Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

Bíbélì Máa Ń Yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà

KÍ LÓ mú kí ọkùnrin kan tí tẹ́tẹ́ títa àti olè jíjà ti di bárakú fún jáwọ́ nínú àṣà yìí, tó sì yí ìgbésí ayé rẹ̀ pa dà? Ẹ gbọ́ ohun tó sọ.

“Mo fẹ́ràn ẹṣin àti fífi ẹṣin sáré ìje.”​—RICHARD STEWART

ỌDÚN TÍ WỌ́N BÍ MI: 1965

ORÍLẸ̀-ÈDÈ: JÀMÁÍKÀ

IRÚ ẸNI TÍ MO JẸ́ TẸ́LẸ̀: ATATẸ́TẸ́ ÀTI Ọ̀DARÀN

ÌGBÉSÍ AYÉ MI ÀTẸ̀YÌNWÁ: Agbègbè Kingston tó jẹ́ olú ìlú orílẹ̀-èdè Jàmáíkà ni mo dàgbà sí, èrò pọ̀ gan-an lágbègbè náà, àwọn tálákà sì pọ̀ níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ni kò níṣẹ́ lọ́wọ́, ìwà ọ̀daràn sì pọ̀ níbẹ̀. Àwọn jàǹdùkú tó wà lágbègbè náà máa ń jẹ́ kẹ́rù ba àwọn tó ń gbé ibẹ̀. Ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni mo máa ń gbọ́ ìró ìbọn.

Òṣìṣẹ́ kára ni màmá mi, ó sì ṣe gbogbo nǹkan tó lè ṣe láti bójú tó èmi, àbúrò mi ọkùnrin àti àbúrò mi obìnrin. Ó rí i dájú pé a gba ẹ̀kọ́ tó jíire. Mi ò fí bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ilé ẹ̀kọ́, àmọ́ mo fẹ́ràn ẹṣin àti fífi ẹṣin sáré ìje. Ìgbà míì wà tí mi ò kì í lọ sí ilé ẹ̀kọ́ tí màá lọ sí pápá tí wọ́n ti ń fi ẹṣin sáré ìje. Nígbà tó yá, èmi náà tiẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í gun ẹṣin.

Nígbà tó yá, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ta tẹ́tẹ́ lórí ẹni tó máa gbawájú nínú ìdíje eré ẹṣin. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbé ìgbésí ayé jákujàku, mo sì ń ní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú ọ̀pọ̀ obìnrin. Mò ń mu igbó, mo sì ń jalè kí n lè rówó ná sórí ìgbésí ayé jákujàku tí mò ń gbé. Mo ní ìbọn tó pọ̀, àmọ́ mo dúpẹ́ pé a kò pa èèyàn kankan ní àìmọye ìgbà tí mo lọ́wọ́ nínú olè jíjà.

Nígbà tó yá, ọlọ́pàá mú mi, wọ́n sì sọ mí sẹ́wọ̀n nítorí ìwà ọ̀daràn tí mo hù. Nígbà tí wọ́n fi mí sílẹ̀, mo tún bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé jákujàku tí mò ń gbé tẹ́lẹ̀. Kódà, ọ̀rọ̀ mi tún wá burú ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú mi tutù, mo jẹ́ aṣetinú-ẹni, mo máa ń kanra, mo sì jẹ́ òǹrorò. Ọ̀rọ̀ ara mi nìkan ló jẹ mí lógún, mi ò bìkítà fún àwọn èèyàn.

BÍ BÍBÉLÌ ṢE YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ MI PA DÀ: Lákòókò tí mò ń gbé ìgbésí ayé jákujàku yìí, màmá mi bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì di ọ̀kan lára wọn. Mo rí ìyípadà sí rere nínú àwọn ìwà màmá mi, èyí sì mú kí n fẹ́ mọ ìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Mo fẹ́ mọ ohun tó mú kí màmá mi yí pa dà, nítorí náà èmi àtàwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í jíròrò nínú Bíbélì.

Mo rí i pé ẹ̀kọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yàtọ̀ sí ti àwọn ẹ̀sìn yòókù, mo tún rí i pé, gbogbo nǹkan tí wọ́n bá ń kọ́ni ni wọ́n máa ń fi Bíbélì tì lẹ́yìn. Àwọn nìkan ni mo mọ̀ tí wọ́n máa ń wàásù láti ilé dé ilé, bí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ti ṣe. (Mátíù 28:19; Ìṣe 20:20) Mo gbà pé mo ti rí ẹ̀sìn tòótọ́ nígbà tí mo rí ìfẹ́ tòótọ́ tí wọ́n ń fi hàn sí ara wọn.—Jòhánù 13:35.

Látinú ohun tí mo ti kọ́ nínú Bíbélì, mo rí i pé ó yẹ kí n ṣe àwọn àyípadà pàtàkì kan nígbèésí ayé mi. Mo rí i pé Jèhófà Ọlọ́run kórìíra àgbèrè, tí mo bá sì fẹ́ rí ojú rere rẹ̀, mo ní láti fi àwọn àṣà tó ń sọ ara mi di ẹlẹ́gbin sílẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 7:1; Hébérù 13:4) Nígbà tí mo kẹ́kọ̀ọ́ pé ohun tí mo bá ṣe lè múnú Jèhófà dùn tàbí kó bà á nínú jẹ́, ọ̀rọ̀ yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. (Òwe 27:11) Nítorí náà, mo pinnu pé mi ò ní mu igbó mọ́, pé mi ò sì ní lo ìbọn mọ́, mo tún sapá láti mú kí ìwà mi dára sí i. Àmọ́ àyípadà tó ṣòro jù lọ ti mo ṣe ni pé, mo fi ìṣekúṣe àti tẹ́tẹ́ títa sílẹ̀.

Lákọ̀ọ́kọ́, mi ò fẹ́ káwọn ọ̀rẹ́ mi mọ̀ pé mò ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ mo yí èrò mi pa dà nígbà tí mo ka Mátíù 10:33, níbi tí ọ̀rọ̀ Jésù yìí wà pé: “Bi ẹnikan ba si sẹ mi niwaju enia, on na li emi o sẹ pẹlu niwaju Baba mi ti mbẹ li ọrun.” (Bibeli Mimọ) Ọ̀rọ̀ yìí mú kí n sọ fún àwọn ọ̀rẹ́ mi pé, mò ń kẹ́kọ̀ọ́ lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀rọ̀ náà bá wọn lójijì. Wọn kò gbà pé, èèyàn bíi tèmi lè fẹ́ di Kristẹni. Àmọ́ mo sọ fún wọn pé, mi ò ní hu àwọn ìwà tí mo ti ń hù tẹ́lẹ̀ mọ́.

ÀǸFÀÀNÍ TÍ MO TI RÍ: Inú màmá mi dùn gan-an nígbà tó rí i pé mo ti ń tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì nínú ìgbésí ayé mi. Ní báyìí, ọ̀rọ̀ mi ò kó ìdààmú bá a mọ́ pé bóyá mo tún ti lọ hùwà burúkú. Ìfẹ́ tí àwa méjèèjì ní fún Jèhófà la jọ ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ báyìí. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, mo máa ń ronú nípa irú ẹni tí mo jẹ́ tẹ́lẹ̀, ìyàlẹ́nu ló sì máa ń jẹ́ fún mi láti rí àwọn àyípadà tí Ọlọ́run ti ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe. Mi ò kì í ṣe ìṣekúṣe mọ́, mi ò sì lépa kíkó ohun ìní tára jọ mọ́.

Ká ní mi ò fetí sí ohun tí Bíbélì sọ ni, ó ṣeé ṣe kí n ti kú tàbí kí n wà lẹ́wọ̀n lónìí. Àmọ́ ní báyìí, mo ní ìdílé aláyọ̀ tó fini lọ́kàn balẹ̀. Inú mi ń dùn láti máa sin Jèhófà Ọlọ́run pẹ̀lú aya mi tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ rere àti ọmọ wa obìnrin tó ń gbọ́ràn sí wa lẹ́nu. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà tó jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti wà lára àwọn Kristẹni tí wọ́n wà níṣọ̀kan kárí ayé, tí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Inú mi dùn pé ẹnì kan sapá láti kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ tó wà nínú Bíbélì. Èmi náà sì mọyì àǹfààní tí mo ní láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní pàtàkì, mo dúpẹ́ mo tún ọpẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà Ọlọ́run fún inú rere àti ìfẹ́ tó fi hàn sí mi tó sì fà mí wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 11]

“Mo kẹ́kọ̀ọ́ pé ohun tí mo bá ṣe lè múnú Jèhófà dùn tàbí kó bà á nínú jẹ́”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Èmi, ìyàwó mi àti ọmọbìnrin wa rèé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Mo rí ìyípadà sí rere nínú àwọn ìwà màmá mi