Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Pè Wọ́n Ní “Àwọn Ọmọ Ààrá”

A Pè Wọ́n Ní “Àwọn Ọmọ Ààrá”

Kọ́ Ọmọ Rẹ

A Pè Wọ́n Ní “Àwọn Ọmọ Ààrá”

O MÁA ń gbọ́ ìró ààrá tí òjò bá ń rọ̀ tí atẹ́gùn líle sì ń fẹ́. Ǹjẹ́ ìró yìí ti dẹ́rù bà ẹ́ rí? * Jésù pe méjì lára àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ní “Àwọn Ọmọ Ààrá.” Jẹ́ ká wo ohun tó fà á tó fi pè wọ́n bẹ́ẹ̀.

Jákọ́bù àti Jòhánù ni àwọn ọmọlẹ́yìn náà. Tẹ̀gbọ́n-tàbúrò ni wọ́n, Sébédè ni bàbá wọn, Sàlómẹ̀ sì ni ìyá wọn. Ó ṣeé ṣe kí Sàlómẹ̀ jẹ́ arábìnrin Màríà ìyá Jésù. Nítorí náà, ó ṣeé ṣe kí Jésù, Jákọ́bù àti Jòhánù jẹ́ ẹbí, ó sì ṣeé ṣe kí wọ́n jẹ́ ọ̀rẹ́ láti kékeré.

Iṣẹ́ ẹja pípa ni Sébédè ń ṣe, Jákọ́bù àti Jòhánù náà sì ń ṣiṣẹ́ yìí. Àwọn méjèèjì wà lára àwọn ọmọlẹ́yìn tí Jésù kọ́kọ́ yàn. Nígbà tó ké sí wọn, ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n fi iṣẹ́ ẹja pípa sílẹ̀ tí wọ́n sì tẹ̀ lé e. Nígbà tó yá, Jésù yan méjìlá lára àwọn ọmọlẹ́yìn láti di àpọ́sítélì. Jákọ́bù àti Jòhánù wà lára wọn.

Ní àwọn oṣù bíi mélòó kan ṣáájú kí wọ́n tó pa Jésù, òun àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ gba àgbègbè òkè Samáríà kọjá. Ilẹ̀ ti ń ṣú, ó sì ti rẹ gbogbo wọn gan-an. Àmọ́ àwọn ará Samáríà sọ pé àwọn kò fẹ́ kí Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀ sun ìlú àwọn mọ́jú. Ǹjẹ́ o mọ ìdí tí wọ́n fi sọ bẹ́ẹ̀?— Jẹ́ ká wò ó.

Júù ni Jésù àtàwọn àpọ́sítélì rẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni kò sì fẹ́ràn àwọn ará Samáríà. Àmọ́ Jésù yàtọ̀. Ó fi àánú hàn sí wọn, ohun tó sì yẹ kí Jákọ́bù àti Jòhánù náà ṣe nìyẹn. Àmọ́, inú bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí sí àwọn ará Samáríà tí kò gbà wọ́n sí ìlú wọn, wọ́n sì sọ fún Jésù pé: ‘Ṣé ìwọ fẹ́ kí á pe iná kí ó sọ̀ kalẹ̀, kí ó sì pa wọ́n?’ Kí lo rò pé Jésù sọ?— Ó sọ fún wọn pé, èrò búburú tí wọ́n ní yẹn kò dára! Jákọ́bù àti Jòhánù ní láti kẹ́kọ̀ọ́ láti túbọ̀ mọ ohun tí àánú jẹ́.

Ìṣòro míì tó lágbára tí Jákọ́bù àti Jòhánù ní ni pé, wọ́n fẹ́ máa wà nípò àkọ́kọ́, wọ́n sì máa ń fẹ́ jẹ́ ẹni tó ṣe pàtàkì jù lọ. Kété kí Jésù tó kú, wọ́n rán màmá wọn pé kó sọ fún Jésù pé: “Sọ ọ̀rọ̀ náà kí àwọn ọmọkùnrin mi méjì wọ̀nyí lè jókòó, ọ̀kan ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ àti ọ̀kan ní òsì rẹ, nínú ìjọba rẹ.” Tóò, nígbà tí àwọn àpọ́sítélì mẹ́wàá yòókù gbọ́ ohun tí Jákọ́bù àti Jòhánù ṣe, inú bí wọn. Ṣé ìwọ náà á bínú tó o bá wà níbẹ̀?

Ó ṣeé ṣe kó o bínú. Inú wa kì í dùn tí àwọn kan bá ń fẹ́ láti wà nípò àkọ́kọ́ tí wọ́n sì ń fẹ́ láti máa fi hàn pé àwọn ṣe pàtàkì ju àwọn míì lọ. Nígbà tó yá, Jákọ́bù àti Jòhánù mọ̀ pé òun tí àwọn ṣe kò dára àti pé àwọn kò fi àánú hàn, nítorí náà wọ́n yí ìwà wọn pa dà. Wọ́n wá di àpọ́sítélì tó nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, tí wọ́n sì láàánú. Kí la lè rí kọ́ nínú èyí?

Ẹ̀kọ́ tí a rí kọ́ lára Jésù ni pé, ó yẹ kí àwa náà máa fi àánú hàn sí àwọn èèyàn. Jésù hùwà tó dáa sí ọkùnrin, obìnrin àtàwọn ọmọdé. Ṣé wàá sapá láti máa rántí àpẹẹrẹ Jésù, tí wàá sì máa tẹ̀ lé e?

Kà á nínú bíbélì rẹ

Máàkù 3:17

Mátíù 27:55, 56; Máàkù 15:40, 41

Mátíù 4:18-22

Jòhánù 4:4-15, 21-26; Lúùkù 9:51-55

Mátíù 20:20-24; Máàkù 10:35-37, 41

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Tó bá jẹ́ ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kí ọmọ náà sọ tinú rẹ̀.