Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Ló Yẹ Kí Àwọn Ọmọdé Kọ́?

Kí Ló Yẹ Kí Àwọn Ọmọdé Kọ́?

Kí Ló Yẹ Kí Àwọn Ọmọdé Kọ́?

“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo.” —2 TÍMÓTÌ 3:16.

Ó YẸ kí àwọn ọmọdé kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Ibo ni wọ́n ti máa kọ́ òtítọ́ náà? Látinú ìwé ìsìn táwọn èèyàn bọ̀wọ̀ fún jù lọ kárí ayé ni, ìyẹn Bíbélì.

Bíbélì dà bíi lẹ́tà kan látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Nínú lẹ́tà yìí, Ọlọ́run sọ irú ẹni tí òun jẹ́ àti bí ó ṣe yẹ kí gbogbo àwọn ọmọ òun ṣe máa hùwà, ì báà jẹ́ ọmọdé tàbí àgbà. Wo díẹ̀ lára àwọn ẹ̀kọ́ tó wà nínú Bíbélì àti nǹkan tí àwọn ọmọdé pàápàá lè rí kọ́ nínú wọn.

Kí ni Ọlọ́run fẹ́ ká mọ̀ nípa òun?

Ohun tí Bíbélì kọ́ni: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Sáàmù 83:18.

Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́: Ẹni gidi ni Ọlọ́run, ó sì ní orúkọ.

Ohun tí Bíbélì kọ́ni: “Gbogbo ọkàn-àyà ni Jèhófà ń wá, gbogbo ìtẹ̀sí ìrònú sì ni ó ń fi òye mọ̀. Bí ìwọ bá wá a, yóò jẹ́ kí o rí òun.”—1 Kíróníkà 28:9.

Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́: Jèhófà Ọlọ́run ń bójú tó gbogbo wa títí kan àwọn ọmọdé. (Sáàmù 10:14; 146:9) Ó fẹ́ kí á mọ̀ nípa òun.

Ohun tí Bíbélì kọ́ni: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ ṣẹ́ . . . ọmọdékùnrin aláìníbaba níṣẹ̀ẹ́. Bí o bá ṣẹ́ ẹ níṣẹ̀ẹ́ pẹ́nrẹ́n, tí ó sì ké jáde sí mi pẹ́nrẹ́n, èmi yóò gbọ́ igbe ẹkún rẹ̀ láìkùnà.”—Ẹ́kísódù 22:22-24.

Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́: Jèhófà máa ń fetí sí àdúrà àwọn ọmọdé pàápàá. A lè máa bá Ọlọ́run sọ̀rọ̀, kí á sì máa sọ bí ọ̀rọ̀ ṣe rí lára wa fún un.

Ohun tí Bíbélì kọ́ni: “Léraléra ni wọ́n sì ń dán Ọlọ́run wò, àní wọ́n ṣe ohun tí ó dun Ẹni Mímọ́ Ísírẹ́lì.”—Sáàmù 78:41.

Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́: Ọ̀rọ̀ wa àti ìwà wa lè múnú Jèhófà dùn tàbí kó bà á nínú jẹ́, nítorí náà, ó yẹ ká máa ronú ká tó sọ̀rọ̀ àti ká tó hùwà.

Báwo ló ṣe yẹ kí á máa ṣe sáwọn tó yàtọ̀ sí wa?

Ohun tí Bíbélì kọ́ni: “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú, ṣùgbọ́n ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.”—Ìṣe 10:34, 35.

Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́: Bí Ọlọ́run bá tẹ́wọ́ gba àwọn èèyàn tó wá láti ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, kò yẹ kí á máa rò pé a ṣe pàtàkì ju àwọn yòókù lọ nítorí pé àwọ̀ ara wọn tàbí ìrísí ojú wọn yàtọ̀ sí tiwa.

Ohun tí Bíbélì kọ́ni: “Kí ẹ wà ní ìmúratán nígbà gbogbo láti ṣe ìgbèjà níwájú olúkúlùkù ẹni tí ó bá fi dandan béèrè lọ́wọ́ yín ìdí fún ìrètí tí ń bẹ nínú yín, ṣùgbọ́n kí ẹ máa ṣe bẹ́ẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú inú tútù àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.”—1 Pétérù 3:15.

Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́: Nígbà tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀sìn, ó yẹ ká sọ èrò wa pẹ̀lú ìdánilójú, àmọ́ kì í ṣe pẹ̀lú ìkanra. A tún ní láti fi ọ̀wọ̀ hàn fún àwọn tí ẹ̀kọ́ ìsìn wọn yàtọ̀ sí tiwa.

Báwo ló ṣe yẹ ká máa ṣe sí àwọn ará ilé wa?

Ohun tí Bíbélì kọ́ni: “Ẹ̀yin ọmọ, ẹ jẹ́ onígbọràn sí àwọn òbí yín nínú ohun gbogbo, nítorí èyí dára gidigidi nínú Olúwa.”—Kólósè 3:20.

Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́: Nígbà táwọn ọmọ bá jẹ́ onígbọràn, ìyẹn fi hàn pé wọ́n fẹ́ràn òbí wọn, wọ́n sì fẹ́ láti wu Ọlọ́run.

Ohun tí Bíbélì kọ́ni: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe.”—Kólósè 3:13.

Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́: Nígbà míì, àwọn èèyàn àtàwọn ará ilé wa pàápàá máa ń ṣe ohun tó dùn wá. Àmọ́, tá a bá fẹ́ kí Ọlọ́run dárí jì wá, a gbọ́dọ̀ kọ́ bí a ṣe ń dárí ji àwọn èèyàn.—Mátíù 6:14, 15.

Kí nìdí tó fi yẹ ká jẹ́ olóòótọ́ àti onínúure?

Ohun tí Bíbélì kọ́ni: “Fi èké ṣíṣe sílẹ̀, [àmọ́] kí olúkúlùkù yín máa bá aládùúgbò rẹ̀ sọ òtítọ́.”—Éfésù 4:25.

Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́: Nígbà tí a bá ń sọ òtítọ́, Ọlọ́run là ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀, a ó sì múnú rẹ̀ dùn. Tá a bá sọ ọ́ dàṣà láti máa purọ́, a máa dà bí ọ̀tá Ọlọ́run, ìyẹn Èṣù tó jẹ́ “baba irọ́.”—Jòhánù 8:44; Títù 1:2.

Ohun tí Bíbélì kọ́ni: “Gbogbo ohun tí ẹ bá fẹ́ kí àwọn ènìyàn máa ṣe sí yín, kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sí wọn.”—Mátíù 7:12.

Ẹ̀kọ́ tá a rí kọ́: A gbọ́dọ̀ máa gba ti àwọn ará ilé wa àti ti àwọn aládùúgbò wa rò. Nígbà tí a bá fi “ìmọ̀lára fún ọmọnìkejì” hàn, àwọn èèyàn á hùwà sí wa lọ́nà rere.—1 Pétérù 3:8; Lúùkù 6:38.

Àwọn àpẹẹrẹ yẹn fi hàn pé, àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì lè mú kí àwọn ọmọdé di ẹni tó moore, tó ń bọ̀wọ̀ fúnni, tó sì máa ń gba tẹni rò nígbà tí wọ́n bá dàgbà. Àmọ́ ta ló yẹ kí ó kọ́ àwọn ọmọdé ní ẹ̀kọ́ wọ̀nyí?