Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Kẹ́kọ̀ọ́ Látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?

Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a béèrè àwọn ìbéèrè tó o ti lè máa ṣe kàyéfì nípa wọn, a sì tún sọ ibi tó o ti lè rí ìdáhùn wọn kà nínú Bíbélì rẹ. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti bá ẹ sọ̀rọ̀ lórí ohun tí àwọn ìdáhùn náà jẹ́.

1. Kí ni Ìjọba Ọlọ́run?

Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ ìjọba kan ní ọ̀run. Òun ló máa rọ́pò gbogbo ìjọba tó wà lónìí, á sì mú kí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ ní ọ̀run àti ní ayé. Nítorí náà, Ìjọba Ọlọ́run ló máa bá wa yanjú ìṣòro wa, ìyẹn bí kò ṣe sí ìjọba rere ní báyìí.—Ka Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 6:9, 10.

Àmọ́, ó yẹ kí ìjọba kan ní ọba. Nítorí náà, Jèhófà ti yan Jésù Ọmọ rẹ̀ láti jẹ́ ọba Ìjọba Ọlọ́run.—Ka Lúùkù 1:30-33.

2. Kí nìdí tó fi jẹ́ pé Jésù lẹ́ni tó tọ́ láti jẹ́ Alákòóso náà?

Ọmọ Ọlọ́run ló tọ́ láti jẹ́ Ọba náà, nítorí pé, ó láàánú, ó máa ń ṣe ohun tó tọ́ nígbà gbogbo, ó sì lágbára láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́. (Mátíù 11:28-30) Lẹ́yìn tí Jésù jíǹde, ó lọ sí ọ̀run, ó sì dúró ní ọwọ́ ọ̀tún Jèhófà. (Hébérù 10:12, 13) Níkẹyìn, Ọlọ́run fún un ní agbára pé kó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso láti ọ̀run.—Ka Dáníẹ́lì 7:13, 14.

3. Àwọn wo ló máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù?

Àwùjọ kan tí wọ́n pè ní, àwọn “ẹni mímọ́” ni Ọlọ́run yàn láti ṣàkóso pẹ̀lú Jésù ní ọ̀run. (Dáníẹ́lì 7:27) Àwọn àpọ́sítélì Jésù tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ ni àkọ́kọ́ lára àwọn ẹni mímọ́ tí Jèhófà yàn. Jèhófà ṣì ń bá a nìṣó títí di àkókò yìí láti máa yan àwọn olóòótọ́ lọ́kùnrin lóbìnrin láti wà lára àwọn ẹni mímọ́ náà. Bíi Jésù, àwọn èèyàn yìí ń jíǹde pẹ̀lú ara ẹ̀mí sí ọ̀run.—Ka Jòhánù 14:1-3; 1 Kọ́ríńtì 15:42-45.

Àwọn mélòó ló ń lọ sí ọ̀run? Jésù pè wọ́n ní “agbo kékeré.” (Lúùkù 12:32) Iye wọn lápapọ̀ máa jẹ́ ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000], wọ́n sì máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù lé ilẹ̀ ayé lórí.—Ka Ìṣípayá 5:9, 10; 14:1.

4. Ìgbà wo ni Ìjọba Ọlọ́run bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso?

Jésù di Ọba ní ọdún 1914. * Ní àkókò díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà náà, ó fi Sátánì àtàwọn ẹ̀mí èṣù rẹ̀ sọ̀kò sí ayé. (Ìṣípayá 12:7-10, 12) Láti ìgbà yẹn ni ìṣòro ọmọ aráyé ti pọ̀ sí i. Ogun, ìmìtìtì ilẹ̀, ìyàn, àjàkálẹ̀ àrùn àti ìwà àìlófin jẹ́ ara àmì tó fi hàn pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí. (2 Tímótì 3:1-5) Gbogbo àwọn tó bá fẹ́ láti jàǹfààní nínú Ìjọba Ọlọ́run ní láti kẹ́kọ̀ọ́ kí wọ́n sì di ọmọlẹ́yìn Jésù tó jẹ́ Ọba náà.—Ka Lúùkù 21:7, 10, 11, 31, 34, 35.

5. Àwọn nǹkan wo ni Ìjọba Ọlọ́run ń ṣe?

Nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù tó kárí ayé, Ìjọba Ọlọ́run ti ṣèrànwọ́ fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ní gbogbo orílẹ̀-èdè kí wọ́n lè mọ ọ̀nà Ọlọ́run. (Mátíù 24:14) Ìjọba yìí máa dáàbò bo “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí wọ́n fi ara wọn sábẹ́ Jésù, nígbà tó bá fòpin sí ìṣàkóso búburú tó ń darí ayé ní báyìí.—Ka Ìṣípayá 7:9, 10, 13-17.

Láàárín ẹgbẹ̀rún ọdún, Ìjọba yìí máa sọ ayé yìí di Párádísè. Àmọ́ níkẹyìn, Jésù máa gbé Ìjọba náà pa dà fún Bàbá rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 15:24-26) Ǹjẹ́ ẹnì kan wà tó wù ẹ́ láti sọ ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run fún?—Ka Sáàmù 37:10, 11, 29.

Fún ìsọfúnni síwájú sí i, ka orí 8 àti 9 ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Fún ẹ̀kún-rẹ́rẹ́ àlàyé lórí bí àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣe fi hàn pé ọdún 1914 ni Jésù di Ọba, ka ojú ìwé 215 sí 218 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.