Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Báwo Ni Màá Ṣe Lè Wàásù?’

‘Báwo Ni Màá Ṣe Lè Wàásù?’

‘Báwo Ni Màá Ṣe Lè Wàásù?’

Jákèjádò ayé, ọ̀pọ̀ àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin máa ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn tó le gan-an ń ṣe wọ́n. Àpẹẹrẹ títayọ ni irú àwọn ará bẹ́ẹ̀ jẹ́. Ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa Dalia, tó ń gbé ní ìlú Vilnius, olú ìlú orílẹ̀-èdè Lithuania.

Arábìnrin Dalia ti lé ní ọmọ ọgbọ̀n [30] ọdún. Látìgbà tí wọ́n ti bí i ló ti ní àrùn rọpárọsẹ̀. Àrùn yìí kì í jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ̀ já gaara. Torí náà, àwọn tí wọ́n jẹ́ ìbátan rẹ̀ nìkan ni ọ̀rọ̀ rẹ̀ máa ń yé. Galina ni màmá Dalia. Màmá rẹ̀ sì máa ń tọ́jú rẹ̀ dáadáa torí pé wọ́n jọ ń gbé ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìsàn yìí ti kó ìdààmú bá a tó sì máa ń mú kó ṣàníyàn, síbẹ̀ kò sọ ìrètí nù. Kí ló fà á tí kò fi sọ ìrètí nù?

Màmá rẹ̀ ṣàlàyé pé: “Ní ọdún 1999, Apolonija, ọmọ àbúrò màmá mi, wá kí wa. A kíyè sí i pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó mọ Bíbélì dáadáa, Dalia sì bẹ̀rẹ̀ sí í bi í ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè. Láìpẹ́ láìjìnnà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ Dalia lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo máa ń wà níbi ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan kí n lè máa ṣàlàyé ohun tí Dalia ń sọ fún un. Àmọ́, mo ṣàkíyèsí pé òótọ́ ni Dalia ń jàǹfààní nínú gbogbo nǹkan tó ń kọ́. Kò sì pẹ́ tí èmi náà fi ní kí wọ́n máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Bí Dalia ṣe ń lóye ẹ̀kọ́ Bíbélì, ìbéèrè kan wà tó túbọ̀ ń jẹ ẹ́ lọ́kàn. Lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ó sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ nípa bíbéèrè lọ́wọ́ Apolonija pé: “Báwo ni ẹni tó rọ lápá rọ lẹ́sẹ̀ bíi tèmi yìí á ṣe lè wàásù?” (Mát. 28:19, 20) Apolonija fi Dalia lọ́kàn balẹ̀, ó sì sọ fún un pé: “Má bẹ̀rù. Jèhófà máa ràn ẹ́ lọ́wọ́.” Jèhófà sì ràn án lọ́wọ́ ní tòótọ́.

Báwo wá ni Dalia ṣe ń wàásù? Ó máa ń wàásù ní onírúurú ọ̀nà. Àwọn arábìnrin máa ń bá a kọ lẹ́tà tó dá lórí Bíbélì. Bí wọ́n ṣe ń ṣe é ni pé Dalia á kọ́kọ́ sọ ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀ fún wọn. Lẹ́yìn náà, wọ́n á kọ ohun tó sọ sínú lẹ́tà. Dalia tún máa ń lo fóònù alágbèéká rẹ̀ láti fi kọ ọ̀rọ̀ ránṣẹ́ sí àwọn èèyàn. Bí ojú ọjọ́ bá sì dára, àwọn ará nínú ìjọ máa ń wá mú un jáde kó lè bá àwọn tó wà ní ibi ìgbafẹ́ tó wà ládùúgbò wọn tàbí àwọn tó bá ń kọjá lọ ní òpópónà sọ̀rọ̀.

Dalia àti màmá rẹ̀ ń tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí. Àwọn méjèèjì ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, wọ́n sì ṣèrìbọmi ní oṣù November ọdún 2004. Ní oṣù September ọdún 2008, wọ́n dá àwùjọ kan tó ń sọ èdè Polish sílẹ̀ ní ìlú Vilnius. Níwọ̀n bí àwùjọ náà ti nílò àwọn akéde púpọ̀ sí i, Dalia àti màmá rẹ̀ dara pọ̀ mọ́ wọn. Dalia sọ pé: “Ọkàn mi kì í balẹ̀ láwọn oṣù míì tí mi ò bá tíì lọ sóde ẹ̀rí. Àmọ́, lẹ́yìn tí mo bá ti gbàdúrà sí Jèhófà nípa rẹ̀, kò ní pẹ́ tí ẹnì kan á fi sọ pé òun máa wá mú mi ká lè jọ lọ sóde ẹ̀rí.” Báwo ni ipò tí arábìnrin wa ọ̀wọ́n yìí wà ṣe rí lára rẹ̀? Dalia sọ pé: “Àìsàn tó ń ṣe mí rọ mí ní apá àti ẹsẹ̀ àmọ́ kò ra mí níyè. Inú mi dùn pé ó ṣeé ṣe fún mi láti máa sọ fún àwọn mìíràn nípa Jèhófà!”