Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ẹ Ní Ẹ̀mí Ìkanisí Fún Àwọn Tí Ń Ṣiṣẹ́ Kára Láàárín Yín”

“Ẹ Ní Ẹ̀mí Ìkanisí Fún Àwọn Tí Ń Ṣiṣẹ́ Kára Láàárín Yín”

“Ẹ Ní Ẹ̀mí Ìkanisí Fún Àwọn Tí Ń Ṣiṣẹ́ Kára Láàárín Yín”

“Ẹ ní ẹ̀mí ìkanisí fún àwọn tí ń ṣiṣẹ́ kára láàárín yín, tí wọ́n ń ṣe àbójútó yín nínú Olúwa, tí wọ́n sì ń ṣí yín létí.”—1 TẸS. 5:12.

1, 2. (a) Báwo ni nǹkan ṣe rí nínú ìjọ Tẹsalóníkà nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ lẹ́tà rẹ̀ àkọ́kọ́ sí wọn? (b) Kí ni Pọ́ọ̀lù gba àwọn ará Tẹsalóníkà níyànjú pé kí wọ́n ṣe?

 JẸ́ KÁ sọ pé o wà nínú ìjọ Tẹsalóníkà, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìjọ tí wọ́n kọ́kọ́ dá sílẹ̀ ní ilẹ̀ Yúróòpù ní ọ̀rúndún kìíní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti lo àkókò tó pọ̀ láti fi gbé àwọn ará tó wà níbẹ̀ ró. Ó tiẹ̀ ṣeé ṣe kó ti yan àwọn àgbà ọkùnrin láti máa múpò iwájú níbẹ̀, bó ṣe ṣe nínú àwọn ìjọ míì. (Ìṣe 14:23) Àmọ́ lẹ́yìn tí wọ́n ti dá ìjọ náà sílẹ̀, àwọn Júù tó wà níbẹ̀ kó àwọn jàǹdùkú jọ kí wọ́n lè lé Pọ́ọ̀lù àti Sílà jáde kúrò nínú ìlú náà. Ó lè máa ṣe àwọn Kristẹni tó kù síbẹ̀ bíi pé a ti pa wọ́n tì, ó sì ṣeé ṣe kí ẹ̀rù máa bà wọ́n.

2 Torí náà, lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti kúrò ní Tẹsalóníkà, a lè rí ìdí tó fi ń ṣàníyàn nípa ìjọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ dá sílẹ̀ náà. Ó gbìyànjú láti pa dà lọ síbẹ̀, àmọ́ “Sátánì dábùú” ọ̀nà rẹ̀. Torí náà, ó rán Tímótì láti lọ fún ìjọ náà níṣìírí. (1 Tẹs. 2:18; 3:2) Nígbà tí Tímótì mú ìròyìn rere wá nípa wọn, inú Pọ́ọ̀lù dùn láti kọ lẹ́tà sí àwọn ará Tẹsalóníkà. Yàtọ̀ sí àwọn nǹkan míì tí Pọ́ọ̀lù bá wọn sọ, ó tún gbà wọ́n níyànjú láti ‘ní ẹ̀mí ìkanisí fún àwọn tí ń ṣe àbójútó wọn.’—Ka 1 Tẹsalóníkà 5:12, 13.

3. Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà ní ìkàsí tó ju àrà ọ̀tọ̀ lọ fún àwọn àgbà ọkùnrin?

3 Àwọn arákùnrin tó ń mú ipò iwájú láàárín àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà kò ní ìrírí tó Pọ́ọ̀lù àtàwọn tí wọ́n ń bá a rìnrìn àjò, wọn kò sì tíì sìn fún ọjọ́ pípẹ́ bíi tàwọn alàgbà tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Ó ṣe tán, kò tíì tó ọdún kan tí wọ́n dá ìjọ náà sílẹ̀! Síbẹ̀, ìdí wà fún àwọn tó wà nínú ìjọ náà láti dúpẹ́ nítorí àwọn àgbà ọkùnrin tó wà láàárín wọn, torí pé wọ́n ń “ṣiṣẹ́ kára,” wọ́n “ń ṣe àbójútó” ìjọ, wọ́n sì ‘ń ṣí àwọn ará létí.’ Nítorí náà, ó bá a mu wẹ́kú pé kí wọ́n “máa fún [àwọn alàgbà náà] ní ìkàsí tí ó ju àrà ọ̀tọ̀ lọ nínú ìfẹ́.” Lẹ́yìn èyí ni Pọ́ọ̀lù wá gbà wọ́n níyànjú pé: “Ẹ jẹ́ ẹlẹ́mìí àlàáfíà pẹ̀lú ara yín lẹ́nì kìíní-kejì.” Bó o bá wà ní ìjọ Tẹsalóníkà, ṣé wàá fi ìmọrírì tó pọ̀ hàn fún iṣẹ́ táwọn alàgbà ń ṣe? Ojú wo lo fi ń wo “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” tí Ọlọ́run tipasẹ̀ Kristi pèsè láti máa bójú tó ìjọ yín?—Éfé. 4:8.

Wọ́n “Ń Ṣiṣẹ́ Kára”

4, 5. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà láyé àti lóde òní kí nìdí tá a fi lè sọ pé àwọn àgbà ọkùnrin máa ń ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n tó lè kọ́ ìjọ?

4 Lẹ́yìn tí àwọn ará ti rán Pọ́ọ̀lù àti Sílà jáde lọ sí Bèróà, báwo ni àwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Tẹsalóníkà ṣe “ń ṣiṣẹ́ kára”? Kò sí iyè méjì pé wọ́n tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù láti máa fi Ìwé Mímọ́ kọ́ ìjọ. Síbẹ̀ o lè máa ronú pé, ‘Ǹjẹ́ àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà mọrírì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?’ Ó ṣe tán, Bíbélì sọ pé àwọn ará Bèróà “ní ọkàn-rere ju àwọn ti Tẹsalóníkà lọ, . . . wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́.” (Ìṣe 17:11) Ṣé àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà ni Pọ́ọ̀lù ń fi àwọn ará Bèróà wé? Rárá o. Àwọn Júù tó ń gbé ìlú Tẹsalóníkà ni Pọ́ọ̀lù fi wọ́n wé. Ìwé Mímọ́ sọ pé àwọn tó di onígbàgbọ́ ‘gba ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.’ (1 Tẹs. 2:13) Torí náà, àwọn àgbà ọkùnrin ti ní láti ṣiṣẹ́ kára kí wọ́n lè máa fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ ìjọ.

5 Lónìí, ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye ń pèsè “oúnjẹ” fún agbo Ọlọ́run “ní àkókò tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu.” (Mát. 24:45) Bí ẹrú yìí ṣe ń darí àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ, àwọn náà ń ṣiṣẹ́ kára láti máa fi oúnjẹ tẹ̀mí bọ́ àwọn ará. Àwọn tó wà nínú ìjọ lè ní ọ̀pọ̀ ìwé tá a fi ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, bó bá sì jẹ́ láwọn èdè kan ni, wọ́n lè ní ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index àti Watchtower Library tó wà lórí àwo CD. Àmọ́, kí àwọn alàgbà bàa lè fi ẹ̀kọ́ tó jíire kọ́ àwọn ará, wọ́n máa ń lo ọ̀pọ̀ wákàtí láti fi múra iṣẹ́ tí wọ́n bá ní sílẹ̀, kí àwọn ará lè jàǹfààní látinú ohun tí wọ́n bá sọ. Àwọn alàgbà máa ń múra iṣẹ́ tí wọ́n bá ní láwọn ìpàdé ìjọ, àpéjọ àkànṣe, àyíká àti ti àgbègbè. Ṣùgbọ́n, ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti ronú lórí bí àkókò tí wọ́n fi ń múra àwọn iṣẹ́ náà ṣe pọ̀ tó?

6, 7. (a) Kí ni àwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Tẹsalóníkà rí kọ́ lára Pọ́ọ̀lù? (b) Lónìí, kí ló lè mú kó ṣòro fún àwọn alàgbà láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù?

6 Àwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Tẹsalóníkà rántí àpẹẹrẹ rere tí Pọ́ọ̀lù fi lélẹ̀ nípa bó ṣe yẹ kí wọ́n máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run. Bí Pọ́ọ̀lù bá bẹ̀ wọ́n wò, ó máa ń fi ìfẹ́ hàn ó sì máa ń bá wọn lò lọ́nà jẹ̀lẹ́ńkẹ́. Kò wulẹ̀ jẹ́ kó dà bí ohun àìgbọ́dọ̀máṣe kan lásán. Gẹ́gẹ́ bí a ṣe jíròrò rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí, Pọ́ọ̀lù “di ẹni pẹ̀lẹ́ . . . , bí ìgbà tí abiyamọ ń ṣìkẹ́ àwọn ọmọ tirẹ̀.” (Ka 1 Tẹsalóníkà 2:7, 8.) Kódà, ó múra tán ‘láti fún wọn ní ọkàn òun fúnra rẹ̀’! Bí àwọn àgbà ọkùnrin ṣe ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run, ó yẹ kí wọ́n máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀.

7 Àwọn Kristẹni tó ń ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run lónìí ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù, àwọn náà sì máa ń fìfẹ́ bójú tó agbo Ọlọ́run. Àwọn àgùntàn kan lè máà yá mọ́ni. Síbẹ̀, àwọn alàgbà máa ń fi ọgbọ́n bá wọn lò wọ́n á sì wá ibi tí wọ́n dára sí. Ó lè ṣòro fún alàgbà kan láti máa fi ojú tó tọ́ wo ẹnì kọ̀ọ̀kan torí pé òun náà jẹ́ aláìpé. Síbẹ̀, bó ṣe ń sa gbogbo ipá rẹ̀ kó lè jẹ́ ẹni pẹ̀lẹ́ sí gbogbo èèyàn, ǹjẹ́ kò yẹ ká gbóríyìn fún un pé ó ń sapá láti jẹ́ olùṣọ́ àgùntàn rere lábẹ́ Kristi?

8, 9. Kí ni díẹ̀ lára ọ̀nà tí àwọn alàgbà ń gbà ‘ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn wa’ lónìí?

8 Ìdí wà tí gbogbo wa fi gbọ́dọ̀ “jẹ́ ẹni tí ń tẹrí ba” fún àwọn alàgbà. Gẹ́gẹ́ bí Pọ́ọ̀lù ṣe sọ, ‘wọ́n ń ṣọ́ ẹ̀ṣọ́ lórí ọkàn wa.’ (Héb. 13:17) Gbólóhùn yẹn rán wa létí bí olùṣọ́ àgùntàn ṣe máa ń dá oorun mọ́jú kó lè dáàbò bo àwọn àgùntàn rẹ̀. Bákan náà, àwọn alàgbà lónìí lè fi oorun díẹ̀ du ara wọn kí wọ́n lè bójú tó àwọn ará tó ní àìlera tàbí tí wọ́n ní ìdààmú ọkàn tàbí àwọn tó ṣòro fún láti máa fi àwọn ìlànà Bíbélì ṣèwà hù. Bí àpẹẹrẹ, àwọn tó nílò ìtọ́jú máa ń dá oorun mọ́ àwọn arákùnrin tó ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí Ìgbìmọ̀ Alárinà Ilé Ìwòsàn lójú kí wọ́n lè bá wọn dá sí àwọn ọ̀ràn tó ń fẹ́ àbójútó ìṣègùn. Bó bá jẹ́ pé àwa la nílò irú ìtọ́jú bẹ́ẹ̀, ẹ wo bá a ṣe máa mọrírì iṣẹ́ wọn tó!

9 Àwọn alàgbà tó wà lára àwọn tó ń ṣètìlẹyìn fún Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Kíkọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba àti àwọn ìgbìmọ̀ tó ń pèsè ìrànwọ́ fún àwọn tí ìjábá bá ṣẹlẹ̀ sí ń ṣiṣẹ́ kára láti máa ran àwọn ará lọ́wọ́. Ó yẹ ká máa kọ́wọ́ tì wọ́n látọkànwá! Àpẹẹrẹ kan tá a lè gbé yẹ̀ wò ni ti Ìjì Òjò kan tí wọ́n pè ní Nargis, èyí tó wáyé ní orílẹ̀-èdè Myanmar lọ́dún 2008. Ibi tí odò Irrawaddy ti ya wọnú òkun wà lára àgbègbè tí ìjì náà ti ṣọṣẹ́ jù lọ, ibẹ̀ sì ni Ìjọ Bothingone wà. Kí àwọn tó ń pèsè ìrànwọ́ tó lè dé ibẹ̀ wọ́n ní láti rìn gba àwọn ibi tí ìjì náà ti ṣọṣẹ́ kọjá, òkú àwọn èèyàn sì wà káàkiri lórí ilẹ̀. Nígbà tí àwọn ará tó wà níbẹ̀ rí i pé alábòójútó àyíká wọn tẹ́lẹ̀ wà lára àwọn tó kọ́kọ́ débẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n lọgun pé: “Àbẹ́ ò rí nǹkan! Alábòójútó àyíká wa náà mà bá wọn wá! Jèhófà ti ṣe ọ̀nà àbáyọ fún wa!” Ǹjẹ́ o mọrírì iṣẹ́ ribiribi tí àwọn alàgbà ń ṣe tọ̀sán tòru? A máa ń yan àwọn alàgbà míì láti sìn nínú ìgbìmọ̀ àkànṣe láti bójú tó àwọn ẹjọ́ tó bá díjú. Àwọn alàgbà wọ̀nyí kì í fọ́nnu nítorí ohun tí wọ́n ti gbé ṣe; síbẹ̀ àwọn tó ń jàǹfààní látinú iṣẹ́ wọn máa ń kún fún ọpẹ́ gidigidi.—Mát. 6:2-4.

10. Àwọn iṣẹ́ tí kò hàn sí gbogbo èèyàn wo làwọn alàgbà máa ń ṣe?

10 Ọ̀pọ̀ àwọn alàgbà lónìí tún ní ọ̀pọ̀ iṣẹ́ tó jẹ mọ́ ìwé kíkọ láti ṣe. Bí àpẹẹrẹ, olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà máa ń ṣe ìtòlẹ́sẹẹsẹ àwọn ìpàdé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀. Akọ̀wé ìjọ máa ń kó ìròyìn iṣẹ́ ìsìn pápá oṣooṣù àti ti ọdọọdún jọ. Alábòójútó Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run máa ń fara balẹ̀ ronú lórí àwọn tó máa yanṣẹ́ fún nílé ẹ̀kọ́. Ètò wà fún ṣíṣe àyẹ̀wò àkáǹtì ìjọ lóṣù mẹ́ta mẹ́ta. Àwọn alàgbà máa ń ka lẹ́tà tó wá láti ẹ̀ka ọ́fíìsì wọ́n sì máa ń ṣiṣẹ́ lórí ìtọ́ni tó máa mú kí ìjọ máa wà ní “ìṣọ̀kanṣoṣo nínú ìgbàgbọ́.” (Éfé. 4:3, 13) Bí àwọn alàgbà wọ̀nyí ṣe ń ṣiṣẹ́ kára ń mú kí “ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tí ó bójú mu àti nípa ìṣètò.”—1 Kọ́r. 14:40.

Wọ́n “Ń Ṣe Àbójútó Yín”

11, 12. Àwọn wo ló ń ṣe àbójútó ìjọ, ọ̀nà wo ni wọ́n sì ń gbà ṣe é?

11 Pọ́ọ̀lù sọ pé àwọn àgbà ọkùnrin tó ń ṣiṣẹ́ kára ní ìjọ Tẹsalóníkà “ń ṣe àbójútó” ìjọ. Ohun tí gbólóhùn tó wá látinú èdè Gíríìkì ìpilẹ̀ṣẹ̀ yẹn ń sọ ni pé wọ́n “ń dúró níwájú” ìjọ. A sì tún lè túmọ̀ rẹ̀ sí “ń darí; ń mú ipò iwájú láàárín” ìjọ. (1 Tẹs. 5:12, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Pọ́ọ̀lù tún sọ nípa àwọn alàgbà yìí kan náà pé wọ́n “ń ṣiṣẹ́ kára.” Torí náà, kì í ṣe alàgbà kan ṣoṣo tó jẹ́ “alága àwọn alábòójútó,” ni Pọ́ọ̀lù ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, gbogbo àwọn àgbà ọkùnrin tó wà nínú ìjọ ló ń bá wí. Lónìí, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú àwọn alàgbà ló ń dúró níwájú ìjọ tí wọ́n sì ń darí àwọn ìpàdé ìjọ. Àtúnṣe tá a ṣe láìpẹ́ yìí pé ká máa lo gbólóhùn náà “olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà” mú ká lè máa wo gbogbo àwọn alàgbà gẹ́gẹ́ bí ara ìgbìmọ̀ kan ṣoṣo tó wà ní ìṣọ̀kan.

12 ‘Ṣíṣe àbójútó’ ìjọ kò mọ sórí kéèyàn máa kọ́ni. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù lo gbólóhùn kan náà nínú 1 Tímótì 3:4, ó sọ pé alábòójútó gbọ́dọ̀ jẹ́ “ọkùnrin kan tí ń ṣe àbójútó agbo ilé tirẹ̀ lọ́nà tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀, tí ó ní àwọn ọmọ tí wọ́n ní ìtẹríba pẹ̀lú gbogbo ìwà àgbà.” Bó ṣe lo gbólóhùn náà “tí ń ṣe àbójútó” níbí jẹ́ ká rí i pé ìtumọ̀ rẹ̀ kò mọ sórí kíkọ́ àwọn ọmọ, àmọ́ ó tún kan mímú ipò iwájú nínú ìdílé àti mímú kí ‘àwọn ọmọ wà ní ìtẹríba.’ Ojúṣe àwọn alàgbà ni pé kí wọ́n máa mú ipò iwájú nínú ìjọ kí wọ́n sì máa ran àwọn ará lọ́wọ́ láti wà ní ìtẹríba fún Jèhófà.—1 Tím. 3:5.

13. Bí àwọn alàgbà bá ń ṣèpàdé, kí nìdí tó fi lè gba àkókò kí wọ́n tó dórí ìpinnu?

13 Kí àwọn alàgbà bàa lè máa ṣe olùṣọ́ àgùntàn agbo Ọlọ́run dáadáa, wọ́n jùmọ̀ máa ń jíròrò ohun tí wọ́n máa ṣe nípa àwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ. Ó lè dà bíi pé ó máa yá bó bá jẹ́ pé alàgbà kan ṣoṣo ló ń ṣe gbogbo ìpinnu. Síbẹ̀ lónìí, bí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà bá ń jíròrò, wọ́n máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbìmọ̀ olùdarí ti ọ̀rúndún kìíní nípa sísọ ohun tó wà lọ́kàn wọn láìlọ́ tìkọ̀, wọ́n sì máa ń tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà inú Ìwé Mímọ́. Àfojúsùn wọn ni bí wọ́n á ṣe máa fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò bí wọ́n bá ń jíròrò àwọn ohun tó ń fẹ́ àbójútó nínú ìjọ. Irú ìjíròrò yìí túbọ̀ máa ń múná dóko bí alàgbà kọ̀ọ̀kan bá ń múra ìpàdé àwọn alàgbà sílẹ̀, tó ń ṣàyẹ̀wò àwọn ìlànà inú Ìwé Mímọ́ àtàwọn ìtọ́ni tó wá látọ̀dọ̀ ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye. Èyí máa ń gba àkókò ṣá o. Bí èrò àwọn alàgbà bá yàtọ̀ síra, bó ṣe rí nígbà tí ìgbìmọ̀ olùdarí gbé ọ̀rọ̀ ìdádọ̀dọ́ yẹ̀ wò ní ọ̀rúndún kìíní, ó lè gba pé kí wọ́n lo àkókò díẹ̀ sí i, kí wọ́n sì túbọ̀ ṣèwádìí kí ohùn wọn tó lè ṣọ̀kan ní ìbámu pẹ̀lú Ìwé Mímọ́.—Ìṣe 15:2, 6, 7, 12-14, 28.

14. Ǹjẹ́ o mọrírì rẹ̀ pé ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ń ṣiṣẹ́ pọ̀ ní ìṣọ̀kan? Kí nìdí tó o fi mọrírì rẹ̀?

14 Kí ló lè ṣẹlẹ̀ bí alàgbà kan bá ń fẹ́ kó jẹ́ pé èrò tòun láá máa lékè ní gbogbo ìgbà tàbí tó ń gbìyànjú láti gbé èrò tirẹ̀ lárugẹ? Bó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹnì kan ń fẹ́ láti dá ìyapa sílẹ̀ bí Dìótíréfè ti ṣe ní ọ̀rúndún kìíní ńkọ́? (3 Jòh. 9, 10) Gbogbo ìjọ pátá ló máa fara gbá a. Níwọ̀n bí Sátánì ti gbìyànjú láti dá wàhálà sílẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní, ó yẹ kó dá wa lójú pé ó máa fẹ́ láti ba àlàáfíà ìjọ Ọlọ́run jẹ́ lónìí pẹ̀lú. Ó lè máa lo ìfẹ́ ìmọtara-ẹni-nìkan tí ẹ̀dá èèyàn ní, irú bíi wíwá ipò ọlá. Torí náà, àwọn alàgbà gbọ́dọ̀ jẹ́ onírẹ̀lẹ̀ kí wọ́n sì máa ṣiṣẹ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbìmọ̀ kan ṣoṣo tó wà ní ìṣọ̀kan. A mà mọrírì ìwà ìrẹ̀lẹ̀ àwọn alàgbà tí wọ́n ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbìmọ̀ kan o!

Wọ́n “Ń Ṣí Yín Létí”

15. Kí ló ń mú kí àwọn alàgbà ṣí arákùnrin tàbí arábìnrin kan létí?

15 Wàyí o, Pọ́ọ̀lù wá mẹ́nu kan iṣẹ́ kan tó nira àmọ́ tó ṣe pàtàkì tí àwọn àgbà ọkùnrin ń ṣe, ìyẹn ni ṣíṣí agbo Ọlọ́run létí. Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, Pọ́ọ̀lù nìkan ló lo ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “ṣí létí” lédè Yorùbá. Irú ìṣílétí bẹ́ẹ̀ lè jẹ́ ìbáwí líle tí kò la ìkórìíra lọ. (Ìṣe 20:31; 2 Tẹs. 3:15) Bí àpẹẹrẹ, nínú lẹ́tà Pọ́ọ̀lù sí àwọn ará Kọ́ríńtì, ó sọ pé: “Èmi kò kọ̀wé nǹkan wọ̀nyí láti dójú tì yín, bí kò ṣe láti ṣí yín létí gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n.” (1 Kọ́r. 4:14) Ìfẹ́ ló mú kí ọ̀rọ̀ àwọn míì jẹ Pọ́ọ̀lù lógún débi tó fi ṣí wọn létí.

16. Kí ló dára kí àwọn alàgbà fi sọ́kàn bí wọ́n bá ń ṣí àwọn míì létí?

16 Àwọn alàgbà kò jẹ́ gbàgbé bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí wọ́n máa kíyè sí ọ̀nà tí wọ́n ń gbà ṣí àwọn míì létí. Wọ́n ń sapá láti tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù nípa jíjẹ́ onínúure, ẹni tó ń fìfẹ́ hàn àti ẹni tó ń ranni lọ́wọ́. (Ka 1 Tẹsalóníkà 2:11, 12.) Àmọ́ ṣá o, àwọn alàgbà máa ń ‘di ọ̀rọ̀ ṣíṣeégbíyèlé mú ṣinṣin ní ti ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ wọn, kí wọ́n bàa lè gbani níyànjú pẹ̀lú ẹ̀kọ́ afúnni-nílera.’—Títù 1:5-9.

17, 18. Kí lo gbọ́dọ̀ fi sọ́kàn bí alàgbà kan bá ṣí ẹ létí?

17 Àmọ́ ṣá o, aláìpé ni àwọn alàgbà, torí náà, wọ́n lè sọ ohun tí wọ́n máa kábàámọ̀ rẹ̀ bó bá yá. (1 Ọba 8:46; Ják. 3:8) Bákan náà, àwọn alàgbà mọ̀ pé fún àwọn ará nínú ìjọ láti gba ìbáwí kì í sábàá jẹ́ ‘ohun ìdùnnú, bí kò ṣe akó-ẹ̀dùn-ọkàn-báni.’ (Héb. 12:11) Torí náà, kí alàgbà kan tó lọ ṣí ẹnì kan létí, ó ṣeé ṣe kó ti kọ́kọ́ gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò, kó sì ti gbàdúrà nípa rẹ̀. Bí alàgbà kan bá ti ṣí ẹ létí rí, ǹjẹ́ o mọrírì ìfẹ́ tó ní àti bí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe jẹ ẹ́ lógún?

18 Ká sọ pé ò ń ṣàìsàn, tó sì ṣòro fáwọn dókítà láti ṣàlàyé irú àìsàn tó jẹ́. Ó wá ṣẹlẹ̀ pé ó ṣeé ṣe fún dókítà kan láti sọ irú àìsàn tó jẹ́, ṣùgbọ́n ó ṣòro fún ẹ láti gbà pé irú àìsàn tó ń ṣe ẹ́ nìyẹn. Ṣé wàá bẹ̀rẹ̀ sí í bínú sí dókítà náà? Rárá o! Ńṣe lo máa fara mọ́ irú ìtọ́jú tó bá ní kó o gbà. Ì báà tiẹ̀ dámọ̀ràn pé kí wọ́n ṣiṣẹ́ abẹ fún ẹ, o ṣeé ṣe kó o gbà fún un torí pé àǹfààní ara rẹ ló wà fún. Bí dókítà ṣe ṣàlàyé àìsàn náà fún ẹ lè máà bá ẹ lára dé, ṣùgbọ́n ṣé wàá jẹ́ kí ìyẹn nípa lórí ìpinnu tó o máa ṣe? Bóyá ni. Lọ́nà kan náà, má tìtorí ọ̀nà tí alàgbà gbà ṣí ẹ létí kọ etí ikún sí àwọn tó ṣeé ṣe kí Jèhófà àti Jésù máa lò láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè máa tẹ̀ síwájú nínú òtítọ́ tàbí kí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà má bàa bà jẹ́.

Mọrírì Àwọn Alàgbà Tí Jèhófà Fi Fún Wa

19, 20. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọrírì “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn”?

19 Kí lo máa ṣe tó o bá rí ẹ̀bùn tí ẹnì kan dìídì fi ránṣẹ́ sí ẹ gbà? Ṣé wàá fi hàn pé o mọrírì ẹ̀bùn náà nípa lílò ó? Jèhófà tipasẹ̀ Jésù Kristi fún ẹ ní “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn.” Ọ̀nà kan tó o lè gbà fi ìmoore hàn fún àwọn ẹ̀bùn yìí ni pé kó o máa tẹ́tí sílẹ̀ dáadáa sí àsọyé tí wọ́n bá ń sọ kó o sì tún máa fi àwọn ohun tí wọ́n sọ sílò. O tún lè fi ìmọrírì rẹ hàn nípa lílóhùn sí àwọn ìpàdé, kó o máa ṣe àlàyé tó nítumọ̀. Máa kọ́wọ́ ti iṣẹ́ táwọn alàgbà ń múpò iwájú nínú rẹ̀, irú bí iṣẹ́ ìwàásù. Bó o bá ti jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn tí alàgbà kan fún ẹ, o ò ṣe sọ fún un? Yàtọ̀ síyẹn, o ò ṣe máa fi ìmọrírì hàn fún àwọn tó wà nínú ìdílé àwọn alàgbà? Ẹ má ṣe gbàgbé pé kí alàgbà kan tó lè ṣiṣẹ́ kára nínú ìjọ, ìdílé rẹ̀ ti ní láti fi àkókò tó yẹ kí wọ́n fi wà pẹ̀lú rẹ̀ du ara wọn.

20 Láìsí àníàní, ọ̀pọ̀ ìdí wà tá a fi gbọ́dọ̀ máa fi ìmoore hàn fún àwọn alàgbà tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára láàárín wa, tí wọ́n ń ṣe àbójútó wa, tí wọ́n sì ń ṣí wa létí. Ní tòótọ́, Jèhófà ló fìfẹ́ pèsè “àwọn ẹ̀bùn tí ó jẹ́ ènìyàn” wọ̀nyí fún wa!

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Kí nìdí tó fi yẹ kí àwọn Kristẹni tó wà ní Tẹsalóníkà mọrírì àwọn tó ń múpò iwájú láàárín wọn?

• Báwo ni àwọn alàgbà ìjọ rẹ ṣe ń ṣiṣẹ́ kára nítorí rẹ?

• Báwo lo ṣe ń jàǹfààní látinú bí àwọn alàgbà ṣe ń ṣe àbójútó rẹ?

• Bí alàgbà kan bá ṣí ẹ létí, kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]

Ǹjẹ́ o mọrírì ọ̀pọ̀ ọ̀nà tí àwọn alàgbà ń gbà ṣe olùṣọ́ àgùntàn ìjọ?