Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Làwọn Bàbá Lè Ṣe Tí Àjọṣe Wọn Pẹ̀lú Ọmọkùnrin Wọn Kò Fi Ní Bà Jẹ́?

Kí Làwọn Bàbá Lè Ṣe Tí Àjọṣe Wọn Pẹ̀lú Ọmọkùnrin Wọn Kò Fi Ní Bà Jẹ́?

Kí Làwọn Bàbá Lè Ṣe Tí Àjọṣe Wọn Pẹ̀lú Ọmọkùnrin Wọn Kò Fi Ní Bà Jẹ́?

“DÁDÌ, báwo lẹ ṣe mọ ohun tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ yẹn?” Ṣé ọmọkùnrin rẹ ti bi ẹ́ ní ìbéèrè tó yà ẹ́ lẹ́nu bí èyí rí? Ní àkókò yẹn, ó ṣeé ṣe kí inú rẹ dùn pé bàbá ni ọ́. Àmọ́ ṣá o, bí ọmọkùnrin rẹ bá tún wá fi àwọn ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tó o fún un sílò tó sì jàǹfààní rẹ̀, kò sí àní-àní pé ọkàn rẹ á yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀. *Òwe 23:15, 24.

Àmọ́, ṣé ọmọkùnrin rẹ ṣì ń kà ẹ́ sí bọ́dún ṣe ń gorí ọdún? Àbí bó ṣe ń dàgbà, kò fi bẹ́ẹ̀ kà ẹ́ sí mọ́? Kí lo lè ṣe tí àjọṣe àárín ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ kò fi ní bà jẹ́ bí ó ṣe ń ti ipò ọmọdé bọ́ sí ipò àgbà? Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàgbéyẹ̀wò díẹ̀ lára ìṣòro táwọn bàbá má ń dojú kọ.

Ìṣòro Mẹ́ta Tó Wọ́pọ̀

1. KÒ SÍ ÀKÓKÒ: Ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn bàbá ló ń gbọ́ èyí tó pọ̀ jù nínú bùkátà ìdílé. Lọ́pọ̀ ìgbà, iṣẹ́ wọn máa ń gba ọ̀pọ̀ wákàtí lójúmọ́, ìyẹn kì í sì í jẹ́ kí wọ́n gbélé. Ní àwọn ibì kan, àkókò tó kéré gan-an ni àwọn bàbá máa ń lò pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn. Bí àpẹẹrẹ, ìwádìí kan tí wọ́n ṣe ní orílẹ̀-èdè Faransé lẹ́nu àìpẹ́ yìí fi hàn pé àwọn bàbá tó wà lórí-èdè náà máa ń lo ohun tí kò tó ìṣẹ́jú méjìlá lóòjọ́ láti fi bójú tó àwọn ọmọ wọn.

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ: Báwo ni àkókò tí ò ń lò pẹ̀lú ọmọkùnrin rẹ ti pọ̀ tó? Fún ọ̀sẹ̀ kan tàbí ọ̀sẹ̀ méjì tó ń bọ̀, o ò ṣe ṣàkọsílẹ̀ gbogbo àkókò tó o lò pẹ̀lú ọmọkùnrin rẹ lọ́jọ́ kọ̀ọ̀kan? Ohun tó o máa rí lè yà ọ́ lẹ́nu.

2. KÒ SÍ ÀPẸẸRẸ RERE: Nígbà táwọn ọkùnrin kan wà lọ́mọdé wọn ò fi bẹ́ẹ̀ da nǹkan pọ̀ pẹ̀lú àwọn bàbá wọn. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jean-Marie tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Faransé sọ pé, “Èmi àti bàbá mi kì í fi bẹ́ẹ̀ dá nǹkan pọ̀.” Ipa wo nìyẹn ní lórí Jean-Marie? Ó sọ pé, “Ó ti dá àwọn ìṣòro tí n kò ronú kàn sílẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ó ṣòro fún mi gan-an láti bá àwọn ọmọkùnrin mi sọ̀rọ̀ lọ́nà tó mọ́yán lórí.” Nínú ọ̀ràn ti àwọn míì, nígbà tí wọ́n wà lọ́mọdé, bàbá wọn kò jìnnà sí wọn, síbẹ̀ àjọṣe tó wà láàárín àwọn àti bàbá wọn kò fi bẹ́ẹ̀ dán mọ́rán. Ọ̀gbẹ́ni Phillipe tó jẹ́ ẹni ọdún mẹ́tàlélógójì [43] sọ pé: “Kò rọrùn fún bàbá mi láti máa fìfẹ́ hàn sí mi. Ohun tí èyí yọrí sí ni pé, mo ní láti sapá gan-an kí n tó lè máa fìfẹ́ hàn sí ọmọkùnrin mi.”

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ: Ṣé bí bàbá rẹ ṣe ṣe sí ọ nígbà tó o wà lọ́mọdé ti nípa lórí bí ìwọ náà ṣe ń ṣe sí ọmọkùnrin rẹ? Ṣé o ti kíyè sí i pé àpẹẹrẹ ìwà búburú tàbí ìwà rere bàbá rẹ lò ń tẹ̀ lé? Báwo ló ṣe jẹ́ bẹ́ẹ̀?

3. KÒ SÍ ÀMỌ̀RÀN TÓ YẸ: Nínú àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ kan, wọn kò fọwọ́ pàtàkì mú ipa tí ó yẹ kí àwọn bàbá kó nínú títọ́ ọmọ. Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Luca tó dàgbà ní Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù sọ pé, “Níbi tí mo dàgbà sí, èrò àwọn èèyàn ni pé, obìnrin ló máa ń tọ́ ọmọ.” Ní àwọn àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ míì, wọ́n sọ pé àwọn bàbá ní láti jẹ́ ẹni tó le. Bí àpẹẹrẹ, orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà ni wọ́n ti tọ́ ọkùnrin kan tó ń jẹ́ George dàgbà. Ó sọ pé: “Ní àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ wa, àwọn bàbá kì í bá àwọn ọmọ wọn ṣeré nítorí wọ́n rò pé àwọn ọmọ náà á rí àwọn fín. Nítorí náà, kò rọrùn fún mi láti bá ọmọ mi ọkùnrin ṣeré.”

OHUN TÓ YẸ KÓ O RONÚ LÉ LÓRÍ: Ní àgbègbè rẹ, ipa wo ni wọ́n rò pé ó yẹ kí àwọn bàbá máa kó nínú ọ̀ràn ọmọ títọ́? Ṣé èrò wọn ni pé obìnrin ló máa ń tọ́ ọmọ? Ǹjẹ́ wọ́n ń rọ àwọn bàbá láti máa fìfẹ́ hàn sí àwọn ọmọ wọn, àbí wọ́n fojú burúkú wo irú nǹkan bẹ́ẹ̀?

Tó o bá ní ọ̀kan tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ lára àwọn ìṣòro yìí, báwo lo ṣe lè yanjú rẹ̀? Ṣàgbéyẹ̀wò àwọn àbá tá a fẹ́ sọ yìí.

Bẹ̀rẹ̀ Nígbà Tí Ọmọkùnrin Rẹ Ṣì Kéré

Ó jọ pé ó máa ń wu àwọn ọmọkùnrin láti fara wé bàbá wọn. Nítorí náà, nígbà tí ọmọ rẹ ṣì kéré, lo àǹfààní yẹn láti mú kí àjọṣe yín dára sí i. Báwo lo ṣe máa ṣe é? Báwo lo sì ṣe máa rí àkókò tó o máa lò pẹ̀lú ọmọkùnrin rẹ?

Tó bá ṣeé ṣe, kí ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ jọ máa ṣe àwọn nǹkan tí ò ń ṣe lójoojúmọ́. Bí àpẹẹrẹ, tó o bá ń ṣiṣẹ́ ilé, sọ pé kí ó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Fún un ní ìgbálẹ̀ kékeré tàbí ṣọ́bìrì kékeré. Kò sí àní-àní pé, inú ọmọ náà á dùn pé òun ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ẹni tí ó wu òun láti fara wé! Ó lè pẹ́ díẹ̀ kó o tó ṣiṣẹ́ náà tán, àmọ́, wàá túbọ̀ mú kí àjọṣe àárín ìwọ àti ọmọ náà lágbára sí i, wàá sì tipa bẹ́ẹ̀ kọ́ ọ pé ó yẹ kéèyàn fọwọ́ pàtàkì mú iṣẹ́. Tipẹ́tipẹ́ ni Bíbélì ti rọ àwọn bàbá pé kí àwọn àtàwọn ọmọ wọn jọ máa ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n ń ṣe lójoojúmọ́, kí wọ́n sì máa lo àkókò náà láti fi bá wọn sọ̀rọ̀ àti láti fi kọ́ wọn lẹ́kọ̀ọ́. (Diutarónómì 6:6-9) Àmọ̀ràn yẹn ṣì wúlò lóde òní.

Yàtọ̀ sí pé kó o máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ọmọ rẹ, tún wá àkókò láti máa bá a ṣeré. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé bíbá àwọn ọmọ ṣeré máa ń gbádùn mọ́ àwọn ọmọ àtàwọn òbí, ó tún máa ń ṣí àwọn àǹfààní míì sílẹ̀. Ìwádìí fi hàn pé tí àwọn bàbá bá ń ṣeré pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn, ó máa ń mú káwọn ọmọ túbọ̀ fẹ́ láti máa ṣe àwọn nǹkan, ó sì máa ń mú kí wọ́n jẹ́ onígboyà.

Àǹfààní tó pọ̀ ló wà nínú kí bàbá àti ọmọkùnrin rẹ̀ jọ máa ṣeré. Ọ̀gbẹ́ni Michel Fize tó jẹ́ aṣèwádìí sọ pé, “Ìgbà tó rọrùn jù lọ tí ọmọkùnrin kan máa ń bá bàbá rẹ̀ sọ̀rọ̀ ni ìgbà tí wọ́n bá jọ ń ṣeré.” Ní àkókò eré, àǹfààní máa ń ṣí sílẹ̀ fún bàbá láti fìfẹ́ hàn sí ọmọ rẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ àti ìṣe. Bó ṣe ń ṣe bẹ́ẹ̀, ńṣe ló ń kọ́ ọmọ náà béèyàn ṣe lè máa fìfẹ́ hàn sáwọn èèyàn. Bàbá kan nílẹ̀ Jámánì tó ń jẹ́ André sọ pé, “Nígbà tí ọmọkùnrin mi wà lọ́mọdé, a jọ máa ń ṣeré. Mo máa ń gbá a mọ́ra, ó sì wá kẹ́kọ̀ọ́ pé ó yẹ kí òun náà máa fìfẹ́ hàn sí èmi náà.”

Àkókò míì tí bàbá lè mú kí ìfẹ́ àárín òun àti ọmọkùnrin rẹ̀ lágbára sí i ni ìgbà tí wọ́n bá fẹ́ lọ sùn. Máa ka ìtàn fún un déédéé, kó o sì máa fetí sí i nígbà tó bá ń sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí i lọ́jọ́ náà tó mú inú rẹ̀ dùn àti ohun tó ń da ọkàn rẹ̀ láàmú. Tó o bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, wàá mú kó rọrùn fún un láti máa bá ọ sọ̀rọ̀ bó ṣe ń dàgbà.

Ẹ Jọ Máa Ṣe Nǹkan Pa Pọ̀

Àwọn ọmọdékùnrin kan tí wọn kò tíì pé ogún ọdún kì í fẹ́ sọ̀rọ̀ nígbà tí bàbá wọn bá fẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀. Tí ọmọkùnrin rẹ bá fẹ́ máa yẹra fún àwọn ìbéèrè rẹ, má ṣe rò pé ńṣe ni kò fẹ́ bá ọ sọ̀rọ̀. Ó lè fẹ́ láti sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ tó o bá wá ọ̀nà tó dára láti gbà bá a sọ̀rọ̀.

Bàbá kan tó ń jẹ́ Jacques tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Faransé sọ pé kì í rọrùn fún òun nígbà míì láti bá Jérôme ọmọkùnrin òun sọ̀rọ̀. Àmọ́, kàkà kí ó fipá mú ọmọ rẹ̀ láti sọ̀rọ̀, ńṣe ló wá ọ̀nà kan tó dára jù láti gbà bá a sọ̀rọ̀, ìyẹn ni pé wọ́n jọ ń gba bọ́ọ̀lù aláfẹsẹ̀gbá. Jacques sọ pé, “Lẹ́yìn tá a bá ti gbá bọ́ọ̀lù tán, a óò jókòó sórí pápá, a óò sì sinmi díẹ̀. Ọmọkùnrin mi sábà máa ń sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ ní àkókò yẹn. Ìdí tó fí rí bẹ́ẹ̀ ni pé a jọ wà pa pọ̀, ohun míì ti mo rò ni pé, òun nìkan ni mò ń lo àkókò yẹn fún, èyí mú kí àjọṣe àárín wa dára gan-an.”

Bí ọmọ rẹ kò bá fẹ́ràn eré ìdárayá ńkọ́? Inú André dùn nígbà tó rántí ìgbà tí òun àti ọmọ rẹ̀ jọ máa ń wo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run. André sọ pé: “A máa ń gbé ìjókòó síta nínú òtútù lálẹ́. A óò wá fi aṣọ bora kí òtútù má bàa mú wa, a ó sì gbé ife tíì sọ́wọ́, tí á ó sì máa wo ojú ọ̀run lálẹ́. A máa ń sọ̀rọ̀ nípa Ẹni tó dá àwọn ìràwọ̀. A máa ń sọ nípa ọ̀rọ̀ ara wa. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo nǹkan ni a máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.”—Aísáyà 40:25, 26.

Àmọ́ tó bá jẹ́ pé o kò nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ohun tí ọmọkùnrin rẹ fẹ́ràn ńkọ́? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó gba pé kó o bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn nǹkan tí o kò nífẹ̀ẹ́ sí nìyẹn. (Fílípì 2:4) Bàbá kan tó ń jẹ́ Ian tó ń gbé South Africa sọ pé, “Mo fẹ́ràn eré ìdárayá gan-an ju Vaughan ọmọkùnrin mi lọ. Òun fẹ́ràn ọkọ̀ òfúrufú àti kọ̀ǹpútà. Nítorí náà, mo sapá láti fẹ́ràn àwọn nǹkan yẹn, mò sì ń mú ọmọ náà lọ sí ibi tí wọ́n ti ń fi ọkọ̀ òfúrufú dárà lójú ọ̀run, a sì tún máa ń fi kọ̀ǹpútà kọ́ bá a ṣe ń wa ọkọ̀ òfúrufú. Mo rí i pé nítorí a jọ ń ṣe ohun kan náà tá a sì ń gbádùn rẹ̀, ó ṣeé ṣe fún Vaughan láti bá mi sọ̀rọ̀ fàlàlà.”

Ran Ọmọ Rẹ Lọ́wọ́ Kí Ọkàn Rẹ̀ Lè Balẹ̀

“Ẹ wò ó, Dádì, ẹ wò ó!” Ǹjẹ́ ọmọ rẹ ọkùnrin ti pariwo bẹ́ẹ̀ rí nígbà tí ó ṣe ohun kan láṣeyọrí? Tí ọmọ náà kò bá tíì tó ọmọ ogún ọdún, ṣé ó ṣì máa ń pe àfiyèsí rẹ sí ohun tó ń ṣe? Ó lè máà rí bẹ́ẹ̀. Àmọ́, ó ṣì yẹ kó o máa wo ohun tí ọmọ náà ń ṣe, kí ó bàa lè dáńgájíá nígbà tó bá dàgbà.

Kíyè sí àpẹẹrẹ tí Jèhófà Ọlọ́run fi lélẹ̀ nínú ohun tó ṣe fún ọ̀kan lára àwọn ọmọ rẹ̀. Nígbà tí Jésù fẹ́ bẹ̀rẹ̀ apá pàtàkì kan nínú iṣẹ́ rẹ̀ lákòókò tó wà lórí ilẹ̀ ayé, Ọlọ́run sọ ní gbangba pé òun fẹ́ràn rẹ̀, ó ní: “Èyí ni Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ẹni tí mo ti tẹ́wọ́ gbà.” (Mátíù 3:17; 5:48) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojúṣe rẹ ni láti tọ́ ọmọkùnrin rẹ sọ́nà kó o sì kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́. (Éfésù 6:4) Àmọ́, ǹjẹ́ o máa ń wá ọ̀nà láti gbóríyìn fún un nítorí ohun rere tó sọ tàbí tó ṣe?

Ó máa ń ṣòro fún àwọn ọkùnrin kan láti gbóríyìn fúnni kí wọ́n sì fìfẹ́ hàn síni. Ó lè jẹ́ pé àṣìṣe táwọn èèyàn ṣe làwọn òbí wọn máa ń sọ dípò kí wọ́n máa gbóríyìn fúnni. Tó bá jẹ́ irú ilé bẹ́ẹ̀ lo ti wá, o ní láti máa sapá láti ran ọmọkùnrin rẹ lọ́wọ́ kí ọkàn rẹ̀ lè balẹ̀ láti máa ṣe àwọn nǹkan tó bá fẹ́ ṣe. Báwo lo ṣe lè ṣe é? Luca tá a sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ máa ń ṣiṣẹ́ déédéé pẹ̀lú Manuel ọmọkùnrin rẹ̀ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nígbà tí wọ́n bá ń ṣe iṣẹ́ ilé. Luca sọ pé, “Nígbà míì, màá sọ fún Manuel pé kó lọ ṣe iṣẹ́ kan fúnra rẹ̀, mo máa ń jẹ́ kó mọ̀ pé màá ràn án lọ́wọ́ tó bá nílò mi. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa ń ṣiṣẹ́ náà yanjú fúnra rẹ̀. Àṣeyọrí tó ń ṣe yẹn máa ń múnú rẹ̀ dùn, ìyẹn sì máa ń mú kí ọkàn rẹ̀ balẹ̀ láti máa ṣe nǹkan tó bá fẹ́ ṣe. Nígbà tó bá ṣe dáadáa, mo máa ń gbóríyìn fún un. Nígbà tí kò bá lè ṣe tó bó ti fẹ́, mo máa ń jẹ́ kó mọ̀ pé mo mọyì ohun tó ṣe.”

O tún lè mú kí ọkàn ọmọkùnrin rẹ balẹ̀ láti máa ṣe nǹkan tó bá fẹ́ ṣe, tó o bá ràn án lọ́wọ́ kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ àwọn ohun pàtàkì nígbèésí ayé rẹ̀. Bí ọmọkùnrin rẹ bá pẹ́ ju bó o ṣe rò lọ kí ọwọ́ rẹ̀ tó tẹ àwọn ohun pàtàkì náà ńkọ́? Tàbí tó bá jẹ́ pé àwọn nǹkan tí ọmọkùnrin rẹ fẹ́ ṣe ko burú, àmọ́ tó yàtọ̀ sí ohun tí ìwọ fẹ́ ńkọ́? Tí ọ̀ràn bá rí bẹ́ẹ̀, ó lè gba pé kó o tún inú rẹ rò lórí ohun tó o fẹ́ kí ọmọ náà ṣe. Bàbá tó ń jẹ́ Jacques tá a sọ ọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ sọ pé: “Mo ran ọmọkùnrin mi lọ́wọ́ láti máa lépa àwọn ohun tí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ̀. Àmọ́ mo tún rí i dájú pé àwọn ohun tó wù ú ni, kì í ṣe ohun tó wu èmi. Nítorí náà, mi ò kan án lójú torí mo gbà pé ó ní láti ṣe nǹkan náà títí ọwọ́ rẹ̀ á fi tẹ̀ ẹ́.” Tí ọmọkùnrin rẹ bá ń sọ èrò ọkàn rẹ̀, gbóríyìn fún un nítorí ohun to ti ṣe, gbà á níyànjú láti borí ìfàsẹ́yìn tó dé bá a, kó o sì ràn án lọ́wọ́ kí ọwọ́ rẹ̀ lè tẹ àwọn ohun tó ń wá.

Òótọ́ ni pé ìṣòro díẹ̀díẹ̀ á máa wà láàárín ìwọ àti ọmọkùnrin rẹ bí ẹ ti jọ ń ṣe nǹkan pa pọ̀. Àmọ́, tí o bá ti ṣe gbogbo ohun tó yẹ, àjọṣe ọmọkùnrin rẹ pẹ̀lú rẹ kò ní bà jẹ́. Ó ṣe tán, kò sẹ́ni tó máa fẹ́ kí àjọṣe òun bà jẹ́ pẹ̀lú ẹni tó ran òun lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àpilẹ̀kọ yìí sọ nípa àjọṣe tó wà láàárín àwọn bàbá àtàwọn ọmọ wọn ọkùnrin, síbẹ̀ àwọn ìlànà náà tún lè ṣèrànwọ́ nínú àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn obìnrin.