Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

Àwọn Kristẹni Tòótọ́ Bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run

“Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.”—JÒH. 17:17.

1. Nígbà tó o kọ́kọ́ bá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà pà dé, sọ ohun pàtàkì kan tó o kíyè sí pé wọ́n fi yàtọ̀ sí àwọn ẹlẹ́sìn tó kù.

 RONÚ nípa ìgbà tó o kọ́kọ́ ní ìfọ̀rọ̀wérọ̀ pẹ̀lú ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kí lo rántí nínú ohun tẹ́ ẹ jọ sọ? Ọ̀pọ̀ èèyàn tí wọ́n bá bi ní ìbéèrè yìí á sọ pé: ‘Ohun tí mo gbádùn jù lọ nínú ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tí mo ní pẹ̀lú Ẹlẹ́rìí tó bá mi sọ̀rọ̀ ni pé ó lo Bíbélì láti dáhùn gbogbo ìbéèrè mi.’ Ẹ sì wo bó ti dùn mọ́ wa tó láti lóye ohun tó jẹ́ ètè Ọlọ́run nípa ilẹ̀ ayé, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa tá a bá kú àti bí Ọlọ́run ṣe máa jí àwọn ìbátan wa tó ti kú dìde lọ́jọ́ iwájú!

2. Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tó mú kó o wá mọrírì Bíbélì?

2 Àmọ́, bá a ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì síwájú sí i, à ń rí i pé kì í ṣe àwọn ohun tó rú wa lójú nípa ìgbésí ayé, ikú àti ọjọ́ iwájú nìkan ni Bíbélì mú kó ṣe kedere. A wá mọ̀ pé nínú gbogbo ìwé tó wà láyé, ìmọ̀ràn inú Bíbélì ló wúlò jù lọ, ó sì máa ń bágbà mu. Ìgbésí ayé àwọn tó bá ń tẹ̀ lé ìmọ̀ràn rẹ̀ nígbà gbogbo á nítumọ̀, wọ́n á sì máa láyọ̀. (Ka Sáàmù 1:1-3.) Látilẹ̀ wá làwọn Kristẹni tòótọ́ ti gba Bíbélì, “kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ènìyàn, ṣùgbọ́n, gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ lótìítọ́, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” (1 Tẹs. 2:13) Tá a bá ṣe àyẹ̀wò ṣókí nípa ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá, a máa rí bí àwọn tó bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní tòótọ́ ṣe yàtọ̀ sí àwọn tí kò bọ̀wọ̀ fún un.

WỌ́N RÍ OJÚTÙÚ SÍ ÌṢÒRO KAN TÓ TA KOKO

3. Awuyewuye wo ló fẹ́ ba ìṣọ̀kan ìjọ Kristẹni jẹ́ ní ọ̀rúndún kìíní, kí sì nìdí tó fi ṣòro láti yanjú rẹ̀?

3 Ní ọdún mẹ́tàlá lẹ́yìn tí Ọlọ́run ti fẹ̀mí yan Kọ̀nílíù, Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ tó kọ́kọ́ di onígbàgbọ́, ọ̀pọ̀ àwọn Kèfèrí ló ti di Kristẹni. Láàárín àkókò yìí, awuyewuye kan wáyé tó fẹ́ ba ìṣọ̀kan ìjọ Kristẹni jẹ́, èyí tó mú kí ìbéèrè náà jẹ yọ pé, Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwọn ọkùnrin wọ̀nyí máa dádọ̀dọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àṣà àwọn Júù kí wọ́n tó ṣèrìbọmi? Ìbéèrè tó ṣòro dáhùn fún ẹnì kan tó jẹ́ Júù lèyí. Ìdí sì ni pé àwọn Júù tó ń pa Òfin mọ́ kò tiẹ̀ ní í wọnú ilé ẹnì kan tó jẹ́ Kèfèrí, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ pé kí wọ́n ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. Àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ Kristẹni ṣì ń fojú winá inúnibíni tó gbóná janjan torí pé wọ́n kúrò nínú ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe tẹ́lẹ̀. Bí wọ́n bá tún wá ń bá àwọn Kèfèrí aláìdádọ̀dọ́ tó wà láàárín wọn kẹ́gbẹ́ pọ̀, ńṣe ló wulẹ̀ máa dá kún awuyewuye tó wà láàárín àwọn tó ń pa àṣà àwọn Júù mọ́ àti àwọn Kristẹni, èyí á sì mú kí wọ́n túbọ̀ máa kẹ́gàn àwọn Kristẹni.—Gál. 2:11-14.

4. Àwọn wo ni wọ́n ké sí láti yanjú awuyewuye náà, àti pé látàrí ìyẹn, ìbéèrè wo ló ṣeé ṣe kó wà lọ́kàn àwọn tó wà níbẹ̀?

4 Ní ọdún 49 Sànmánì Kristẹni, àwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin tó wà ní Jerúsálẹ́mù, tí àwọn fúnra wọn jẹ́ Júù tó dádọ̀dọ́, “kóra jọpọ̀ láti rí sí àlámọ̀rí yìí.” (Ìṣe 15:6) Ní ìpàdé náà, wọn kò bára wọn jiyàn lórí àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ tí kò ṣe pàtàkì tó máa ń tètè súni, àmọ́ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ni ìjíròrò wọn dá lé, ìjíròrò náà sì lárinrin. Àwọn tó wà níbẹ̀ sọ èrò wọn nípa ọ̀ràn náà. Àmọ́, ṣé wọ́n máa jẹ́ kí ohun tó wu ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn tàbí ẹ̀tanú ní ipa lórí ìpinnu tí wọ́n máa ṣe? Ṣé àwọn àgbà ọkùnrin tó yẹ kó yanjú ọ̀ràn náà máa sún ìpinnu náà síwájú títí dìgbà tí awuyewuye tó wà láàárín àwọn Júù tó ń pa Òfin Mósè mọ́ àtàwọn Júù tó di Kristẹni bá parí? Àbí wọ́n a wulẹ̀ ṣe ìpinnu tí kò bá ohun tí wọ́n gbà gbọ́ mu torí kí wọ́n ṣáà ti lè wá ibì kan parí ọ̀rọ̀ náà sí?

5. Àwọn ọ̀nà pàtàkì wo ni ìpàdé tó wáyé ní Jerúsálẹ́mù lọ́dún 49 Sànmánì Kristẹni fi yàtọ̀ sí àpérò táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn náà?

5 Níbi àpérò táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe lóde òní, àwọn aṣáájú ẹ̀sìn sábà máa ń tẹ òtítọ́ lójú, àwọn kan lára wọn sì máa ń wá bí àwọn míì á ṣe fara mọ́ èrò wọn. Àmọ́, àwọn tó wà níbi ìpàdé tó wáyé ní Jerúsálẹ́mù kò tẹ òtítọ́ lójú, wọn kò sì wá bí àwọn míì á ṣe fara mọ́ èrò wọn. Síbẹ̀, wọ́n ṣe ìpinnu tí gbogbo wọ́n fara mọ́. Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún wọn láti fohùn ṣọ̀kan? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé olúkúlùkù wọn ló ní èrò tirẹ̀ lọ́kàn, gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ sì ni wọ́n fi yanjú awuyewuye náà.—Ka Sáàmù 119:97-101.

6, 7. Báwo ni wọ́n ṣe lo Ìwé Mímọ́ láti yanjú awuyewuye tó wáyé lórí ọ̀ràn ìdádọ̀dọ́?

6 Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí wọ́n fi yanjú ọ̀ràn náà ni Ámósì 9:11, 12. Ìwé Ìṣe 15:16, 17 tọ́ka sí ohun tó wà nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ náà pé: “Èmi yóò padà, èmi yóò sì tún àtíbàbà Dáfídì tí ó ti wó lulẹ̀ kọ́; èmi yóò sì tún àwókù rẹ̀ kọ́, èmi yóò sì gbé e nà ró lẹ́ẹ̀kan sí i, kí àwọn tí ó ṣẹ́ kù lára àwọn ènìyàn náà lè fi taratara wá Jèhófà, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ènìyàn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn ènìyàn tí a fi orúkọ mi pè, ni Jèhófà wí.”

7 Àmọ́, ẹnì kan lè sọ pé, ‘ẹsẹ yẹn kò sọ pé kí àwọn Kèfèrí tó di onígbàgbọ́ má ṣe dádọ̀dọ́.’ Òótọ́ ni, á sì ti yé àwọn Júù tó di Kristẹni pé ohun tí ẹsẹ yẹn ń sọ nìyẹn. Kí nìdí? Ìdí ni pé arákùnrin ni àwọn Júù tó di Kristẹni ka àwọn Kèfèrí tó dádọ̀dọ́ sí, wọn ò kà wọ́n sí ‘àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè.’ (Ẹ́kís. 12:48, 49) Bí àpẹẹrẹ, nínú ẹ̀dà Bíbélì Septuagint tí Bagster ṣe, Ẹ́sítérì 8:17 sọ pé: “Ọ̀pọ̀ lára àwọn Kèfèrí náà dádọ̀dọ́, wọ́n sì di Júù.” Torí náà, nígbà tí Ìwé Mímọ́ sọ tẹ́lẹ̀ pé àwọn tó ṣẹ́ kù lára ilé Ísírẹ́lì (àwọn Júù àti àwọn aláwọ̀ṣe Júù tó dádọ̀dọ́) pa pọ̀ pẹ̀lú “àwọn ènìyàn gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè” (àwọn Kèfèrí tí kò dádọ̀dọ́) máa di èèyàn kan tá à ń fi orúkọ Ọlọ́run pè, ó wá ṣe kedere sí wọn pé ohun tí Ìwé Mímọ́ ń sọ ni pé kò pọn dandan kí àwọn Kèfèrí tó fẹ́ di Kristẹni dádọ̀dọ́.

8. Kí nìdí tó fi gba ìgboyà kí wọ́n tó lè ṣe ìpinnu yẹn?

8 Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti ẹ̀mí rẹ̀ ran àwọn Kristẹni tòótọ́ wọ̀nyẹn lọ́wọ́ láti ‘fi ìmọ̀ ṣọ̀kan.’ (Ìṣe 15:25) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kí ìpinnu náà mú káwọn Júù tó di Kristẹni túbọ̀ máa fojú winá inúnibíni, àwọn tó jẹ́ olùṣòtítọ́ láàárín wọn fara mọ́ ìpinnu tí wọ́n gbé karí Bíbélì tọkàntọkàn.—Ìṣe 16:4, 5.

ÌYÀTỌ̀ NÁÀ TÚBỌ̀ ṢE KEDERE

9. Kí ni ọ̀nà pàtàkì kan tí ẹ̀kọ́ èké gbà kó àbààwọ́n bá ẹ̀sìn Kristẹni, ẹ̀kọ́ pàtàkì wo ni wọ́n sì sọ dìbàjẹ́?

9 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ tẹ́lẹ̀ pé lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, ẹ̀kọ́ èké máa kó àbààwọ́n bá ẹ̀sìn Kristẹni. (Ka 2 Tẹsalóníkà 2:3, 7.) Díẹ̀ lára àwọn tó wà nípò àbójútó máa wà lára àwọn tí kò ní fara mọ́ “ẹ̀kọ́ afúnni-nílera.” (2 Tím. 4:3) Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fún àwọn alàgbà nígbà ayé rẹ̀ pé: “Láàárín ẹ̀yin fúnra yín ni àwọn ènìyàn yóò ti dìde, wọn yóò sì sọ àwọn ohun àyídáyidà láti fa àwọn ọmọ ẹ̀yìn lọ sẹ́yìn ara wọn.” (Ìṣe 20:30) Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ The New Encyclopædia Britannica ṣàlàyé ohun pàtàkì kan tó mú kí àwọn wọ̀nyí ní èrò òdì. Ó sọ pé: “Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe àwọn Kristẹni tí wọ́n ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ díẹ̀ nípa ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn Gíríìkì bíi pé kí wọ́n máa fi ohun tí wọ́n kọ́ ṣàlàyé ohun tí wọ́n gbà gbọ́, kí wọ́n lè tẹ́ ìfẹ́ ara wọn lọ́rùn kí wọ́n sì lè yí àwọn abọ̀rìṣà tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé lọ́kàn pa dà.” Ọ̀kan lára àwọn ohun pàtàkì táwọn Kristẹni gbà gbọ́, tí wọ́n fi ẹ̀kọ́ àwọn abọ̀rìṣà kó àbààwọ́n bá ni ohun tí Bíbélì fi kọ́ni nípa Jésù Kristi. Bíbélì sọ pé Ọmọ Ọlọ́run ni Jésù, àmọ́ àwọn tó gba ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn Gíríìkì gbọ́ sọ pé òun ni Ọlọ́run.

10. Ibo làwọn olórí ẹ̀sìn ì bá ti rí ojútùú sí awuyewuye tó wáyé nípa ẹni tí Kristi jẹ́?

10 Àwọn olórí ẹ̀sìn jiyàn lórí ọ̀rọ̀ yìí níbi àpérò mélòó kan tí wọ́n ṣe. Wọn ì bá sì ti yanjú ọ̀ràn náà wọ́ọ́rọ́wọ́ bó bá jẹ́ pé wọ́n gbé ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa rẹ̀ yẹ̀ wò, àmọ́ ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀. Kódà, kí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn tó dé ibi àwọn àpérò náà ni wọ́n ti pinnu ohun tí wọ́n máa sọ, lẹ́yìn tí wọ́n sì kúrò níbẹ̀, wọn ò ṣe tán láti yí ohun tó wà lọ́kàn wọn pa dà. Bóyá tiẹ̀ ni àwọn ìlànà àtàwọn ìpolongo tí wọ́n ṣe níbi àwọn ìpàdé wọ̀nyí dá lórí Ìwé Mímọ́.

11. Orí àṣẹ tá ni àwọn aṣáájú ẹ̀sìn gbé ìpinnu wọn kà, kí sì nìdí?

11 Kí nìdí tí wọn kò fi yẹ ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ wò dáadáa? Ọ̀mọ̀wé Charles Freeman sọ pé àwọn tó gbà gbọ́ pé Ọlọ́run ni Jésù “kò lè fi ẹ̀rí tì í lẹ́yìn pé ọ̀pọ̀ ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, tó fi hàn pé ó rẹlẹ̀ sí Ọlọ́run tó jẹ́ Baba, kò rí bẹ́ẹ̀.” Nítorí èyí, wọ́n fi ẹ̀kọ́ àtọwọ́dọ́wọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni àti èrò àwọn míì tó lẹ́nu láwùjọ rọ́pò ohun tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. Títí dòní, ọ̀pọ̀ lára àwọn àlùfáà ti gbé ọ̀rọ̀ tí kò ní ìmísí Ọlọ́run táwọn aṣáájú ẹ̀sìn ń sọ ga kọjá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run! Ó ṣeé ṣe kó o ti kíyè sí èyí bó o bá ti jíròrò ọ̀rọ̀ nípa Mẹ́talọ́kan pẹ̀lú ẹni tó ń kọ́ṣẹ́ àlùfáà rí.

12. Ipa búburú wo ni olú ọba ní lórí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn?

12 Ohun kan tó gbàfiyèsí níbi àwọn àpérò yẹn ni bí àwọn olú ọba Róòmù ṣe máa ń bá wọn dá sí i. Látàrí èyí, nínú ìwé tí Ọ̀jọ̀gbọ́n Richard E. Rubenstein kọ nípa àpérò tí wọ́n ṣe ní ìlú Niséà, ó sọ pé: “Kọnsitatáìnì ti fojúure hàn sí [àwọn bíṣọ́ọ̀bù] ó sì sọ wọ́n di ọlọ́rọ̀ ju bí wọ́n ti lè rò lọ. Kí ọdún kan tó pé lẹ́yìn tí olú ọba náà gorí àlééfà, ó dá gbogbo ṣọ́ọ̀ṣì àwọn ẹlẹ́sìn pa dà fún wọn tàbí kó tún wọn kọ́. Ó sì tún dá iṣẹ́ wọn àti oyè tí wọ́n fi dá wọn lọ́lá pa dà fún wọn . . . Ó gbé àǹfààní tó jẹ́ tàwọn babalóòṣà tẹ́lẹ̀ fún àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì.” Torí náà, “Kọnsitatáìnì wà nípò táá mú kó ní ipa tó lágbára lórí ìpinnu tí wọ́n bá ṣe níbi àpérò náà tàbí kó tiẹ̀ sọ ohun tí wọ́n máa ṣe fún wọn.” Ọ̀mọ̀wé Charles Freeman tún sọ pé: “Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé olú ọba lè dá sí ọ̀rọ̀ Ṣọ́ọ̀ṣì, kó jẹ́ igi lẹ́yìn ọgbà fún wọn kó sì máa nípa lórí ẹ̀kọ́ tí wọ́n á máa kọ́ni.”—Ka Jákọ́bù 4:4.

13. Àwọn nǹkan wo lo rò pé ó fà á tí àwọn aṣáájú ẹ̀sìn tó gbáyé ní ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn ìgbà àwọn àpọ́sítélì fi pa àwọn ẹ̀kọ́ tó ṣe kedere tí Bíbélì fi kọ́ni tì?

13 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣòro fún àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn nínú ṣọ́ọ̀ṣì láti sọ bí Jésù Kristi ṣe jẹ́ gan-an, ọ̀pọ̀ lára àwọn gbáàtúù kò ní irú ìṣòro bẹ́ẹ̀. Torí pé àwọn gbáàtúù kò retí láti rí tọwọ́ olú ọba gbà tàbí pé kó fi wọ́n sí ipò ńlá kan nínú ṣọ́ọ̀ṣì, ó ṣeé ṣe fún wọn láti túbọ̀ fi ojú tó tọ́ wo ọ̀ràn náà, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ. Ohun tí wọ́n sì ṣe gan-an nìyẹn. Gregory ti ìlú Nyssa, tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn nígbà ayé rẹ̀ fi àwọn gbáàtúù, ìyẹn àwọn tó ń ta aṣọ, àwọn tó ń pààrọ̀ owó, àwọn tó ń ta ọjà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ àtàwọn ẹrú, ṣẹ̀sín nínú ọ̀rọ̀ tó sọ. Gregory kò fara mọ́ àlàyé tí àwọn gbáàtúù máa ń ṣe pé Ọmọ yàtọ̀ sí Baba, pé Baba ju Ọmọ lọ àti pé Ọlọ́run ti dá Ọmọ ṣáájú ohun gbogbo. Ó ṣeé ṣe fún àwọn gbáàtúù láti fi Bíbélì ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ yìí. Àmọ́, Gregory ti ìlú Nyssa àti àwọn olórí ẹ̀sìn kò ṣe bẹ́ẹ̀ ní tiwọn. Ohun tí ì bá dára kí wọ́n ṣe ni pé kí wọ́n fetí sí ohun táwọn gbáàtúù ń sọ!

“ÀLÌKÁMÀ” ÀTI “ÀWỌN ÈPÒ” DÀGBÀ PA PỌ̀

14. Kí ló lè mú ká gbà pé láti ọ̀rúndún kìíní wá ni àwọn ojúlówó Kristẹni mélòó kan tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró á ti máa wà lórí ilẹ̀ ayé?

14 Nínú àkàwé kan, ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ fi hàn pé láti ọ̀rúndún kìíní wá ni àwọn ojúlówó Kristẹni mélòó kan tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró á ti máa wà lórí ilẹ̀ ayé. Ó fi wọ́n wé “àlìkámà” tó ń dàgbà láàárín “àwọn èpò.” (Mát. 13:30) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a kò lè sọ ẹnì kan pàtó tàbí àwùjọ àwọn èèyàn kan tó jẹ́ ara ẹgbẹ́ àlìkámà ti àwọn ẹni àmì òróró, ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ wà pé kò sígbà kan tí kò sí àwọn èèyàn kan tí wọ́n ń fi ìgboyà gbèjà Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń túdìí àṣírí àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu tí ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa díẹ̀ lára wọn.

15, 16. Sọ díẹ̀ lára àwọn tó bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

15 Bíṣọ́ọ̀bù Àgbà ti ìlú Lyons, ní orílẹ̀-èdè Faransé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Agobard, tó gbé ayé láàárín ọdún 779 sí ọdún 840 Sànmánì Kristẹni, sọ pé kò dára láti máa jọ́sìn ère, ó sọ pé kò tọ́ láti máa ya ṣọ́ọ̀ṣì sí mímọ́ fún àwọn ẹni mímọ́, ó sì bẹnu àtẹ́ lu àwọn ààtò àti àṣà ẹ̀sìn tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Ọ̀kan lára àwọn tí wọ́n jọ gbáyé ní àkókò kan náà, ìyẹn Bíṣọ́ọ̀bù Claudius, pẹ̀lú kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni, gbígbàdúrà sí àwọn ẹni mímọ́ àti jíjúbà àwọn eré. Ní ọ̀rúndún kọkànlá, wọ́n lé Díákónì Àgbà ti olú ìlú Tours, lórílẹ̀-èdè Faransé, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Berengarius, kúrò nínú ìjọ torí pé kò fara mọ́ ẹ̀kọ́ tí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fi kọ́ni pé búrẹ́dì àti wáìnì máa ń di ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa. Yàtọ̀ síyẹn, ó tún gbà pé ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ló yẹ kéèyàn máa tẹ̀ lé dípò àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì.

16 Àwọn méjì míì tí ọ̀rọ̀ wọ́n wá sójútáyé ní ọ̀rúndún kejìlá ni Peter ti Bruys àti Henry ti Lausanne, tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni gan-an. Peter kọ̀wé fiṣẹ́ àlùfáà sílẹ̀ torí pé kò rí bí ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì fi ń kọ́ni ṣe bá Ìwé Mímọ́ mu, irú bíi ṣíṣe ìrìbọmi fún àwọn ọmọ ọwọ́, sísọ pé búrẹ́dì àti wáìnì máa ń di ẹran ara àti ẹ̀jẹ̀ Jésù Kristi nígbà Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa, gbígbàdúrà fún àwọn òkú àti jíjọ́sìn àgbélébùú. Ní ọdún 1140, wọ́n pa Peter nítorí ohun tó gbà gbọ́. Ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé kan tó ń jẹ́ Henry, sọ pé ìwà ìbàjẹ́ tó ń lọ nínú ṣọ́ọ̀ṣì kò dáa, ó sì tún sọ nípa àwọn apá tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu nínú ààtò ẹ̀sìn. Wọ́n fàṣẹ mú un ní ọdún 1148, ẹ̀wọ̀n ló sì ti lo èyí tó kù nínú ìgbésí ayé rẹ̀.

17. Àwọn ìgbésẹ̀ pàtàkì wo ni Waldo àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ gbé?

17 Ní àárín ìgbà tí wọ́n dáná sun Peter ti Bruys lóòyẹ̀ torí pé ó sọ ohun tó rí pé ó kù díẹ̀ káàtó nínú ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n bí ẹnì kan tó máa tó ṣe gudugudu méje láti mú kí ohun tí Bíbélì fi kọ́ni tàn kálẹ̀. Orúkọ àpèlé rẹ̀ ni Valdès, tàbí Waldo. * Kì í ṣe àlùfáà bíi Peter ti Bruys àti Henry ti Lausanne, ọmọ ìjọ ni, àmọ́ ó mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run débi pé ó ta gbogbo nǹkan tó ní ó sì ṣètò pé kí wọ́n túmọ̀ apá kan Bíbélì sí èdè táwọn èèyàn ń sọ jù lọ ní gúúsù ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Faransé. Inú àwọn kan dùn láti gbọ́ ohun tí Bíbélì fi kọ́ni ní èdè wọn débi pé àwọn náà yọ̀ǹda gbogbo ohun ìní wọn, wọ́n sì yááfì ara wọn fún fífi ẹ̀kọ́ Bíbélì kọ́ àwọn mìíràn. Èyí kò dùn mọ́ àwọn aṣáájú ẹ̀sìn nínú rárá. Ní ọdún 1184, póòpù lé àwọn ọkùnrin àti obìnrin onítara táwọn èèyàn wá ń pè ní ọmọlẹ́yìn Waldo yìí kúrò nínú ìjọ, àwọn bíṣọ́ọ̀bù sì lé wọn jáde kúrò nínú ilé tí wọ́n ń gbé. Ohun tí wọ́n ṣe yìí mú kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tàn kálẹ̀ dé àwọn àgbègbè mìíràn. Nígbà tó ṣe, àwọn ọmọlẹ́yìn Waldo, Peter ti Bruys àti Henry ti Lausanne àti àwọn mìíràn tí kò fara mọ́ ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì fi ń kọ́ni, ti wà káàkiri apá ibi tó pọ̀ ní ilẹ̀ Yúróòpù. Ní àwọn ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé e, a rí àwọn mìíràn tí wọ́n gbèjà ẹ̀kọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni, àwọn bíi: John Wycliffe, tó gbáyé ní nǹkan bí ọdún 1330 sí ọdún 1384, William Tyndale tó gbáyé ní nǹkan bí ọdún 1494 sí ọdún 1536, Henry Grew, tó gbáyé ní ọdún 1781 sí ọdún 1862 àti George Storrs, tó gbáyé ní ọdún 1796 sí ọdún 1879.

“A KÒ DE Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN”

18. Ṣàlàyé ọ̀nà tí àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tọkàntọkàn gbà ṣe bẹ́ẹ̀ ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún àti ìdí tó fi gbéṣẹ́.

18 Bí àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ ẹ̀kọ́ Bíbélì ṣe gbìyànjú tó, kò ṣeé ṣe fún wọn láti pa àwọn èèyàn lẹ́nu mọ́ kí wọ́n má bàa tan ẹ̀kọ́ Bíbélì kálẹ̀. Ìwé 2 Tímótì 2:9 sọ pé: “A kò de ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.” Ní ọdún 1870, àwùjọ àwọn èèyàn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tọkàntọkàn bẹ̀rẹ̀ sí í ṣèwádìí kí wọ́n lè lóye ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Ọ̀nà wo ni wọ́n ń gbà kẹ́kọ̀ọ́? Ẹnì kan á béèrè ìbéèrè. Gbogbo wọn á jíròrò ìbéèrè náà. Wọ́n á wo gbogbo ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ṣàlàyé kókó náà, bó bá sì ti tẹ́ wọn lọ́rùn pé ohun tí àwọn ẹsẹ náà sọ bára mu, wọ́n á lò wọ́n láti fi pinnu ìdáhùn sí ìbéèrè náà, wọ́n á sì ṣe àkọsílẹ̀ rẹ̀. Ǹjẹ́ kò fi ẹ́ lọ́kàn balẹ̀ pé bíi tàwọn àpọ́sítélì àtàwọn àgbà ọkùnrin ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn ọkùnrin olùṣòtítọ́ tí wọ́n jẹ́ “baba ńlá wa nípa tẹ̀mí,” tí wọ́n gbáyé láàárín ọdún 1870 sí ọdún 1899 wọ̀nyẹn, ti pinnu láti mú kí ohun tí wọ́n gbà gbọ́ bá Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mú látòkèdélẹ̀?

19. Kí ni ẹsẹ Ìwé Mímọ́ ti ọdún 2012, kí sì nìdí tó fi bá a mu wẹ́kú?

19 Orí Bíbélì la ṣì gbé àwọn ohun tá a gbà gbọ́ kà. Pẹ̀lú ìyẹn lọ́kàn, Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti yan gbólóhùn tí Jésù fi ìdánilójú sọ nínú Jòhánù 17:17 gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2012. Ó sọ pé: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.” Níwọ̀n bí gbogbo àwọn tó bá fẹ́ rí ìtẹ́wọ́gbà Ọlọ́run ti gbọ́dọ̀ máa rìn nínú òtítọ́, ǹjẹ́ kí gbogbo wa máa bá a nìṣó láti sa ipá wa kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè máa darí wa.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Orúkọ tí wọ́n ń pe Valdès tẹ́lẹ̀ ni Pierre Valdès tàbí Peter Waldo, àmọ́ a kò mọ orúkọ àbísọ rẹ̀.

WÁ ÌDÁHÙN SÍ ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:

․․․․․

Báwo ni ìpàdé tó wáyé ní Jerúsálẹ́mù ní ọdún 49 Sànmánì Kristẹni ṣe yàtọ̀ sí àpérò táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ń ṣe lẹ́yìn ìgbà náà?

․․․․․

Àwọn díẹ̀ wo ni wọ́n bọ̀wọ̀ fún Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lẹ́yìn ìgbà ayé àwọn àpọ́sítélì?

․․․․․

Ọ̀nà wo ni àwọn Kristẹni tó jẹ́ olùṣòtítọ́ gbà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láàárín ọdún 1870 sí ọdún 1899, kí sì nìdí tó fi gbéṣẹ́?

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí tó wà ní ojú ìwé 8]

Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ wa ti ọdún 2012: “Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ rẹ.”—Jòh. 17:17

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Waldo

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Wycliffe

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Tyndale

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Grew

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Storrs