Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ìgbésí Ayé Yìí Tiẹ̀ Já Mọ́ Nǹkan Kan?

Ǹjẹ́ Ìgbésí Ayé Yìí Tiẹ̀ Já Mọ́ Nǹkan Kan?

Ǹjẹ́ Ìgbésí Ayé Yìí Tiẹ̀ Já Mọ́ Nǹkan Kan?

“ǸJẸ́ ìgbésí ayé yìí já mọ́ nǹkan kan?” Àìmọye èèyàn ló ti béèrè ìbéèrè yìí. Ó bani nínú jẹ́ pé, èrò yòówù tí àwọn èèyàn ì báà ní nípa ìgbésí ayé, síbẹ̀ ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní ‘èrò pé ìgbésí ayé àwọn jẹ́ asán, kò sì já mọ́ nǹkan kan.’ Ohun tí ọ̀gbẹ́ni Viktor E. Frankl ọmọ ilẹ̀ Austria, tó jẹ́ onímọ̀ nípa ètò àti àrùn iṣan ara sì sọ nìyẹn.

Kí nìdí tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ní irú èrò yìí? Ìdí kan ni pé, ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kárí ayé ló wà nínú ipò òṣì, tí ìbànújẹ́ sì bá wọn. Ìṣẹ́, àìsàn, ìwà ipá tó burú jáì àti ìnilára ló ń bá wọn fínra lójoojúmọ́. Ńṣe ni ìgbésí ayé wọn “kún fún ṣìbáṣìbo” gẹ́gẹ́ bí Jóòbù tó gbé láyé ìgbàanì ti sọ nípa ìyà tó ń jẹ ẹ̀dá èèyàn. (Jóòbù 14:1) Ohun tó jẹ wọ́n lógún jù lọ ni bí wọ́n ṣe máa bójú tó ọ̀ràn ara wọn lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan.

Ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn míì sì wà tí wọ́n ní owó rẹpẹtẹ. Nǹkan ṣẹnuure fún wọn, wọ́n sì ní ìtẹ́lọ́rùn ní ìgbésí ayé wọn. Àmọ́ ọ̀pọ̀ ló ṣì wà tí nǹkan kò ṣẹnuure fún. Kí nìdí? Ìdí ni pé, gbogbo ìgbà ni “ìdààmú àti àwọn ohun aṣenilọ́ṣẹ́,” bíi kí ọrọ̀ ajé dédé dojú rú tàbí kí àjálù burúkú ṣẹlẹ̀, irú bíi kí ọmọ wọn kú, èyí sì máa ń mú kí ìrètí wọn já sófo kí ayọ̀ wọn sì bà jẹ́.—Sáàmù 90:10.

Ohun míì tún wà tó ń mú káwọn èèyàn ní èrò pé ìgbésí ayé àwọn “jẹ́ asán, kò sì ní ìtumọ̀.” Kí ni nǹkan náà? Ìyẹn ni kíkúrú tí ìwàláàyè èèyàn kúrú. Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, kò bọ́gbọ́n mu pé àwa èèyàn tí Ọlọ́run dá pẹ̀lú ẹ̀bùn láti ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan ló jẹ́ pé ìwàláàyè wa kì í gùn. Ìgbẹ̀yìn àwa èèyàn máa ń jọni lójú gan-an ni, nítorí pé bí a bá tiẹ̀ la àwọn àjálù tó le koko já ní ìgbésí ayé wa pàápàá, bópẹ́ bóyá ikú máa ń gba gbogbo nǹkan lọ́wọ́ wa.—Oníwàásù 3:19, 20.

Ṣé Títí Láé ni Ìgbésí Ayé Yìí Máa Jẹ́ Asán?

Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì láyé ìgbàanì ṣe àkópọ̀ ọ̀rọ̀ náà lọ́nà tó dáa. Ó rí báwọn èèyàn nígbà ayé rẹ̀ ṣe ń ṣe iṣẹ́ àṣekára, tí wọ́n ń lo ẹ̀bùn wọn àti okun wọn láti gbin nǹkan, láti kórè, láti kọ́lé, tí wọ́n sì ń lò ó láti fi bójú tó ìdílé wọn, bí a ṣe máa ń ṣe lónìí. Níkẹyìn ó béèrè pé, ‘Kí ló máa gbẹ̀yìn gbogbo nǹkan yìí?’ Ó parí ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé, gbogbo ohun tí èèyàn ń ṣe ló jẹ́, “asán . . . àti lílépa ẹ̀fúùfù.”—Oníwàásù 2:17.

Àmọ́ ṣé ohun tí Sólómọ́nì Ọba ń sọ ni pé, títí láé ni gbogbo nǹkan tí èèyàn bá ṣe yóò máa jẹ́ “asán . . . àti lílépa ẹ̀fúùfù”? Rárá. Ńṣe ló kàn ń sọ bí ìgbésí ayé ṣe máa ń rí nínú ayé tí kò gún régé yìí. Àmọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa jẹ́ kó o mọ̀ pé nǹkan kò ní máa rí báyìí títí láé!

Kí lo lè ṣe tí wàá fi lè ní ìdánilójú yìí? A rọ̀ ẹ́ pé kó o ka àwọn àpilẹ̀kọ méjì tó tẹ̀ lé èyí. Wọ́n lè jẹ́ kó o mọ ìdí tó fi jọ pé ìgbésí ayé kò já mọ́ nǹkan kan, bí ìṣòro yìí ṣe máa yanjú àti bí o ṣe lè mú kí ìgbésí ayé rẹ dára nísinsìnyí pàápàá.