Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

O Lè Rí “Ìmọ̀ Ọlọ́run”

O Lè Rí “Ìmọ̀ Ọlọ́run”

Sún Mọ́ Ọlọ́run

O Lè Rí “Ìmọ̀ Ọlọ́run”

JÈHÓFÀ ỌLỌ́RUN ti fún wa láǹfààní láti ní ìṣura iyebíye kan tí kò ṣeé díye lé, ó sì fẹ́ kí ọwọ́ wa tẹ̀ ẹ́. Òótọ́ ni pé ìṣura yìí kò ní sọni di ọlọ́rọ̀, àmọ́ gbogbo owó ayé yìí kò tó láti ra ohun tó máa jẹ́ ìyọrísí rẹ̀ tá a bá wá ìṣúra náà rí, ohun náà ni, ìbàlẹ̀ ọkàn, ìtẹ́lọ́rùn àti ìgbésí ayé tó dára. Kí wá ni ìṣúra yìí? Ọ̀rọ̀ tí Sólómọ́nì ọlọ́gbọ́n Ọba sọ nínú ìwé Òwe 2:1-6 ṣàlàyé rẹ̀.

Sólómọ́nì pe ìṣúra iyebíye yìí ní “ìmọ̀ Ọlọ́run,” ìyẹn òtítọ́ nípa Ọlọ́run àti òtítọ́ nípa àwọn nǹkan tí ó ní lọ́kàn láti ṣe gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú Bíbélì. (Ẹsẹ 5) Oríṣiríṣi ọ̀nà ni ìṣúra yìí pín sí.

Ẹ̀kọ́ òtítọ́. Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè bíi, Kí ni orúkọ Ọlọ́run? (Sáàmù 83:18) Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí èèyàn nígbà tó bá kú? (Sáàmù146:3, 4) Kí nìdí tá a fi wà láyé? (Jẹ́nẹ́sísì 1:26-28; Sáàmù 115:16) Ẹ gbọ́ ná, èló lèèyàn lè san fún ìdáhùn àwọn ìbéèrè yìí?

Ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n. Bíbélì sọ ọ̀nà tó dára jù lọ tá a lè gbà gbé ìgbé ayé wa. Kí lo lè ṣe tí ìgbéyàwó rẹ á fi wà pẹ́ títí? (Éfésù 5:28, 29, 33) Kí lo lè ṣe tí o fi lè tọ́ àwọn ọmọ ní àtọ́yanjú? (Diutarónómì 6:5-7; Éfésù 6:4) Kí lo lè ṣe tí wàá fi láyọ̀ ní ìgbésí ayé rẹ? (Mátíù 5:3; Lúùkù 11:28) Ẹ ò tún rí i pé ìṣúra iyebíye làwọn ìmọ̀ràn tó ṣeé gbára lé lórí àwọn kókó yìí!

Òye tó jinlẹ̀ nípa ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àti ìwà rẹ̀. Bíbélì ni olórí àwọn ibi téèyàn ti lè mọ òtítọ́ nípa Ọlọ́run. Irú ẹni wo ni Ọlọ́run jẹ́? (Jòhánù 1:18; 4:24) Ǹjẹ́ ó bìkítà nípa wa? (1 Pétérù 5:6, 7) Kí ni díẹ̀ lára àwọn olórí ìwà rẹ̀? (Ẹ́kísódù 34:6, 7; 1 Jòhánù 4:8) Èló lo rò pé èèyàn lè san fún mímọ òtítọ́ nípa Ẹlẹ́dàá wa?

Ìṣura iyebíye ni “ìmọ̀ Ọlọ́run” jẹ́ lóòótọ́. Kí lo lè ṣe láti rí i? Nínú ìwé Òwe 2:4, Sólómọ́nì sọ ohun kan téèyàn lè ṣe, níbẹ̀ ó fi ìmọ̀ yìí wé “ìṣúra fífarasin.” Àmọ́ ṣá o, ìṣúra iyebíye tó wà ní ìpamọ́ kó ní fúnra rẹ̀ jáde níbi tó wà, kó sì bọ́ sọ́wọ́ ẹni tí kò wá a. A ní láti sapá gan-an ká tó lè rí i. Bákan náà, kéèyàn tó lè rí ìmọ̀ Ọlọ́run, èèyàn ní láti wá a. Bí ìṣura tó wà lábẹ́ ilẹ̀, bẹ́ẹ̀ náà ni ìmọ̀ Ọlọ́run wà nínú Bíbélì. Kéèyàn tó lè rí i, èèyàn ní láti sapá gan-an.

Sólómọ́nì sọ ohun tó yẹ ká ṣe ká tó lè rí “ìmọ̀ Ọlọ́run.” Ọ̀rọ̀ náà, “gba àwọn àsọjáde mi” àti “fi ọkàn-àyà rẹ sí” fi hàn pé a ní láti múra ọkàn wa sílẹ̀ kó lè gba ẹ̀kọ́. (Ẹsẹ 1, 2) Ọ̀rọ̀ náà “ké pe,” “bá a nìṣó ní wíwá a” àti “bá a nìṣó ní wíwá a kiri” fi hàn pé a ní láti sapá gan-an, ká fi hàn pé lóòótọ́ la fẹ́ ìmọ̀ náà. (Ẹsẹ 3, 4) Nítorí náà, láti rí ìṣura yìí a ní láti fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tọkàntọkàn.—Lúùkù 8:15.

Tí a bá ṣe ipa tiwa láti wá ìṣura yìí, Jèhófà á ṣe ìyókù. Ẹsẹ 6 sọ pé, “Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n.” Ipasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run nìkan lèèyàn lè fi ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ òye òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. (Jòhánù 6:44; Ìṣe 16:14) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé, tó o bá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tọkàntọkàn, wàá rí “ìmọ̀ Ọlọ́run” ìyẹn ìṣura tó máa jẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ láyọ̀ kó lóyin.—Òwe 2:10-21. *

Bíbélì kíkà tá a dábàá fún October:

Òwe 1-21

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Kárí ayé, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ àwọn èèyàn tí wọ́n bá fẹ́ lóye Bíbélì lẹ́kọ̀ọ́ lọ́fẹ̀ẹ́ nínú ilé wọn. A rọ̀ ẹ́ pé kí ìwọ náà wá wọn kàn ládùúgbò rẹ tàbí kó o kọ̀wé sí àdírẹ́sì tó yẹ nínú èyí tó wà lójú ìwé 4 ìwé ìròyìn yìí.