Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ìdáhùn Ìbéèrè Yẹn Ṣe Pàtàkì?

Ǹjẹ́ Ìdáhùn Ìbéèrè Yẹn Ṣe Pàtàkì?

Ǹjẹ́ Ìdáhùn Ìbéèrè Yẹn Ṣe Pàtàkì?

“Láti ìgbà tí mo ti wà ní ọmọ ọdún mẹ́wàá ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọmọkùnrin jáde. Nígbà tá a kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, a máa ń di ara wa lọ́wọ́ mú, a sì máa ń fi ẹnu ko ara wa lẹ́nu. Àmọ́ kò pẹ́ tí a fi bẹ̀rẹ̀ sí í fọwọ́ kan àwọn ibi kọ́lọ́fín ara tí ìyẹn sì túbọ̀ ń peléke sí i. Nígbà tí mo di ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́, àwọn ọkùnrin tá a jọ ń ṣiṣẹ́ máa ń wá sọ́dọ̀ mi, ohun tí wọ́n sì ń fẹ́ ni ìbálòpọ̀. Mo fẹ́ kí àwọn tá a jọ ń ṣiṣẹ́ mọ̀ pé èmi náà kò kẹ̀rẹ̀ nínú gbogbo nǹkan tí wọ́n ń ṣe. Mo fẹ́ kí àwọn ẹlẹgbẹ́ mi gba tèmi, èyí sì mú kí n bẹ̀rẹ̀ sí í lọ́wọ́ nínú oríṣiríṣi ìbálòpọ̀.”—SARAH, * AUSTRALIA.

ǸJẸ́ kò ní yà ẹ́ lẹ́nu pé, inú ilé tí wọ́n ti fọwọ́ pàtàkì mú ìjọsìn ni wọ́n ti tọ́ Sarah dàgbà? Àwọn òbí rẹ̀ sapá, wọ́n tọ́ ọ láti máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nínú ìgbésí ayé rẹ̀. Àmọ́ Sarah yàn láti ṣe ohun tó wù ú.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa sọ pé kò sóhun tó burú nínú ohun tí Sarah yàn láti ṣe. Èrò wọn ni pé, ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀ kò bóde mu mọ́. Ọ̀pọ̀ kò rí ohun tó burú nínú kéèyàn sọ pé òun jẹ́ onísìn, lẹ́sẹ̀ kan náà kí ẹni náà tún máa lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe bó ṣe wù ú.

Ǹjẹ́ ó ṣe pàtàkì kéèyàn mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀, kéèyàn sì máa fi ṣèwà hù? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run ló “mí sí” Bíbélì, “ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni.” (2 Tímótì 3:16) Tó o bá gbà pé Ọlọ́run ló dá èèyàn, tó o sì gbà pé òun ló mí sí Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, nígbà náà, ó yẹ ká mọ ohun tí Bíbélì sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí.

Ó ṣeni láàánú pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣiyèméjì lórí ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn aṣáájú ìsìn sọ pé àwọn bọ̀wọ̀ fún Bíbélì, síbẹ̀ ohun tí wọ́n ń kọ́ni nípa ìbálòpọ̀ kò bá Bíbélì mu. Kódà, ọ̀ràn yìí tiẹ̀ ti dá ìyapa sílẹ̀ láàárín ọ̀pọ̀ ṣọ́ọ̀ṣì jàǹkànjàǹkàn.

Dípò tí wàá fi gba ohun tí àwọn èèyàn sọ lórí kókó yìí, o ò ṣe fúnra rẹ ṣèwádìí ohun tí Bíbélì sọ? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí dáhùn ìbéèrè mẹ́wàá tí àwọn èèyàn sábà máa ń béèrè nípa ohun tí Bíbélì sọ nípa ìbálòpọ̀. Nínú àpilẹ̀kọ náà, wàá rí àwọn ìdáhùn tó ṣe tààràtà nípa ohun tí Bíbélì kọ́ni. Àpilẹ̀kọ tó kẹ́yìn nínú ọ̀wọ́ àpilẹ̀kọ yìí máa sọ̀rọ̀ nípa ìdí tí ohun tá a yàn láti ṣe fi ṣe pàtàkì.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A ti yí orúkọ rẹ̀ pa dà.