Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Jẹ́ Ká Jọ Máa Yọ̀!

Ẹ Jẹ́ Ká Jọ Máa Yọ̀!

Ẹ Jẹ́ Ká Jọ Máa Yọ̀!

ŃṢE ni ayọ̀ àti ìdùnnú túbọ̀ ń di ohun àléèbá. Ọ̀pọ̀ èèyàn sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máà ní ìròyìn ayọ̀ kankan tí wọ́n lè sọ fáwọn ẹlòmíì. Irú ìgbé ayé táwọn èèyàn ń gbé lóde òní, pàápàá nínú àwọn ìlú ńláńlá, máa ń mú kí wọ́n máà fẹ́ dá sí ẹnikẹ́ni, wọ́n á sì di ẹni tí kò rí ti ẹlòmíràn rò.

Ọ̀jọ̀gbọ́n onímọ̀ nípa ìwà táwọn ohun alààyè ń hù, Alberto Oliverio, sọ pé “ó wọ́pọ̀ pé káwọn èèyàn máa dá wà. Ó sì dájú pé ìgbé ayé táwọn èèyàn ń gbé láwọn ìlú ńlá kì í jẹ́ kí wọ́n rí ti ẹlòmíì rò. Lọ́pọ̀ ìgbà, irú ìgbé ayé bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ ká fiyè sí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí alábàáṣiṣẹ́ wa, aládùúgbò wa, tàbí akọ̀wé tó ń gbowó ọjà ní ilé ìtajà tó wà ládùúgbò wa.” Èyí sì sábà máa ń mú kí irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ sorí kọ́.

Àmọ́ ipò táwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni wà yàtọ̀, èrò wọn sì yàtọ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo.” (1 Tẹs. 5:16) Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ ká máa yọ̀ ká sì tún máa bá àwọn míì yọ̀. À ń jọ́sìn Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, Jèhófà; a lóye òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì; a nírètí ìgbàlà àti ìyè ayérayé; a sì tún lè ran àwọn míì lọ́wọ́ kí àwọn náà lè rí àwọn ìbùkún wọ̀nyí gbà.—Sm. 106:4, 5; Jer. 15:16; Róòmù 12:12.

Lára ohun tá a fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀ ni pé wọ́n máa ń láyọ̀, wọ́n sì máa ń bá àwọn mìíràn yọ̀. Torí náà kò yani lẹ́nu pé Pọ́ọ̀lù sọ nínú ìwé tó kọ sí àwọn ará Fílípì pé: “Mo yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, mo sì bá gbogbo yín yọ̀. Wàyí o, lọ́nà kan náà, ẹ̀yin fúnra yín pẹ̀lú ẹ máa yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, kí ẹ sì máa bá mi yọ̀.” (Fílí. 2:17, 18) Nínú ọ̀rọ̀ ṣókí tí Pọ́ọ̀lù sọ yìí, ẹ̀ẹ̀mejì ló sọ̀rọ̀ nípa yíyọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ àti pé kí wọ́n jọ máa yọ̀.

Àmọ́, ó ṣe pàtàkì pé kí àwọn Kristẹni ṣọ́ra kí wọ́n má bàa di ẹni tí kò rí ti ẹlòmíì rò. Kò sí bí ẹni tó bá ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ ṣe lè máa bá àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ yọ̀. Torí náà, báwo la ṣe lè tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tí Pọ́ọ̀lù sọ fún wa pé ká “máa bá a lọ ní yíyọ̀ nínú Olúwa” pẹ̀lú àwọn ará wa?—Fílí. 3:1.

Gẹ́gẹ́ Bí Ará, Ẹ Jọ Máa Yọ̀

Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìgbà tí wọ́n ju Pọ́ọ̀lù sẹ́wọ̀n ní ìlú Róòmù nítorí iṣẹ́ ìwàásù tó ń ṣe ló kọ lẹ́tà rẹ̀ sí àwọn ará Fílípì. (Fílí. 1:7; 4:22) Síbẹ̀, àtìmọ́lé tó wà kò bomi paná ìtara tó ní fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, inú rẹ̀ dùn láti máa ṣe gbogbo ohun tó lè ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, ó sì gbà pé kí a ‘tú òun jáde bí ọrẹ ẹbọ ohun mímu.’ (Fílí. 2:17) Ọwọ́ tí Pọ́ọ̀lù fi mú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀ fi hàn pé a lè láyọ̀ láìka ipòkípò tá a bá wà sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Pọ́ọ̀lù wà ní àtìmọ́lé, ó sọ pé: “Ṣe ni èmi yóò tún máa bá a nìṣó ní yíyọ̀.”—Fílí. 1:18.

Pọ́ọ̀lù ló dá ìjọ tó wà ní Fílípì sílẹ̀, ó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ tó wà níbẹ̀ gan-an. Ó mọ̀ pé bí òun bá ṣàlàyé fún wọn nípa ayọ̀ tí òun ní lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ó tún máa fún wọn níṣìírí. Torí náà ó kọ̀wé pé: “Wàyí o, mo fẹ́ kí ẹ mọ̀, ẹ̀yin ará, pé àwọn àlámọ̀rí mi ti yọrí sí ìlọsíwájú ìhìn rere dípò kí ó jẹ́ òdì-kejì, tí ó fi jẹ́ pé àwọn ìdè mi ti di mímọ̀ fún gbogbo ènìyàn ní ìsopọ̀ pẹ̀lú Kristi láàárín gbogbo Ẹ̀ṣọ́ Ọba àti gbogbo àwọn yòókù.” (Fílí. 1:12, 13) Ọ̀kan lára ohun tó fún Pọ́ọ̀lù láyọ̀ tó sì jẹ́ ọ̀nà tó gbà bá àwọn arákùnrin àti arábìnrin rẹ̀ yọ̀ ni pé ó sọ ìrírí tó máa fún wọn níṣìírí yìí fún wọn. Ó dájú pé àwọn ará Fílípì náà ti ní láti bá Pọ́ọ̀lù yọ̀. Àmọ́, èyí gba pé kí wọ́n má ṣe jẹ́ kí àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù ń jìyà rẹ̀ mú kí wọ́n rẹ̀wẹ̀sì. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. (Fílí. 1:14; 3:17) Síbẹ̀ àwọn ará Fílípì ṣì lè máa mẹ́nu kan Pọ́ọ̀lù nínú àdúrà wọn, kí wọ́n máa ṣe ìrànlọ́wọ́ èyíkéyìí tí wọ́n bá lè ṣe fún un kí wọ́n sì máa tì í lẹ́yìn.—Fílí. 1:19; 4:14-16.

Ǹjẹ́ àwa náà máa ń láyọ̀ bíi ti Pọ́ọ̀lù? Ǹjẹ́ a máa ń gbìyànjú láti rí àǹfààní tó wà nínú ipò tá a bára wa àti nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni wa? Bá a bá wà pẹ̀lú àwọn arákùnrin tàbí arábìnrin wa, ó dára ká jẹ́ kí iṣẹ́ ìwàásù máa fún wa láyọ̀. Kò dìgbà tá a bá ní àwọn ìrírí tó ṣàrà ọ̀tọ̀ ká tó lè ṣe èyí. Ó lè jẹ́ pé ńṣe la gbé ọ̀rọ̀ wa kalẹ̀ lọ́nà tó gbéṣẹ́ tàbí tá a bá ẹnì kan fèrò wérò lọ́nà tó mú kó nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ Ìjọba náà. Ó sì lè jẹ́ pé ńṣe la gbádùn bá a ṣe jíròrò ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan pẹ̀lú onílé lóde ẹ̀rí. Tàbí kẹ̀ ó lè jẹ́ pé wọ́n dá wa mọ̀ gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù wa, tí èyí sì mú ká láǹfààní láti jẹ́rìí fáwọn èèyàn lọ́nà tó gbámúṣé. Sísọ irú àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀ láàárín ara wa jẹ́ ọ̀nà kan tá a lè gbà máa bára wa yọ̀.

Ọ̀pọ̀ lára àwọn èèyàn Jèhófà ti fi àwọn nǹkan kan du ara wọn kí wọ́n bàa lè máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù, wọ́n sì ń bá a lọ ní ṣíṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn aṣáájú-ọ̀nà, àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò, àwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì, àwọn míṣọ́nnárì àti àwọn òṣìṣẹ́ káyé máa ń lo ara wọn kíkankíkan lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún, wọ́n sì ń láyọ̀ bí wọ́n ti ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ṣé inú wa máa ń dùn, ṣé a sì máa ń bá wọn yọ̀? Bó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ jẹ́ ká fi hàn pé a mọrírì àwọn ẹni ọ̀wọ́n yìí tí wọ́n jẹ́ ‘alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wa fún ìjọba Ọlọ́run.’ (Kól. 4:11) A lè gbóríyìn fún wọn nígbà tá a bá wà pẹ̀lú wọn ní àwọn ìpàdé ìjọ tàbí láwọn àpéjọ àkànṣe, ti àyíká tàbí ti àgbègbè. A tún lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìtara tí wọ́n fi hàn. A lè wá “àyè” láti gbọ́ àwọn ìrírí wọn àtàwọn ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró tí wọ́n bá sọ nípa gbígbà wọ́n lálejò, bóyá ká tiẹ̀ jọ jẹun pa pọ̀.—Fílí. 4:10.

Ẹ Máa Yọ̀ Pẹ̀lú Àwọn Tó Ń Dojú Kọ Àdánwò

Bí Pọ́ọ̀lù ṣe ń fara da inúnibíni tó sì ń borí àwọn àdánwò mú kó túbọ̀ dúró lórí ìpinnu rẹ̀ pé òun á jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà. (Kól. 1:24; Ják. 1:2, 3) Torí pé ó mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ará Fílípì dojú kọ irú àdánwò tí òun dojú kọ tí ìfaradà rẹ̀ sì máa fún wọn níṣìírí, inú rẹ̀ dùn, ó sì bá wọn yọ̀. Ìyẹn ló fi kọ̀wé pé: “Ẹ̀yin ni a fún ní àǹfààní náà nítorí Kristi, kì í ṣe láti ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ nìkan ni, ṣùgbọ́n láti jìyà nítorí rẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí ẹ̀yin ní irú ìjàkadì kan náà tí ẹ rí nínú ọ̀ràn mi, tí ẹ sì ń gbọ́ nísinsìnyí nípa rẹ̀ nínú ọ̀ràn mi.”—Fílí. 1:29, 30.

Bákan náà lónìí, wọ́n máa ń ṣe inúnibíni sí àwa Kristẹni nítorí iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe. Nígbà míì wọ́n lè gbéjà kò wá, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà ó sábà máa ń jẹ́ lọ́nà ọgbọ́n ẹ̀wẹ́. Àwọn apẹ̀yìndà lè fẹ̀sùn èké kàn wá, àwọn ìbátan wa lè gbéjà kò wá, àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tàbí àwọn ọmọléèwé wa lè fi wá ṣẹ̀sín. Jésù kìlọ̀ fún wa pé ká má ṣe jẹ́ kí àwọn àdánwò yìí yà wá lẹ́nu tàbí kí wọ́n mú ká rẹ̀wẹ̀sì. Kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló yẹ kí wọ́n máa mú ká láyọ̀. Ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi. Ẹ yọ̀, kí ẹ sì fò sókè fún ìdùnnú, níwọ̀n bí èrè yín ti pọ̀ ní ọ̀run.”—Mát. 5:11, 12.

A kò gbọ́dọ̀ jáyà tàbí ká jẹ́ kí jìnnìjìnnì bò wá tá a bá gbọ́ pé àwọn arákùnrin wa ń dojú kọ inúnibíni tó le koko láwọn ilẹ̀ kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká máa yọ̀ torí pé wọ́n ń fara dà á. A lè gbàdúrà sí Jèhófà pé kó má ṣe jẹ́ kí ìgbàgbọ́ wọ́n jó rẹ̀yìn kó sì jẹ́ kí wọ́n lè má bá a nìṣó láti fara dà á. (Fílí. 1:3, 4) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ohun tá a lè ṣe fún àwọn arákùnrin wa ọ̀wọ́n wọ̀nyẹn lè má ju pé ká gbàdúrà fún wọn, a lè ran àwọn tó ń dojú kọ àdánwò nínú ìjọ tiwa lọ́wọ́. A lè fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọ́n jẹ wá lógún ká sì kọ́wọ́ tì wọ́n. A lè ṣe ohun táá mú ká máa yọ̀ pẹ̀lú wọn tá a bá ń ké sí wọn wá sílé wa lóòrèkóòrè láti dara pọ̀ mọ wá nínú Ìjọsìn Ìdílé, tá a bá jọ ń lọ sóde ẹ̀rí, tá a sì jọ ń ṣeré ìtura.

Ọ̀pọ̀ ìdí ló wà tó fi yẹ ká jọ máa yọ̀! Ẹ má ṣe jẹ́ ká fàyè gba ẹ̀mí ayé tí kì í jẹ́ kéèyàn rí ti ẹlòmíì rò, kàkà bẹ́ẹ̀ ẹ jẹ́ ká máa bá a nìṣó láti yọ̀ pẹ̀lú àwọn ará wa. Tá a bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, a máa pa kún ìfẹ́ àti ìṣọ̀kan tó wà nínú ìjọ, a sì tún máa gbádùn àjọṣe àárín àwa àti ti ẹgbẹ́ àwọn ará tá a jọ jẹ́ Kristẹni dé ìwọ̀n tó kún rẹ́rẹ́. (Fílí. 2:1, 2) Bẹ́ẹ̀ ni, “ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa,” torí Pọ́ọ̀lù rọ̀ wá pé: “Lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣe ni èmi yóò wí pé, Ẹ máa yọ̀!”—Fílí. 4:4.

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 6]

Àwòrán Àgbáyé: Replogle Globes ló yọ̀ǹda pé ká lo fọ́tò yìí