fa àwọn èèyàn wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀ kì í ṣe àwa.

Ọ̀pọ̀ nǹkan la ti kọ́ níbi tí wọ́n yàn wá sí yìí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àárò ìdílé wa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa máa ń sọ wá, ńṣe ló dà bíi pé wọ́n wà pẹ̀lú wa. A sábà máa ń sọ̀rọ̀ nípa wọn fún àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tó wà níbí, nígbà tó yá, àwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí í béèrè àlàáfíà wọn lọ́wọ́ wa. À ń fojú sọ́nà fún àkókò tí àwọn ọ̀rẹ́ wa níbí àtàwọn ìdílé wa yóò rí ara wọn.

Ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn ń sọ ṣì máa ń dún bí orin ní etí mi. Àmọ́ ní báyìí, mo ti ń lóye àwọn ọ̀rọ̀ náà. Mò ń fojú sọ́nà fún àkókò kan tí èmi náà á lè máa sọ èdè yìí lọ́nà tó já gaara dípò kí n máa sọ ọ́ gátagàta. Jésù sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé nípa ọ̀la, nítorí ọ̀la yóò ní àwọn àníyàn tirẹ̀.” (Mátíù 6:34) Nítorí náà, ọ̀rọ̀ tàbí gbólóhùn díẹ̀díẹ̀ là ń kọ́ lẹ́ẹ̀kan náà. Àmọ́ nísinsìnyí, màá túbọ̀ máa fetí sílẹ̀ dáadáa, màá sì máa ronú dáadáa kí n bàa lè máa sọ èdè yìí bí mo ti ń bá àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin mi onífẹ̀ẹ́ tí wọ́n sì jẹ́ onísùúrù yìí ṣiṣẹ́ ní Madagásíkà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Èmi àti Hasina ń wàásù