Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ta Ló Yẹ Kí Ó Kọ́ Àwọn Ọmọdé Nípa Ọlọ́run?

Ta Ló Yẹ Kí Ó Kọ́ Àwọn Ọmọdé Nípa Ọlọ́run?

Ta Ló Yẹ Kí Ó Kọ́ Àwọn Ọmọdé Nípa Ọlọ́run?

“Ọmọ ilé ẹ̀kọ́ kan kò ga ju olùkọ́ rẹ̀ lọ, ṣùgbọ́n gbogbo ẹni tí a fún ní ìtọ́ni lọ́nà pípé yóò dà bí olùkọ́ rẹ̀.” —LÚÙKÙ 6:40.

ÀWỌN òbí kan rò pé àwọn kò tóótun láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Ọlọ́run. Wọ́n lè rò pé àwọn kò fi bẹ́ẹ̀ kàwé tàbí ohun táwọn mọ̀ nípa ẹ̀sìn kò tó nǹkan. Nítorí náà, wọ́n á fẹ́ láti fi iṣẹ́ pàtàkì yìí sílẹ̀ fún ẹbí wọn kan tàbí olórí ẹ̀sìn kan láti máa bá wọn ṣe é.

Àmọ́, ta lẹni tó yẹ kó kọ́ àwọn ọmọdé ní òtítọ́ nípa ẹ̀sìn àti ìlànà ìwà rere? Ṣàgbéyẹ̀wò ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí, kí o sì fi wé àwárí tí àwọn olùṣèwádìí ṣe.

Kí Ni Ojúṣe Bàbá?

Ohun tí Bíbélì kọ́ni: “Ẹnyin baba, ẹ máṣe mu awọn ọmọ nyin binu; ṣugbọn ẹ ma tọ wọn ninu ẹkọ́ ati ikilọ Oluwa.”—Éfésù 6:4, Bibeli Mimọ.

Àwárí tí àwọn olùṣèwádìí ṣe: Àǹfààní wo ni àwọn bàbá máa jẹ tí wọ́n bá jẹ́ ẹni tó fọwọ́ pàtàkì mú ẹ̀sìn? Àpilẹ̀kọ kan tó sọ̀rọ̀ nípa àwọn bàbá, ìyẹn Fathers’ Religious Involvement and Early Childhood Behavior, tí wọ́n tẹ̀ jáde ní ọdún 2009, sọ pé: “Tí àwọn ọkùnrin bá dara pọ̀ mọ́ ẹ̀sìn kan, ìyẹn lè mú kí wọ́n di bàbá rere. Ẹ̀sìn máa ń ní ipa rere lórí èèyàn, ó máa ń jẹ́ kéèyàn rí àtìlẹ́yìn látọ̀dọ̀ àwọn téèyàn jọ ń ṣe ẹ̀sìn, ó tún ń pèsè ẹ̀kọ́ àti ìtọ́sọ́nà nípa béèyàn ṣe máa gbé ìgbésí ayé rẹ̀.”

Bíbélì sọ ọ̀pọ̀ nǹkan nípa ìdí tí ojúṣe bàbá fi ṣe pàtàkì nínú títọ́ ọmọ dàgbà. (Òwe 4:1; Kólósè 3:21; Hébérù 12:9) Àmọ́, ṣé ohun tí Bíbélì sọ ṣì wúlò lónìí? Lọ́dún 2009, ilé ẹ̀kọ́ University of Florida tẹ àpilẹ̀kọ kan jáde tó sọ ipa tí àwọn bàbá ń kó lórí àwọn ọmọ wọn. Àwọn olùṣèwádìí ti rí i pé àwọn ọmọ tí bàbá wọn tọ́ lọ́nà tó dáa sábà máa ń jẹ́ agbatẹnirò àti ẹni tó níyì lọ́wọ́ ara wọn. Irú àwọn ọmọ bẹ́ẹ̀ tí wọ́n jẹ́ ọkùnrin kì í fi bẹ́ẹ̀ ṣìwà hù, orí àwọn tí wọ́n jẹ́ obìnrin sì máa ń pé dáadáa. Ó dájú pé, ìmọ̀ràn Bíbélì ṣì wúlò gan-an.

Báwo Ni Ojúṣe Ìyá Ti Ṣe Pàtàkì Tó?

Ohun tí Bíbélì kọ́ni: “Má [ṣe] ṣá òfin ìyá rẹ tì.”—Òwe 1:8.

Àwárí tí àwọn olùṣèwádìí ṣe: Lọ́dún 2006, ìwé kan tó sọ nípa àwọn ọmọdé, ìyẹn Handbook of Child Psychology sọ pé: “Nígbà tá a gbé ìṣirò lé ìyàtọ̀ tó wà láàárín àkókò tí bàbá àti ìyá máa ń fi bá ọmọ kan ṣoṣo sọ̀rọ̀, àkókò tí ìyà ń lò fi nǹkan bí ìlọ́po méje ju ti bàbá lọ, ohun tó sì máa ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ nìyẹn.” Tí ìyá bá ń lo irú àkókò bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ọmọ kan, ìyẹn fi hàn pé ọ̀rọ̀, ìṣe àti ìwà ìyá máa ń kó ipa tó pọ̀ láti mú kí ọmọ kan di ọmọlúwàbí.

Nígbà tí ìyá àti bàbá bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti kọ́ àwọn ọmọ wọn ní òtítọ́ nípa Ọlọ́run, ó kéré tán, ẹ̀bùn iyebíye méjì ni wọ́n fún àwọn ọmọ náà. Àkọ́kọ́, àwọn ọmọ náà á ní àǹfààní láti di ọ̀rẹ́ Bàbá wọn ọ̀run, ìyẹn jẹ́ ìbádọ́rẹ̀ẹ́ tó lè ṣe wọ́n láǹfààní títí ayérayé. Èkejì, àwọn ọmọ náà á kẹ́kọ̀ọ́ látinú àpẹẹrẹ òbí wọn nípa bó ṣe yẹ kí ọkọ àti aya máa fọwọ́ sowọ́ pọ̀ kí wọ́n bàa lè ṣe iṣẹ́ pàtàkì kan láṣeyọrí. (Kólósè 3:18-20) Àwọn ẹlòmíì lè ṣèrànwọ́ fún àwọn òbí nípa ọ̀ràn yìí, àmọ́ ojúṣe àwọn òbí ni pé kí wọ́n fúnra wọn kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Ọlọ́run àti ohun tí Ọlọ́run fẹ́ kí ìdílé máa ṣe.

Àmọ́, báwo ló ṣe yẹ kí àwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn? Ọ̀nà wo ló dára jù lọ tí wọ́n lè gbà kọ́ wọn?