Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ò Ń Fi Jèhófà Ṣe Ìpín Rẹ?

Ǹjẹ́ Ò Ń Fi Jèhófà Ṣe Ìpín Rẹ?

Ǹjẹ́ Ò Ń Fi Jèhófà Ṣe Ìpín Rẹ?

“Ẹ máa bá a nìṣó . . . ní wíwá ìjọba náà àti òdodo Rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí ni a ó sì fi kún un fún yín.”—MÁT. 6:33.

1, 2. (a) Àwọn wo ni “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” tí ìwé Gálátíà 6:16 sọ̀rọ̀ nípa wọn ṣàpẹẹrẹ? (b) Nínú Mátíù 19:28, àwọn wo ni “ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá” ṣàpẹẹrẹ?

 BÍ O bá ń ka Bíbélì tó o sì rí orúkọ náà Ísírẹ́lì, kí ló máa ń wá sọ́kàn rẹ? Ṣé o máa ń ronú nípa Jékọ́bù ọmọ Ísákì, tí Ọlọ́run yí orúkọ rẹ̀ pa dà sí Ísírẹ́lì? Àbí ńṣe lo máa ń ronú nípa àwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀, ìyẹn orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́? Ísírẹ́lì tẹ̀mí ńkọ́? Bí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa Ísírẹ́lì tẹ̀mí, èyí sábà máa ń tọ́ka sí “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” ìyẹn àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] èèyàn tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yàn láti di ọba àti àlùfáà lókè ọ̀run. (Gál. 6:16; Ìṣí. 7:4; 21:12) Àmọ́ ronú nípa ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ tí Bíbélì gbà tọ́ka sí ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá nínú Mátíù 19:28.

2 Jésù sọ pé: “Ní àtúndá, nígbà tí Ọmọ ènìyàn bá jókòó sórí ìtẹ́ ògo rẹ̀, ẹ̀yin tí ẹ ti tọ̀ mí lẹ́yìn yóò jókòó pẹ̀lú sórí ìtẹ́ méjìlá, ẹ óò máa ṣèdájọ́ ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá.” Nínú ẹsẹ yìí, “ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá” ni àwọn tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù tí Ọlọ́run fi ẹ̀mí yàn máa ṣèdájọ́ wọn, tí wọ́n sì ń fojú sọ́nà fún jíjogún ìyè ayérayé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. Wọ́n máa jàǹfààní látinú iṣẹ́ àlùfáà tí àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì máa ṣe.

3, 4. Àpẹẹrẹ àtàtà wo làwọn ẹni àmì òróró tó jẹ́ olùṣòtítọ́ fi lélẹ̀?

3 Bíi ti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì ìgbà àtijọ́, àwọn tó jẹ́ ẹni àmì òróró lóde òní náà ka iṣẹ́ ìsìn wọn sí àǹfààní tí Ọlọ́run fi jíǹkí wọn. (Núm. 18:20) Àwọn ẹni àmì òróró kò retí pé kí Ọlọ́run fún àwọn ní ìpínlẹ̀ tàbí ibì kan tó máa jẹ́ tiwọn lórí ilẹ̀ ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń wọ̀nà fún dídi ọba àti àlùfáà lókè ọ̀run pẹ̀lú Jésù Kristi. Wọ́n á máa bá a nìṣó láti máa sin Jèhófà lẹ́nu iṣẹ́ yìí, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí ìwé Ìṣípayá 4:10, 11 sọ nípa àwọn ẹni àmì òróró nínú ipò wọn ní ọ̀run.—Ìsík. 44:28.

4 Lórí ilẹ̀ ayé níbí, àwọn ẹni àmì òróró ń gbé ìgbé ayé wọn lọ́nà tó fi hàn pé Jèhófà ni ìpín wọn. Àǹfààní tí wọ́n ní láti máa sin Ọlọ́run ni wọ́n ń fi sípò àkọ́kọ́. Wọ́n ń lo ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Kristi, wọ́n ń tọ̀ ọ́ lẹ́yìn nígbà gbogbo, wọ́n sì ń tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ‘pípè àti yíyàn wọn dájú.’ (2 Pét. 1:10) Ipò tí ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn wà àti ohun tí wọ́n lè ṣe yàtọ̀ síra. Síbẹ̀, wọn kò torí pé ó níbi tí agbára wọ́n mọ kí wọ́n wá máa ṣe ohun tí kò tó nǹkan nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n fi iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́, wọ́n sì ń ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe. Wọ́n tún fi àpẹẹrẹ tó dára lélẹ̀ fún àwọn tó ń retí láti gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.

5. Báwo ni gbogbo àwọn Kristẹni ṣe lè ní Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ìpín wọn, kí sì nìdí tí ìyẹn fi lè ṣòro?

5 Yálà à ń fojú sọ́nà fún lílọ sọ́run tàbí láti máa gbé lórí ilẹ̀ ayé, a gbọ́dọ̀ ‘sẹ́ níní ara wa, ká gbé òpó igi oró wa, ká sì máa tọ Kristi lẹ́yìn nígbà gbogbo.’ (Mát. 16:24) Bí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn tó ń fojú sọ́nà fún gbígbé nínú Párádísè ilẹ̀ ayé náà sì ṣe ń sin Ọlọ́run nìyí tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé Kristi. Wọn kì í wulẹ̀ ṣe ìwọ̀nba díẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ Jèhófà bí wọ́n bá mọ̀ pé agbára àwọn gbé e láti ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ọ̀pọ̀ ti jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tẹ́ wọn lọ́rùn kí wọ́n bàa lè di aṣáájú-ọ̀nà. Àwọn míì máa ń gbìyànjú láti ṣe aṣáájú-ọ̀nà fún oṣù mélòó kan lọ́dọọdún. Síbẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan kò lè ṣe aṣáájú-ọ̀nà, wọ́n máa ń ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Irú àwọn bẹ́ẹ̀ dà bíi Màríà tó jẹ́ olùfọkànsìn, tó da òróró onílọ́fínńdà sí orí Jésù. Jésù sọ pé: “Ó ṣe iṣẹ́ tí ó dára púpọ̀ sí mi. . . . Ó ṣe ohun tí ó lè ṣe.” (Máàkù 14:6-8) Ó lè má rọrùn fún wa láti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, torí pé inú ayé tí Sátánì ń ṣàkóso rẹ̀ là ń gbé. Síbẹ̀, à ń tiraka tokuntokun a sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà. Ní báyìí, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà mẹ́rin pàtó tá a lè gbà ṣe bẹ́ẹ̀.

Wíwá Ìjọba Ọlọ́run Lákọ̀ọ́kọ́

6. (a) Báwo làwọn èèyàn ṣe sábà máa ń fi hàn pé ayé yìí nìkan làwọn fi ṣe ìpín àwọn? (b) Kí nìdí tó fi sàn jù pé ká máa wo nǹkan lọ́nà tí Dáfídì gbà wò ó?

6 Jésù kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wá Ìjọba náà àti òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́. Torí pé àwọn èèyàn ayé sábà máa ń fi àǹfààní ara wọn sípò àkọ́kọ́, Bíbélì pè wọ́n ní “àwọn ènìyàn ètò àwọn nǹkan yìí . . . tí ìpín wọ́n ń bẹ nínú ìgbésí ayé yìí.” (Ka Sáàmù 17:1, 13-15.) Ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi ti Ẹlẹ́dàá wọn ṣe mọ́, ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ ni wọ́n ń lé kiri, wọn ò sì mọ̀ ju kí wọ́n bímọ, kí wọ́n sì rí ogún fi sílẹ̀ fọ́mọ. Inú ayé yìí nìkan ni ìpín wọ́n wà. Àmọ́, ohun tó jẹ Dáfídì lógún ni bó ṣe máa ní “orúkọ rere” lọ́dọ̀ Jèhófà. Ìyẹn sì ni ohun tí ọmọ Ọlọ́run dámọ̀ràn lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn pé kí gbogbo wá ṣe. (Oníw. 7:1, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Bíi ti Ásáfù, Dáfídì rí i pé bóun ṣe fi Jèhófà ṣe Ọ̀rẹ́ òun sàn ju kóun fi àǹfààní ti ara òun sí ipò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé. Inú rẹ̀ dùn láti máa bá Ọlọ́run rìn. Ní àkókò tá à ń gbé yìí, ọ̀pọ̀ Kristẹni ti fi àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí ṣáájú iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́.

7. Àwọn ìbùkún wo ni arákùnrin kan gbádùn rẹ̀ torí pé ó fi Ìjọba Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́?

7 Ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Jean-Claude tó wá láti orílẹ̀-èdè Central African Republic. Alàgbà ni, ó sì ní ọmọ mẹ́ta. Ó ṣòro láti rí iṣẹ́ ní orílẹ̀-èdè yẹn, ọ̀pọ̀ ló sì máa ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe kí iṣẹ́ má bàa bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Lọ́jọ́ kan, ọ̀gá rẹ̀ níbi iṣẹ́ sọ fún un pé kó bẹ̀rẹ̀ sí í fi gbogbo ọjọ́ tó wà nínú ọ̀sẹ̀ ṣiṣẹ́ alẹ́, kó sì máa bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní aago mẹ́fà ààbọ̀ ìrọ̀lẹ́. Jean-Claude ṣàlàyé fún un pé, yàtọ̀ sí pé òun fẹ́ pèsè ohun tí ìdílé òun nílò nípa tara, ó tún pọn dandan pé kí òun ràn wọ́n lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run. Ó tún fi kún un pé òun ní iṣẹ́ tí òun ń bójú tó nínú ìjọ. Kí ni ọ̀gá rẹ̀ wá sọ? Ó sọ pé: “Bó o bá láǹfààní láti ríṣẹ́ ṣe, o gbọ́dọ̀ gbàgbé gbogbo nǹkan yòókù, tó fi mọ́ ìyàwó rẹ, àwọn ọmọ rẹ àti gbogbo ìṣòro rẹ. Iṣẹ́ rẹ ni kó o gbájú mọ́, ohun mìíràn kò sì gbọ́dọ̀ di iṣẹ́ rẹ lọ́wọ́. Yan èyí tó o bá fẹ́: ẹ̀sìn rẹ tàbí iṣẹ́ rẹ.” Ká sọ pé ìwọ ni Jean-Claude, kí ni wàá ṣe? Jean-Claude mọ̀ pé bí iṣẹ́ bá bọ́ lọ́wọ́ òun, Ọlọ́run kò ní fi òun sílẹ̀. Ó ṣì máa ní púpọ̀ láti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, Jèhófà sì máa ràn án lọ́wọ́ kó lè pèsè àwọn ohun kòṣeémánìí tí ìdílé rẹ̀ nílò. Torí náà, lọ́sẹ̀ yẹn, kò pa ìpàdé tí wọ́n máa ń ṣe láàárín ọ̀sẹ̀ jẹ. Lẹ́yìn yẹn, ó múra láti lọ síbi iṣẹ́, láìmọ̀ bóyá wọ́n máa jẹ́ kóun ṣiṣẹ́. Bí wọ́n ṣe ké sí i lórí fóònù nìyẹn. Wọ́n ti lé ọ̀gá náà kúrò lẹ́nu iṣẹ́, àmọ́ iṣẹ́ kò bọ́ lọ́wọ́ arákùnrin wa.

8, 9. Ọ̀nà wo la lè gbà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì tá a bá fẹ́ kí Jèhófà jẹ́ ìpín wa?

8 Àwọn kan tí wọ́n ti dojú kọ ipò tó dà bíi pé ó lè mú kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ wọn lè ti ronú pé, ‘Báwo ni mo ṣe máa bójú tó ojúṣe mi láti pèsè ohun tí ìdílé mi nílò?’ (1 Tím. 5:8) Yálà o ti dojú kọ irú ipò tó jọ èyí rí tàbí o kò tíì dojú kọ ọ́ rí, ó ṣeé ṣe kí ìrírí tí ìwọ fúnra rẹ ti ní mú kó dá ẹ lójú pé bó bá jẹ́ pé Ọlọ́run ni ìpín rẹ tó o sì mọyì àǹfààní tó o ní láti máa sìn ín, kò ní já ẹ kulẹ̀ láé. Nígbà tí Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa bá a nìṣó ní wíwá ìjọba náà, ó mú kó dá wọn lójú pé: “Gbogbo nǹkan mìíràn wọ̀nyí,” irú bí ohun tí wọ́n máa jẹ, tí wọ́n máa mu, tàbí tí wọ́n máa wọ̀ sọ́rùn, “ni a ó sì fi kún un fún [wọn].”—Mát. 6:33.

9 Ronú nípa àwọn ọmọ Léfì, tí wọn kò rí ilẹ̀ gbà gẹ́gẹ́ bí ogún. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìjọsìn mímọ́ ni wọ́n fi sípò àkọ́kọ́, wọ́n gbọ́dọ̀ ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà máa pèsè ohun ìgbẹ́mìíró fún àwọn, torí ó sọ fún wọn pé: “Èmi ni ìpín rẹ.” (Núm. 18:20) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe inú tẹ́ńpìlì nípa tara la ti ń sin Jèhófà bíi ti àwọn àlùfáà àti àwọn ọmọ Léfì, àwa náà lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn, ká sì ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà máa pèsè fún wa. Bá a ṣe túbọ̀ ń sún mọ́ òpin àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí, ló túbọ̀ ń ṣe pàtàkì pé ká máa ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run lágbára láti pèsè fún wa.—Ìṣí. 13:17.

Bá A Ṣe Lè Máa Wá Òdodo Ọlọ́run Lákọ̀ọ́kọ́

10, 11. Báwo ni àwọn kan ṣe gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà ní ti ọ̀ràn iṣẹ́ wọn? Fúnni ní àpẹẹrẹ kan.

10 Jésù tún rọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n ‘máa bá a nìṣó ní wíwá òdodo Ọlọ́run lákọ̀ọ́kọ́.’ (Mát. 6:33) Èyí túmọ̀ sí fífi ìlànà Jèhófà nípa ohun tó tọ́ àti ohun tí kò tọ́ ṣáájú ohun táwọn èèyàn rò pé ó tọ́. (Ka Aísáyà 55:8, 9.) O lè rántí pé nígbà kan, àwọn èèyàn kan máa ń gbin tábà, wọ́n máa ń ta àwọn nǹkan bíi sìgá, wọ́n ń kọ́ àwọn míì ní iṣẹ́ ogun jíjà, tàbí kí wọ́n máa ṣe àwọn nǹkan ìjà ogun kí wọ́n sì tún máa tà á. Lẹ́yìn tí ọ̀pọ̀ lára wọn ti kẹ́kọ̀ọ́, tí òtítọ́ sì ti yé wọn, wọ́n yàn láti wá iṣẹ́ míì ṣe, wọ́n sì tóótun láti ṣe ìrìbọmi.—Aísá. 2:4; 2 Kọ́r. 7:1; Gál. 5:14.

11 Andrew jẹ́ ọ̀kan lára àwọn tó wá iṣẹ́ míì ṣe. Nígbà tí òun àti ìyàwó rẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà, wọ́n pinnu pé òun làwọn máa sìn. Andrew nífẹ̀ẹ́ iṣẹ́ rẹ̀ gan-an, àmọ́ ó fi iṣẹ́ náà sílẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé ilé iṣẹ́ tó ń bá ṣiṣẹ́ máa ń lọ́wọ́ sí ogun, ó sì ti múra tán láti fi òdodo Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́. Nígbà tí Andrew fi iṣẹ́ náà sílẹ̀, ó ti ní ọmọ méjì, owó ò wọlé fún un mọ́, kò sì lè ju oṣù bíi mélòó kan lọ tí ìwọ̀nba owó tó kù sí i lọ́wọ́ fi máa tán. Tá a bá fojú èèyàn wò ó, ó lè dà bíi pé kò ní ‘ogún’ kankan. Ó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Ọlọ́run, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í wáṣẹ́. Tí Andrew bá pa dà ronú lórí ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn, òun àti ìdílé rẹ̀ máa ń jẹ́rìí sí i pé ọwọ́ Jèhófà kò kúrú. (Aísá. 59:1) Torí pé Andrew àti ìyàwó rẹ̀ jẹ́ kí ìwọ̀nba ohun ìní tara tẹ́ wọn lọ́rùn, ó ti wá ṣeé ṣe fún wọn láti wọṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ó sọ pé: “Àwọn ìgbà kan wà tó jẹ́ pé ríronú nípa ìṣúnná owó, ilé, ìlera àti bá a ṣe ń dàgbà sí i máa ń mú ká ṣàníyàn. Àmọ́ Jèhófà kò fi wá sílẹ̀ nígbà kan. . . . A lè sọ láìsí iyè méjì kankan pé sísin Jèhófà ni ohun tó bọ́gbọ́n mu jù lọ tó sì lérè nínú jù lọ tí ẹ̀dá èèyàn lè dáwọ́ lé.” *Oníw. 12:13.

12. Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí títẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run gbapò iwájú? Sọ àwọn àpẹẹrẹ tó o mọ̀ ládùúgbò yín.

12 Jésù sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Bí ẹ bá ní ìgbàgbọ́ ìwọ̀n hóró músítádì, ẹ ó sọ fún òkè ńlá yìí pé, ‘Ṣípò kúrò ní ìhín lọ sí ọ̀hún,’ yóò sì ṣípò, kò sì sí ohunkóhun tí kì yóò ṣeé ṣe fún yín.” (Mát. 17:20) Ṣé wàá lè jẹ́ kí títẹ̀ lé àwọn ìlànà Ọlọ́run gbapò iwájú bí ìyẹn bá máa mú kí nǹkan nira fún ẹ? Bí kò bá dá ẹ lójú pé wàá lè ṣe bẹ́ẹ̀, bá àwọn míì sọ̀rọ̀ nínú ìjọ. Ó dájú pé bó o bá gbọ́ ìrírí wọn, ó máa mú kí àjọṣe tó o ní pẹ̀lú Jèhófà sunwọ̀n sí i.

Bá A Ṣe Lè Mọrírì Àwọn Ìpèsè Jèhófà

13. Tá a bá ṣiṣẹ́ kára lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kí ló yẹ kó dá wa lójú nípa àwọn ìpèsè tẹ̀mí tó ń ti ọ̀dọ̀ rẹ̀ wá?

13 Tó o bá fọwọ́ pàtàkì mú àǹfààní iyebíye tó o ní láti máa sin Jèhófà, jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ọlọ́run máa fún ẹ ní àwọn ohun tó o nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí, bó ṣe rí sí i pé àwọn ọmọ Léfì rí ohun ìgbẹ́mìíró. Tún ronú nípa Dáfídì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó wà nínú hòrò, ìyẹn ihò inú àpáta tàbí ti abẹ́ ilẹ̀, ó ṣì ní ìgbọ́kànlé pé Ọlọ́run máa pèsè fún òun. Àwa pẹ̀lú lè gbọ́kàn lé Jèhófà bó bá tiẹ̀ dà bíi pé a kò rí ọ̀nà àbáyọ. Má ṣe gbàgbé pé ìgbà tí Ásáfù wá “sínú ibùjọsìn títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run,” ló ní ìjìnlẹ̀ òye nípa ohun tó ń kó ìdààmú ọkàn bá a. (Sm. 73:17) Bákan náà, ó pọn dandan ká ní ìgbẹ́kẹ̀lé pé Jèhófà máa fún wa ní ohun tá a nílò kí ohunkóhun má bàa ba àjọṣe wa pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́. Nípa báyìí, a ó lè máa fi hàn pé a mọyì àǹfààní tá a ní láti máa sin Ọlọ́run láìka ipò yòówù tá a lè wà sí. A ó sì máa fi hàn lọ́nà yìí pé à ń jẹ́ kí Jèhófà jẹ́ ìpín wa.

14, 15. Kí ló yẹ ká ṣe bí àtúnṣe bá dé bá òye tá a ní nípa ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan, kí sì nìdí?

14 Báwo ló ṣe máa ń rí lára rẹ nígbà tí Jèhófà, tó jẹ́ Orísun ìlàlóye tẹ̀mí, bá tànmọ́lẹ̀ sórí “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run” tó wà nínú Bíbélì? (1 Kọ́r. 2:10-13) A lè rí àpẹẹrẹ tó dára jù lọ tá a lè tẹ̀ lé látinú ohun tí àpọ́sítélì Pétérù ṣe nígbà tí Jésù sọ fún àwọn tó ń bá sọ̀rọ̀ pé: “Láìjẹ́ pé ẹ jẹ ẹran ara Ọmọ ènìyàn, kí ẹ sì mu ẹ̀jẹ̀ rẹ̀, ẹ kò ní ìyè kankan nínú ara yín.” Ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn tí wọn kò lóye pé èdè ìṣàpẹẹrẹ ni Jésù lò sọ pé: “Ọ̀rọ̀ yìí ń múni gbọ̀n rìrì; ta ní lè fetí sí i?” Wọ́n pa dà “lọ sídìí àwọn nǹkan àtẹ̀yìnwá.” Àmọ́ Pétérù sọ pé: “Olúwa, ọ̀dọ̀ ta ni àwa yóò lọ? Ìwọ ni ó ní àwọn àsọjáde ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòh. 6:53, 60, 66, 68.

15 Pétérù kò ní òye kíkún nípa ohun tí Jésù ń sọ nígbà tó ní wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ ẹran ara Òun kí wọ́n sì mu ẹ̀jẹ̀ Òun. Àmọ́ àpọ́sítélì náà gbára lé Ọlọ́run láti fún òun ní ìlàlóye tẹ̀mí. Nígbà tí ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí bá ń tàn síwájú àti síwájú sí i lórí ọ̀rọ̀ kan, ǹjẹ́ o máa ń gbìyànjú láti lóye ìdí tó bá Ìwé Mímọ́ mu tí ìyípadà náà fi wáyé? (Òwe 4:18) Àwọn ará Bèróà ọ̀rúndún kìíní gba ọ̀rọ̀ náà “pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́.” (Ìṣe 17:11) Bó o bá ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ wọn, o máa túbọ̀ mọyì àǹfààní tó o ní láti máa sin Jèhófà àti láti ní in gẹ́gẹ́ bí ìpín rẹ.

Gbéyàwó Kìkì Nínú Olúwa

16. Báwo ni Ọlọ́run ṣe lè jẹ́ ìpín wa ní ìbámu pẹ̀lú àṣẹ tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 7:39?

16 Ọ̀nà mìíràn táwọn Kristẹni tún lè gbà fi hàn pé àwọn ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú àwọn ìlérí Ọlọ́run ni pé kí wọ́n máa fi ìtọ́ni Bíbélì sílò, èyí tó sọ pé ká gbéyàwó “kìkì nínú Olúwa.” (1 Kọ́r. 7:39) Ọ̀pọ̀ ti yàn láti wà láìgbéyàwó kí wọ́n má bàa ṣe ohun tó lòdì sí ìtọ́ni Ọlọ́run yìí. Ọlọ́run máa ń bójú tó àwọn tó bá ṣe bẹ́ẹ̀. Kí ni Dáfídì ṣe nígbà tó ṣe é bíi pé ó wà lóun nìkan tó sì tún dà bíi pé kò ní olùrànlọ́wọ́ kankan? Ó sọ pé: “Mo ń bá a nìṣó ní títú ìdàníyàn mi jáde níwájú [Ọlọ́run]. Mo ń bá a lọ ní sísọ̀rọ̀ nípa wàhálà mi níwájú rẹ̀. Nígbà tí àárẹ̀ mú ẹ̀mí mi nínú mi.” (Sm. 142:1-3) Wòlíì Jeremáyà fi ọ̀pọ̀ ọdún sin Ọlọ́run láìyẹsẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àpọ́n, ó sì ṣeé ṣe kí àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ sí i mú kóun náà ronú bíi ti Dáfídì. A jíròrò ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i nínú ìwé náà, Ọ̀rọ̀ Tí Ọlọ́run Bá Wa Sọ Nípasẹ̀ Jeremáyà. O lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa rẹ̀ nínú orí 8 ìwé náà.

17. Báwo ni arábìnrin kan tí kò tíì lọ́kọ ṣe kojú ìṣòro dídá wà?

17 Arábìnrin kan ní orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà sọ pé: “Mi ò pinnu rẹ̀ rí pé mi ò ní lọ́kọ. Ká ní irú ẹni tó wù mí láti fẹ́ dẹnu kọ mí ni, mo ṣe tán láti gbà. Màmá mi tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbìyànjú láti mú kí n fẹ́ ẹnikẹ́ni tó bá ṣáà ti sọ pé òun fẹ́ fẹ́ mi. Mo wá bi màmá mi pé bí ìgbéyàwó mi bá yíwọ́ ṣé wọ́n máa dáhùn fún un. Àmọ́, nígbà tí màmá mi rí i pé mo níṣẹ́ tó dáa lọ́wọ́, mò ń tọ́jú ara mi, mo sì láyọ̀, wọn ò yọ mí lẹ́nu mọ́.” Nígbà míì, ó máa ń ṣe arábìnrin yìí bíi pé ó dá wà. Ó sọ pé: “Bó bá ṣe mí bíi pé mo dá nìkan wà, mo máa ń gbìyànjú láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Kò já mi kulẹ̀ rí.” Kí ló mú kó ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Jèhófà? Ó sọ pé: “Àdúrà ràn mí lọ́wọ́ láti rí i pé òótọ́ ni Ọlọ́run wà àti pé mi ò dá wà lémi nìkan. Ẹni Gíga Jù Lọ láyé àtọ̀run ń tẹ́tí gbọ́ mi, kí wá nìdí tí mi ò fi ní gbà pé Ọlọ́run kà mí kún kí n sì máa láyọ̀?” Níwọ̀n bó ti dá a lójú pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ,” ó sọ pé: “Mo máa ń gbìyànjú láti ṣe nǹkan fáwọn ẹlòmíràn, mi ò sì ń retí pé kí wọ́n san án pa dà. Ìgbàkigbà tí mo bá ń ronú pé, ‘Kí ni mo lè ṣe fẹ́ni yìí o?’ Mo máa ń ní ayọ̀ àtọkànwá.” (Ìṣe 20:35) Kò sí àní-àní pé ó ti fi Jèhófà ṣe ìpín rẹ̀, ó sì ń gbádùn àǹfààní tó ní láti máa sìn ín.

18. Ọ̀nà wo ni Jèhófà lè gbà mú kó o jẹ́ ìpín òun?

18 Ipò yòówù kó o wà, o lè jẹ́ kí Ọlọ́run jẹ́ ìpín rẹ. Bó o ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá wà lára àwọn èèyàn rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ aláyọ̀. (2 Kọ́r. 6:16, 17) Èyí lè mú kó o jẹ́ ìpín Jèhófà bí àwọn míì ṣe láǹfààní láti jẹ́ ìpín rẹ̀ nígbà àtijọ́. (Ka Diutarónómì 32:9, 10.) Bí Ísírẹ́lì ṣe jẹ́ ìpín Ọlọ́run láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, ó lè fi ìwọ náà ṣe ìpín rẹ̀ kó sì máa bójú tó ẹ tìfẹ́tìfẹ́.—Sm. 17:8.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Wo Jí! [Gẹ̀ẹ́sì] November 2009, ojú ìwé 12 sí 14.

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí Jèhófà jẹ́ ìpín rẹ

• nípa wíwá Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́?

• nípa fífi ìmọrírì hàn fún oúnjẹ tẹ̀mí?

• nípa ṣíṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run pé ká gbéyàwó kìkì nínú Olúwa?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 13]

Jèhófà máa jẹ́ ìpín wa tá a bá fi iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ sípò àkọ́kọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àpẹẹrẹ Jeremáyà ń gbéni ró