Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó Yẹ Kí Àwọn Ọmọdé Ṣe Ìrìbọmi?

Ṣó Yẹ Kí Àwọn Ọmọdé Ṣe Ìrìbọmi?

Ṣó Yẹ Kí Àwọn Ọmọdé Ṣe Ìrìbọmi?

ARÁKÙNRIN CARLOS * tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Philippines, sọ nípa ọmọbìnrin rẹ̀ pé: “Inú mi dùn gan-an pé ọmọbìnrin mi ti di ìránṣẹ́ Jèhófà báyìí, mo sì mọ̀ pé inú òun pẹ̀lú dùn.” Bàbá mìíràn tó kọ̀wé láti orílẹ̀-èdè Gíríìsì sọ pé: “Inú èmi àti ìyàwó mi dùn pé àwọn ọmọ wa mẹ́tẹ̀ẹ̀ta ṣèrìbọmi wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà tí wọ́n ṣì wà lọ́dọ̀ọ́. Wọ́n ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, inú wọn sì dùn pé wọ́n ń sin Jèhófà.”

Bí àwọn ọmọ tí òbí wọ́n jẹ́ Kristẹni bá ṣe ìrìbọmi, inú àwọn òbí náà sábà máa ń dùn gan-an. Síbẹ̀, ìgbà míì wà tí ọkàn àwọn òbí náà kì í balẹ̀. Ìyá kan sọ pé: “Inú mi dùn gan-an, síbẹ̀ àyà mi ń já.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ìyá yìí dùn, kí ló ń já a láyà? Ó sọ pé: “Mo mọ̀ pé ọmọ mi ló máa dáhùn níwájú Jèhófà fún ohunkóhun tó bá ṣe lẹ́yìn ìrìbọmi.”

Ó yẹ kí gbogbo àwọn ọmọdé fi ṣíṣe ìrìbọmi ṣe àfojúsùn wọn kí wọ́n lè máa sin Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀. Síbẹ̀, àwọn òbí tó bẹ̀rù Ọlọ́run lè máa ronú pé, ‘Mo mọ̀ pé ọmọ mi ń ṣe dáadáa lóòótọ́, àmọ́ bí wọ́n bá ń fi ìṣekúṣe lọ̀ ọ́ ṣé ó lè kọ̀ kó sì máa bá a nìṣó láti wà ní mímọ́ lójú Jèhófà?’ Àwọn òbí míì lè bi ara wọn pé, ‘Ṣé ọmọ mi á ṣì máa fi ayọ̀ àti ìtara sin Ọlọ́run bí àwọn ojúgbà rẹ̀ bá ń kó ohun ìní tara jọ?’ Ǹjẹ́ ìtọ́ni èyíkéyìí tiẹ̀ wà nínú Ìwé Mímọ́ tó lè ran àwọn òbí lọ́wọ́ láti mọ̀ bóyá ọmọ wọ́n ti tóótun láti ṣe ìrìbọmi?

Kí Ló Lè Mú Kí Ẹnì Kan Tóótun Láti Ṣe Ìrìbọmi?

Bíbélì kò sọ iye ọmọ ọdún téèyàn gbọ́dọ̀ jẹ́ kó tó lè ṣe ìrìbọmi. Àmọ́, kí ẹnì kan tó lè tóótun láti ṣe ìrìbọmi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ irú àjọṣe tó gbọ́dọ̀ ní pẹ̀lú Jèhófà. Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni pé: “Ẹ lọ sọ gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ-ẹ̀hìn mi; kí ẹ máa ṣe ìrìbọmi fún wọn.” (Mát. 28:19, Ìròyìn Ayọ̀) Torí náà, lẹ́yìn téèyàn bá ti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi ló tó lè ṣe ìrìbọmi.

Àwọn wo ni ọmọ ẹ̀yìn? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Insight on the Scriptures, ṣàlàyé pé: “Àwọn tí ọ̀rọ̀ náà sábà máa ń tọ́ka sí ni àwọn tó gba ẹ̀kọ́ Kristi gbọ́, tí wọ́n sì tún ń tẹ̀ lé e pẹ́kípẹ́kí.” Ǹjẹ́ àwọn ọmọdé lè di ojúlówó ọmọ ẹ̀yìn Kristi? Arábìnrin kan tó ti ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní ilẹ̀ Látìn Amẹ́ríkà fún ohun tó lé ní ogójì [40] ọdún sọ nípa ara rẹ̀ àtàwọn obìnrin méjì tí wọ́n jọ jẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò pé: “A kò kéré jù láti mọ̀ pé a fẹ́ láti sin Jèhófà ká lè gbé nínú Párádísè. Bá a ṣe ya ara wa sí mímọ́ ràn wá lọ́wọ́ láti kojú àwọn ìdẹwò tó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ọ̀dọ́. A kò kábàámọ̀ pé láti kékeré la ti ya ara wa sí mímọ́ fún Ọlọ́run.”

Báwo lo ṣe lè mọ̀ bí ọmọ rẹ bá ti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi? Bíbélì sọ pé: “Àní nípa àwọn ìṣe rẹ̀, ọmọdékùnrin kan ń mú kí a dá òun mọ̀, ní ti bóyá ìgbòkègbodò rẹ̀ mọ́ gaara tí ó sì dúró ṣánṣán.” (Òwe 20:11) Ìsọ̀rí tó kàn sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìṣe tàbí ìwà tó lè fi hàn pé ọmọ kan ti ń jẹ́ ‘kí ìlọsíwájú òun fara hàn kedere’ gẹ́gẹ́ bí ọmọ ẹ̀yìn.—1 Tím. 4:15.

Bó O Ṣe Lè Mọ̀ Pé Ọmọ Rẹ Ti Di Ọmọ Ẹ̀yìn Kristi

Ṣé ọmọ rẹ máa ń gbọ́ràn sí ẹ lẹ́nu? (Kól. 3:20) Ṣé ó máa ń ṣe iṣẹ́ ilé tẹ́ ẹ bá ní kó ṣe? Nígbà tí Jésù wà ní ọmọ ọdún méjìlá, Bíbélì sọ nípa rẹ̀ pé: “Ó sì ń bá a lọ ní fífi ara rẹ̀ sábẹ́ [àwọn òbí rẹ̀].” (Lúùkù 2:51) Òótọ́ ni pé kò sí ọmọ tó lè ṣègbọràn sí àwọn òbí rẹ̀ láìkù síbì kan. Àmọ́ àwọn Kristẹni tòótọ́ gbọ́dọ̀ máa “tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ [Jésù] pẹ́kípẹ́kí.” Torí náà, àwọn ọmọ tó bá fẹ́ ṣèrìbọmi gbọ́dọ̀ jẹ́ àwọn tó ń ṣègbọràn sí àwọn òbí wọn.—1 Pét. 2:21.

Ronú nípa àwọn ìbéèrè yìí ná: Ǹjẹ́ ọmọ rẹ ń ‘bá a nìṣó ní wíwá Ìjọba náà lákọ̀ọ́kọ́’ nípa lílọ sí òde ẹ̀rí déédéé? (Mát. 6:33) Ṣé ó máa ń fẹ́ láti wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn àbí ńṣe lẹ máa ń tì í kó tó jáde òde ẹ̀rí? Ǹjẹ́ ó máa ń ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí akéde tí kò tíì ṣe ìrìbọmi? Ṣé ó máa ń fẹ́ lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò sọ́dọ̀ àwọn tó bá fetí sí ìwàásù rẹ̀? Ṣé ó jẹ́ kí àwọn ọmọ iléèwé rẹ̀ àtàwọn olùkọ́ rẹ̀ mọ̀ pé Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni òun?

Ṣé ó fọwọ́ pàtàkì mú lílọ sí ìpàdé ìjọ? (Sm. 122:1) Ṣé ó máa ń dáhùn nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ àti ní Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ? Ṣé ó máa ń ṣiṣẹ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run?—Héb. 10:24, 25.

Ṣé ọmọ rẹ kì í bá àwọn tó lè ba ìwà rere rẹ̀ jẹ́ kẹ́gbẹ́ ní iléèwé àti ní àdúgbò? (Òwe 13:20) Irú orin wo ló máa ń tẹ́tí sí? Irú fíìmù wo ló máa ń wò? Irú ètò orí tẹlifíṣọ̀n wo ló fẹ́ràn? Irú géèmù fídíò wo ló máa ń gbá? Àwọn ìkànnì wo ló máa ń bẹ̀ wò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì? Ṣé ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ àti ìwà tó ń hù fi hàn pé ohun tó bá ìlànà Bíbélì mu ló máa ń ṣe?

Báwo ni ọmọ rẹ ṣe mọ Bíbélì tó? Ṣé ó lè sọ ohun tó bá kọ́ nígbà Ìjọsìn Ìdílé yín lọ́rọ̀ ara rẹ̀? Ṣé ó lè ṣàlàyé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni? (Òwe 2:6-9) Ṣé ó fẹ́ràn láti máa ka Bíbélì kó sì máa kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìtẹ̀jáde tí ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ń pèsè? (Mát. 24:45) Ṣé ó máa ń béèrè ìbéèrè nípa àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì àti àwọn ẹsẹ Bíbélì tí kò bá yé e?

Ó máa dára kó o gbé àwọn ìbéèrè yìí yẹ̀ wò kó o lè mọ bí ọmọ rẹ ṣe ń tẹ̀ síwájú sí nípa tẹ̀mí. Lẹ́yìn náà, o lè wá pinnu pé àwọn ohun kan wà tó yẹ kí ọmọ rẹ ṣiṣẹ́ lé lórí kó tó ṣe ìrìbọmi. Àmọ́, bí ìtẹ̀síwájú rẹ̀ nípa tẹ̀mí bá fi hàn pé ó ti di ọmọ ẹ̀yìn tó sì ti ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Ọlọ́run, o lè jẹ́ kó ṣe ìrìbọmi.

Àwọn Ọmọdé Lè Yin Jèhófà

Láti ìgbà ọmọdé ni ọ̀pọ̀ àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run ti fi hàn pé àwọn jẹ́ olùṣòtítọ́ àti adúróṣinṣin. Lára irú àwọn ọmọdé bẹ́ẹ̀ ni Jósẹ́fù, Sámúẹ́lì, Jòsáyà àti Jésù. (Jẹ́n. 37:2; 39:1-3; 1 Sám. 1:24-28; 2:18-20; 2 Kíró. 34:1-3; Lúùkù 2:42-49) Ó sì dájú pé láti kékeré ni Fílípì ti ní láti kọ́ àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ mẹ́rin tí wọ́n ń sọ tẹ́lẹ̀.—Ìṣe 21:8, 9.

Ní orílẹ̀-èdè Gíríìsì, arábìnrin kan sọ pé: “Ọmọ ọdún méjìlá ni mí nígbà tí mo ṣèrìbọmi. Mi ò sì kábàámọ̀ ìpinnu tí mo ṣe yẹn. Láti ìgbà yẹn sí àkókò tá a wà yìí, ọdún mẹ́rìnlélógún [24] ti kọjá, mo sì ti lo ọdún mẹ́tàlélógún [23] lára rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ìfẹ́ tí mo ní fún Jèhófà ló ń mú kí n lè fara da ìṣòro ìgbà ọmọdé. Òye díẹ̀ ni mo ní nípa Ìwé Mímọ́ nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá. Àmọ́ mo mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà mo sì fẹ́ máa sìn ín títí láé. Inú mi dùn pé ó ti mú kó ṣeé ṣe fún mi láti máa bá a nìṣó nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.”

Yálà ẹnì kan jẹ́ ọmọdé tàbí ó ti dàgbà, bó bá ti fi hàn pé òótọ́ ni òun jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi, ó yẹ kó ṣe ìrìbọmi. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Nítorí ọkàn-àyà ni a fi ń lo ìgbàgbọ́ fún òdodo, ṣùgbọ́n ẹnu ni a fi ń ṣe ìpolongo ní gbangba fún ìgbàlà.” (Róòmù 10:10) Bí ọ̀dọ́mọdé kan tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi bá ṣe ìrìbọmi, àṣeyọrí pàtàkì ni ìyẹn jẹ́ fún òun àti àwọn òbí rẹ̀. Ǹjẹ́ kí ohunkóhun má ṣe dí ìwọ tàbí àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ láti gbádùn ayọ̀ tẹ́ ẹ máa ní.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 5]

Ojú Tó Yẹ Láti Fi Wo Ìrìbọmi

Àwọn òbí kan gbà pé ìrìbọmi ṣàǹfààní fún àwọn ọmọ wọn, àmọ́ ó tún léwu. Ńṣe ló dà bí ìgbà téèyàn gba ìwé àṣẹ ìwakọ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ewu wà nínú ọkọ̀ wíwà. Àmọ́, ṣé ìrìbọmi àti iṣẹ́ ìsìn mímọ́ máa ń fi ọjọ́ iwájú ẹni sínú ewu? Bíbélì dáhùn pé ọ̀rọ̀ kò rí bẹ́ẹ̀. Ìwé Òwe 10:22 sọ pé: “Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.” Pọ́ọ̀lù sì sọ nínú lẹ́tà tó kọ sí ọ̀dọ́ náà Tímótì pé: “Láìsí àní-àní, ó jẹ́ ọ̀nà èrè ńlá, àní fífọkànsin Ọlọ́run pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀mí ohun-moní-tómi.”—1 Tím. 6:6.

Òótọ́ ni pé kò rọrùn láti máa sin Jèhófà. Nígbà tí Jeremáyà ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì Ọlọ́run, ó dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro. Síbẹ̀, ó kọ̀wé nípa bó ṣe jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́. Ó ní: “Ọ̀rọ̀ rẹ sì di ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà mi; nítorí a ti fi orúkọ rẹ pè mí, Jèhófà Ọlọ́run àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun.” (Jer. 15:16) Jeremáyà mọ̀ pé iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run ló mú kí òun láyọ̀. Àmọ́ wàhálà ni ayé Sátánì má ń kó báni. Torí náà, ó pọn dandan káwọn òbí ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ayé Sátánì àti iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.—Jer. 1:19.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]

Ṣó Yẹ Kí Ọmọ Mi Sún Ìrìbọmi Síwájú?

Nígbà míì, bí àwọn ọmọ bá tiẹ̀ tóótun láti ṣe ìrìbọmi, àwọn òbí wọn lè pinnu pé kí wọ́n jẹ́ kó ṣe díẹ̀ sí i. Kí ló lè fà á tí wọ́n fi ń ṣe bẹ́ẹ̀?

Ẹ̀rù ń bà mí pé bí ọmọ mi bá ṣe ìrìbọmi, ó ṣeé ṣe kó dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì kí wọ́n sì yọ ọ́ lẹ́gbẹ́. Ṣé ó bọ́gbọ́n mu láti gbà gbọ́ pé ohun tí kò ní jẹ́ kí ọmọ kan dáhùn fún ohun tó bá ṣe níwájú Ọlọ́run ni pé kó sún ìrìbọmi rẹ̀ síwájú? Àwọn ọmọdé ni Sólómọ́nì ń bá wí nígbà tó sọ pé: “Mọ̀ pé ní tìtorí [ìwà rẹ] ni Ọlọ́run tòótọ́ yóò ṣe mú ọ wá sínú ìdájọ́.” (Oníw. 11:9) Bákan náà, Pọ́ọ̀lù kò dá ọjọ́ orí kankan sí nígbà tó kọ̀wé pé: “Olúkúlùkù wa ni yóò ṣe ìjíhìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.”—Róòmù 14:12.

Gbogbo àwọn tó ń sin Ọlọ́run ni wọ́n máa jíhìn fún un yálà wọ́n ti ṣe ìrìbọmi tàbí wọn kò tíì ṣe ìrìbọmi. Má sì ṣe gbàgbé pé Jèhófà máa ń dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ní ti pé ‘kì í jẹ́ kí a dẹ wọ́n wò ré kọjá ohun tí wọ́n lè mú mọ́ra.’ (1 Kọ́r. 10:13) Àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà mọ̀ pé bí àwọn bá ń ‘pa agbára ìmòye àwọn mọ́’ tí àwọn kò sì hùwà tí kò tọ́, Ọlọ́run á máa ti àwọn lẹ́yìn. (1 Pét. 5:6-9) Arábìnrin kan sọ pé: “Àwọn ọmọ tó ti ṣèrìbọmi máa ń ní ìdí púpọ̀ sí i láti sá fún àwọn nǹkan búburú táwọn èèyàn ń ṣe. Ọmọ mi ọkùnrin tó ṣèrìbọmi nígbà tó wà lọ́mọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] gbà pé ìrìbọmi máa ń dáàbò boni. Ó sọ pé: ‘Kò ní wù ẹ́ láti ṣe ohun tó lòdì sí òfin Jèhófà.’ Ńṣe ni ìrìbọmi máa ń mú kó wuni láti ṣe ohun tó tọ́.”

Nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ àti àpẹẹrẹ tó ò ń fi lélẹ̀ o lè kọ́ àwọn ọmọ rẹ láti máa ṣègbọràn sí Jèhófà. Bí àwọn ọmọ rẹ bá sì ti ń ṣègbọràn sí Jèhófà, ó máa dá ẹ lójú pé wọ́n á máa ṣe bẹ́ẹ̀ nìṣó lẹ́yìn tí wọ́n bá ti ṣèrìbọmi. Ìwé Òwe 20:7 sọ pé: “Olódodo ń rìn nínú ìwà títọ́ rẹ̀. Aláyọ̀ ni àwọn ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.”

Mo fẹ́ kí ọwọ́ ọmọ mi kọ́kọ́ tẹ àwọn àfojúsùn kan kó tó ṣèrìbọmi. Ó yẹ kí àwọn ọmọ mọ béèyàn ṣe ń ṣiṣẹ́, kí wọ́n lè mọ bí wọ́n á ṣe máa gbọ́ bùkátà ara wọn tó bá yá. Ṣùgbọ́n ewu wà nínú kí òbí máa rọ àwọn ọmọ pé kí wọ́n kàwé kí wọ́n lè rí tajé ṣe dípò kí wọ́n fi ọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn tòótọ́. Nígbà tí Jésù ń sọ̀rọ̀ nípa “irúgbìn” kan, tàbí ọ̀rọ̀ Ìjọba náà, èyí tí kò dàgbà, ó sọ pé: “Ní ti èyí tí a fún sáàárín àwọn ẹ̀gún, èyí ni ẹni tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà, ṣùgbọ́n tí àníyàn ètò àwọn nǹkan yìí àti agbára ìtannijẹ ọrọ̀ fún ọ̀rọ̀ náà pa, ó sì di aláìléso.” (Mát. 13:22) Bí òbí bá rọ ọmọ láti máa gbé ìgbé ayé tó máa mú kó fi àfojúsùn nípa tara ṣáájú àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, èyí lè mú kí ọmọ náà máà fẹ́ sin Ọlọ́run mọ́.

Nígbà tí alàgbà onírìírí kan ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ tó tóótun láti ṣe ìrìbọmi ṣùgbọ́n tí àwọn òbí wọn kò jẹ́ kí wọ́n ṣe ìrìbọmi, ó sọ pé: “Bí àwọn òbí kò bá jẹ́ kí ọmọ wọn ṣe ìrìbọmi, ọmọ náà lè máà tẹ̀ síwájú mọ́ nípa tẹ̀mí ó sì tún lè rẹ̀wẹ̀sì.” Alábòójútó arìnrìn-àjò kan sì kọ̀wé pé: “Ọmọ kan lè bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé òun kò lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run tàbí kó ro ara rẹ̀ pin. Ó lè máa rò pé àfi kí òun kọjá sínú ayé kí òun tó lè ṣe àṣeyọrí.”

[Àwòrán]

Ṣó yẹ kéèyàn kọ́kọ́ lọ sí yunifásítì?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Ọmọdé kan lè fi hàn pé òun jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Kristi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 3]

Mímúra ìpàdé sílẹ̀ àti kíkópa nínú rẹ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Ṣíṣègbọràn sí òbí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Lílọ sí òde ẹ̀rí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Gbígbàdúrà