Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Wàá Gbọ́ Ìkìlọ̀ Tó Ṣe Kedere Tí Jèhófà Ń fún wa?

Ṣé Wàá Gbọ́ Ìkìlọ̀ Tó Ṣe Kedere Tí Jèhófà Ń fún wa?

Ṣé Wàá Gbọ́ Ìkìlọ̀ Tó Ṣe Kedere Tí Jèhófà Ń fún wa?

“Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.”—AÍSÁ. 30:21.

1, 2. Kí ni Sátánì ti pinnu pé òun máa ṣe, báwo sì ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń ràn wá lọ́wọ́?

 BÓ O bá ń lọ sí ibì kan, bí àmì ojú ọ̀nà tó tọ́ka sí ibi tó ò ń lọ kò bá tọ̀nà, kì í ṣe pé ó lè ṣì ẹ́ lọ́nà nìkan ni, àmọ́ ó tún léwu. Jẹ́ ká wá sọ pé ọ̀rẹ́ rẹ kan kìlọ̀ fún ẹ pé ẹni ibi kan ti mọ̀ọ́mọ̀ yí ohun tí wọ́n kọ sára àmì ojú ọ̀nà náà pa dà kó lè fi ẹ̀mí àwọn arìnrìn-àjò tí kò bá fura wewu. Ṣé wàá gbọ́ ìkìlọ̀ náà àbí o kò ní gbọ́?

2 Sátánì ni ẹni ibi tá a mẹ́nu kàn nínú àpèjúwe yìí, ó sì ti pinnu láti ṣì wá lọ́nà. (Ìṣí. 12:9) Gbogbo ewu tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí ni Sátánì máa ń lò láti mú ká yà kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè ayérayé. (Mát. 7:13, 14) A dúpẹ́ pé Ọlọ́run wa olóore-ọ̀fẹ́ ń kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe jẹ́ kí Sátánì ṣì wá lọ́nà. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun mẹ́ta míì tí Sátánì fi ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà. Tá a bá ń ronú nípa bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń tọ́ wa sọ́nà ká má bàa ṣìnà, ó lè dà bíi pé Jèhófà ń tọ̀ wá lẹ́yìn, ó ń tọ́ka wa sí ibi tó yẹ ká gbà, ó wá ń sọ fún wa pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” (Aísá. 30:21) Tá a bá ń ronú lórí àwọn ìkìlọ̀ tó ṣe kedere tí Jèhófà ń fún wa yìí, a ó lè túbọ̀ pinnu lọ́kàn ara wa pé a ó máa gbọ́ àwọn ìkìlọ̀ náà.

Ẹ Má Ṣe Tẹ̀ Lé “Àwọn Olùkọ́ Èké”

3, 4. (a) Báwo ni àwọn olùkọ́ èké ṣe dà bíi kànga tí kò lómi nínú? (b) Ibo làwọn olùkọ́ èké ti sábà máa ń wá, kí ni wọ́n sì ń fẹ́?

3 Jẹ́ ká sọ pé o rìnrìn àjò lọ sí agbègbè kan tó gbẹ táútáú. Nígbà tó o wo ọ̀ọ́kán, o rí kànga kan, o sì rìn lọ sídìí kànga náà nírètí pé wàá rí omi níbẹ̀ tó o máa fi pòùngbẹ. Àmọ́, nígbà tó o débẹ̀, o rí i pé kò sómi kankan nínú kànga náà. Ó dájú pé ó máa dùn ẹ́ gan-an! Bí àwọn olùkọ́ èké ṣe rí nìyẹn, wọ́n dà bíi kànga tí kò lómi nínú. Ẹní bá wá omi òtítọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ sọ́dọ̀ wọn kò ní rí nǹkan kan mú bọ̀. Jèhófà lo àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Pétérù láti kìlọ̀ fún wa nípa àwọn olùkọ́ èké. (Ka Ìṣe 20:29, 30; 2 Pétérù 2:1-3.) Àwọn wo ni olùkọ́ èké yìí? Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí àwọn àpọ́sítélì méjì yìí láti kọ máa jẹ́ ká mọ ibi táwọn olùkọ́ èké yìí ti wá àti bí wọ́n ṣe ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà.

4 Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn alàgbà tó wà nínú ìjọ Éfésù pé: “Láàárín ẹ̀yin fúnra yín ni àwọn ènìyàn yóò ti dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà.” Pétérù náà sì sọ nínú lẹ́tà tó kọ sí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni pé: ‘Àwọn olùkọ́ èké yóò wà láàárín yín.’ Ibo ni àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé àwọn olùkọ́ èké yóò ti wá? Wọ́n lè wá látinú ìjọ. Apẹ̀yìndà sì ni irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀. * Kí ni wọ́n ń fẹ́? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti fi ètò Ọlọ́run tó ṣeé ṣe kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ nígbà kan sílẹ̀, ìyẹn kò tó wọn. Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé wọ́n ń fẹ́ láti “fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” Ìyẹn àwọn tó ti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi. Èyí tó túmọ̀ sí pé dípò kí àwọn apẹ̀yìndà lọ wá àwọn tí wọ́n máa sọ di ọmọ ẹ̀yìn tara wọn, àwọn tó ti di ọmọ ẹ̀yìn Kristi ni wọ́n fẹ́ láti fà lọ sọ́dọ̀ ara wọn. Jésù tiẹ̀ sọ pé ńṣe làwọn olùkọ́ èké náà dà bí “ọ̀yánnú ìkookò,” wọ́n ń wá bí wọ́n ṣe máa pa àwọn tó jẹ́ adúróṣinṣin nínú ìjọ jẹ, wọ́n fẹ́ ba ìgbàgbọ́ wọn jẹ́, wọ́n sì fẹ́ fà wọ́n lọ kúrò nínú òtítọ́.—Mát. 7:15; 2 Tím. 2:18.

5. Báwo ni àwọn olùkọ́ èké ṣe ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà?

5 Báwo ni àwọn olùkọ́ èké ṣe ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà? Ọgbọ́n àdàkàdekè ni wọ́n máa ń lò. Àwọn apẹ̀yìndà máa ń “yọ́ mú” èrò tó ń sọni dìbàjẹ́ wọlé wá. Bí àwọn onífàyàwọ́ tí wọ́n máa ń dọ́gbọ́n kó ẹrù òfin wọ̀lú ni wọ́n ṣe máa ń dọ́gbọ́n mú èrò ìpẹ̀yìndà wọn wọnú ìjọ. Àti pé bí ìgbà tí àwọn ọ̀daràn bá ń mú kí ohun tó jẹ́ ayédèrú fara hàn bí ojúlówó, wọ́n tún máa ń lo “àwọn ayédèrú ọ̀rọ̀,” tàbí ìjiyàn tí kò lẹ́sẹ̀ nílẹ̀ láti gbé èrò tí wọ́n hùmọ̀ kalẹ̀ bíi pé wọ́n jẹ́ òtítọ́. Wọ́n ń tan “àwọn ẹ̀kọ́ ìtannijẹ” kálẹ̀, wọ́n ‘ń lọ́ Ìwé Mímọ́,’ kó lè bá èrò wọn mu. (2 Pét. 2:1, 3, 13; 3:16) Ó ṣe kedere nígbà náà pé àwọn apẹ̀yìndà kò nífẹ̀ẹ́ wa. Bá a bá ń tẹ̀ lé wọn, ńṣe ni wọ́n máa mú ká yà kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè ayérayé.

6. Ìkìlọ̀ tó ṣe kedere wo ni Bíbélì fún wa nípa àwọn olùkọ́ èké?

6 Báwo la ṣe lè dáàbò bo ara wa kúrò lọ́wọ́ àwọn olùkọ́ èké? Bíbélì fún wa ní ìkìlọ̀ tó ṣe kedere nípa ojú tó yẹ ká fi máa wò wọ́n. (Ka Róòmù 16:17; 2 Jòhánù 9-11.) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé ká “yẹra fún wọn.” Àwọn ìtumọ̀ Bíbélì míì sọ pé ká “yí pa dà kúrò lọ́dọ̀ wọn,” ká “kúrò lọ́dọ̀ wọn,” àti ká “ta kété sí wọn!” Ìkìlọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yẹn ṣe kedere. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí dókítà bá kìlọ̀ fún ẹ pé kó o yẹra fún ẹnì kan tó ní àìsàn tó lè ranni, tó sì lè ṣekú pani. Ohun tí dókítà náà sọ á ti yé ẹ, wàá sì rí i pé o tẹ̀ lé ìkìlọ̀ tó fún ẹ. Aláìsàn làwọn apẹ̀yìndà. Bíbélì pè wọ́n ní “olókùnrùn ní èrò orí.” Ìyẹn ni wọ́n ṣe máa ń fẹ́ láti kó èèràn ran àwọn ẹlòmíì nípa lílo àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. (1 Tím. 6:3, 4) Jèhófà la lè fi wé dókítà inú àpèjúwe yìí. Gẹ́gẹ́ bí Àgbà Dókítà, ó kìlọ̀ fún wa pé ká yẹra fún àwọn apẹ̀yìndà. Ohun tí Ọlọ́run ń sọ yé wa, àmọ́ ṣé a ti pinnu láti máa ṣègbọràn sí ìkìlọ̀ rẹ̀ nínú ohun gbogbo?

7, 8. (a) Báwo la ṣe lè yẹra fún àwọn olùkọ́ èké? (b) Kí nìdí tó o fi pinnu láti má ṣe ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn olùkọ́ èké?

7 Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà yẹra fún àwọn olùkọ́ èké? A kì í jẹ́ kí wọ́n wá sínú ilé wa, a kì í sì í kí wọn. Bákan náà, a kì í ka ìwé wọn, a kì í wo ètò orí tẹlifíṣọ̀n tó bá ń gbé wọn sáfẹ́fẹ́, a kì í ka ohun tí wọ́n kọ sínú ìkànnì wọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tàbí ká fi àlàyé tiwa kún tiwọn lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Kí nìdí tá a fi pinnu láti má ṣe ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn olùkọ́ èké? Ìdí àkọ́kọ́ ni pé a nífẹ̀ẹ́ “Ọlọ́run òtítọ́,” torí náà a kò fẹ́ láti máa tẹ́tí sí àwọn ẹ̀kọ́ èké tó ta ko òtítọ́ tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Sm. 31:5; Jòh. 17:17) Ìdí mìíràn ni pé a nífẹ̀ẹ́ ètò Jèhófà tó kọ́ wa ní àwọn ẹ̀kọ́ òtítọ́ tó jẹ́ àgbàyanu. Ètò Ọlọ́run ló kọ́ wa ní orúkọ Jèhófà àti ìtumọ̀ rẹ̀, ìdí tí Ọlọ́run fi dá ilẹ̀ ayé, ipò tí àwọn òkú wà, ó sì tún kọ́ wa nípa ìrètí àjíǹde. Ǹjẹ́ o ṣì lè rántí bí ayọ̀ rẹ ṣe pọ̀ tó nígbà tó o kọ́kọ́ kẹ́kọ̀ọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí àtàwọn òtítọ́ míì tó ṣeyebíye? Torí náà, kí nìdí tí wàá fi jẹ́ kí ẹnikẹ́ni tó fẹ́ láti máa bu ẹnu àtẹ́ lu ètò tó kọ́ ẹ ní gbogbo òtítọ́ tó o mọ̀ yìí ba ayọ̀ rẹ jẹ́?—Jòh. 6:66-69.

8 Ohun yòówù káwọn olùkọ́ èké sọ, a kò ní tẹ̀ lé wọn! Kí tiẹ̀ nìdí tá a fi máa lọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tó dà bíi kànga tí kò lómi nínú yẹn, nígbà tó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n máa tàn wá jẹ tí wọ́n á sì já wa kulẹ̀? Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká pinnu láti jẹ́ adúróṣinṣin. Ká má ṣe fi Jèhófà àti ètò rẹ̀ sílẹ̀. Ètò Jèhófà kò já wa kulẹ̀ rí, ìgbà gbogbo ló máa ń fún wa ní omi òtítọ́ mímọ́ gaara tó ń tuni lára látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó ní ìmísí. Omi òtítọ́ yìí la sì fi ń pòùngbẹ wa nípa tẹ̀mí.—Aísá. 55:1-3; Mát. 24:45-47.

Ẹ Má Ṣe Tẹ̀ Lé “Àwọn Ìtàn Èké”

9, 10. Ìkìlọ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù fún Tímótì nípa “àwọn ìtàn èké,” kí ló sì ṣeé ṣe kí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn? (Tún wo àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé.)

9 Nígbà míì, ó lè rọrùn láti mọ̀ pé ẹnì kan ti yí ohun tí wọ́n kọ sára àmì ojú ọ̀nà pa dà kó lè tọ́ka sí ibòmíràn tó yàtọ̀. Àmọ́ nígbà míì ó lè ṣòro láti mọ̀ pé ẹnì kan ti hu irú ìwà ẹ̀tàn bẹ́ẹ̀. Bí àwọn nǹkan tí Sátánì fi ń ṣi àwọn èèyàn lọ́nà ṣe rí nìyẹn. Ó rọrùn láti dá àwọn kan nínú wọn mọ̀ ju àwọn mìíràn lọ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún wa nípa ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tí Sátánì ń gbà yọ́ kẹ́lẹ́ ṣọṣẹ́, ìyẹn ni nípa lílo “àwọn ìtàn èké.” (Ka 1 Tímótì 1:3, 4.) Kí Èṣù má bàa mú ká kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè, a gbọ́dọ̀ wá ìdáhùn sáwọn ìbéèrè méjì yìí, Kí ni àwọn ìtàn èké? Kí la lè ṣe tá ò fi ní máa tẹ́tí sí wọn?

10 Inú lẹ́tà tí Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ kọ sí Tímótì, tó jẹ́ alábòójútó nínú ìjọ Kristẹni, ló ti kìlọ̀ fún un nípa àwọn ìtàn èké. Ojúṣe Tímótì ni láti rí sí i pé ìjọ wà ní mímọ́ tónítóní kó sì ran àwọn onígbàgbọ́ bíi tirẹ̀ lọ́wọ́ láti jẹ́ adúróṣinṣin. (1 Tím. 1:18, 19) Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Pọ́ọ̀lù lò fún “àwọn ìtàn èké” túmọ̀ sí ìtàn àròsọ tàbí irọ́. Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé ọ̀rọ̀ yìí túmọ̀ sí “ìtàn (ẹ̀sìn) tí kò ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú bí ọ̀rọ̀ ṣe rí gangan.” (The International Standard Bible Encyclopædia) Torí náà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé irọ́ tí ẹ̀sìn èké fi ń kọ́ni, èyí táwọn èèyàn máa ń sọ nínú ìtàn àtẹnudẹ́nu, tó sì máa ń wu àwọn èèyàn láti tẹ́tí sí ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn. * Irú àwọn ìtàn bẹ́ẹ̀, wulẹ̀ máa “ń mú àwọn ìbéèrè fún ìwádìí jinlẹ̀ wá” ni, torí pé ó máa ń yọrí sí àwọn ìbéèrè tó ń fi àkókò ṣòfò, táá mú kéèyàn máa ṣe ìwádìí tí kò wúlò. Àwọn ìtàn èké jẹ́ ọ̀kan lára ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ olórí ẹlẹ̀tàn náà, Sátánì, tó ń lo àwọn irọ́ tí ẹ̀sìn èké fi ń kọ́ni àti àwọn ìtàn àròsọ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu láti mú káwọn tí kò fura yà kúrò lójú ọ̀nà tó lọ sí ìyè. Torí náà, ìkìlọ̀ tó ṣe kedere tí Pọ́ọ̀lù ń fún wa ni pé ká má ṣe máa tẹ́tí sí àwọn ìtàn èké.

11. Báwo ni Sátánì ṣe ń fi ẹ̀sìn èké tan àwọn èèyàn jẹ, ìkìlọ̀ wo la sì gbọ́dọ̀ fetí sí kó má bàa tàn wá jẹ?

11 Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìtàn èké tó lè ṣi àwọn tí kò bá kíyè sára lọ́nà? A lè sọ pé “àwọn ìtàn èké” jẹ́ irọ́ èyíkéyìí tí àwọn ẹlẹ́sìn bá pa tàbí ìtàn àròsọ tó lè mú ká yà “kúrò nínú òtítọ́.” (2 Tím. 4:3, 4) Sátánì, tó máa ń díbọ́n pé òun jẹ́ “áńgẹ́lì ìmọ́lẹ̀” ti fi ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ lo ẹ̀sìn èké láti tan àwọn èèyàn jẹ. (2 Kọ́r. 11:14) Bí àpẹẹrẹ, àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì sọ pé Kristẹni làwọn, síbẹ̀ wọ́n ń fi àwọn ẹ̀kọ́ tó kún fún ìtàn àròsọ àti ìtàn èké kọ́ni, irú bíi Mẹ́talọ́kan, iná ọ̀rún àpáàdì àti àìleèkú ọkàn. Àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tún rò pé inú Ọlọ́run dùn sí i pé káwọn máa ṣe ọdún Kérésìmesì àti Ọdún Àjíǹde. Àmọ́ inú ìtàn àròsọ àti ẹ̀sìn abọ̀rìṣà ni àwọn ààtò ayẹyẹ ọdún tó dà bíi pé kò léwu wọ̀nyẹn ti wá. Àwọn ìtàn èké wọ̀nyí kò ní ṣì wá lọ́nà tá a bá gbọ́ ìkìlọ̀ Ọlọ́run pé ká ya ara wa sọ́tọ̀ ká sì “jáwọ́ nínú fífọwọ́kan ohun àìmọ́.”—2 Kọ́r. 6:14-17.

12, 13. (a) Àwọn irọ́ wo ni Sátánì ti pa, kí ló sì yẹ ká mọ̀ nípa ọ̀kọ̀ọ̀kan lára àwọn irọ́ náà? (b) Kí la gbọ́dọ̀ ṣe kí Sátánì má bàa fi ìtàn èké ṣì wá lọ́nà?

12 Sátánì tún ti pa àwọn irọ́ míì tó lè ṣì wá lọ́nà bí a kò bá ṣọ́ra. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa mẹ́ta lára àwọn irọ́ náà. Irọ́ àkọ́kọ́ ni pé: O lè ṣe ohunkóhun tó o bá fẹ́; ọwọ́ rẹ ló kù sí láti pinnu ohun tó tọ́ àti èyí tí kò tọ́. A sábà máa ń gbọ́ ohun tó jọ èyí lórí tẹlifíṣọ̀n, nínú fíìmù, nínú àwọn ìwé ìròyìn àti lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Torí pé ìgbà gbogbo là ń gbọ́ àwọn irọ́ tó jìnnà sóòótọ́ wọ̀nyí, a lè bẹ̀rẹ̀ sí í pa àwọn ìlànà Ọlọ́run tì ká sì máa ṣe bá a ti fẹ́. Àmọ́, òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé a nílò ẹni tí yóò máa pinnu ohun tó tọ́ àtèyí tí kò tọ́ fún wa, Ọlọ́run nìkan ló ṣì lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Jer. 10:23) Irọ́ kejì ni pé: Ọlọ́run kò ní dá sí ọ̀ràn aráyé. Bá a bá gba irọ́ yìí gbọ́, a lè máa fẹ́ láti jayé òní ká sì gbàgbé ọ̀la, èyí sì lè sọ wá “di aláìṣiṣẹ́ tàbí aláìléso.” (2 Pét. 1:8) Òtítọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé ọjọ́ Jèhófà ń yára kánkán bọ̀ wá, a sì gbọ́dọ̀ máa dúró dè é. (Mát. 24:44) Irọ́ kẹta ni pé: Ọlọ́run kò kà ẹ́ sí. Bá a bá gba irọ́ Sátánì yìí gbọ́ ó lè mú ká juwọ́ sílẹ̀, ká máa rò pé Ọlọ́run kò lè nífẹ̀ẹ́ wa. Òótọ́ tó wà níbẹ̀ ni pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwọn tó ń sìn ín, ó sì mọyì wọn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan.—Mát. 10:29-31.

13 A gbọ́dọ̀ wà lójú fò, torí pé ó lè dà bíi pé kò sóhun tó burú nínú ìrònú àti ìwà tí ayé Sátánì ń gbé lárugẹ. Àmọ́, má ṣe gbàgbé pé kò sí ẹlẹ̀tàn tó dà bíi Sátánì. Àyàfi tá a bá ń ṣègbọràn sí àwọn ìránnilétí tá à ń rí gbà látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Sátánì kò ní lè tàn wá jẹ nípa lílo “àwọn ìtàn èké àdọ́gbọ́nhùmọ̀ lọ́nà àrékendá” tàbí “àwọn irọ́ tá a fọgbọ́n ẹ̀wẹ́ gbé kalẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìtàn àròsọ.” (Bíbélì The New American Bible.)—2 Pét. 1:16.

Ẹ Má Ṣe “Tẹ̀ Lé Sátánì”

14. Ìkìlọ̀ wo ni Pọ́ọ̀lù fún àwọn opó kan tí wọ́n kéré ní ọjọ́ orí, kí sì nìdí tí gbogbo wa fi gbọ́dọ̀ fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ́kàn?

14 Jẹ́ ká sọ pé o rí àmì ojú ọ̀nà kan tí ohun tí wọ́n kọ sára rẹ̀ kà pé, “Gba Ibí Yìí Bó O Bá Fẹ́ Tẹ̀ Lé Sátánì.” Èwo nínú wa ló máa fẹ́ láti gbabẹ̀? Síbẹ̀, Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún wa nípa onírúurú ọ̀nà tí Kristẹni kan tó ti ya ara rẹ̀ sí mímọ́ lè gbà “yí sápá kan láti tẹ̀ lé Sátánì.” (Ka 1 Tímótì 5:11-15.) “Àwọn opó” kan “tí wọ́n kéré ní ọjọ́ orí” ni Pọ́ọ̀lù ń bá wí, ṣùgbọ́n gbogbo wa ni ìlànà tó wà nínú ọ̀rọ̀ tó sọ kàn. Àwọn Kristẹni obìnrin tí Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ yìí fún ní ọ̀rúndún kìíní lè má mọ̀ pé Sátánì ni àwọn ń tẹ̀ lé, àmọ́ ìwà wọn fi hàn pé ohun tí wọ́n ń ṣe gangan nìyẹn. Kí la lè ṣe ká má bàa tẹ̀ lé Sátánì láìmọ̀? Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ìkìlọ̀ tí Pọ́ọ̀lù fún wa nípa òfófó tí ń pani lára.

15. Kí ni Sátánì ń fẹ́ láti ṣe, báwo sì ni Pọ́ọ̀lù ṣe jẹ́ ká mọ ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì ń lò?

15 Ńṣe ni Sátánì ń fẹ́ láti pa wá lẹ́nu mọ́ ká má bàa wàásù ìhìn rere mọ́. (Ìṣí. 12:17) Torí náà, ó ń gbìyànjú láti mú ká máa ṣe àwọn ohun tó ń fi àkókò ṣòfò tàbí ohun tó lè dá ìyapa sílẹ̀ láàárín wa. Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa àwọn opó kan nígbà ayé rẹ̀ jẹ́ ká mọ ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ tí Sátánì ń lò. Ó ní àwọn kan lára àwọn opó náà jẹ́ “olóòrayè, wọ́n ń rin ìrìn ìranù kiri.” Nínú ayé tí Íńtánẹ́ẹ̀tì àti fóònù alágbèéká ti wà káàkiri yìí, ó rọrùn láti fi àkókò tiwa àti tàwọn ẹlòmíì ṣòfò. Ọ̀nà kan tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé ká máa ka àwọn lẹ́tà orí kọ̀ǹpútà tí kò ṣe pàtàkì tàbí tó tiẹ̀ lè máà jóòótọ́ tí wọ́n kọ sí wa ká sì tún máa fi ránṣẹ́ sí àwọn míì. Pọ́ọ̀lù tún sọ pé àwọn kan lára àwọn opó náà jẹ́ “olófòófó.” Òfófó tó ń pani lára lè di ìbanilórúkọjẹ́, ó sì sábà máa ń dá ìjà sílẹ̀. (Òwe 26:20) Yálà àwọn tó ń bani lórúkọ jẹ́ mọ̀ tàbí wọn kò mọ̀, Sátánì Èṣù ni wọ́n fìwà jọ. * Lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù tún sọ pé àwọn kan lára àwọn opó náà ń ṣe ‘àtojúbọ̀ àlámọ̀rí àwọn ẹlòmíràn.’ Kì í ṣe tiwa láti máa pinnu báwọn ẹlòmíì á ṣe máa bojú tó ọ̀ràn ara wọn fún wọn. Irú ìwà àìríkan-ṣèkan tó máa ń dá wàhálà sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ kò ní jẹ́ ká lè pọkàn pọ̀ sórí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Bí a kò bá kọ́wọ́ ti iṣẹ́ tí Jèhófà gbé lé wa lọ́wọ́ mọ́, a bẹ̀rẹ̀ sí í tọ Sátánì lẹ́yìn nìyẹn. Torí náà, a gbọ́dọ̀ pinnu ẹni tá a bá fẹ́ jẹ́ tirẹ̀ láàárín Ọlọ́run àti Sátánì.—Mát. 12:30.

16. Ìkìlọ̀ wo ló yẹ ká gbọ́ ká má bàa “yí sápá kan láti tẹ̀ lé Sátánì”?

16 Bá a bá gbọ́ ìkìlọ̀ Bíbélì, a kò ní “yí sápá kan láti tẹ̀ lé Sátánì.” Ẹ jẹ́ ká gbé díẹ̀ yẹ̀ wò lára àwọn ìmọ̀ràn ọlọgbọ́n tí Pọ́ọ̀lù fún wa. Ẹ máa ‘ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa.’ (1 Kọ́r. 15:58) Bá a bá ń lọ́wọ́ déédéé nínú àwọn ìgbòkègbodò Ìjọba Ọlọ́run, a kò ní di aláìríkan-ṣèkan, a kò sì ní máa ráyè fún àwọn nǹkan tó ń fi àkókò ṣòfò. (Mát. 6:33) Ẹ máa sọ ohun tí ó “dára fún gbígbéniró.” (Éfé. 4:29) Pinnu láti má ṣe tẹ́tí sí òfófó tí ń pani lára, má sì ṣe máa sọ irú òfófó bẹ́ẹ̀ fáwọn ẹlòmíì. * Máa gbẹ̀rí àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ jẹ́ kó o sì máa bọ̀wọ̀ fún wọn. Èyí á mú ká lè máa sọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró kì í ṣe èyí tí ń pani lára. Pọ́ọ̀lù tún sọ pé ká ‘fi í ṣe ìfojúsùn wa láti má máa yọjú sí ọ̀ràn ọlọ́ràn.’ (1 Tẹs. 4:11) Fi hàn pé ọ̀ràn àwọn ẹlòmíì jẹ ẹ́ lógún, àmọ́ kó o ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó máa fi hàn pé o kò ṣe àtojúbọ̀ ọ̀ràn wọn, kó sì tún jẹ́ lọ́nà tó máa buyì kún wọn. Tún rántí pé bí ohun kan bá wà tó yẹ káwọn èèyàn dá ṣe ìpinnu lé lórí kò yẹ ká máa bá wọn ṣe irú ìpinnu bẹ́ẹ̀.—Gál. 6:5.

17. (a) Kí nìdí tí Jèhófà fi kìlọ̀ fún wa nípa àwọn ohun tí kò yẹ ká máa tẹ̀ lé? (b) Kí lo pinnu láti ṣe nípa ọ̀nà tí Jèhófà fẹ́ ká máa tọ̀?

17 A mà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ó sọ àwọn ohun tí a gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé fún wa lọ́nà tó ṣe kedere o! Ká má sì ṣe gbàgbé pé ìfẹ́ ńláǹlà tí Jèhófà ní sí wa ló mú kó fún wa ní àwọn ìkìlọ̀ tá a jíròrò nínú àpilẹ̀kọ yìí àtèyí tó ṣáájú rẹ̀. Kò fẹ́ kí Sátánì ṣì wá lọ́nà, kò sì fẹ́ kó fa ìbànújẹ́ àti ìnira fún wa. Òótọ́ ni pé ọ̀nà tí Jèhófà fẹ́ ká gbà lè há, àmọ́ ọ̀nà kan ṣoṣo tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun nìyẹn. (Mát. 7:14) Ǹjẹ́ ká má ṣe yẹsẹ̀ kúrò láé lórí ìpinnu wa láti gbọ́ ìkìlọ̀ Jèhófà, èyí tó sọ fún wa pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.”—Aísá. 30:21.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ “Ìpẹ̀yìndà” túmọ̀ sí kíkúrò nínú ìjọsìn tòótọ́, ṣíṣubú kúrò, ìyapa-kúrò, ìṣọ̀tẹ̀, ìpatì.

^ Bí àpẹẹrẹ, ìwé Tobit (tàbí Tobias), táwọn kan rò pé ó jẹ́ apá kan Bíbélì jẹ́ ọ̀kan lára irú ìtàn èké bẹ́ẹ̀. Ní nǹkan bí ọ̀rúndún kẹta ṣáájú Sànmánì Kristẹni ni wọ́n kọ ọ́, tó fi hàn pé ó ti wà nígbà ayé Pọ́ọ̀lù. Ìwé náà sọ ọ̀pọ̀ ìtàn nípa ìgbàgbọ́ nínú àwọn ohun asán, àwọn ìtàn tí kò bọ́gbọ́n mu nípa idán pípa àti iṣẹ́ oṣó lọ́nà tó fi dà bíi pé òótọ́ ni wọ́n ṣẹlẹ̀.—Wo ìwé gbédègbẹ́yọ̀ Insight on the Scriptures, Apá Kìíní, ojú ìwé 122.

^ Ọ̀rọ̀ Gíríìkì tá a túmọ̀ sí “èṣù” lédè Yorùbá ni di·aʹbo·los, èyí tó túmọ̀ sí “abanijẹ́.” Ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ ọ̀kan lára orúkọ Sátánì, òpùrọ́ àkọ́kọ́.—Jòh. 8:44; Ìṣí. 12:9, 10.

Kí Ni Ìdáhùn Rẹ?

Báwo lo ṣe lè fi àwọn ìlànà tó wà nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí sílò?

2 Pétérù 2:1-3

1 Tímótì 1:3, 4

1 Tímótì 5:11-15

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

 Má Ṣe Fọ́n Ìyẹ́ Sínú Afẹ́fẹ́

Ìtàn àtijọ́ kan táwọn Júù máa ń sọ jẹ́ ká rí ohun tí òfófó tó ń pani lára máa ń dá sílẹ̀. Àwọn èèyàn ti sọ ìtàn yìí ní onírúurú ọ̀nà, àmọ́ kókó inú ìtàn náà rèé.

Ọkùnrin kan fi ọ̀rọ̀ èké ba ọkùnrin ọlọgbọ́n kan tó wà nílùú lórúkọ jẹ́. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, abanijẹ́ yìí rí i pé ohun tóun ṣe ò dáa. Torí náà, ó lọ bá ọkùnrin ọlọgbọ́n náà kó lè tọrọ àforíjì lọ́wọ́ rẹ̀. Ó sì pinnu pé òun ò kọ ohunkóhun tó lè ná òun láti ṣàtúnṣe. Ọkùnrin ọlọgbọ́n náà sọ fún un pé ohun kan ṣoṣo lòun máa fẹ́ kó ṣe. Ó ní kí olófòófó náà mú ìrọ̀rí kan tí wọ́n kó ìyẹ́ sínú rẹ̀, kó là á, kó kó ìyẹ́ inú rẹ̀ jáde, kó sì fọ́n ìyẹ́ náà sínú afẹ́fẹ́. Ọkùnrin olófòófó yìí kò mọ ohun tí ọkùnrin ọlọgbọ́n náà ní lọ́kàn, àmọ́ ó ṣe ohun tó ní kó ṣe ó sì pa dà lọ jábọ̀ fún ọkùnrin ọlọgbọ́n náà pé òun ti ṣe tán.

Ó wá béèrè lọ́wọ́ ọkùnrin ọlọgbọ́n náà pé: “Ṣó o ti dárí jì mí báyìí?”

Ọkùnrin ọlọgbọ́n náà dáhùn pé: “Kọ́kọ́ lọ ṣa gbogbo ìyẹ́ tí afẹ́fẹ́ gbé lọ yẹn wá.”

Olófòófó náà wá sọ pé: “Báwo ni mo ṣe lè rí i ṣà? Afẹ́fẹ́ ti gbé gbogbo rẹ̀ lọ.”

Ọkùnrin ọlọgbọ́n yẹn wá fèsì pé: “Bó ṣe ṣòro fún ẹ láti ṣa àwọn ìyẹ́ yẹn jọ, bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe ṣòro láti ṣàtúnṣe irọ́ tó o pa láti bà mí lórúkọ jẹ́.”

Ẹ̀kọ́ inú ìtàn yìí ṣe kedere. Ẹ̀kọ́ náà sì ni pé ẹyin lohùn, bó bá ti bọ́ ńṣe ló máa ń fọ́, bó bá sì ti fọ́ kò ṣeé kó jọ mọ́. Béèyàn bá fọ̀rọ̀ ba ẹlòmíì jẹ́, irú ìbàjẹ́ bẹ́ẹ̀ kì í ṣeé tún ṣe mọ́. Torí náà, ká tó dẹ́nu lé òfófó èyíkéyìí, ó bọ́gbọ́n mu ká rántí pé ńṣe lọ̀rọ̀ náà dà bí ìgbà tá a fẹ́ fọ́n ìyẹ́ sínú afẹ́fẹ́.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Báwo làwọn kan ṣe lè jẹ́ kí àwọn apẹ̀yìndà wá sínú ilé wọn?