Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Kí Á “Máa Bá A Nìṣó ní Ṣíṣọ́nà”?

Kí Nìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Kí Á “Máa Bá A Nìṣó ní Ṣíṣọ́nà”?

Kí Nìdí Tó Fi Ṣe Pàtàkì Pé Kí Á “Máa Bá A Nìṣó ní Ṣíṣọ́nà”?

“KÍ NI yóò . . . jẹ́ àmì wíwàníhìn-ín rẹ àti ti ìparí ètò àwọn nǹkan?” (Mát. 24:3) Jésù dáhùn ìbéèrè yìí nígbà tó fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní àmì kan tó ṣe kedere, tó kún tó, tó yéni, tí kò sì lọ́jú pọ̀, èyí tó wà nínú Mátíù orí 24, Máàkù orí 13 àti Lúùkù orí 21. Ó wá fi kún un pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.”—Mát. 24:42.

Bó bá jẹ́ pé òótọ́ ló máa rọrùn gan-an láti dá àmì náà mọ̀, kí nìdí tí Jésù fi fi ìṣílétí yìí kún ọ̀rọ̀ rẹ̀? Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ìdí méjì tó ṣeé ṣe kó fà á tó fi ṣe bẹ́ẹ̀. Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ìpínyà ọkàn lè mú kí àwọn kan máà kíyè sí àmì náà kí èyí ba àjọṣe wọn pẹ̀lú Ọlọ́run jẹ́ kí wọ́n má sì wà lójúfò mọ́. Ìdí kejì ni pé, Kristẹni kan lè dá àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan mọ̀ gẹ́gẹ́ bí apá kan àmì náà àmọ́ nítorí ibi tó ń gbé ó lè rò pé ọ̀ràn náà kò kan òun gbọ̀ngbọ̀n. Ó lè wá máa rò pé “ìpọ́njú ńlá” tó máa kádìí àsọtẹ́lẹ̀ Jésù ṣì máa pẹ́ kó tó dé àti pé kò tíì pọn dandan pé kí òun “máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.”—Mát. 24:21.

‘Wọn Kò Fiyè Sí I’

Jésù rán àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ létí nípa àwọn èèyàn ìgbà ayé Nóà. Kò sí báwọn èèyàn náà kò ṣe ní mọ̀ pé Nóà ṣe iṣẹ́ ìwàásù, ó kan ọkọ̀ áàkì gìrìwò àti pé ìwà ipá gbilẹ̀ nígbà yẹn. Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ ‘kò fiyè sí i.’ (Mát. 24:37-39) Bíi ti ìgbà yẹn ọ̀pọ̀ ni kì í kọbi ara sí ìkìlọ̀ lónìí. Bí àpẹẹrẹ, àmì ojú ọ̀nà tó máa ń kìlọ̀ fún àwọn awakọ̀ nípa ìwọ̀n eré tó yẹ kí wọ́n sá máa ń ṣe kedere, àmọ́ ọ̀pọ̀ ni kì í tẹ̀ lé àmì náà. Lọ́pọ̀ ìgbà, èyí ló máa ń mú kí àwọn aláṣẹ mọ àwọn ibì kan ga láwọn ojú ọ̀nà tó gba àárín ìlú kọjá kí àwọn awakọ̀ lè dín eré sísá kù bí wọ́n bá débẹ̀. Lọ́nà kan náà, Kristẹni kan lè mọ àmì tó fi hàn pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí, síbẹ̀ kí àwọn ìgbòkègbodò tó ń lọ́wọ́ sí fi hàn pé kò ka àmì náà sí. Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arielle, ọ̀dọ́ kan láti Ìwọ Oòrùn Áfíríkà nìyẹn.

Arielle fẹ́ràn bọ́ọ̀lù tí àwọn obìnrin máa ń fọwọ́ gbá, torí náà ó máa ń wò ó lórí tẹlifíṣọ̀n. Nígbà tí iléèwé rẹ̀ dá ẹgbẹ́ kan tó ń gbá bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá sílẹ̀, bó ṣe wù ú láti wà lára àwọn ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà ò jẹ́ kó lè ronú jinlẹ̀ nípa bí ìyẹn ṣe lè ba àjọṣe rẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́. Ó gbà láti máa bá wọn ṣọ́lé. Kí ló wá ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn náà? Ó ṣàlàyé pé: “Àwọn kan lára àwọn tá a jọ ń gbá bọ́ọ̀lù ní àwọn ọ̀rẹ́kùnrin tí wọ́n ń lo oògùn olóró tí wọ́n sì ń mu sìgá. Wọ́n máa ń fi mí ṣe yẹ̀yẹ́ torí pé mi ò ṣe bíi tiwọn, àmọ́ mo rò pé ìyẹn ò lè tu irun kankan lára mi. Ká tó wí ká tó fọ̀, eré bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá yẹn gan-an ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóbá fún àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà. Òun ló sì gba gbogbo ọkàn àti èrò mi. Nígbà tí mo bá wà láwọn ìpàdé ìjọ, ọkàn mi kì í sábà sí nínú ohun tó ń lọ ní Gbọ̀ngàn Ìjọba, ibi tá a ti máa ń gbá bọ́ọ̀lù ni ọkàn mi máa ń wà. Ó tún nípa tí kò dáa lórí ọ̀nà tí mo gbà ń ronú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ńṣe ni mo fẹ́ láti máa fi gbígbá bọ́ọ̀lù náà dára yá tẹ́lẹ̀, ní báyìí ó ti wá ń ṣe mí bíi pé ká ṣáà borí ní gbogbo ọ̀nà. Torí bó ṣe máa ń wù mí gan-an pé ká borí yìí, mo máa ń sapá kíkankíkan láti múra sílẹ̀. Ọkàn mi ò balẹ̀ mọ́. Mo tiẹ̀ pa àwọn ọ̀rẹ́ mi tì torí bọ́ọ̀lù àfọwọ́gbá.

“Pabanbarì ẹ̀ wá ni pé lọ́jọ́ kan tá à ń gbá bọ́ọ̀lù, wọ́n ní kí àwọn tá a jọ ń bára wa díje ju bọ́ọ̀lù sínú ilé wa torí pé a rú òfin eré. Mo ti gbára dì láti mú bọ́ọ̀lù náà kó má bàa wọnú àwọ̀n. Kí n tó mọ̀, mo ti gbàdúrà sí Jèhófà pé kó jẹ́ kí n rí bọ́ọ̀lù náà mú! Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló jẹ́ kí n rí i pé mo ti jó rẹ̀yìn gan-an nípa tẹ̀mí. Báwo ni mo ṣe mú kí ipò tẹ̀mí mi sunwọ̀n sí i?

“Mo ti wo fídíò wa tó dá lórí àwọn ọ̀dọ́, èyí tí wọ́n ṣe sórí àwo DVD, ìyẹn Young People Ask—What Will I Do With My Life? * Mo pinnu láti tún un wò kí n sì fi ẹ̀kọ́ tí mo kọ́ nínú rẹ̀ sílò. Ó ṣe tán, ohun tó jẹ́ ìṣòro fún André, ọ̀dọ́kùnrin tó wà nínú àwòkẹ́kọ̀ọ́ náà, ló jẹ́ ìṣòro fún èmi náà. Ohun tó gbàfiyèsí mi jù lọ ni ohun tí alàgbà kan dámọ̀ràn pé kí André ṣe. Ó ní kó ka Fílípì 3:8 kó sì ronú lé e lórí. Ohun tó ràn mí lọ́wọ́ nìyẹn. Mo fi ẹgbẹ́ agbábọ́ọ̀lù náà sílẹ̀.

“Nǹkan wá yàtọ̀ fún mi gan-an! Mi ò ronú mọ́ pé ó yẹ ká borí ní gbogbo ọ̀nà, mo sì ní ìbàlẹ̀ ọkàn. Mo túbọ̀ ń láyọ̀ mo sì túbọ̀ fà mọ́ àwọn ọ̀rẹ́ mi tí wọ́n jẹ́ Kristẹni. Mo ka àwọn ìgbòkègbodò tẹ̀mí sí èyí tó túbọ̀ ṣe pàtàkì. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í pọkàn pọ̀ láwọn ìpàdé ìjọ mo sì ń gbádùn wọn bíi ti tẹ́lẹ̀. Iṣẹ́ òjíṣẹ́ mi náà gbé pẹ́ẹ́lí sí i. Ní báyìí, mo máa ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ déédéé.”

Bí ohun kan bá ń pín ọkàn rẹ níyà tí kò jẹ́ kó o fiyè sí àmì tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀, ó yẹ kó o gbé ìgbésẹ̀ tó ṣe gúnmọ́ bí Arielle ti ṣe. Díẹ̀ lára àwọn ohun tó o lè gbìyànjú láti ṣe rèé. Wo ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index, táwọn kan sọ pé ó jẹ́ ìwé atọ́nà téèyàn lè fi wá ìsọfúnni tó fara sin. Níbẹ̀ ni wàá ti rí àwọn ìmọ̀ràn tó gbámúṣé àti ìtàn táwọn kan sọ nípa bí wọ́n ṣe dojú kọ àwọn ìdẹwò. Máa jàǹfààní kíkún látinú àwọn ìpàdé ìjọ nípa mímúra sílẹ̀ dáadáa kó o sì máa ṣe àkọsílẹ̀. Àwọn kan ti rí i pé ó sàn jù káwọn máa jókòó sápá iwájú láwọn ìpàdé. Bó bá kan ibi tí àwùjọ ti lè lóhùn sí ìpàdé, gbìyànjú láti tètè lóhùn sí i. Ní àfikún, máa wà lójúfò nípa tẹ̀mí nípa fífi àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ tí ìròyìn ń gbé jáde wé àmì tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ àtàwọn nǹkan mìíràn tó ń fi hàn pé a ti wà ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn.”—2 Tím. 3:1-5; 2 Pét. 3:3, 4; Ìṣí. 6:1-8.

“Ẹ Wà ní Ìmúratán”

Níbi gbogbo lágbàáyé la ti ń rí àmì tó fi hàn pé ọjọ́ ìkẹyìn la wà yìí, ó sì kárí “gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé.” (Mát. 24:7, 14) Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ń gbé láwọn ibi tí àjàkálẹ̀ àrùn, àìtó oúnjẹ, ìmìtìtì ilẹ̀, àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mìíràn tí Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ ti ń ṣọṣẹ́. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ọ̀pọ̀ àwọn míì ń gbé níbi tí àlàáfíà wà dé ìwọ̀n àyè kan tí kò sì fi bẹ́ẹ̀ sí ìṣòro. Bí ìwọ fúnra rẹ kò bá tíì rí àwọn apá kan lára àmì náà, ṣó yẹ kó o máa ronú pé ó ṣì máa pẹ́ gan-an kí ìpọ́njú ńlá tó bẹ̀rẹ̀? Kò bọ́gbọ́n mu láti ronú bẹ́ẹ̀.

Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa “àjàkálẹ̀ àrùn àti àìtó oúnjẹ.” (Lúùkù 21:11) Lákọ̀ọ́kọ́ ná, kò sọ pé àwọn nǹkan wọ̀nyí máa ṣẹlẹ̀ níbi gbogbo nígbà kan náà tàbí pé ọṣẹ́ tí wọ́n máa ṣe á dọ́gba. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé àwọn nǹkan wọ̀nyí máa ṣẹlẹ̀ “láti ibì kan dé ibòmíràn.” Torí náà, a kò lè retí pé kí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà wáyé níbi gbogbo ní àkókò kan náà. Èkejì, láìpẹ́ lẹ́yìn tí Jésù ti sọ̀rọ̀ nípa àìtó oúnjẹ, ó sọ ohun tó fi hàn pé àwọn kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn òun gbọ́dọ̀ kíyè sí ara wọn kí wọ́n má bàa jẹ àjẹjù. Ó ní: “Ẹ kíyè sí ara yín, kí ọkàn-àyà yín má bàa di èyí tí a dẹrù pa pẹ̀lú àjẹjù.” (Lúùkù 21:34) Torí náà, gbogbo Kristẹni kò gbọ́dọ̀ retí pé gbogbo apá àmì náà máa ṣẹlẹ̀ níbi táwọn wà. Kàkà bẹ́ẹ̀, Jésù sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá nǹkan wọ̀nyí tí ń ṣẹlẹ̀, kí ẹ mọ̀ pé ìjọba Ọlọ́run sún mọ́lé.” (Lúùkù 21:31) Àwọn ohun èlò ìbánisọ̀rọ̀ ìgbàlódé ti mú kó ṣeé ṣe fún wa láti rí gbogbo àpà àmì náà, yálà irú apá àmì bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀ níbi tá à ń gbé tàbí kò ṣẹlẹ̀.

Sì tún rántí pé, Jèhófà ti yan “ọjọ́ àti wákàtí” tí ìpọ́njú ńlá máa bẹ̀rẹ̀. (Mát. 24:36) Bí nǹkan ṣe ń lọ sí lórí ilẹ̀ ayé kò ní yí ọjọ́ tí Jèhófà ní lọ́kàn pa dà.

Jésù gba àwọn Kristẹni níbi gbogbo níyànjú pé: “Ẹ wà ní ìmúratán.” (Mát. 24:44) A gbọ́dọ̀ máa wà ní ìmúratán nígbà gbogbo. Àmọ́ ṣá o, kò sí bá a ṣe lè máa wà lẹ́nu iṣẹ́ Ọlọ́run lójoojúmọ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀. Kò sì sí ẹnikẹ́ni nínú wa tó mọ ohun tí òun á máa ṣe lọ́wọ́ nígbà tí ìpọ́njú ńlá bá bẹ̀rẹ̀. Àwọn míì lè máa ṣiṣẹ́ nínú pápá tàbí kí wọ́n máa bójú tó iṣẹ́ ilé. (Mát. 24:40, 41) Torí náà, kí la lè ṣe ká lè fi hàn pé a wà ní ìmúratán?

Ilẹ̀ Áfíríkà ni Emmanuel, Victorine àti àwọn ọmọ wọn obìnrin mẹ́fà ń gbé. Àmọ́, wọn kò rí gbogbo àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó para pọ̀ di àmì tí Jésù sọ yẹn lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ ní apá ibi tí wọ́n wà. Torí náà, wọ́n pinnu láti máa jíròrò àwọn nǹkan tẹ̀mí lójoojúmọ́ kó lè ṣeé ṣe fún wọn láti wà ní ìmúratán. Emmanuel ṣàlàyé pé: “Ó ṣòro láti rí àkókò tó tẹ́ gbogbo wa lọ́rùn. Níkẹyìn, a yàn láti máa lo ọgbọ̀n ìṣẹ́jú tó wà láàárín aago mẹ́fà àti aago mẹ́fà ààbọ̀ ní òwúrọ̀. Lẹ́yìn tá a bá ti yẹ ẹsẹ ojoojúmọ́ wò, a máa múra ìpínrọ̀ díẹ̀ sílẹ̀ nínú ọ̀kan lára àwọn ìtẹ̀jáde tá a máa lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ ní ìpàdé ìjọ láàárín ọ̀sẹ̀.” Ǹjẹ́ ìṣètò yìí ti ràn wọ́n lọ́wọ́ láti máa wà lójúfò? Dájúdájú, ó ti ràn wọ́n lọ́wọ́! Emmanuel ni olùṣekòkáárí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà ní ìjọ tó ń dara pọ̀ mọ́. Victorine sábà máa ń gba iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, ó sì ti ran ọ̀pọ̀ èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Gbogbo àwọn ọmọ wọn obìnrin ń tẹ̀ síwájú dáadáa nípa tẹ̀mí.

Jésù gbà wá níyànjú pé: “Ẹ máa wọ̀nà, ẹ wà lójúfò.” (Máàkù 13:33) Má ṣe jẹ́ kí àwọn ohun tí kò ní jẹ́ kó o pọkàn pọ̀ dín bó ṣe yẹ kó o wà lójúfò nípa tẹ̀mí kù. Kàkà bẹ́ẹ̀, bíi ti Arielle, máa kíyè sí àwọn ìmọ̀ràn àtàtà tá à ń rí gbà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa àti láwọn ìpàdé ìjọ. Bíi ti ìdílé Emmanuel, máa gbìyànjú lójoojúmọ́ láti ṣe ohun tó máa fi hàn pé o wà ní ìmúratán, ó sì ń “bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà.”

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Àwòkẹ́kọ̀ọ́ òde òní kan tó dá lórí bí Kristẹni kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ ṣe sapá láti ṣe ohun tó tọ́ lójú Jèhófà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]

Bí Emmanuel àti ìdílé rẹ̀ ṣe ń jíròrò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ ń mú kí wọ́n lè ‘máa wà ní ìmúratán’