Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Tó Wà Nínú Ìdílé Tí Wọ́n Ti Ń Ṣe Ẹ̀sìn Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Lè Láyọ̀

Àwọn Tó Wà Nínú Ìdílé Tí Wọ́n Ti Ń Ṣe Ẹ̀sìn Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Lè Láyọ̀

Àwọn Tó Wà Nínú Ìdílé Tí Wọ́n Ti Ń Ṣe Ẹ̀sìn Ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ Lè Láyọ̀

“Báwo ni o ṣe mọ̀ bóyá ìwọ yóò gba [ọkọ tàbí aya] rẹ là?”—1 KỌ́R. 7:16.

ǸJẸ́ O LÈ WÁ ÌDÁHÙN SÍ ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ?

․․․․․

Kí ni àwọn Kristẹni tó wà nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lè ṣe kí àlàáfíà lè máa wà nínú ìdílé wọn?

․․․․․

Báwo ni Kristẹni kan ṣe lè ran àwọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìdílé rẹ̀ lọ́wọ́ láti wá sínú ìjọsìn tòótọ́?

․․․․․

Kí la lè ṣe láti ran àwọn tá a jọ jẹ́ Kristẹni àmọ́ tí wọ́n wà nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́wọ́?

1. Bí ẹnì kan bá gba ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, ipa wo ló lè ní lórí àwọn tó kù nínú ìdílé?

 NÍ ÌGBÀ kan tí Jésù rán àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ jáde, ó sọ fún wọn pé: “Bí ẹ ti ń lọ, ẹ máa wàásù, pé, ‘Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.’” (Mát. 10:1, 7) Ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run yìí máa mú àlàáfíà àti ayọ̀ wá fún gbogbo àwọn tó bá fi ìmọrírì gbà á. Àmọ́, Jésù kìlọ̀ fún àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ pé ọ̀pọ̀ èèyàn máa ṣe àtakò sí wọn torí iṣẹ́ ìwàásù wọn. (Mát. 10:16-23) Àtakò tó sábà máa ń nira jù lọ ni èyí tó bá wá látọ̀dọ̀ ẹni tó jẹ́ ara ìdílé ẹni àmọ́ tí kò fara mọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.—Ka Mátíù 10:34-36.

2. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni fi lè láyọ̀ bí wọ́n bá tiẹ̀ ń gbé nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀?

2 Ṣé ohun tí èyí túmọ̀ sí ni pé àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tí wọ́n wà nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ kò lè láyọ̀? Rárá o! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé nígbà míì àtakò tí àwọn tó wà nínú ìdílé ń ṣe síni lè nira gan-an, gbogbo ìgbà kọ́ ló máa ń rí bẹ́ẹ̀, ó sì tún ṣeé ṣe kó má máa bá a lọ títí. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó sinmi lórí ọwọ́ tí àwọn Kristẹni bá fi mú àtakò náà tàbí ojú tí wọ́n fi wo àwọn tí kò nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ nínú ìdílé wọn. Bákan náà, Jèhófà máa ń bù kún àwọn tó bá jẹ́ adúróṣinṣin, ó máa ń mú kí wọ́n láyọ̀ bí wọ́n bá tiẹ̀ bára wọn nínú ipò tó le koko. Àwọn Kristẹni lè mú kí ayọ̀ wọn pọ̀ sí i (1) bí wọ́n bá ń sapá láti mú kí àlàáfíà wà nínú ìdílé àti (2) bí wọ́n bá ń fi tọkàntọkàn ran àwọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìdílé wọn lọ́wọ́ láti wá sínú ìjọsìn tòótọ́.

MÚ KÍ ÀLÀÁFÍÀ WÀ NÍNÚ ÌDÍLÉ

3. Kí nìdí tó fi yẹ kí Kristẹni mú kí àlàáfíà wà nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀?

3 Kí irúgbìn òdodo tó lè sèso nínú ìdílé, ìyẹn ni pé kí àwọn tó wà nínú ìdílé tó lè gba òtítọ́, ó ṣe pàtàkì pé kí àlàáfíà kọ́kọ́ jọba nínú ìdílé. (Ka Jákọ́bù 3:18.) Bí àwọn tó wà nínú ìdílé Kristẹni kan ò bá tiẹ̀ tíì dara pọ̀ mọ́ ọn nínú ìjọsìn mímọ́, ó gbọ́dọ̀ sapá gidigidi láti mú kí àlàáfíà wà nínú ìdílé. Báwo ló ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀?

4. Báwo ni àwọn Kristẹni ṣe lè máa ṣe ohun tá á mú kí wọ́n ní àlàáfíà ọkàn?

4 Kristẹni kọ̀ọ̀kan gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tá á mú kó ní àlàáfíà ọkàn. Èyí gba pé kéèyàn máa gbàdúrà látọkàn wá, ìyẹn ló sì máa ń fúnni ní “àlàáfíà Ọlọ́run” tí kò láfiwé. (Fílí. 4:6, 7) A máa ní ayọ̀ àti àlàáfíà tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà tá a sì ń fi àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́ sílò nínú ìgbésí ayé wa. (Aísá. 54:13) Ó tún ṣe pàtàkì pé ká máa lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ ká sì tún máa fìtara kópa nínú ìgbòkègbodò iṣẹ́ ìwàásù ká lè máa wà ní àlàáfíà ká sì máa láyọ̀. Ó máa ń ṣeé ṣe fún àwọn tó bá wà nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láti wá bí wọ́n ṣe máa lọ́wọ́ nínú àwọn ìgbòkègbodò yìí. Bí àpẹẹrẹ, ronú nípa ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Enza, * ẹni tí ọkọ rẹ̀ ṣe àtakò líle koko sí. Tó bá parí iṣẹ́ ilé tán ló máa ń lọ sóde ẹ̀rí. Ó sọ pé, “Ní gbogbo ìgbà tí mo bá sapá láti wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn, Jèhófà máa ń bù kún mi gan-an, mo sì máa ń rí àbájáde rere.” Ó dájú pé irú ìbùkún bẹ́ẹ̀ máa ń mú àlàáfíà, ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ wá.

5 Ìṣòro wo làwọn Kristẹni tó wà nínú àwọn ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sábà máa ń dojú kọ, kí ló sì lè ràn wọ́n lọ́wọ́?

5 A gbọ́dọ̀ sapá gan-an láti máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìdílé wa. Èyí lè nira torí pé ohun tí wọ́n á fẹ́ ká ṣe nígbà míì lè ta ko àwọn ìlànà Bíbélì. Tá a bá tẹpẹlẹ mọ́ ṣíṣe ohun tó bá ìlànà tòótọ́ mu, àwọn kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìdílé wa lè bínú, àmọ́ ńṣe ni ìyẹn máa mú kí àlàáfíà jọba lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn. Ṣùgbọ́n tá a bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú ìdílé wa nígbà tí ohun kan kò bá ta ko àwọn ìlànà Ìwé Mímọ́, a kò ní máa dá èdèkòyédè sílẹ̀ láìnídìí. (Ka Òwe 16:7.) Tá a bá dojú kọ ìṣòro, ó ṣe pàtàkì pé ká wá ìmọ̀ràn inú Ìwé Mímọ́ látinú àwọn ìtẹ̀jáde ẹgbẹ́ ẹrú olóòótọ́ àti olóye àti látọ̀dọ̀ àwọn alàgbà.—Òwe 11:14.

6, 7. (a) Kí nìdí tí àwọn kan fi máa ń ṣe àtakò sí ẹni tó jẹ́ ara ìdílé wọn tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà? (b) Kí ló yẹ kí ẹnì kan tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí Kristẹni kan ṣe bí wọ́n bá ń ṣe àtakò sí i nínú ìdílé?

6 Ká tó lè mú kí àlàáfíà máa wà nínú ìdílé, a gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ká sì ní òye nípa bí ọ̀ràn ṣe rí lára àwọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìdílé wa. (Òwe 16:20) Kódà, ó yẹ kí àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà lo ìfòyemọ̀. Àwọn ọkọ tàbí aya kan tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ lè ṣàì dí ẹnì kejì wọn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n tiẹ̀ lè gbà pé irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ lè ṣe ìdílé àwọn láǹfààní. Àmọ́, àwọn míì lè máa ṣe ẹ̀tanú sí ọkọ tàbí aya wọn. Obìnrin kan tó ń jẹ́ Esther, tó ti wá di Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí sọ pé òun “fa ìbínú yọ” nígbà tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọkọ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ pé: “Mo lè kó ìwé tó fi ń kẹ́kọ̀ọ́ dà nù tàbí kí n dáná sun ún.” Ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Howard, tí òun náà ta ko ìyàwó rẹ̀ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ pé: “Ẹ̀rù máa ń ba ọ̀pọ̀ ọkọ pé ńṣe ni wọ́n ń tan àwọn aya wọn láti dara pọ̀ mọ́ ẹ̀ya ìsìn. Ọkọ kan lè má mọ ohun tó máa ṣe nípa ohun tó sọ pé ó ń ba òun lẹ́rù yìí, ó sì lè tipa bẹ́ẹ̀ di alátakò.”

7 Bí ẹnì kan bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ sì ń ta kò ó, ó yẹ ká ràn án lọ́wọ́ kó lè mọ̀ pé kò yẹ kó torí ìyẹn dẹ́kun láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lọ́pọ̀ ìgbà, ó máa lè yanjú àwọn ìṣòro tó jẹ yọ tó bá jẹ́ onínú tútù, tó sì bọ̀wọ̀ fún ọkọ tàbí aya rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́. (1 Pét. 3:15) Howard sọ pé, “Mo dúpẹ́ pé ìyàwó mi fara balẹ̀ kò sì fara ya!” Ìyàwó rẹ̀ ṣàlàyé pé: “Ọkọ mi sọ pé kí n máà kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ́. Ó sọ pé ńṣe ni wọ́n ń tàn mí. Dípò tí màá fi máa bá a jiyàn, mo sọ pé ó lè jẹ́ bọ́rọ̀ ṣe rí nìyẹn lóòótọ́, àmọ́ mo jẹ́ kó yé e pé kò rí bẹ́ẹ̀ lójú tèmi. Torí náà, mo ní kó ka ìwé tí wọ́n fi ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́. Ó ka ìwé náà, ó sì gbà pé òótọ́ ni ohun tó wà nínú rẹ̀. Ohun tó kà yìí nípa lórí rẹ̀ gan-an.” Ó ṣe pàtàkì ká máa rántí pé bí ọkọ tàbí aya tó jẹ́ Kristẹni bá lọ kópa nínú àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni, ẹnì kejì rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ lè máa ronú pé ó pa òun tì tàbí pé ìgbéyàwó àwọn wà nínú ewu. Àmọ́ bí èyí tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tàbí tó ti di Ẹlẹ́rìí nínú àwọn méjèèjì bá ń fi ìfẹ́ sọ ọ̀rọ̀ tó fi ẹnì kejì rẹ̀ lọ́kàn balẹ̀, èyí lè mú irú ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ kúrò.

RÀN WỌ́N LỌ́WỌ́ KÍ WỌ́N LÈ WÁ SÍNÚ ÌJỌSÌN TÒÓTỌ́

8. Ìmọ̀ràn wo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fún àwọn Kristẹni tí wọ́n ní ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́?

8 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn Kristẹni nímọ̀ràn pé kí wọ́n má ṣe fi ọkọ tàbí aya wọn sílẹ̀ torí pé ó jẹ́ aláìgbàgbọ́. * (Ka 1 Kọ́ríńtì 7:12-16.) Bí ọkọ tàbí aya tó jẹ́ Kristẹni bá ń fi sọ́kàn pé ó ṣeé ṣe kí ẹnì kejì òun di Kristẹni, èyí lè jẹ́ kó máa láyọ̀ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ń gbé nínú ilé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àmọ́, àwọn ìrírí tá a fẹ́ sọ yìí fi hàn pé bí Kristẹni kan bá ń gbìyànjú láti wàásù fún ọkọ tàbí aya rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́, ó gbọ́dọ̀ ṣọ́ra.

9. Tá a bá ń ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Bíbélì fún àwọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìdílé wa, kí ló yẹ ká ṣọ́ra fún?

9 Nígbà tí ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Jason ń sọ bó ṣe rí lára rẹ̀ nígbà tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ní: “Ńṣe ló ń wù mí kí n máa sọ fún gbogbo èèyàn!” Bí akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan bá ti rí i dájú pé òtítọ́ ni ohun tí wọn fi ń kọ́ òun látinú Ìwé Mímọ́, inú rẹ̀ lè dùn débi pé ńṣe ni yóò máa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ṣáá. Ó lè máa retí pé kí àwọn tó wà nínú ìdílé òun tètè gbọ́rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, àmọ́ wọ́n lè má ṣe bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Jason bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, ipa wo ni ìtara rẹ̀ ní lórí ìyàwó rẹ̀? Ìyàwó rẹ̀ sọ pé: “Ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún mi ti pọ̀ jù.” Obìnrin kan tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ ní ọdún méjìdínlógún [18] lẹ́yìn tí ọkọ rẹ̀ ti kẹ́kọ̀ọ́ sọ pé: “Ní tèmi, ó gba pé kí n máa kọ́ ẹ̀kọ́ náà díẹ̀díẹ̀.” Tó o bá ń kọ́ ẹnì kan lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ tí ọkọ tàbí aya rẹ̀ kò fẹ́ dara pọ̀ mọ́ ìjọsìn tòótọ́, o lè máa ṣe ìfidánrawò látìgbàdégbà pẹ̀lú ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ kó lè mọ bó ṣe máa fi ọgbọ́n bójú tó ọ̀rọ̀ náà. Mósè sọ pé: “Ìtọ́ni mi yóò máa wẹ bí òjò, àsọjáde mi yóò máa sẹ̀ jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ bí ìrì, bí òjò winniwinni sára koríko.” (Diu. 32:2) Tá a bá rọra ń sọ ọ̀rọ̀ òtítọ́ fún àwọn mọ̀lẹ́bí wa tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́ bí ìgbà tí òjò ń fọ́n winniwinni, ó máa ṣàǹfààní gan-an ju rírọ́ òtítọ́ sí wọn lórí bí ọ̀wààrà òjò.

10-12. (a) Ìmọ̀ràn wo ni àpọ́sítélì Pétérù fún àwọn Kristẹni tí wọ́n ní ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́? (b) Báwo ni akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan ṣe kọ́ láti fi ìmọ̀ràn inú 1 Pétérù 3:1, 2 sílò?

10 Àpọ́sítélì Pétérù fún àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ aya nínú ilé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ní ìmọ̀ràn tí Ọlọ́run mí sí. Ó sọ pé: “Ẹ wà ní ìtẹríba fún àwọn ọkọ tiyín, kí ó lè jẹ́ pé, bí ẹnikẹ́ni kò bá ṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ náà, kí a lè jèrè wọn láìsọ ọ̀rọ̀ kan nípasẹ̀ ìwà àwọn aya wọn, nítorí fífi tí wọ́n fi ojú rí ìwà mímọ́ yín pa pọ̀ pẹ̀lú ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀.” (1 Pét. 3:1, 2) Aya kan lè jèrè ọkọ rẹ̀ wá sínú ìsìn tòótọ́ tó bá ń tẹrí ba fún un tó sì ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀, kódà bí ọkọ rẹ̀ bá tiẹ̀ ń fi ọwọ́ líle koko mú un. Bákan náà, ó yẹ kí ọkọ tó jẹ́ onígbàgbọ́ máa hùwà ọmọlúwàbí, kó sì jẹ́ ọkọ tó ń fi ìfẹ́ lo ipò orí rẹ̀ nínú ìdílé, láìka àtakò tí aya rẹ̀ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ lè máa ṣe sí.—1 Pét. 3:7-9.

11 Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ ló wà lóde òní tó jẹ́ ká rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká fi ìmọ̀ràn Pétérù yìí sílò. Jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa obìnrin kan tó ń jẹ́ Selma. Nígbà tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, inú ọkọ rẹ̀ tó ń jẹ́ Steve kò dùn sí i. Ó sọ pé: “Inú bí mi, mo bẹ̀rẹ̀ sí í jowú, mi ò kì í fẹ́ rí ẹlòmíì pẹ̀lú rẹ̀, ọkàn mi kì í sì í balẹ̀.” Selma sọ pé: “Kí n tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pàápàá, àjọgbé èmi àti ọkọ mi gbẹgẹ́. Onínú fùfù èèyàn ni. Ìwà yìí tún wá burú sí i nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Báwo ni wọ́n ṣe borí ìṣòro yìí?

12 Selma rántí ohun kan tó rí kọ́ lọ́dọ̀ Ẹlẹ́rìí tó kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó sọ pé: “Lọ́jọ́ kan báyìí, mi ò fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ yẹn, ọkọ mi fi ìbínú gbá mi nígbà tí mò ń gbìyànjú láti ṣàlàyé ọ̀rọ̀ kan fún un, inú mi ò dùn, àánú ara mi sì ṣe mí. Lẹ́yìn tí mo sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ fún arábìnrin tó ń kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ àti bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí lára mi, ó sọ fún mi pé kí n ka 1 Kọ́ríńtì 13:4-7. Bí mo ṣe ń kà á, mo bẹ̀rẹ̀ sí í ronú pé ‘Ọkọ mi kì í ṣe àwọn ohun tó fìfẹ́ hàn tí Bíbélì sọ yìí.’ Àmọ́, arábìnrin náà ràn mí lọ́wọ́ láti tún inú rò, ó béèrè lọ́wọ́ mi pé, ‘Mélòó nínú àwọn nǹkan tó fi ìfẹ́ hàn yìí lò ń ṣe fún ọkọ rẹ?’ Mo dá a lóhùn pé, ‘Kò sí èyí tí mò ń ṣe nínú rẹ̀, torí pé ọkọ mi ò rọrùn láti bá gbé.’ Arábìnrin náà wá rọra sọ fún mi pé, ‘Selma, ta ló ń gbìyànjú láti di Kristẹni nínú ẹ̀yin méjèèjì? Ṣé ìwọ ni àbí ọkọ rẹ?’ Mo wá rí i pé ó yẹ kí n yí èrò mi pa dà, mo gbàdúrà pé kí Jèhófà ràn mí lọ́wọ́ kí n lè túbọ̀ máa fi ìfẹ́ hàn sí ọkọ mi. Nǹkan sì bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà díẹ̀díẹ̀.” Lẹ́yìn ọdún mẹ́tàdínlógún [17], ọkọ rẹ̀ wá sínú òtítọ́.

BÍ ÀWỌN MÍÌ ṢE LÈ ṢÈRÀNWỌ́

13, 14. Báwo ni àwọn ará nínú ìjọ ṣe lè ran àwọn tó ń gbé nínú ilé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́wọ́?

13 Bí òjò tó ń fọ́n winniwinni ṣe máa ń fomi rin ilẹ̀ táá sì mú kí irúgbìn dàgbà, bẹ́ẹ̀ ni ọ̀pọ̀ àwọn ará nínú ìjọ ṣe máa ń pa kún ayọ̀ àwọn Kristẹni tó ń gbé nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Elvina láti orílẹ̀-èdè Brazil sọ pé: “Ìfẹ́ tí àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin fi hàn sí mi ló jẹ́ kí n dúró gbọn-in nínú òtítọ́.”

14 Bí àwọn míì nínú ìjọ bá fi inú rere hàn sí ẹni tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìdílé Kristẹni kan, tí wọ́n sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ àwọn lógún, ó lè yí irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́kàn pa dà. Ọkọ kan lórílẹ̀-èdè Nàìjíríà tó wá sínú òtítọ́ lẹ́yìn ọdún mẹ́tàlá [13] tí ìyàwó rẹ̀ ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, sọ pé: “Nígbà tí èmi àti Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan jọ ń rìnrìn àjò, mọ́tò rẹ̀ bà jẹ́ sọ́nà. Ó wá àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní abúlé tó wà ní ìtòsí kàn, wọ́n sì fún wa ní ilé tá a sùn mọ́jú. Wọ́n gbà wá lálejò bíi pé a ti mọra láti ìgbà ọmọdé. Lójú ẹsẹ̀, mo rí ìfẹ́ Kristẹni tí ìyàwó mi ti máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.” Nílẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ìyàwó kan tó wá sínú òtítọ́ lẹ́yìn ọdún méjìdínlógún [18] tí ọkọ rẹ̀ ti wà nínú òtítọ́ sọ pé: “Àwọn Ẹlẹ́rìí pe èmi àti ọkọ mi pé ká wá bá àwọn jẹun. Gbogbo ìgbà ni wọ́n máa ń gbà mí tọwọ́ tẹsẹ̀.” * Ọkọ kan láti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì tí òun náà pàpà di Ẹlẹ́rìí sọ pé: “Àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin máa ń wá kí wa nílé tàbí kí wọ́n pè wá lọ sílé wọn, mo sì rí i pé wọ́n mọ bá a ṣe ń ṣaájò èèyàn. Èyí sì túbọ̀ wá hàn gbangba nígbà tí mo wà nílé ìwòsàn tí ọ̀pọ̀ sì wá wò mí níbẹ̀.” Ǹjẹ́ o lè wá ọ̀nà láti túbọ̀ fi hàn pé ọ̀rọ̀ àwọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìdílé àwọn Kristẹni jẹ ìwọ náà lógún?

15, 16. Kí ló lè ran Kristẹni kan lọ́wọ́ láti máa láyọ̀ bí àwọn tó kù nínú ìdílé bá ṣì jẹ́ aláìgbàgbọ́?

15 Òótọ́ ni pé kì í ṣe gbogbo ọkọ, aya, àwọn ọmọ, àwọn òbí tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ ló máa ń wá sínú ìjọsìn tòótọ́, kódà lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí ẹni tó jẹ́ Ẹlẹ́rìí ti ń hùwà tó dáa, tó sì ti ń fi ọgbọ́n wàásù fún wọn. Àwọn kan kì í nífẹ̀ẹ́ sí òtítọ́ tàbí kí wọ́n tiẹ̀ máa ṣe àtakò nìṣó. (Mát. 10:35-37) Àmọ́, bí àwọn Kristẹni bá ń hùwà ọmọlúwàbí, ó lè ní ipa tó dáa lórí àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìgbàgbọ́. Ọkọ kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ nígbà kan rí sọ pé: “Bí ọkọ tàbí aya tó jẹ́ Kristẹni bá bẹ̀rẹ̀ sí í fi àwọn ànímọ́ àtàtà hàn, o kò lè mọ ohun tí ẹni tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ ń rò tàbí ohun tó wà lọ́kàn rẹ̀. Torí náà, má ṣe ronú pé ọkọ tàbí aya rẹ tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ kò lè yí pa dà láé.”

16 Kódà, bí ọkọ tàbí aya kan tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ kò bá wá sínú ìjọsìn tòótọ́, ẹni tó jẹ́ Kristẹni ṣì lè máa láyọ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lẹ́yìn tí arábìnrin kan ti sapá fún ọdún mọ́kànlélógún [21] kí ọkọ rẹ̀ lè gbọ́ ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run, kò tíì wá sínú òtítọ́, ó sọ pé: “Mo ṣì ń láyọ̀ torí pé mò ń ṣe ohun tí inú Jèhófà dùn sí, mo jẹ́ adúróṣinṣin sí i mo sì ń sapá láti mú kí àjọṣe mi pẹ̀lú rẹ̀ dára sí i. Bí mo ṣe jẹ́ kí ọwọ́ mi dí fún ṣíṣe àwọn nǹkan tó jẹ mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run, bí ìdákẹ́kọ̀ọ́, lílọ sí ìpàdé, òde ẹ̀rí àti ríran àwọn ará nínú ìjọ lọ́wọ́, ti jẹ́ kí n túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ó sì ti jẹ́ kí n máa fi ìṣọ́ ṣọ́ ọkàn-àyà mi.”—Òwe 4:23.

MÁ ṢE JUWỌ́ SÍLẸ̀!

17, 18. Kí ni kò ní jẹ́ kí Kristẹni kan sọ̀rètí nù bó bá tiẹ̀ wà nínú ìdílé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀?

17 Bó o bá jẹ́ Kristẹni tòótọ́ tó ń gbé nínú ilé tí wọ́n ti ń ṣe ẹ̀sìn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, má ṣe juwọ́ sílẹ̀. Rántí pé “Jèhófà kì yóò kọ àwọn ènìyàn rẹ̀ tì, nítorí orúkọ ńlá rẹ̀.” (1 Sám. 12:22) Bí o kò bá fi Jèhófà sílẹ̀, òun náà kò ní fi ẹ́ sílẹ̀. (Ka 2 Kíróníkà 15:2.) Torí náà, “máa ní inú dídùn kíkọyọyọ nínú Jèhófà.” Bákan náà, “yí ọ̀nà rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, kí o sì gbójú lé e.” (Sm. 37:4, 5) “Máa ní ìforítì nínú àdúrà,” kó o sì ní ìgbàgbọ́ pé Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti fara da onírúurú ìnira.—Róòmù 12:12.

18 Bẹ Jèhófà pé kó fún ẹ ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ kó o lè máa mú kí àlàáfíà jọba nínú ìdílé rẹ. (Héb. 12:14) Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, àlàáfíà tó máa wà nínú ìdílé lè mú kí òtítọ́ wọ àwọn tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ nínú ìdílé lọ́kàn, bó bá yá. Wàá ní ayọ̀ àti ìbàlẹ̀ ọkàn bó o ṣe ń “ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.” (1 Kọ́r. 10:31) Bó o ṣe ń sa gbogbo ipá rẹ, wàá rí i pé ìṣírí ńlá gbáà ló jẹ́ pé àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin nínú ìjọ Kristẹni ń tì ẹ́ lẹ́yìn tìfẹ́tìfẹ́!

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ A ti yí àwọn orúkọ náà pa dà.

^ Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù kò fagi lé ìpínyà lọ́nà tí ó bófin mu lábẹ́ àwọn ipò kan tó le koko. Ìpinnu pàtàkì tó yẹ kéèyàn dá ṣe lèyí. Wo ìwé ‘Ẹ Dúró Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run,’ ojú ìwé 220 sí 221.

^ Ìwé Mímọ́ kò sọ pé ká má ṣe bá àwọn aláìgbàgbọ́ jẹun.—1 Kọ́r. 10:27.

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]

Wá àkókò tó wọ̀ láti ṣàlàyé ohun tó o gbà gbọ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

Ẹ fi hàn pé ọ̀rọ̀ ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́ jẹ yín lógún