Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ṣé òótọ́ ni pé àwọn èèyàn máa ń fun fèrè níbi ìsìnkú nígbà ayé Jésù?

Ó wà nínú Bíbélì pé àwọn èèyàn fun fèrè nígbà ayẹyẹ. (1 Àwọn Ọba 1:40; Aísáyà 5:12; 30:29) Ó tún wà níbẹ̀ pé wọ́n fun ún níbi ìsìnkú kan. Fèrè nìkan sì ni ohun èlò orin tí ibẹ̀ mẹ́nu kàn pé wọ́n lò níbi ìsìnkú yẹn. Ìwé Ìhìn Rere Mátíù sọ pé ọ̀kan lára olùṣàkóso àwọn Júù sọ pé kí Jésù wá bá òun mú ọmọbìnrin òun tó ń kú lọ lára dá. Àmọ́ nígbà tí Jésù dé ilé olùṣàkóso náà, ó “tajú kán rí àwọn afunfèrè àti ogunlọ́gọ̀ nínú ìdàrúdàpọ̀ aláriwo,” torí pé ọmọdébìnrin náà ti kú.—Mátíù 9:18, 23.

Ǹjẹ́ ohun tí Mátíù sọ yìí bá àṣà ayé ìgbà yẹn mu? Ọ̀gbẹ́ni William Barclay tó jẹ́ atúmọ̀ Bíbélì sọ pé: “Níbi tó pọ̀ jù láyé àtijọ́, yálà nílẹ̀ Róòmù, Gíríìsì, Fòníṣíà, Ásíríà tàbí Palẹ́sìnì, ó ti di àṣà wọn láti máa fi fèrè kọrin arò nígbà tí ọ̀fọ̀ bá ṣẹ̀ tàbí nígbà ìbànújẹ́.” Ìwé Támọ́dì sọ pé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, bó ti wù kí Júù kan ya akúṣẹ̀ẹ́ tó, tí aya rẹ̀ bá kú, yóò háyà afunfèrè méjì àti obìnrin kan tó máa kọrin arò lórí aya rẹ̀ tó kú. Òpìtàn kan tó ń jẹ́ Flavius Josephus, tó gbé láyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, sọ pé, nígbà tí ìròyìn dé Jerúsálẹ́mù lọ́dún 67 Sànmánì Kristẹni, pé àwọn ará Róòmù ti ṣẹ́gun ìlú Jotapata ní Gálílì, àti pé wọ́n pa àwọn èèyàn ibẹ̀ ní ìpakúpa, ṣe ni “ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ háyà àwọn afunfèrè kí wọ́n máa fun fèrè bí wọ́n ṣe ń kọrin arò.”

Kí ni ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ọ̀daràn tí wọ́n kàn mọ́gi lẹ́gbẹ̀ẹ́ Jésù?

Bíbélì pe àwọn ọ̀daràn náà ní “àwọn ọlọ́ṣà.” (Mátíù 27:38; Máàkù 15:27) Àwọn ìwé atúmọ̀ ọ̀rọ̀ Bíbélì kan sọ pé Ìwé Mímọ́ máa ń lo ọ̀rọ̀ tó yàtọ̀ síra láti fi ṣe ìyàtọ̀ láàárín ọ̀daràn kan àti òmíràn. Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà kleptes túmọ̀ sí olè tó ń yọ́ kẹ́lẹ́ jí nǹkan. Irú ẹni tí Júdásì Ísíkáríótù jẹ́ nìyẹn, torí ó máa ń dọ́gbọ́n jí owó nínú àpótí owó àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù. (Jòhánù 12:6) Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà lestes, sábà máa ń tọ́ka sí ẹnì kan tó ń fipá jani lólè, ó sì tún lè tọ́ka sí ajàjàgbara, ẹni tó fẹ́ gbàjọba tàbí agbábẹ́lẹ̀jagun. Irú èyí tá a sọ gbẹ̀yìn yìí ni ẹ̀ṣẹ̀ àwọn tí wọ́n kàn mọ́gi pẹ̀lú Jésù. Kódà Bíbélì ní ọ̀kan lára wọn sọ pé: “Ohun tí ó tọ́ sí wa ni àwa ń gbà ní kíkún nítorí àwọn ohun tí a ṣe.” (Lúùkù 23:41) Èyí fi hàn pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ wọn ju olè jíjà lọ.

Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà lestes, tí wọ́n lò fún àwọn olè méjèèjì yẹn náà ni wọ́n lò fún Bárábà. (Jòhánù 18:40) Ó hàn kedere látinú ọ̀rọ̀ inú Lúùkù 23:19 pé ẹ̀ṣẹ̀ Bárábà ju olè jíjà lásán lọ. Ẹsẹ Bíbélì náà sọ pé “a sọ [ọ́] sínú ẹ̀wọ̀n nítorí ìdìtẹ̀ kan sí ìjọba tí ń ṣẹlẹ̀ nínú ìlú ńlá náà àti nítorí ìṣìkàpànìyàn.”

Nítorí náà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọ̀daràn tí wọ́n kàn mọ́gi pẹ̀lú Jésù jalè, ó ṣeé ṣe kí wọ́n kópa nínú ìdìtẹ̀ sí ìjọba tàbí kí wọ́n tiẹ̀ jẹ́ apànìyàn. Èyí ó wù kí wọ́n jẹ́, ará ilẹ̀ Róòmù náà Pọ́ńtíù Pílátù tó jẹ́ gómìnà gbà pé wọ́n jẹ̀bí ẹ̀ṣẹ̀ tó fi yẹ kí wọ́n kàn wọ́n mọ́gi.