Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí ni Amágẹ́dọ́nì?

Kí ni Amágẹ́dọ́nì?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Kí ni Amágẹ́dọ́nì?

▪ Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn, ọ̀rọ̀ náà “Amágẹ́dọ́nì” máa ń mú kéèyàn ronú nípa ìparun yán-án-yán, ìyẹn ogun runlérùnnà, àjálù tó pọ̀ rẹpẹtẹ tàbí kí mímóoru tí ayé túbọ̀ ń móoru fa ìparun bá ilẹ̀ ayé. Àmọ́ bí Bíbélì ṣe lo ọ̀rọ̀ náà Amágẹ́dọ́nì yàtọ̀ sí àwọn nǹkan yìí. Nígbà náà, kí ni Amágẹ́dọ́nì tí Bíbélì sọ?

Ọ̀rọ̀ náà, “Amágẹ́dọ́nì” (“Ha–Mágẹ́dọ́nì”) wà nínú ìwé Ìṣípayá inú Bíbélì. Ó sọ nípa ogun àrà ọ̀tọ̀ kan, ìyẹn “ogun ọjọ́ ńlá Ọlọ́run Olódùmarè,” nínú èyí tí “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé” ti kó ara wọn jọ, tí wọ́n fẹ́ bá Ọlọ́run ja ìjà àjàkẹ́yìn. Ọ̀pọ̀ ibi ni Ìwé Mímọ́ tún ti sọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ ogun yìí.—Ìṣípayá 16:14-16; Ìsíkíẹ́lì 38:22, 23; Jóẹ́lì 3:12-14; Lúùkù 21:34, 35; 2 Pétérù 3:11, 12.

Kí làwọn nǹkan tó máa ṣẹlẹ̀ nígbà ogun yìí? Ìwé Ìṣípayá sọ fún wa lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ bí ó ṣe máa ṣẹlẹ̀, ó ní: “Àwọn ọba ilẹ̀ ayé àti àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wọn . . . kóra jọpọ̀ láti bá ẹni tí ó jókòó sórí ẹṣin àti ẹgbẹ́ ọmọ ogun rẹ̀ ja ogun.” Jésù Kristi Ọmọ Ọlọ́run ni “ẹni tí ó jókòó sórí ẹṣin,” òun ni Ọlọ́run yàn láti ṣáájú ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ áńgẹ́lì láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá Ọlọ́run. (Ìṣípayá 19:11-16, 19-21) Ìwé Jeremáyà 25:33 sọ bí iye àwọn ọ̀tá Ọlọ́run tó máa kú ṣe pọ̀ tó, ó ní: “Àwọn tí Jèhófà pa yóò sì wà dájúdájú ní ọjọ́ yẹn láti ìpẹ̀kun kan ilẹ̀ ayé títí lọ dé ìpẹ̀kun kejì ilẹ̀ ayé.”

Kí nìdí tó fi yẹ kí ogun Amágẹ́dọ́nì jà? Àwọn orílẹ̀-èdè kò fara mọ́ ọn pé Ọlọ́run ni Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run, kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ni wọ́n ń gbé àṣẹ tiwọn kalẹ̀. (Sáàmù 24:1) Ìwé Sáàmù 2:2, ṣàlàyé ìwà àfojúdi tí wọ́n ń hù, ó ní: “Àwọn ọba ilẹ̀ ayé mú ìdúró wọn, àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga sì ti wọ́ jọpọ̀ ṣe ọ̀kan lòdì sí Jèhófà àti lòdì sí ẹni àmì òróró rẹ̀.”

Ńṣe làwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí dà bí àwọn tó máa ń gba ilé onílé, tí wọ́n ń sọ pé àwọn làwọn ni ilé náà, tí wọ́n sì tún ń bà á jẹ́. Àwọn orílẹ̀-èdè òde òní ń pa ilẹ̀ ayé run wọ́n sì ń ba afẹ́fẹ́ ilẹ̀ ayé jẹ́. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa yánpọnyánrin yìí pé: “Àwọn orílẹ̀-èdè kún fún ìrunú, ìrunú [Ọlọ́run] sì dé.” Nítorí náà, Ọlọ́run yóò “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18) Ọlọ́run ti pinnu pé, Amágẹ́dọ́nì ni òun máa fi yanjú ọ̀ràn nípa ẹni tó lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ alákòóso àwọn èèyàn.—Sáàmù 83:18.

Ìgbà wo ni Amágẹ́dọ́nì máa jà? Ọmọ Ọlọ́run sọ ní kedere pé: “Ní ti ọjọ́ àti wákàtí yẹn, kò sí ẹnì kankan tí ó mọ̀ ọ́n, àwọn áńgẹ́lì ọ̀run tàbí Ọmọ pàápàá kò mọ̀ ọ́n, bí kò ṣe Baba nìkan.” (Mátíù 24:36) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí ọ̀rọ̀ ṣe rí nìyẹn, síbẹ̀ nígbà tí Jésù Kristi Ọba Ajagun yìí ń sọ̀rọ̀ nípa Amágẹ́dọ́nì, ó fi kún un pé: “Wò ó! Mo ń bọ̀ bí olè. Aláyọ̀ ni ẹni tí ó wà lójúfò.” (Ìṣípayá 16:15) Nítorí náà, ogun tó máa kárí ayé yìí ní í ṣe pẹ̀lú àkókò tí Kristi máa wà níhìn-ín, ìyẹn ìgbà tó máa bẹ̀rẹ̀ sí í jọba, àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì sì fi hàn pé, ó ti ń jọba báyìí.

Àwọn tó kọ̀ jálẹ̀ láti jáwọ́ nínú ìwà ìbàjẹ́ nìkan ni Amágẹ́dọ́nì máa pa, “ogunlọ́gọ̀ ńlá” èèyàn ló sì máa là á já. (Ìṣípayá 7:9-14) Wọ́n máa rí i nígbà tí ọ̀rọ̀ yìí bá ṣẹ pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́; dájúdájú, ìwọ yóò sì fiyè sí ipò rẹ̀, òun kì yóò sì sí. Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:10, 11.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]

“Àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà”