Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ábúráhámù Jẹ́ Onífẹ̀ẹ́

Ábúráhámù Jẹ́ Onífẹ̀ẹ́

Ábúráhámù Jẹ́ Onífẹ̀ẹ́

Ọ̀fọ̀ ńlá ṣẹ Ábúráhámù. Sárà aya rẹ̀ ọ̀wọ́n kú. Nígbà tó fẹ́ sin ín, ó ń ṣàárò rẹ̀ gan-an bó ṣe ń rántí ìgbà tí àwọn méjèèjì jọ wà pa pọ̀. Ìbànújẹ́ bá a gidigidi, ni omijé bá bẹ̀rẹ̀ sí í dà lójú rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 23:1, 2) Kò ka ẹkún tó sun sí ohun ìtìjú rárá, tàbí pé òun ti ba ọkùnrin jẹ́. Ṣe ni omijé tó ń dà lójú rẹ̀ fi hàn pé ó lọ́kàn tó dáa, pé ó ní ìfẹ́.

KÍ NI ÌFẸ́? Ìfẹ́ ni pé kí ọkàn ẹni fà mọ́ọ̀yàn lọ́nà tó jinlẹ̀, kéèyàn sì fẹ́ràn onítọ̀hún látọkàn wá. Ẹni tó ní ìfẹ́ máa ń fi ìfẹ́ yìí hàn nínú ìwà àti ìṣe rẹ̀ sí àwọn tó fẹ́ràn, kódà tó bá tiẹ̀ gba pé kó fi àwọn nǹkan kan du ara rẹ̀.

BÁWO NI ÁBÚRÁHÁMÙ ṢE FI HÀN PÉ ÒUN NÍ ÌFẸ́? Ábúráhámù ṣe ohun tó fi hàn pé ó fẹ́ràn ìdílé rẹ̀. Láìsí àní-àní, ẹni tí ọwọ́ rẹ̀ máa ń dí gan-an ni Ábúráhámù. Síbẹ̀, ọ̀rọ̀ ìdílé rẹ̀ jẹ ẹ́ lógún, kò sì fi ọ̀rọ̀ ìjọsìn ìdílé rẹ̀ ṣeré rárá. Kódà, Jèhófà fúnra rẹ̀ kíyè sí i pé Ábúráhámù tó jẹ́ olórí ìdílé ló ń mú ipò iwájú nínú ìdílé rẹ̀ tó bá kan ọ̀rọ̀ ìjọsìn. (Jẹ́nẹ́sísì 18:19) Ìyẹn nìkan kọ́, Jèhófà dìídì mẹ́nu kan bí Ábúráhámù ṣe jẹ́ onífẹ̀ẹ́. Nígbà kan tí Ọlọ́run ń bá a sọ̀rọ̀ nípa Ísákì, ó ní “ọmọkùnrin rẹ . . . tí o nífẹ̀ẹ́ gidigidi.”—Jẹ́nẹ́sísì 22:2.

A tún lè rí i pé Ábúráhámù jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ tá a bá wo ohun tó ṣe nígbà tí Sárà aya rẹ̀ ọ̀wọ́n kú. Ṣe ló pohùn réré ẹkún lórí rẹ̀. Lóòótọ́ alágbára àti akíkanjú èèyàn ni Ábúráhámù, síbẹ̀ kò tijú láti sunkún ní gbangba. Ẹ ò rí i pé bó ṣe jẹ́ alágbára èèyàn náà ló tún jẹ́ oníwà pẹ̀lẹ́!

Ábúráhámù ṣe ohun tó fi hàn pé ó fẹ́ràn Ọlọ́run. Ìfẹ́ yìí hàn nínú gbogbo bó ṣe gbé ìgbé ayé rẹ̀. Lọ́nà wo? Ẹ jẹ́ ká rántí ohun tí Bíbélì sọ nínú 1 Jòhánù 5:3 pé: “Èyí ni ohun tí ìfẹ́ fún Ọlọ́run túmọ̀ sí, pé kí a pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́.” Tá a bá fi ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ wé gbogbo ohun tí Ábúráhámù ṣe, a óò rí i pé ó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run lọ́nà tó ta yọ.

Nígbàkigbà tí Jèhófà bá pàṣẹ kan fún Ábúráhámù, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Ábúráhámù máa ń ṣègbọràn. (Jẹ́nẹ́sísì 12:4; 17:22, 23; 21:12-14; 22:1-3) Yálà àṣẹ yẹn rọ Ábúráhámù lọ́rùn láti pa mọ́ tàbí kò rọ̀ ọ́ lọ́rùn, yálà ó mọ ìdí tí Jèhófà fi pàṣẹ yẹn tàbí kò mọ̀ ọ́n, ó ti gbà ní tiẹ̀ pé ti Ọlọ́run làṣẹ. Ohun tí Ọlọ́run bá ṣáà ti sọ ló máa ṣe. Ṣe ni Ábúráhámù máa ń ka pípa gbogbo àṣẹ Jèhófà mọ́ sí àǹfààní ńlá láti fi hàn pé òun nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.

Ẹ̀KỌ́ WO LA RÍ KỌ́? Àwa náà lè ṣe bíi ti Ábúráhámù, ká jẹ́ ẹni tó máa ń nífẹ̀ẹ́ ọmọnìkejì wa látọkàn wá, pàápàá àwọn tó wà nínú ìdílé wa. A ò sì ní máa jẹ́ kí ìgbòkègbodò ojoojúmọ́ gba àkókò tó yẹ ká fi gbọ́ táwọn èèyàn tó ṣe pàtàkì sí wa.

Ó tún dára pé ká jẹ́ ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà látọkàn wá. Ìfẹ́ yìí jẹ́ ohun pàtàkì tí yóò máa ràn wá lọ́wọ́ nígbèésí ayé wa. Bí àpẹẹrẹ, ó lè mú ká ṣe ìyípadà nínú ìwà, nínú ọ̀rọ̀ àti nínú ìṣe wa ká bàa lè múnú Ọlọ́run dùn.—1 Pétérù 1:14-16.

Lóòótọ́, kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn láti pa àwọn àṣẹ Jèhófà mọ́. Ṣùgbọ́n, ká jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run tó ran Ábúráhámù lọ́wọ́, tó tún pè é ní “ọ̀rẹ́ mi,” yóò tì wá lẹ́yìn. (Aísáyà 41:8) Ìlérí tó wà nínú Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni pé: “Yóò fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, yóò sì sọ yín di alágbára.” (1 Pétérù 5:10) Ìlérí tí Ọlọ́run atóófaratì tó jẹ́ ọ̀rẹ́ Ábúráhámù ṣe fún wa yìí, mà wúni lórí o!

Ṣé Ọkùnrin Tó Bá Sunkún Ti Ba Ọkùnrin Jẹ́?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló máa sọ pé bẹ́ẹ̀ ni. Ṣùgbọ́n ó lè yà wọ́n lẹ́nu láti gbọ́ pé, Ábúráhámù wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ èèyàn tó nígbàgbọ́ tó lágbára tó sì jẹ́ akíkanjú, àmọ́ tí Bíbélì sọ pé wọ́n sunkún nígbà ìbànújẹ́. Àwọn míì lára wọn ni Jósẹ́fù, Dáfídì, àpọ́sítélì Pétérù, àwọn alàgbà nínú ìjọ Éfésù, àti Jésù pàápàá. (Jẹ́nẹ́sísì 50:1; 2 Sámúẹ́lì 18:33; Lúùkù 22:61, 62; Jòhánù 11:35; Ìṣe 20:36-38) Ó ṣe kedere pé Bíbélì kò kọ́ni pé ọkùnrin tó bá sunkún ti ba ọkùnrin jẹ́.