Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Tu Gbogbo Àwọn Tí Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú”

“Tu Gbogbo Àwọn Tí Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú”

“Tu Gbogbo Àwọn Tí Ń Ṣọ̀fọ̀ Nínú”

“Jèhófà ti fòróró yàn mí . . . láti tu gbogbo àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú.”—AÍSÁ. 61:1, 2.

1. Kí ni Jésù ṣe fún àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀, kí sì nìdí?

 JÉSÙ KRISTI sọ pé: “Oúnjẹ mi ni kí n ṣe ìfẹ́ ẹni tí ó rán mi àti láti parí iṣẹ́ rẹ̀.” (Jòh. 4:34) Nígbà tí Jésù ń ṣiṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé e lọ́wọ́, ó lo àwọn ànímọ́ títayọ irú èyí tí Baba rẹ̀ ní. Lára àwọn ànímọ́ náà ni ìfẹ́ ńláǹlà tí Jèhófà ní fún àwọn èèyàn. (1 Jòh. 4:7-10) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà fi ìfẹ́ yìí hàn nígbà tó sọ pé Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo.” (2 Kọ́r. 1:3) Irú ìfẹ́ yìí ni Jésù fi hàn gẹ́gẹ́ bí Aísáyà ṣe sọ tẹ́lẹ̀ pé ó máa ṣe. (Ka Aísáyà 61:1, 2.) Jésù ka àsọtẹ́lẹ̀ náà nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nínú sínágọ́gù tó wà ní Násárétì, ó sì sọ pé ó ṣẹ sí òun lára. (Lúùkù 4:16-21) Jálẹ̀ gbogbo ìgbà tí Jésù fi ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ìfẹ́ mú kó tu àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ nínú, ó fún wọn níṣìírí ó sì fi wọ́n lọ́kàn balẹ̀.

2, 3. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé kí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi máa tu àwọn ẹlòmíì nínú bí Jésù ti ṣe?

2 Ó ṣe pàtàkì pé kí gbogbo àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi máa tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú bí Jésù ti ṣe. (1 Kọ́r. 11:1) Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa tu ara yín nínú lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa gbé ara yin ró lẹ́nì kìíní-kejì.” (1 Tẹs. 5:11) Ó túbọ̀ ṣe pàtàkì pé ká máa tu àwọn ẹlòmíì nínú torí pé lákòókò tá à ń gbé yìí aráyé ń dojú kọ “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tím. 3:1) Àwọn olóòótọ́ ọkàn jákèjádò ayé túbọ̀ ń bá àwọn tí ọ̀rọ̀ àti ìwà wọn ń kó ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ báni pàdé.

3 Gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ tẹ́lẹ̀, ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn ètò àwọn nǹkan búburú yìí, ọ̀pọ̀ jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn, olùfẹ́ owó, ajọra-ẹni-lójú, onírera, asọ̀rọ̀ òdì, aṣàìgbọràn sí òbí, aláìlọ́pẹ́, aláìdúróṣinṣin, aláìní ìfẹ́ni àdánidá, aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan, afọ̀rọ̀-èké-banijẹ́, aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu, òǹrorò, aláìní ìfẹ́ ohun rere, afinihàn, olùwarùnkì, awúfùkẹ̀ pẹ̀lú ìgbéraga, olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run.” Irú ìwà báwọ̀nyí ti wá burú ju ti ìgbàkígbà rí lọ, torí pé ‘àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà ti tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.’—2 Tím. 3:2-4, 13.

4. Báwo ni ipò àwọn nǹkan ṣe rí lórí ilẹ̀ ayé lákòókò tá à ń gbé yìí?

4 Kò yẹ kí gbogbo nǹkan wọ̀nyí yà wá lẹ́nu, níwọ̀n bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti mú kó ṣe kedere pé “gbogbo ayé wà lábẹ́ agbára ẹni burúkú náà.” (1 Jòh. 5:19) “Gbogbo ayé” tí ẹsẹ Bíbélì yìí ń sọ ní nínú ètò ìṣèlú, ètò ẹ̀sìn àti ètò ìṣòwò ayé yìí títí kan gbogbo ọ̀nà tí Sátánì ń gbà tan èrò rẹ̀ kálẹ̀. Ó bá a mu nígbà náà pé Bíbélì pe Sátánì Èṣù ní “olùṣàkóso ayé” àti “ọlọ́run ètò àwọn nǹkan yìí.” (Jòh. 14:30; 2 Kọ́r. 4:4) Ipò ayé túbọ̀ ń burú sí í torí pé Sátánì ní ìbínú ńlá, ó sì mọ̀ pé sáà àkókò kúkúrú ni òun ní kí Jèhófà tó mú òun kúrò. (Ìṣí. 12:12) Ó mà fini lọ́kàn balẹ̀ o láti mọ̀ pé àkókò tí Ọlọ́run fi fàyè gba Sátánì àti ètò burúkú rẹ̀ máa tó dópin, èyí yóò sì yanjú àríyànjiyàn Sátánì nípa ipò Jèhófà gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ!—Jẹ́n., orí 3; Jóòbù, orí 2.

A Ń Wàásù Ìhìn Rere Ní Gbogbo Ayé

5. Báwo ni àsọtẹ́lẹ̀ nípa iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń ní ìmúṣẹ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí?

5 Ohun tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀ nípa àkókò líle koko tá à ń gbé yìí ti ń ní ìmúṣẹ. Ó sọ pé: “A ó . . . wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.” (Mát. 24:14) Àwọn ibi tá a ti ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run kárí ayé túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Lónìí, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó lé ní mílíọ̀nù méje àtààbọ̀ [7,500,000] wà nínú àwọn ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún ó lé méje [107,000] kárí ayé, wọ́n ń wàásù nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ìjọba Ọlọ́run yìí náà sì ni Jésù fi ṣe lájorí iṣẹ́ ìwàásù àti ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. (Mát. 4:17) Àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ń rí ìtùnú ńláǹlà gbà nípasẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe lóde òní. Abájọ tó fi jẹ́ pé ní ọdún méjì kan lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àpapọ̀ àwọn tó ṣèrìbọmi tí wọ́n sì di Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ọ̀kẹ́ méjìdínlọ́gbọ̀n ó lé ẹgbàárùn-ún àti mọ́kànlélẹ́gbẹ̀ta [570,601]!

6. Kí lèrò rẹ nípa ibi tí iṣẹ́ ìwàásù wa ti gbòòrò dé?

6 A máa túbọ̀ mọyì bí iṣẹ́ ìwàásù yìí ṣe gbòòrò tó tá a bá kíyè sí i pé ní báyìí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń túmọ̀ àwọn ìwé tó ń ṣàlàyé Bíbélì sí èdè tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] a sì ń pín wọn káàkiri. Irú èyí kò tíì ṣẹlẹ̀ rí látijọ́ táláyé ti dáyé! Ohun àrà ọ̀tọ̀ ló jẹ́ ní tòótọ́ pé apá kan wà lára ètò Jèhófà tó jẹ́ ti ilẹ̀ ayé, tó ń gbé iṣẹ́ ribiribi ṣe, tó sì ń gbòòrò sí i. Ì bá ṣòro láti ṣe gbogbo èyí láìsí ìtọ́sọ́nà àti ìtìlẹ́yìn ẹ̀mí mímọ́ tó lágbára gan-an, torí pé inú ayé tí Sátánì ń ṣàkóso là ń gbé. Torí pé à ń wàásù ìhìn rere ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé, àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ ń rí ìtùnú gbà látinú Ìwé Mímọ́ nísinsìnyí, bẹ́ẹ̀ náà sì ni àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ń rí ìtùnú gbà bí wọ́n bá gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run.

Bí A Ṣe Lè Máa Tu Àwọn Ará Wa Nínú

7. (a) Kí nìdí tí a kò fi lè retí pé kí Jèhófà mú gbogbo ohun tó ń fa wàhálà kúrò nísinsìnyí? (b) Báwo la ṣe mọ̀ pé a lè fara da inúnibíni àti ìpọ́njú?

7 Nínú ayé tí ìyà ti ń jẹ àwọn èèyàn tó sì kún fún ìwà ibi yìí, ó dájú pé àwọn nǹkan kan máa ṣẹlẹ̀ tó máa kó wàhálà bá wa. A kò lè retí pé kí Ọlọ́run mú gbogbo ohun tó ń fa ìbànújẹ́ tàbí ẹ̀dùn ọkàn kúrò kó tó di pé ó pa ètò àwọn nǹkan yìí run. Ní báyìí ná, bá a ṣe ń kojú inúnibíni tí Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀, èyí á máa dán ìdúróṣinṣin wa sí Jèhófà wò torí pé a fara mọ́ ipò rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run. (2 Tím. 3:12) Àmọ́ bí Baba wa ọ̀run ṣe ń ràn wá lọ́wọ́ tó sì ń tù wá nínú a lè dà bí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó wà ní ìlú Tẹsalóníkà ìgbàanì, tí wọ́n fara da inúnibíni àti ìpọ́njú, tí wọ́n sì fi ìgbàgbọ́ kojú rẹ̀.—Ka 2 Tẹsalóníkà 1:3-5.

8. Ẹ̀rí wo ló wà nínú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé Jèhófà máa ń tu àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú?

8 Ó dájú pé Jèhófà máa ń tu àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ nínú nígbà tí wọ́n bá nílò rẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, nígbà tí Jésíbẹ́lì, ayaba búburú náà fẹ́ pa wòlíì Èlíjà, ẹ̀rù ba wòlíì náà ó sì sá lọ, ó tiẹ̀ sọ pé òun fẹ́ kú. Àmọ́, dípò kí Jèhófà bá Èlíjà wí, ó tù ú nínú ó sì jẹ́ kó ní ìgboyà kó bàa lè ṣe ojúṣe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi wòlíì. (1 Ọba 19:1-21) Ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìjọ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní tún mú ká rí àpẹẹrẹ bí Jèhófà ṣe máa ń tu àwọn èèyàn rẹ̀ nínú. Bí àpẹẹrẹ, a kà pé àkókò kan wà tí “ìjọ jákèjádò Jùdíà àti Gálílì àti Samáríà wọnú sáà àlàáfíà, a ń gbé e ró.” Síwájú sí i, “bí ó sì ti ń rìn ní ìbẹ̀rù Jèhófà àti ní ìtùnú ẹ̀mí mímọ́, ó ń di púpọ̀ sí i ṣáá.” (Ìṣe 9:31) A mà dúpẹ́ o, pé àwa pẹ̀lú ní “ìtùnú ẹ̀mí mímọ́”!

9. Kí nìdí tí kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù fi lè tù wá nínú?

9 Bí àwa Kristẹni ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jésù Kristi tá a sì ń tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ rẹ̀, èyí máa ń tù wá nínú. Jésù sọ pé: “Ẹ wá sọ́dọ̀ mi, gbogbo ẹ̀yin tí ń ṣe làálàá, tí a sì di ẹrù wọ̀ lọ́rùn, dájúdájú, èmi yóò sì tù yín lára. Ẹ gba àjàgà mi sọ́rùn yín, kí ẹ sì kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ mi, nítorí onínú tútù àti ẹni rírẹlẹ̀ ní ọkàn-àyà ni èmi, ẹ ó sì rí ìtura fún ọkàn yín. Nítorí àjàgà mi jẹ́ ti inú rere, ẹrù mi sì fúyẹ́.” (Mát. 11:28-30) Wàhálà yòówù kó bá wa, ará máa tù wá gan-an tá a bá kẹ́kọ̀ọ́ nípa bí Jésù ṣe bá àwọn èèyàn lò lọ́nà tó gbé wọn ró tá a sì tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àtàtà tó fi lélẹ̀.

10, 11. Nínú ìjọ, àwọn wo ló lè tu àwọn ẹlòmíì nínú?

10 Àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni pẹ̀lú lè tù wá nínú. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa bí àwọn alàgbà ìjọ ṣe máa ń ran àwọn tí wàhálà dé bá lọ́wọ́. Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹnikẹ́ni ha wà tí ń ṣàìsàn [nípa tẹ̀mí] láàárín yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì gbàdúrà lé e lórí.” Àǹfààní wo ni èyí máa ṣe onítọ̀hún? Jákọ́bù sọ pé: “Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì mú aláàárẹ̀ náà lára dá, Jèhófà yóò sì gbé e dìde. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí ó bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀, a óò dárí rẹ̀ jì í.” (Ják. 5:14, 15) Àwọn ará míì nínú ìjọ pẹ̀lú lè tù wá nínú.

11 Ó sábà máa ń rọrùn fún àwọn obìnrin láti sọ onírúurú ìṣòro tí wọ́n ní fún obìnrin bíi tiwọn. Ní pàtàkì àwọn arábìnrin tí wọ́n dàgbà tí wọ́n sì túbọ̀ nírìírí lè fún àwọn arábìnrin tí wọn kò tíì fi bẹ́ẹ̀ dàgbà ní ọ̀pọ̀ ìmọ̀ràn àtàtà. Ohun kan náà ti lè ṣẹlẹ̀ rí sí àwọn àgbàlagbà obìnrin tó jẹ́ Kristẹni tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú wọn yìí. Ẹ̀mí ìbánikẹ́dùn àti àwọn ànímọ́ tó jẹ́ ti obìnrin tí wọ́n ní máa ṣèrànwọ́ gan-an ni. (Ka Títù 2:3-5.) Síbẹ̀, àwọn alàgbà àtàwọn míì lè “sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́” láàárín wa, ohun tó sì yẹ kí wọ́n ṣe nìyẹn. (1 Tẹs. 5:14, 15) Ó sì dára ká máa rántí pé Ọlọ́run “ń tù wá nínú nínú gbogbo ìpọ́njú wa, kí àwa lè tu àwọn tí ó wà nínú ìpọ́njú èyíkéyìí nínú.”—2 Kọ́r. 1:4.

12. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ?

12 Ọ̀nà pàtàkì kan tá a lè gbà rí ìtùnú gbà ni pé ká máa lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ, níbi tí àwọn ìjíròrò Bíbélì ti máa fún wa ní ìṣírí. A rí i kà nínú Bíbélì pé Júdásì àti Sílà “fi ọ̀pọ̀ àwíyé fún àwọn ará ní ìṣírí wọ́n sì fún wọn lókun.” (Ìṣe 15:32) Ká tó bẹ̀rẹ̀ ìpàdé àti lẹ́yìn tí ìpàdé bá parí, àwọn ará ìjọ máa ń bá ara wọn sọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró. Torí náà, bó bá tiẹ̀ ṣẹlẹ̀ pé wàhálà tó bá wa mú kí nǹkan nira fún wa, ẹ má ṣe jẹ́ ká ya ara wa sọ́tọ̀, níwọ̀n bí èyí kò ti ní yanjú ìṣòro náà. (Òwe 18:1) Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dára ká tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti fún wa, pé: “Ẹ sì jẹ́ kí a gba ti ara wa rò lẹ́nì kìíní-kejì láti ru ara wa sókè sí ìfẹ́ àti sí àwọn iṣẹ́ àtàtà, kí a má máa kọ ìpéjọpọ̀ ara wa sílẹ̀, bí àwọn kan ti ní àṣà náà, ṣùgbọ́n kí a máa fún ara wa ní ìṣírí lẹ́nì kìíní-kejì, pàápàá jù lọ bí ẹ ti rí i pé ọjọ́ náà ń sún mọ́lé.”—Héb. 10:24, 25.

Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Tù Ẹ́ Nínú

13, 14. Ṣàlàyé bí Ìwé Mímọ́ ṣe lè tù wá nínú.

13 Yálà a jẹ́ Kristẹni tó ti ṣèrìbọmi tàbí a ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti àwọn nǹkan tó fẹ́ ṣe, a lè rí ọ̀pọ̀ ìtùnú látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo ohun tí a ti kọ ní ìgbà ìṣáájú ni a kọ fún ìtọ́ni wa, pé nípasẹ̀ ìfaradà wa àti nípasẹ̀ ìtùnú láti inú Ìwé Mímọ́, kí a lè ní ìrètí.” (Róòmù 15:4) Ìwé Mímọ́ lè tù wá nínú ó sì lè mú ká di ẹni tó “pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tím. 3:16, 17) Ó dájú pé bá a ṣe mọ àwọn ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe àti ìrètí tó dájú tá a ní nípa ọjọ́ ọ̀la máa tù wá nínú gan-an ni. Torí náà, ẹ jẹ́ ká máa wá ìrànlọ́wọ́ lọ sínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àtàwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì; wọ́n lè tù wá nínú kí wọ́n sì ṣe wá láǹfààní lónírúurú ọ̀nà.

14 Jésù fi Ìwé Mímọ́ tọ́ àwọn èèyàn sọ́nà, ó fi tù wọ́n nínú, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ fi àpẹẹrẹ àtàtà lélẹ̀ fún wa. Bí àpẹẹrẹ, ìgbà kan wà lẹ́yìn tí Jésù jíǹde tó fara han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ tó sì ‘ṣí Ìwé Mímọ́ payá lẹ́kùn-ún-rẹ́rẹ́’ fún méjì lára wọn. Ọ̀rọ̀ tó bá wọn sọ wọ̀ wọ́n lọ́kàn gan-an ni. (Lúùkù 24:32) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àtàtà tí Jésù fi lélẹ̀, ó bá àwọn èèyàn ‘fi èrò-wérò láti inú Ìwé Mímọ.’ Ní ìlú Bèróà, àwọn tó gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ “gba ọ̀rọ̀ náà pẹ̀lú ìháragàgà ńláǹlà nínú èrò inú, tí wọ́n ń fẹ̀sọ̀ ṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ lójoojúmọ́.” (Ìṣe 17:2, 10, 11) Ẹ wo bó ti bá a mu tó pé ká máa ka Bíbélì lójoojúmọ́ ká lè jàǹfààní látinú rẹ̀ àti látinú àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni tí ètò Ọlọ́run ṣe láti tù wá nínú kó sì fún wa ní ìrètí láwọn àkókò oníyánpọnyánrin yìí!

Àwọn Ọ̀nà Míì Tá A Lè Gbà Tu Àwọn Ẹlòmíì Nínú

15, 16. Àwọn nǹkan wo la lè ṣe láti ran àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni lọ́wọ́ ká sì tù wọ́n nínú?

15 Ọ̀pọ̀ nǹkan ló wà tá a lè ṣe láti ran àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni lọ́wọ́ ká sì tipa bẹ́ẹ̀ tù wọ́n nínú. Bí àpẹẹrẹ, a lè bá àwọn Kristẹni bíi tiwa tí wọ́n ti dàgbà tàbí tí wọ́n ń ṣàìsàn ra nǹkan lọ́jà. A lè bá àwọn míì ṣe àwọn iṣẹ́ ilé, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé ọ̀rọ̀ wọ́n jẹ wá lógún. (Fílí. 2:4) A sì lè sọ fún àwọn tá a jọ ń sin Jèhófà bá a ṣe mọrírì àwọn ànímọ́ rere tí wọ́n ní, irú bí ìfẹ́, ìdánúṣe, ìgboyà àti ìgbàgbọ́.

16 Bá a bá fẹ́ tu àwọn àgbàlagbà nínú, a lè lọ kí wọn ká a sì tẹ́tí dáadáa nígbà tí wọ́n bá ń sọ àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sí wọn rí àtàwọn ìbùkún tó dájú pé wọ́n ti rí gbà lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Kódà, èyí lè fún àwa náà níṣìírí, kó sì tù wá nínú! Àwa àtàwọn tá a bá lọ kí lè jọ ka Bíbélì tàbí àwọn ìtẹ̀jáde tó ń ṣàlàyé Bíbélì. A tiẹ̀ lè jọ ṣàgbéyẹ̀wò àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ ti ọ̀sẹ̀ yẹn tàbí èyí tá a máa gbé yẹ̀ wò nígbà Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ lọ́sẹ̀ yẹn. A lè jọ wo fídíò tí ètò Ọlọ́run ṣe sórí àwo DVD. A tún lè lo àkókò yẹn láti ka àwọn ìrírí tó ń fúnni níṣìírí tó wà nínú àwọn ìtẹ̀jáde wa tàbí ká sọ irú ìrírí bẹ́ẹ̀.

17, 18. Kí nìdí tó fi dá àwa ìránṣẹ́ Jèhófà adúróṣinṣin lójú pé Ọlọ́run máa tì wá lẹ́yìn ó sì máa tù wá nínú?

17 Bí a bá kíyè sí i pé ẹnì kan tá a jọ ń sin Jèhófà nílò ìtùnú, a lè dárúkọ rẹ̀ nínú àdúrà wa. (Róòmù 15:30; Kól. 4:12) Bá a ṣe ń kojú ìṣòro ìgbésí ayé tá a sì ń fẹ̀sọ̀ wá bá a ṣe lè tu àwọn míì nínú, a lè ní irú ìgbàgbọ́ àti ìdánilójú tí onísáàmù náà ní. Ó sọ nínú orín tó kọ pé: “Ju ẹrù ìnira rẹ sọ́dọ̀ Jèhófà fúnra rẹ̀, òun fúnra rẹ̀ yóò sì gbé ọ ró. Kì yóò jẹ́ kí olódodo ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n láé.” (Sm. 55:22) Kò sí àní-àní pé Jèhófà á máa tu àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin nínú á sì máa tì wọ́n lẹ́yìn ní gbogbo ìgbà tí wọ́n bá nílò ìrànlọ́wọ́ rẹ̀.

18 Ọlọ́run sọ fún àwọn tó ń sìn ín ní ìgbàanì pé: “Èmi—èmi fúnra mi ni Ẹni tí ń tù yín nínú.” (Aísá. 51:12) Jèhófà máa tu àwa náà nínú, ó sì máa bù kún wa torí àwọn iṣẹ́ rere tá à ń ṣe àti àwọn ọ̀rọ̀ tá a fi ń tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú. Yálà a ń retí láti lọ sọ́run tàbí láti wà lórí ilẹ̀ ayé, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa lè rí ìtùnú látinú ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni. Ó sọ pé: “Kí Olúwa wa Jésù Kristi fúnra rẹ̀ àti Baba wa Ọlọ́run, ẹni tí ó nífẹ̀ẹ́ wa, tí ó sì fúnni ní ìtùnú àìnípẹ̀kun àti ìrètí rere nípasẹ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, tu ọkàn-àyà yín nínú, kí ó sì fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in nínú gbogbo iṣẹ́ rere àti ọ̀rọ̀.”—2 Tẹs. 2:16, 17.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Báwo ni iṣẹ́ tá a fi ń tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú ṣe gbòòrò tó?

• Kí ni díẹ̀ lára àwọn nǹkan tá a lè ṣe láti tu àwọn míì nínú?

• Àwọn àpẹẹrẹ wo ló wà nínú Ìwé Mímọ́ tó fi hàn pé Jèhófà máa ń tu àwọn èèyàn rẹ̀ nínú?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Ṣéwọ náà máa ń tu àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ nínú?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Tọmọdé tàgbà wa ló lè fúnni níṣìírí