Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Kí ló yẹ kí n ṣe bí mo bá ní ìbéèrè nípa ohun kan tí mo kà nínú Bíbélì tàbí tí mo bá nílò ìmọ̀ràn nípa ìṣòro kan?

Ìwé Òwe 2:1-5 rọ ẹnì kọ̀ọ̀kan wa pé ká máa “bá a nìṣó ní wíwá” òye àti ìfòyemọ̀ “kiri” bí ẹni pé à ń wá “àwọn ìṣúra fífarasin.” Èyí túmọ̀ sí pé a ní láti sapá ká lè ṣe ìwádìí láti rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tá a bá ní lórí Bíbélì àti láti rí ojútùú sí àwọn ìṣòro tó bá dojú kọ wá. Báwo la ṣe lè ṣe irú ìwádìí bẹ́ẹ̀?

Ìwé Jàǹfààní Nínú Ilé Ẹ̀kọ́ Ìjọba Ọlọ́run, ojú ìwé 33 títí dé 38, ṣàlàyé nípa “Bí A Ṣe Ń Ṣe Ìwádìí” nípa lílo àwọn ohun èlò ìṣèwádìí tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” mú jáde. (Mát. 24:45) Ojú ìwé 36 ṣàlàyé bá a ṣe lè lo ìwé atọ́ka Watch Tower Publications Index. Ẹ̀dà atọ́ka kọ̀ọ̀kan la máa ń pín sí ẹ̀ka méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ìyẹn ẹ̀ka atọ́ka kókó ẹ̀kọ́ àti ẹ̀ka atọ́ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́. Èyí máa ń mú kó ṣeé ṣe láti ṣèwádìí ọ̀rọ̀ pàtàkì tàbí àwọn ẹsẹ Bíbélì kan, wà á sì rí i tí wọ́n to àwọn ìwé tó o lè lọ wò síbẹ̀. Fi sùúrù ṣèwádìí tó o fi máa rí ìdáhùn pàtó tàbí ìtọ́ni tó o nílò. Rántí pé “àwọn ìṣúra fífarasin” lò ń wá, ìyẹn sì máa gba àkókò àti ìsapá.

Àmọ́ ṣá o, àwọn kókó ẹ̀kọ́ àtàwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ kan wà táwọn ìwé wa kò tíì sọ̀rọ̀ lé lórí ní tààràtà. Bó bá tiẹ̀ wá ṣẹlẹ̀ pé ìwé wa sọ̀rọ̀ lórí ẹsẹ Bíbélì kan ní pàtó, ó ṣeé ṣe ká má tíì sọ̀rọ̀ lórí ìbéèrè tó o ní lọ́kàn nípa irú ẹsẹ bẹ́ẹ̀. Bákan náà, ìbéèrè lè wáyé lórí àwọn ìtàn kan nínú Bíbélì torí pé Ìwé Mímọ́ kò sọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ rẹ̀. Nípa bẹ́ẹ̀, a kò lè rí ìdáhùn ojú ẹsẹ̀ sí gbogbo ìbéèrè tó bá wáyé. Bí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, a gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má máa méfò nípa àwọn nǹkan tí a kò lè rí ìdáhùn sí, kó sì wá di pé a ó máa jiyàn lórí “àwọn ìbéèrè fún ìwádìí jinlẹ̀ . . . dípò pípín ohunkóhun fúnni láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ní ìsopọ̀ pẹ̀lú ìgbàgbọ́.” (1 Tím. 1:4; 2 Tím. 2:23; Títù 3:9) Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tàbí oríléeṣẹ́ wa kì í ṣàlàyé gbogbo ìbéèrè tí a kò bá tíì gbé yẹ̀ wò nínú àwọn ìwé wa, wọn kì í sì í wá ìdáhùn sí i. Ó yẹ kó tẹ́ wa lọ́rùn pé Bíbélì ní ìsọfúnni tó pọ̀ tó láti jẹ́ ká mọ bó ṣe yẹ ká gbé ìgbé ayé wa, kò sì ṣàlàyé àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ kan fún wa ká lè rí ìdí tá a fi gbọ́dọ̀ ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Ọlọ́run tó fún wa ní Bíbélì.—Wo ojú ìwé 185 sí 187 nínú ìwé Sún Mọ́ Jèhófà.

Bó bá wá ṣẹlẹ̀ pé o ti ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ṣèwádìí nípa ọ̀ràn kan tó kàn ẹ́ gbọ̀ngbọ̀n síbẹ̀ tí o kò rí ìtọ́ni tàbí ojútùú tó o nílò ńkọ́? Má ṣe lọ́ tìkọ̀ láti fọ̀rọ̀ náà lọ Kristẹni mìíràn bíi tìẹ tí òtítọ́ jinlẹ̀ nínú rẹ̀, bóyá tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alàgbà ìjọ. Wọ́n ní ìmọ̀ tó pọ̀ nípa Bíbélì, wọ́n sì mọ púpọ̀ nípa bó ṣe yẹ kí Kristẹni kan máa gbé ìgbé ayé rẹ̀. Bó o bá fẹ́ ìmọ̀ràn lórí ìṣòro kan tó o ní tàbí ìpinnu kan tó o fẹ́ ṣe, ó dájú pé ìrànlọ́wọ́ tí kò pọ̀n síbì kan tí wọ́n máa fún ẹ máa ṣe ẹ́ láǹfààní, torí pé wọ́n mọ̀ ẹ́, wọ́n sún mọ́ ẹ, ohun tó ń ṣe ẹ́ sì lè má ṣàjèjì sí wọn. Má ṣe gbàgbé láti gbàdúrà sí Jèhófà, kó o sì sọ ohun tó ò ń ṣàníyàn nípa rẹ̀ gan-an fún un, kó o sì bẹ̀ ẹ́ pé kó fi ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ darí ìrònú rẹ, “nítorí Jèhófà fúnra rẹ̀ ní ń fúnni ní ọgbọ́n . . . àti ìfòyemọ̀.”—Òwe 2:6; Lúùkù 11:13.