Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Má Ṣe Gba Àwọn Ẹ̀mí Burúkú Láyè!

Má Ṣe Gba Àwọn Ẹ̀mí Burúkú Láyè!

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Má Ṣe Gba Àwọn Ẹ̀mí Burúkú Láyè!

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sí ariwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA JẸ́NẸ́SÍSÌ 6:1-6 ÀTI ÌṢE 19:11-20.

Ṣàpèjúwe bó o ṣe rò pé àwọn Néfílímù tóbi tó, bí wọ́n ṣe ga tó àti bí wọ́n ṣe bani lẹ́rù tó.

․․․․․

Báwo lo ṣe rò pé ó máa rí lára àwọn ọkùnrin tí Bíbélì sọ̀rọ̀ wọn nínú Ìṣe 19:13-16 lẹ́yìn tí ẹ̀mí burúkú bá wọn jà?

․․․․․

2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Lo àwọn ìwé ìwádìí míì tó o mọ̀ láti fi ṣèwádìí síwájú sí i nípa àwọn Néfílímù. Kí lo rò pé ó jẹ́ kí wọ́n burú tó bẹ́ẹ̀?

․․․․․

Ọ̀nà wo la fi lè sọ pé àwọn áńgẹ́lì burúkú náà “ṣá ibi gbígbé tiwọn tí ó bẹ́tọ̀ọ́ mu tì”? (Ka Júúdà 6.) Kí nìdí tó o fi rò pé kò tọ́, tàbí pé ó jẹ́ ìwà ìbàjẹ́, pé kí àwọn áńgẹ́lì wá fẹ́ ìyàwó láàárín àwa èèyàn?

․․․․․

Kí ni ìtàn méjèèjì tó o kà jẹ́ kó o mọ̀ nípa bí ìṣekúṣe àti ìwà ìkà ṣe gba àwọn ẹ̀mí burúkú lọ́kàn tó?

․․․․․

3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Ìwà ìkà àti ẹ̀mí ìmọtara-ẹni-nìkan tí àwọn ẹ̀mí burúkú ní.

․․․․․

ÀWỌN OHUN MÍÌ TÓ O LÈ FI ṢÈWÀ HÙ.

Níwọ̀n bí àwọn ẹ̀mí burúkú kò ti lè para dà di èèyàn mọ́, àwọn ọ̀nà wo ni wọ́n lè fẹ́ gbà máa darí rẹ?

․․․․․

Lóde òní, irú àwọn eré ìnàjú wo ló ń gbé ìwà àwọn ẹ̀mí burúkú àti ìfẹ́ ọkàn wọn lárugẹ?

․․․․․

Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o kò ní gba àwọn ẹ̀mí èṣù láyè rárá? (Tún Ìṣe 19:18, 19 kà.)

․․․․․

4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÀWỌN ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․

Kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa Bíbélì, lórí ìkànnì wa www.watchtower.org àti www.pr418.com