Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Lo Ṣe Lè “Mú Kí Ọ̀nà Rẹ Yọrí sí Rere”?

Báwo Lo Ṣe Lè “Mú Kí Ọ̀nà Rẹ Yọrí sí Rere”?

Báwo Lo Ṣe Lè “Mú Kí Ọ̀nà Rẹ Yọrí sí Rere”?

KÒ SẸ́NI tí kì í fẹ́ kí òun ṣe àṣeyọrí tàbí kí nǹkan tí òun bá dáwọ́ lé yọrí sí rere. Àwọn kan ti dé ipò gíga lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n ti di olówó, wọ́n sì ti di olókìkí. Àmọ́, àléèbá ni àṣeyọrí jẹ́ fún àwọn míì.

Ọ̀pọ̀ ìgbà ló jẹ́ pé ohun tó o bá fi sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ ló máa pinnu bóyá o máa ṣàṣeyọrí. Àwọn ohun pàtàkì méjì míì tó lè mú kó o ṣàṣeyọrí ni bó o bá ṣe lo àkókò àti agbára rẹ àti bóyá o ṣe tán láti lo ìdánúṣe.

Ọ̀pọ̀ Kristẹni ti rí i pé inú àwọn máa ń dùn gan-an bí àwọn bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù àti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn déédéé. A ti rí àwọn ọ̀dọ́ àtàwọn àgbà tó ti ṣàṣeyọrí torí pé wọ́n fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣe iṣẹ́ ìgbésí ayé wọn. Síbẹ̀, àwọn kan lè rí iṣẹ́ ìwàásù bí iṣẹ́ tó ń súni, kí wọ́n fi í sí ipò kejì nínú ìgbésí ayé wọn, kí wọ́n sì máa lépa àwọn nǹkan mìíràn. Kí ló lè mú kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀? Kí lo lè ṣe kó o má bàa gbójú fo ohun tó ṣe pàtàkì ní tòótọ́? Báwo lo sì ṣe lè “mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere”?—Jóṣ. 1:8.

Àwọn Ìgbòkègbodò Tó Máa Ń Wáyé Lẹ́yìn Ilé Ẹ̀kọ́ Àtàwọn Nǹkan Míì Tó O Máa Ń Ṣe Nígbà Tí Ọwọ́ Bá Dilẹ̀

Àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí lílọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò míì gba ìjọsìn Ọlọ́run mọ́ àwọn lọ́wọ́. Lọ́nà yìí, irú àwọn ọ̀dọ́ bẹ́ẹ̀ á mú kí ìgbésí ayé wọn yọrí sí rere, ó sì yẹ ká gbóríyìn fún wọn.

Àmọ́, àwọn ọ̀dọ́ kan tó jẹ́ Kristẹni máa ń jẹ́ kí àwọn ìgbòkègbodò míì tó máa ń wáyé lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́ àti àwọn nǹkan míì tí wọ́n máa ń ṣe nígbà tí ọwọ́ wọn bá dilẹ̀ gba gbogbo àkókò wọn. Irú àwọn ìgbòkègbodò bẹ́ẹ̀ lè má burú. Ṣùgbọ́n, àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ bi ara wọn pé: ‘Báwo ni àwọn ìgbòkègbodò yẹn ṣe ń gba àkókò mi tó? Àwọn wo la jọ ń kópa nínú rẹ̀? Irú ìwà wo ni àwọn tá a jọ ń kópa nínú ìgbòkègbodò náà ń hù? Kí ni ìgbòkègbodò náà máa mú kí n sọ di pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé mi?’ Ìwọ náà lè wá rí i pé àwọn ìgbòkègbodò wọ̀nyẹn lè gbà ẹ́ lọ́kàn débi pé o kò ní ní àkókò tàbí okun tí wàá fi máa mú kí àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Ọlọ́run sunwọ̀n sí i. Nígbà náà, o lè wá rí ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kó o mọ ohun tó o máa fi sípò àkọ́kọ́.—Éfé. 5:15-17.

Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Wiktor. * Ó sọ pé: “Nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún méjìlá, mo dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ tó ń gbá bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá. Nígbà tó yá, mo gba ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀bùn. Mo tún ní àǹfààní láti di gbajúmọ̀ eléré ìdárayá.” Nígbà tó yá, Wiktor ronú nípa bí lílépa eré bọ́ọ̀lù yìí ṣe máa nípa lórí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, èyí sì da ọkàn rẹ̀ láàmú. Oorun tiẹ̀ gbé e lọ lọ́jọ́ kan nígbà tó ń ka Bíbélì. Ó sì tún wá rí i pé iṣẹ́ ìwàásù kò fi bẹ́ẹ̀ fún òun láyọ̀ mọ́. Ó sọ pé: “Eré bọ́ọ̀lù náà máa ń tán mi lókun, kò sì pẹ́ tí mo fi rí i pé ó ti ń jẹ́ kí ìtara mi fún àwọn nǹkan tẹ̀mí máa jó rẹ̀yìn. Mo mọ̀ pé mo lè ṣe púpọ̀ sí i ju bí mo ti ń ṣe lọ.”

Ilé Ẹ̀kọ́ Gíga

Gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ṣe sọ, ojúṣe Kristẹni ni pé kó pèsè fún ìdílé rẹ̀, èyí sì kan pípèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò nípa tara. (1 Tím. 5:8) Àmọ́, ṣé èèyàn gbọ́dọ̀ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga kó tó lè pèsè àwọn ohun wọ̀nyí?

Ó dára kí ẹni tó bá fẹ́ lọ sí ilé ẹ̀kọ́ gíga ronú lórí bó ṣe máa nípa lórí àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà. Jẹ́ ká fi àpẹẹrẹ ẹnì kan nínú Bíbélì ṣàpèjúwe ọ̀ràn náà.

Akọ̀wé wòlíì Jeremáyà ni Bárúkù. Ní àkókò kan, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wá ipò ọlá dípò kó gbájú mọ́ àǹfààní tó ní láti máa sin Jèhófà. Jèhófà rí ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ó sì kìlọ̀ fún un nípasẹ̀ Jeremáyà pé: “Ìwọ ń wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ. Má ṣe wá wọn mọ́.”—Jer. 45:5.

Kí ni “àwọn ohun ńláńlá” tí Bárúkù ń wá fún ara rẹ̀? Ó ṣeé ṣe kó fẹ́ láti di gbajúmọ̀ nínú ètò àwọn nǹkan Júù. Ó sì lè jẹ́ pé bó ṣe máa di ọlọ́rọ̀ ni àwọn ohun ńláńlá tó ń wá náà. Èyí ó wù kó jẹ́, ó ti kùnà láti fi àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù, ìyẹn àwọn ohun tó máa jẹ́ kó ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Jèhófà, sí ipò àkọ́kọ́. (Fílí. 1:10) Ó dájú pé Bárúkù fetí sí ìkìlọ̀ tí Jèhófà fún un nípasẹ̀ Jeremáyà ó sì tipa bẹ́ẹ̀ la ìparun Jerúsálẹ́mù já.—Jer. 43:6.

Kí la lè rí kọ́ látinú ìtàn yìí? Ìkìlọ̀ tí Jèhófà fún Bárúkù nípasẹ̀ Jeremáyà jẹ́ ká rí i pé ó ń ṣe ohun kan tó kù díẹ̀ káàtó. Ó ń wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ̀. Bó o bá ní iṣẹ́ tó o fi ń gbọ́ bùkátà ara rẹ, ṣó tún yẹ kó o lo àkókò, owó àti agbára rẹ láti kàwé sí i kí ọwọ́ rẹ lè tẹ àwọn ohun tó ò ń lépa tàbí kó o lè dé ibi táwọn òbí rẹ tàbí àwọn ìbátan rẹ míì fẹ́ kó o dé?

Jẹ́ ká ronú lórí àpẹẹrẹ ti Grzegorz tó jẹ́ onímọ̀ nípa ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà. Àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ rọ̀ ọ́ pé kó kàwé sí i. Torí náà, ó lọ gba àkànṣe ìdálẹ́kọ̀ọ́ tó máa jẹ́ kó mọ púpọ̀ sí i láàárín àkókò kúkúrú. Bó ṣe di pé kò rí àkókò fún àwọn nǹkan tẹ̀mí mọ́ nìyẹn. Ó tiẹ̀ sọ pé: “Gbogbo ìgbà ni àyà mi máa ń já. Ẹ̀rí ọkàn mi máa ń dà mí láàmú torí pé ọwọ́ mi kò lè tẹ àwọn nǹkan tẹ̀mí tí mo ti fi ṣe àfojúsùn mi.”

Iṣẹ́ Tó Ń Gba Gbogbo Àkókò Ẹni

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run gba àwa Kristẹni tòótọ́ níyànjú pé ká jẹ́ òṣìṣẹ́ kára, ká sì tún jẹ́ òṣìṣẹ́ tàbí agbanisíṣẹ́ tó mọṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ohun yòówù tí ẹ bá ń ṣe, ẹ fi tọkàntọkàn ṣe é bí ẹni pé fún Jèhófà, kì í sì í ṣe fún ènìyàn.” (Kól. 3:22, 23) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sí ohun tó burú nínú jíjẹ́ òṣìṣẹ́ kára, ohun tó ṣe pàtàkì ju ìyẹn lọ ni pé ká ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ẹlẹ́dàá wa. (Oníw. 12:13) Bí iṣẹ́ bá ń gba gbogbo àkókò Kristẹni kan, ó lè mú kó fi àwọn nǹkan tẹ̀mí sí ipò kejì.

Bí iṣẹ́ bá ń gba gbogbo àkókò Kristẹni kan, ó lè ti máa rẹ̀ ẹ́ jù láti dá kẹ́kọ̀ọ́ kó sì ran ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Sólómọ́nì Ọba sọ pé “ẹ̀kúnwọ́ méjì iṣẹ́ àṣekára” sábà máa ń já sí “lílépa ẹ̀fúùfù.” Bí Kristẹni kan bá jẹ́ kí iṣẹ́ gba gbogbo àkókò òun, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìdààmú ọkàn tó máa wà fún àkókò pípẹ́. Iṣẹ́ lè bẹ̀rẹ̀ sí í gba gbogbo àkókò irú ẹni bẹ́ẹ̀ títí tí agara á fi dá a. Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ṣé ó ṣì lè “máa yọ̀ . . . kí ó sì rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ̀”? (Oníw. 3:12, 13; 4:6) Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ṣé iṣẹ́ náà ṣì máa jẹ́ kó ní agbára àti ìfẹ́ tó pọ̀ tó láti máa ṣe ojúṣe rẹ̀ nínú ìdílé kó sì tún máa kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí?

Iṣẹ́ àgbẹ̀ ni Janusz tó ń gbé ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù ń ṣe. Àmọ́ iṣẹ́ náà máa ń gba gbogbo àkókò rẹ̀. Ó tiẹ̀ sọ pé: “Àwọn èèyàn ayé fẹ́ràn mi torí pé mo máa ń lo ìdánúṣe tó pọ̀, mo sì máa ń parí iṣẹ́ kọ̀ọ̀kan tí wọ́n bá gbé fún mi. Àmọ́ ó ṣàkóbá fún mi nípa tẹ̀mí, mi ò sì lọ sóde ẹ̀rí mọ́. Nígbà tó yá, mi ò lọ sí ìpàdé mọ́. Ìgbéraga wọ̀ mí lẹ́wù débi pé mo kọ ìmọ̀ràn táwọn alàgbà fún mi, mo sì fi ìjọ Ọlọ́run sílẹ̀.”

O Lè Mú Kí Ìgbésí Ayé Rẹ Yọrí sí Rere

A ti ṣe àgbéyẹ̀wò àwọn ìgbòkègbodò mẹ́ta tí Kristẹni kan lè jẹ́ kó gba gbogbo àkókò òun, tó sì lè tipa bẹ́ẹ̀ ba àjọṣe tó ní pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́. Ǹjẹ́ ò ń lọ́wọ́ sí èyíkéyìí nínú àwọn ìgbòkègbodò náà? Bó o bá dáhùn pé bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ìbéèrè, ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àtàwọn àlàyé táá fẹ́ ṣe yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti pinnu bóyá lóòótọ́ lo fẹ́ ṣe àṣeyọrí tàbí o kò fẹ́ bẹ́ẹ̀.

Àwọn ìgbòkègbodò tó máa ń wáyé lẹ́yìn ilé ẹ̀kọ́ àtàwọn nǹkan míì tó o máa ń ṣe nígbà tí ọwọ́ bá dilẹ̀: Báwo làwọn ìgbòkègbodò wọ̀nyí ṣe ń gbà ẹ́ lákòókò tó? Ṣé wọ́n ń gba àkókò tó o ti yà sọ́tọ̀ tẹ́lẹ̀ fún ṣíṣe àwọn nǹkan tẹ̀mí? Ṣé ìbákẹ́gbẹ́ rẹ pẹ̀lú àwọn tẹ́ ẹ jọ jẹ́ onígbàgbọ́ kì í fi bẹ́ẹ̀ gbádùn mọ́ ẹ? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ì bá dára kó o tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dáfídì Ọba, tó bẹ Jèhófà pé: “Mú mi mọ ọ̀nà tí ó yẹ kí n máa rìn.”—Sm. 143:8.

Alábòójútó arìnrìn-àjò kan ran Wiktor, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àpilẹ̀kọ yìí lọ́wọ́. Alábòójútó náà sọ fún un pé: “Mo rí i pé inú rẹ máa ń dùn gan-an tó o bá ń sọ̀rọ̀ nípa bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá tó o yàn láàyò.” Wiktor sọ pé: “Àyà mi já nígbà tó sọ bẹ́ẹ̀. Ìgbà yẹn ni mo tó wá mọ̀ pé mo ti lọ jìnnà. Kò pẹ́ púpọ̀ tí mo fi fi àwọn ọ̀rẹ́ ayé tá a jọ ń gbá bọ́ọ̀lù sílẹ̀ tí mo sì wá àwọn ọ̀rẹ́ míì nínú ìjọ.” Ní báyìí, Wiktor ti ń fìtara sin Jèhófà nínú ìjọ tó wà. Ìmọ̀ràn wo ló fún wa? Ó sọ pé: “Ní kí àwọn ọ̀rẹ́, òbí tàbí àwọn alàgbà ìjọ rẹ sọ ohun tí wọ́n bá kíyè sí nípa ìgbòkègbodò ilé ìwé rẹ fún ẹ. Kó o lè mọ̀ bóyá àwọn ìgbòkègbodò yẹn ń jẹ́ kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà tàbí wọ́n ń jẹ́ kó o jìnnà sí i.”

O sì tún lè sọ fún àwọn alàgbà ìjọ rẹ pé wàá fẹ́ láti gba àfikún àǹfààní táá jẹ́ kó o lè máa sin Ọlọ́run. Àbí kẹ̀, ṣó o lè máa ṣètìlẹyìn fún àwọn àgbàlagbà tí wọ́n nílò ẹni táá máa wà pẹ̀lú wọn tàbí ẹni táá máa ràn wọ́n lọ́wọ́, bóyá kó o máa bá wọn lọ ra nǹkan tí wọ́n nílò tàbí kó o bá wọn ṣiṣẹ́ ilé? Láìka ọjọ́ orí rẹ sí, ó lè ṣeé ṣe fún ẹ láti ṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, káwọn míì si tipa bẹ́ẹ̀ máa gbọ́ ìhìn rere tó ń fún ẹ láyọ̀.

Ilé ẹ̀kọ́ gíga: Jésù kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe ‘wá ògo ti ara wa.’ (Jòh. 7:18) Ibi yòówù kó o pinnu pé o fẹ́ kàwé dé, ṣé o ti “wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù”?—Fílí. 1:9, 10.

Grzegorz, tá a sọ pé ó jẹ́ onímọ̀ nípa ẹ̀rọ kọ̀ǹpútà, ṣe àwọn ìyípadà kan nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Ó sọ pé: “Nígbà tí mo ṣe ohun tí àwọn alàgbà sọ, mo já díẹ̀ lára àwọn nǹkan tó ń gba àkókò mi jù sílẹ̀. Mo wá rí i pé kò pọn dandan fún mi láti kàwé sí i. Ńṣe ló kàn máa fi gbogbo àkókò àti okun mi ṣòfò.” Grzegorz wá bẹ̀rẹ̀ sí í kópa púpọ̀ sí i nínú àwọn ìgbòkègbodò ìjọ. Nígbà tó ṣe, ó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ tá à ń pè ní Ilé Ẹ̀kọ́ Bíbélì fún Àwọn Àpọ́n báyìí. Kò sí àníàní pé ńṣe ni Grzegorz ‘ra àkókò pa dà’ kó bàa lè gba ìdánilẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i nínú ètò Ọlọ́run.—Éfé. 5:16.

Iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́: Ṣé iṣẹ́ rẹ ti gba gbogbo àkókò rẹ débi pé o kì í ráyè fún àwọn nǹkan tẹ̀mí mọ́? Ṣé o máa ń wáyè tó pọ̀ tó láti bá àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ sọ̀rọ̀? Ṣó máa ń jẹ́ kó o ráyè mú ọ̀nà tó o gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ sunwọ̀n sí i tó o bá níṣẹ́ nípàdé? Ṣé ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró ni ìwọ àtàwọn míì máa ń sọ? Ìwé Mímọ́ sọ pé: “Bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, kí o sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” Tí o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà wàá sì ‘rí ohun rere nítorí iṣẹ́ àṣekára rẹ.’—Oníw. 2:24; 12:13.

Janusz, tá a sọ́ pé ó jẹ́ àgbẹ̀, kò rọ́wọ́ mú nídìí iṣẹ́ rẹ̀; kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni iṣẹ́ náà dẹnu kọlẹ̀. Nígbà tó di pé owó kankan kò wọlé fún un tí gbèsè sì pọ̀ lọ́rùn rẹ̀, ó yíjú sí Jèhófà. Janusz wá ṣètò àkókò rẹ̀ dáadáa, ó sì ń sìn báyìí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà déédéé àti alàgbà nínú ìjọ tó wà. Ó sọ pé: “Mo wá rí i pé, nígbà tí mo jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun tí mo ní tẹ́ mi lọ́rùn, tí mo sì tún lo àkókò àti okun mi fún àwọn nǹkan tẹ̀mí, mo ní àlàáfíà àti ìbàlẹ̀ ọkàn.”—Fílí. 4:6, 7.

Kó o tó ṣe ohunkóhun fara balẹ̀ ronú lórí ìdí tó o fi fẹ́ ṣe é àti ohun tó o fẹ́ fi sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ. Sísin Jèhófà ló máa jẹ́ kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere. Jẹ́ kí gbogbo ohun tó o bá fẹ́ ṣe rọ̀ mọ́ iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.

Ó lè gba pé kó o ṣe àwọn àtúnṣe kan, tó fi mọ́ pípa àwọn ohun tí kò ṣe pàtàkì tì kó o bàa lè ṣàwárí fúnra rẹ “ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Àmọ́, o lè “mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere” bó o bá ń sin Jèhófà tọkàntọkàn.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A ti yí àwọn orúkọ kan pa dà.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Báwo Lo Ṣe Lè Mú Kí Ọ̀nà Rẹ Yọrí sí Rere?

Ọ̀pọ̀ nǹkan ló máa ń gbà wá lákòókò. Kí lo lè ṣe tí o kò fi ní gbójú fo ohun tó ṣe pàtàkì ní tòótọ́? Kó o tó ṣe ohunkóhun fara balẹ̀ ronú lórí ìdí tó o fi fẹ́ ṣe é àti ohun tó o fẹ́ fi sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé rẹ nípa bíbi ara rẹ láwọn ìbéèrè yìí:

ÀWỌN ÌGBÒKÈGBODÒ TÓ MÁA Ń WÁYÉ LẸ́YÌN ILÉ Ẹ̀KỌ́ ÀTÀWỌN NǸKAN MÍÌ TÓ O MÁA Ń ṢE NÍGBÀ TÍ ỌWỌ́ BÁ DILẸ̀

▪ Irú ìwà wo ni àwọn tẹ́ ẹ jọ ń kópa nínú ìgbòkègbodò náà ń hù?

▪ Báwo làwọn ìgbòkègbodò náà ṣe ń gbà ẹ́ lákòókò tó?

▪ Ṣé wọ́n lè di ohun tó o máa sọ di pàtàkì jù nínú ìgbésí ayé rẹ?

▪ Ṣé àwọn ìgbòkègbodò náà ń gba àkókò tí ò ń lò tẹ́lẹ̀ láti sin Jèhófà?

▪ Irú àwọn èèyàn wo lẹ jọ ń kópa nínú rẹ̀?

▪ Ṣó máa ń wù ẹ́ kó o wà pẹ̀lú àwọn tẹ́ ẹ jọ ń kópa nínú ìgbòkègbodò náà ju kó o wà pẹ̀lú àwọn ará?

ILÉ Ẹ̀KỌ́ GÍGA

▪ Bí o bá ní iṣẹ́ tó o fi ń gbọ́ bùkátà ara rẹ, ṣó tún yẹ kó o máa náwó nára kó o sì tún lo ọ̀pọ̀ àkókò torí àtikàwé sí i?

▪ Ṣó dìgbà tó o bá lọ sí yunifásítì kó o tó lè rówó gbọ́ bùkátà ara rẹ?

▪ Ṣé á jẹ́ kó o lè máa ráyè lọ sí ìpàdé?

▪ Ṣé o ti “wádìí dájú àwọn ohun tí ó ṣe pàtàkì jù”?

▪ Ṣó yẹ kó o túbọ̀ ní ìgbọ́kànlé pé Jèhófà lè pèsè àwọn ohun tó o nílò fún ẹ?

IṢẸ́

▪ Ṣé irú iṣẹ́ tó ò ń ṣe ń jẹ́ kó o lè ‘máa yọ̀ kó o sì máa rí ohun rere nítorí gbogbo iṣẹ́ àṣekára rẹ’?

▪ Ṣé iṣẹ́ náà ṣì máa ń jẹ́ kó o ní agbára àti ìfẹ́ tó pọ̀ tó láti máa ṣe ojúṣe rẹ nínú ìdílé kó o sì tún máa kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí?

▪ Ṣé o máa ń wáyè tó pọ̀ tó láti bá àwọn tó wà nínú ìdílé rẹ sọ̀rọ̀?

▪ Ṣé iṣẹ́ rẹ ti gba gbogbo àkókò rẹ débi pé o kì í ráyè fún àwọn nǹkan tẹ̀mí mọ́?

▪ Ṣó máa ń jẹ́ kó o ráyè mú ọ̀nà tó o gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ sunwọ̀n sí i tó o bá níṣẹ́ nípàdé?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Jèhófà kìlọ̀ fún Bárúkù pé kó má ṣe wá ipò ọlá fún ara rẹ̀