Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọlọ́run Gbà Wọ́n Kúrò Nínú Ìléru Oníná!

Ọlọ́run Gbà Wọ́n Kúrò Nínú Ìléru Oníná!

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Ọlọ́run Gbà Wọ́n Kúrò Nínú Ìléru Oníná!

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sí ariwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

Àwọn tá a sọ̀rọ̀ nípa wọn: Ṣádírákì, Méṣákì, Àbẹ́dínígò àti Nebukadinésárì

Àkópọ̀: Wọ́n dán ìgbàgbọ́ ọ̀dọ́kùnrin Hébérù mẹ́ta wò.

1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA DÁNÍẸ́LÌ 3:1-30.

Ṣàlàyé ìró tó o “gbọ́” nígbà tó ò ń ka ẹsẹ 3 sí 7.

․․․․․

Fojú inú wo bí ìléru oníná náà ṣe rí, kí o sì ṣàlàyé rẹ̀.

․․․․․

Kí lo kíyè sí nínú ohùn Nebukadinésárì bó ṣe ń pàṣẹ pé kí wọ́n mú ìná náà gbóná ní ìlọ́po méje ju ti tẹ́lẹ̀ lọ? (Tún ẹsẹ 19 àti 20 kà.)

․․․․․

Fojú inú wo bí ọkùnrin kẹrin tó wà nínú iná náà ṣe rí, kí o sì ṣàlàyé rẹ̀. (Tún ẹsẹ 24 àti 25 kà.)

․․․․․

Kí lo kíyè sí nínú ìwà Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò nígbà tí wọ́n ń bá Nebukadinésárì sọ̀rọ̀ ní ẹsẹ 16 sí 18?

․․․․․

2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Lo àwọn ìwé ìwádìí tó o mọ̀ láti fi mọ bí ìgbọ̀nwọ́ kan ṣe ga tó, kí o sì ṣírò bí ère tí Nebukadinésárì ṣe náà ṣe tóbi tó. (Tún ẹsẹ 1 kà.)

․․․․․

Nígbà tó o bá fi ẹsẹ 19 àti 20ẹsẹ 28 àti 29, irú èèyàn wo ló jọ pé Nebukadinésárì jẹ́?

․․․․․

3 MÁA FI OHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . . 

Bíbọ̀wọ̀ fún àwọn aláṣẹ.

․․․․․

Bí ó ti ṣe pàtàkì tó láti máa gbèjà ohun tó o gbà gbọ́.

․․․․․

Bí Jèhófà ṣe ń tini lẹ́yìn nígbà àdánwò.

․․․․․

ÀWỌN OHUN MÍÌ TÓ O LÈ FI ṢÈWÀ HÙ.

Ọ̀nà wo ni wọ́n lè gbà dán ìgbàgbọ́ rẹ wò?

․․․․․

Báwo ni ìtàn Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò ṣe máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti jẹ́ olóòótọ́?

․․․․․

4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․

Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa bíbélì, lórí ìkànnì wa www.watchtower.org àti www.pr418.com