Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

1 Ọlọ́run Kò Ṣeé Mọ̀—Ṣé Òótọ́ Ni?

1 Ọlọ́run Kò Ṣeé Mọ̀—Ṣé Òótọ́ Ni?

1 Ọlọ́run Kò Ṣeé Mọ̀—Ṣé Òótọ́ Ni?

Ohun táwọn èèyàn ń sọ: “Bí Ọlọ́run ṣe ń ṣe nǹkan kò lè yé ẹ̀dá.”

“Bàbá jẹ́ Aláìṣeélóye, Ọmọ jẹ́ Aláìṣeélóye, Ẹ̀mí Mímọ́ náà jẹ́ Aláìṣeélóye.”—Ìjẹ́wọ́ Ìgbàgbọ́ Athanasia, tó ń ṣàlàyé Mẹ́talọ́kan tí ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì ń kọ́ni.

Ohun tí Bíbélì kọ́ni: Jésù sọ pé àwọn “tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ . . . Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú” yóò rí ìbùkún gbà. (Jòhánù 17:3) Àmọ́, tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run kò ṣeé mọ̀, báwo la ṣe lè gba ìmọ̀ rẹ̀ sínú? Ọlọ́run kò fi ara rẹ̀ pa mọ́ rára, ó ń fẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ òun.—Jeremáyà 31:34.

Òótọ́ ni pé a kò lè mọ gbogbo nǹkan nípa Ọlọ́run. Àmọ́, kò yẹ kí ìyẹn yà wá lẹ́nu nítorí pé ìrònú àti ọ̀nà rẹ̀ ga ju tiwa lọ fíìfíì.—Oníwàásù 3:11; Aísáyà 55:8, 9.

Bí mímọ òtítọ́ ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́: Tó bá jẹ́ pé òótọ́ ni pé Ọlọ́run kò ṣeé mọ̀, kò ní bọ́gbọ́n mu pé kéèyàn máa sapá láti mọ̀ ọ́n? Àmọ́ ṣá o, yàtọ̀ sí pé Ọlọ́run fẹ́ kí á mọ òun, ó tún fẹ́ kí á di ọ̀rẹ́ òun tímọ́tímọ́. Ọlọ́run pe ọkùnrin olóòótọ́ náà, Ábúráhámù ní “ọ̀rẹ́ mi.” Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì pẹ̀lú sọ pé: “Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ti àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.”—Aísáyà 41:8; Sáàmù 25:14.

Ǹjẹ́ èèyàn lè jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run? Ó lè jọ pé kò ṣeé ṣe, àmọ́ ohun tí ìwé Ìṣe 17:27 sọ ni pé: “[Ọlọ́run] kò jìnnà sí ẹnì kọ̀ọ̀kan wa.” Lọ́nà wo? Nípasẹ̀ Bíbélì, Ọlọ́run fún wa ni ohun tá a nílò láti mọ òun dáadáa. *

Ó sọ orúkọ ara rẹ̀ fún wa, ìyẹn Jèhófà. (Aísáyà 42:8) Ó mú kí wọ́n ṣàkọsílẹ̀ bó ṣe ṣe sí ará ayé kí a lè mọ irú Ẹni tí ó jẹ́. Ní àfikún sí i, Ọlọ́run sọ bí ọ̀ràn ṣe máa ń rí lára òun fún wa. Ó jẹ́ “aláàánú àti olóore ọ̀fẹ́, ó ń lọ́ra láti bínú, ó sì pọ̀ yanturu ní inú-rere-onífẹ̀ẹ́ àti òtítọ.” (Ẹ́kísódù 34:6) Ohun tí a bá ṣe lè mú inú rẹ̀ dùn tàbí kó bà á nínú jẹ́. Bí àpẹẹrẹ, orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ máa ń mú kí “inú rẹ̀ bàjẹ́” nígbà tí wọ́n bá ṣọ̀tẹ̀ sí i, àmọ́ àwọn tó bá ṣègbọràn sí i, máa ń mú inú rẹ̀ dùn.—Sáàmù 78:40; Òwe 27:11.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Fún ìsọfúnni síwájú sí i nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa Ọlọ́run, ka orí 1 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 4]

Bí Ọlọ́run bá jẹ́ Mẹ́talọ́kan tí kò ṣeé lóye, báwo la ṣe lè mọ Ọlọ́run?

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 4]

Mẹ́talọ́kan ní nǹkan bí ọdún 1500, Flemish School, (16th century) / H. Shickman Gallery, New York, USA / The Bridgeman Art Library International