Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Sọ Pé Kí Ábúráhámù Fi Ọmọ Rẹ̀ Rúbọ?

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Sọ Pé Kí Ábúráhámù Fi Ọmọ Rẹ̀ Rúbọ?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé . . .

Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Sọ Pé Kí Ábúráhámù Fi Ọmọ Rẹ̀ Rúbọ?

▪ Ìwé Jẹ́nẹ́sísì sọ pé Jèhófà Ọlọ́run ní kí Ábúráhámù fi ọmọ rẹ̀ Ísákì rúbọ. (Jẹ́nẹ́sísì 22:2) Ìtàn yẹn kò yé àwọn kan tó ń ka Bíbélì. Ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó ń jẹ́ Carol sọ pé: “Ìgbà ti mo kọ́kọ́ gbọ́ ìtàn náà nígbà tí mo wà lọ́mọdé, inú bí mi gan-an. Mò ń rò ó pé irú Ọlọ́run ìkà wo ló sọ pé kí ẹnì kan ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀?” Lóòótọ́, gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́ran ara, èèyàn lè ní irú èrò bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó máa dáa ká fi àwọn ohun kan sọ́kàn.

Lákọ̀ọ́kọ́, wo àwọn ohun tí Jèhófà kò ṣe. Kò jẹ́ kí Ábúráhámù fi ọmọ rẹ̀ rúbọ bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ábúráhámù ti múra tán láti fi ọmọ náà rúbọ lóòótọ́. Bákan náà, yàtọ̀ sí Ábúráhámù, kò tún sí ẹlòmíì tí Ọlọ́run sọ fún pé kó ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ṣe ni Jèhófà fẹ́ kí gbogbo àwọn tó ń sin òun máa gbádùn ayé wọn nìṣó, kí ayé wọn sì dùn bí oyin.

Ìkejì, Bíbélì jẹ́ kó hàn pé ìdí pàtàkì wà tí Jèhófà fi ní kí Ábúráhámù fi Ísákì rúbọ. Ọlọ́run mọ̀ pé ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà, òun náà yóò yọ̀ǹda kí Ọmọ * òun, ìyẹn Jésù, kú fún wa. (Mátíù 20:28) Jèhófà fẹ́ kí àwa èèyàn mọ ohun ńlá tí ikú ìrúbọ tí Ọmọ òun máa kú yìí, yóò ná òun. Àpẹẹrẹ bí ìrúbọ yẹn ṣe máa rí gan-an ló fi hàn wá nígbà tó sọ pé kí Ábúráhámù fi ọmọ rẹ̀ rúbọ. Báwo ló ṣe rí bẹ́ẹ̀?

Wo ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Ábúráhámù, ó ní: “Jọ̀wọ́, mú ọmọkùnrin rẹ, ọmọkùnrin rẹ kan ṣoṣo tí o nífẹ̀ẹ́ gidigidi, Ísákì, kí o sì rìnnà àjò lọ sí ilẹ̀ Móráyà, kí o sì fi í rúbọ níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ ẹbọ sísun.” (Jẹ́nẹ́sísì 22:2) Kíyè sí i pé Jèhófà sọ pé Ísákì jẹ́ ọmọkùnrin tí Ábúráhámù “nífẹ̀ẹ́ gidigidi.” Jèhófà mọ̀ pé Ábúráhámù fẹ́ràn Ísákì bí ẹyinjú rẹ̀. Bákan náà, Ọlọ́run mọ bí ọ̀rọ̀ Jésù Ọmọ òun ṣe rí lára òun náà. Jèhófà fẹ́ràn Jésù gan-an débi pé ẹ̀ẹ̀mejì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló sọ̀rọ̀ látọ̀run, tó dìídì pe Jésù ní “Ọmọ mi, olùfẹ́ ọ̀wọ́n.”—Máàkù 1:11; 9:7.

Tún kíyè sí i pé Jèhófà lo gbólóhùn náà “jọ̀wọ́,” nígbà tó sọ fún Ábúráhámù pé kó ṣe ìrúbọ náà. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé ìdí tí Ọlọ́run fi lo gbólóhùn náà ni pé “OLÚWA mọ̀ pé àdánù ńlá ló máa jẹ́ fún un tó bá fi ọmọ náà rúbọ.” Bí a bá sì fojú inú wò ó, a ó rí i pé yóò dun Ábúráhámù gan-an nígbà tí Ọlọ́run ní kó fi ọmọ rẹ̀ yẹn rúbọ. Èyí jẹ́ ká ní òye díẹ̀ nípa bó ṣe jẹ́ ìrora tó lékenkà fún Jèhófà nígbà tó ń wo Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n bó ṣe ń jìyà títí tó fi kú. Ó dájú pé ìyẹn ló máa jẹ́ ohun tó tíì dun Jèhófà jù, kò sì ní sí ohun míì tó tún máa dùn ún bẹ́ẹ̀ mọ́ láé.

Nítorí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ara wa lè bù mọ́ aṣọ tá a bá ronú nípa ohun tí Jèhófà ní kí Ábúráhámù ṣe, ó bọ́gbọ́n mu ká máa rántí pé lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, Jèhófà kò jẹ́ kí Ábúráhámù, ọkùnrin olóòótọ́ yẹn, fi ọmọ náà rúbọ. Kò jẹ́ kí àdánù tó le jù fún òbí bá Ábúráhámù, ó gba Ísákì sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú. Àmọ́, Jèhófà “kò dá Ọmọ tirẹ̀ pàápàá sí, ṣùgbọ́n . . . ó jọ̀wọ́ rẹ̀ lọ́wọ́ fún gbogbo wa.” (Róòmù 8:32) Kí nìdí tí Jèhófà fi kó ara rẹ̀ sí ẹ̀dùn ọkàn tó lékenkà bẹ́ẹ̀? Torí kí “a lè jèrè ìyè” ló fi ṣe bẹ́ẹ̀. (1 Jòhánù 4:9) Ẹ ò rí i pé Ọlọ́run fẹ́ràn wa gidigidi! Ǹjẹ́ kò yẹ kí àwa náà máa ṣe ohun tó máa fi hàn pé a fẹ́ràn rẹ̀? *

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Bíbélì kò sọ pé ṣe ni obìnrin kan lóyún fún Ọlọ́run tó sì wá bí Jésù. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni Jèhófà dá áńgẹ́lì kan ní ọ̀run, tó sì rán áńgẹ́lì náà wá sí ayé nígbà tó mú kí wúńdíá kan tó ń jẹ́ Màríà bí i lọ́nà ìyanu. Níwọ̀n bó sì ti jẹ́ pé Ọlọ́run ló ṣẹ̀dá Jésù, kò burú tá a bá pè é ní Baba rẹ̀.

^ Tó o bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ìdí tí Jésù fi kú àti bá a ṣe lè fi hàn pé a mọrírì ohun tó ṣe fún wa yìí, wo orí 5 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?