Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí O Máa Gbára Lé Èrò Tó Bá Kọ́kọ́ Wá sí Ọ Lọ́kàn?

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí O Máa Gbára Lé Èrò Tó Bá Kọ́kọ́ Wá sí Ọ Lọ́kàn?

Ǹjẹ́ Ó Yẹ Kí O Máa Gbára Lé Èrò Tó Bá Kọ́kọ́ Wá sí Ọ Lọ́kàn?

DÓKÍTÀ kan jókòó sí pálọ̀ rẹ̀ ó ń wo tẹlifíṣọ̀n, ó sì ń gbọ́ bí wọ́n ṣe ń fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu ẹnì kan tó jẹ́ mínísítà ìjọba orílẹ̀-èdè Ireland. Bí dókítà yìí ṣe kíyè sí ojú mínísítà náà dáadáa, orí ibi tó dà bíi pé ó wú bíi ti ẹni tó ní àrùn jẹjẹrẹ. Ó wá gba mínísítà náà nímọ̀ràn pé kó tètè lọ ṣàyẹ̀wò rẹ̀ lọ́dọ̀ dókítà.

Àbájáde àyẹ̀wò náà sì fi hàn pé òótọ́ ni ohun tí dókítà yẹn rí. Dókítà náà jẹ́ irú ẹni tí àwọn èèyàn sábà máa ń sọ pé tó bá rí aláìsàn sójú lásán, ó lè sọ irú àìsàn tó ń ṣe é. Àmọ́, àwọn èèyàn míì náà máa ń sọ pé tí àwọn bá rí èèyàn sójú lásán àwọn lè sọ irú ẹni tó jẹ́, títí kan ìwà rẹ̀, àti bóyá ó tiẹ̀ jẹ́ ẹni tó ṣeé fọkàn tán.

Láti ọdúnmọ́dún làwọn olùṣèwádìí kan ti gbìyànjú láti fi ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣàlàyé bí èèyàn ṣe lè tipa ìrísí ẹnì kan mọ ìwà àti ìṣe rẹ̀. Ohun tí wọ́n pe ẹ̀kọ́ yìí ni, physiognomy, èyí tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, Encyclopædia Britannica, sọ pé “ó jẹ́ ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ arúmọjẹ tí wọ́n fi ń ṣe àlàyé pé ìrísí ojú tàbí ìrísí ẹnì kan látòkè délẹ̀ lè jẹ́ kéèyàn mọ ìwà àti ìṣe ẹni náà.” Ní nǹkan bí igba [200] ọdún sẹ́yìn, àwọn kan gbé àbá tiwọn kalẹ̀ lórí ọ̀rọ̀ fífi ìrísí èèyàn mọ ìwà rẹ̀. Lára wọn ni àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ẹ̀dá ènìyàn bí ọ̀gbẹ́ni Francis Galton tó jẹ́ ìbátan Charles Darwin, àti àwọn onímọ̀ nípa ìwà ọ̀daràn bí ọ̀gbẹ́ni Cesare Lombroso láti ilẹ̀ Ítálì. Àmọ́ gbogbo àbá wọn yẹn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dohun ìgbàgbé báyìí.

Síbẹ̀, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé èèyàn ṣì lè mọ irú ẹni tí ẹnì kan jẹ́ dáadáa téèyàn bá kàn wo ìrísí onítọ̀hún látòkè délẹ̀. Ṣé ó yẹ ká máa gbára lé èrò tó bá kọ́kọ́ wá sí wa lọ́kan nípa ẹni tá a kàn rí sójú lásán?

Fífi Ìrísí Ṣèpinnu Irú Ẹni Téèyàn Jẹ́

Nínú Bíbélì, ìwé Sámúẹ́lì Kìíní jẹ́ ká rí àpẹẹrẹ bí àwọn kan ṣe fi ìrísí lásán pinnu irú èèyàn tí ẹnì kan jẹ́ tàbí èyí tí kò jẹ́. Jèhófà Ọlọ́run sọ pé kí wòlíì Sámúẹ́lì lọ fi òróró yan ẹnì kan nínú ìdílé Jésè tí yóò di ọba Ísírẹ́lì lọ́jọ́ iwájú. Bíbélì sọ pé: “Ó sì ṣẹlẹ̀ pé, bí [àwọn ọmọ Jésè] ṣe wọlé, tí ó sì tajú kán rí Élíábù, ní kíá, ó sọ pé: ‘Dájúdájú, ẹni àmì òróró rẹ̀ wà níwájú Jèhófà.’ Ṣùgbọ́n Jèhófà sọ fún Sámúẹ́lì pé: ‘Má wo ìrísí rẹ̀ àti gíga rẹ̀ ní ìdúró, nítorí pé èmi ti kọ̀ ọ́. Nítorí kì í ṣe ọ̀nà tí ènìyàn gbà ń wo nǹkan ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan, nítorí pé ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.’” Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọ̀rọ̀ àwọn mẹ́fà míì lára àwọn ọmọ Jésè ṣe rí. Níkẹyìn, ohun tó yàtọ̀ pátápátá sí èrò wòlíì Sámúẹ́lì àti ti Jésè ló ṣẹlẹ̀. Ọmọ kẹjọ tí Jésè bí, ìyẹn Dáfídì, tó jẹ́ ọ̀dọ́mọdé tí ẹnikẹ́ni ò tiẹ̀ kà sí ẹni tó yẹ kó wá síbẹ̀ rárá, ni Ọlọ́run yàn pé ó máa jọba.—1 Sámúẹ́lì 16:6-12.

Irú nǹkan bẹ́ẹ̀ ṣì ń ṣẹlẹ̀ lóde òní. Lọ́dún mélòó kan sẹ́yìn, ní orílẹ̀-èdè Jámánì, ọ̀jọ̀gbọ́n kan tó jẹ́ onímọ̀ nípa ìwà ọ̀daràn ṣe àyẹ̀wò kan, tí ọgọ́rùn-ún márùn-ún [500] akẹ́kọ̀ọ́ tó fẹ́ di amòfin sì kópa níbẹ̀. Ó pe ọkùnrin méjìlá wá láìjẹ́ kí àwọ́n akẹ́kọ̀ọ́ náà mọ ẹni tí wọ́n jẹ́. Lára wọn ni ọ̀gá ọlọ́pàá àdúgbò yẹn, agbẹjọ́rò ìjọba ní àdúgbò yẹn, akápò yunifásítì ibẹ̀ àti alukoro wọn, àwọn amòfin kan àti àwọn òṣìṣẹ́ kan ní kóòtù, pẹ̀lú ọ̀daràn mẹ́ta tó ti ṣẹ̀wọ̀n rí. Ọ̀jọ̀gbọ́n yẹn wá sọ fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé kí wọ́n wo ìrísí àwọn ọkùnrin náà àti eré ìnàjú tí wọ́n bá sọ pé àwọn máa ń ṣe, kí wọ́n wá sọ èwo nínú wọn ló ti ṣẹ̀wọ̀n rí àti ẹ̀ṣẹ̀ tó ṣẹ̀, kí wọ́n sì sọ iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tí olúkúlùkù wọn ń ṣe.

Kí ni àbájáde àyẹ̀wò náà? Ìdá mẹ́ta nínú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà dá àwọn ọ̀daràn mẹ́ta tó wà níbẹ̀ mọ̀. Ṣùgbọ́n èyí tó lé ní ìdajì àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ló sọ pé àwọn mẹ́sàn-án yòókù jẹ́ ọ̀daràn, bẹ́ẹ̀ sì rèé àwọn yẹn kò ní ẹ̀sùn ìwà ọ̀daràn kankan. Ìdá kan nínú méje lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà sọ pé agbẹjọ́rò ìjọba tó wà níbẹ̀ ní láti jẹ́ ẹni tó ń ta oògùn olóró, ìdá kan nínú mẹ́ta wọn sì sọ pé ọ̀gá ọlọ́pàá àárín wọn jẹ́ olè! Ẹ ò rí i pé ìrísí èèyàn lè máà ní nǹkan kan ṣe rárá pẹ̀lú ìwà onítọ̀hún. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀?

Ìrísí Lè Tanni Jẹ

Ó ti mọ́ àwa èèyàn lára pé nígbà àkọ́kọ́ tí a bá pàdé ẹnì kan, a sábà máa ń fẹ́ fi ìrírí wa àtẹ̀yìnwá pinnu irú èèyàn tí a rò pé ó jẹ́. A sábà máa ń ka irú ẹni bẹ́ẹ̀ mọ́ àwùjọ àwọn èèyàn kan, a ó sì wá máa fi irú ojú tá a fi ń wo àwùjọ yẹn wo òun náà. Yàtọ̀ sí ìrísí ẹnì kan, àwọn èèyàn tún lè fi orílẹ̀-èdè tó ti wá, ẹ̀yà rẹ̀, ipò rẹ̀ láwùjọ tàbí ẹ̀sìn rẹ̀ pinnu irú ẹni tí wọ́n rò pé ó jẹ́.

Tí ohun tí a rò nípa ẹni yẹn bá rí bẹ́ẹ̀ lóòótọ́, inú wa máa ń dùn pé ọkàn wa kò tàn wá jẹ, ìyẹn á wá jẹ́ ká túbọ̀ gbà pé a lè gbára lé èrò wa nípa ẹni tí a kàn rí sójú lásán. Àmọ́ tí a bá wá rí i pé èrò wa nípa rẹ̀ tẹ́lẹ̀ kò tọ̀nà kí ló yẹ ká ṣe? Tá ò bá fẹ́ ṣe àbòsí, ṣe ló yẹ ká pa èrò wa tẹ́lẹ̀ tì, ká wá gbìyànjú láti mọ irú ẹni tó jẹ́ gan-an. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ńṣe la ó kàn máa ṣe àìdáa sí àwọn ẹni ẹlẹ́ni tàbí ká tiẹ̀ fi ẹ̀tọ́ wọn dù wọ́n, nítorí pé a ṣáà fẹ́ fi hàn pé ọkàn wa kì í tàn wá jẹ.

Tí a bá ń fi ìrísí lásán pinnu ohun tí ẹnì kan jẹ́, èyí lè ṣe àkóbá tó pọ̀ fún onítọ̀hún àti fún àwa alára. Bí àpẹẹrẹ, ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní, ọ̀pọ̀ àwọn Júù ni kò tiẹ̀ fẹ́ rò ó lẹ́ẹ̀mejì rárá pé Jésù tiẹ̀ lè jẹ́ Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí. Kí nìdí? Torí pé ohun tí wọ́n fojú rí lásán ni wọ́n gbé èrò wọn kà, wọn kò rí nǹkan míì nípa Jésù ju pé ọmọ káfíńtà lásánlàsàn ni. Lóòótọ́, ọ̀rọ̀ ọlọ́gbọ́n àti iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ń ṣe wú wọn lórí, síbẹ̀ wọ́n fàáké kọ́rí, wọn ò gbà pé Jésù ju bí wọ́n ṣe rò lọ, torí èrò tí wọ́n ti gbìn sọ́kàn látẹ̀yìn wá. Ìwà wọn mú kí Jésù pa wọ́n tì, ó sì wá àwọn míì lọ, ó wá sọ pé: “A kì í ṣàìbọlá fún wòlíì kan àyàfi ní ìpínlẹ̀ ìbí rẹ̀ àti ní ilé òun fúnra rẹ̀.”—Mátíù 13:54-58.

Àwọn Júù yẹn jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè tó ti ń retí Mèsáyà látọdúnmọ́dún. Àmọ́ torí pé wọ́n wonkoko mọ́ èrò òdì tí wọ́n kọ́kọ́ ní nípa Jésù, wọn kò mọ̀ pé òun ni Mèsáyà tí wọ́n ti ń retí, bí wọ́n ṣe pàdánù ojú rere Ọlọ́run pátápátá nìyẹn. (Mátíù 23:37-39) Irú ẹ̀mí ẹ̀tanú kan náà làwọn èèyàn ìgbà yẹn ní sí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù. Ọ̀pọ̀ nínú wọn kò gbà rárá pé àwọn tó jẹ́ apẹja lásánlàsàn, tí àwọn ọ̀mọ̀wé ayé ìgbà yẹn àti àwọn aṣáájú ẹ̀sìn ńláńlá ń bẹnu àtẹ́ lù, lè jẹ́ ẹni tó máa sọ̀rọ̀ tó lè ṣeni láǹfààní. Àwọn tó wonkoko mọ́ èrò tí wọ́n kọ́kọ́ ní pàdánù àǹfààní ńláǹlà tó ṣí sílẹ̀ fún wọn láti di ọmọlẹ́yìn Ọmọ Ọlọ́run.—Jòhánù 1:10-12.

Àwọn Kan Yí Èrò Ọkàn Wọn Pa Dà

Ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tí àwọn kan lára àwọn èèyàn ìgbà ayé Jésù ní mú kí wọ́n yí èrò ọkàn wọn pa dà nígbà tí wọ́n rí ẹ̀rí tó dájú. (Jòhánù 7:45-52) Ara irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ni àwọn kan lára àbúrò Jésù tí wọn kò kọ́kọ́ kọbi ara sí ọ̀rọ̀ pé ọ̀kan nínú mọ̀lẹ́bí àwọn lè jẹ́ Mèsáyà. (Jòhánù 7:5) Ó dùn mọ́ni pé, nígbà tó yá, wọ́n yí ọkàn pa dà, wọ́n sì gba Jésù gbọ́. (Ìṣe 1:14; 1 Kọ́ríńtì 9:5; Gálátíà 1:19) Bákan náà, ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, àwọn aṣojú àwọn Júù ní ìlú Róòmù fẹ́ láti gbọ́rọ̀ látẹnu àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù alára dípò tí wọ́n á fi gbára lé àwọn àhesọ ọ̀rọ̀ tí àwọn ọ̀tá ẹ̀sìn Kristẹni ń tàn kálẹ̀. Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ tán, àwọn kan lára wọn di onígbàgbọ́.—Ìṣe 28:22-24.

Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ní èrò òdì nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Lọ́pọ̀ ìgbà, kì í ṣe pé àwọn fúnra wọn tíì ṣèwádìí nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tàbí pé wọ́n ní ẹ̀rí tòótọ́ tó fi hàn pé ìgbàgbọ́ àti ìṣe àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Lójú tiwọn, kò kàn ṣeé gbà gbọ́ ni pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló jẹ́ ẹ̀sìn tòótọ́. Tó o bá sì rántí, wàá rí i pé irú ojú tí ọ̀pọ̀ èèyàn ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní fi ń wo àwọn tó kọ́kọ́ jẹ́ Kristẹni nìyẹn láyé ìgbà náà.

Kò yani lẹ́nu ṣá o, pé àwọn èèyàn ń ṣáátá tàbí wọ́n ń pẹ̀gàn àwọn tó bá ń rí i dájú pé àwọn tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù. Kí nìdí tí kò fi yani lẹ́nu? Ìdí ni pé Jésù ti kìlọ̀ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹ ó sì jẹ́ ẹni ìkórìíra lọ́dọ̀ gbogbo ènìyàn ní tìtorí orúkọ mi.” Ṣùgbọ́n ó gbà wọ́n níyànjú báyìí pé: “Ẹni tí ó bá fara dà á dé òpin ni ẹni tí a ó gbà là.”—Mátíù 10:22.

Àṣẹ tí Jésù pa ni àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé tí wọ́n fi ń ṣe iṣẹ́ ribiribi láti mú ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé ọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn kárí ayé. (Mátíù 28:19, 20) Àwọn tó bá fàáké kọ́rí pé àwọn kò gbọ́ ìwàásù yìí lè pàdánù àǹfààní tí wọ́n ì bá fi dẹni tó ń rìn lọ́nà tó lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. (Jòhánù 17:3) Ìwọ ńkọ́? Ṣé o máa gbára lé èrò tó o ti kọ́kọ́ ní àti ohun tó o ti gbìn sọ́kàn tẹ́lẹ̀ nípa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àbí wàá fara balẹ̀ ṣàyẹ̀wò ohun tó jóòótọ́ ọ̀rọ̀? Rántí o: Ìrísí a máa tanni jẹ, ohun téèyàn sì rò nípa nǹkan kan lè máà jóòótọ́. Ṣùgbọ́n téèyàn bá fẹ̀sọ̀ ṣèwádìí òótọ́ ọ̀rọ̀, ó lè yọrí sí ìdùnnú àti ayọ̀ fúnni.—Ìṣe 17:10-12.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 11]

Èrò tí ọ̀pọ̀ àwọn Júù ti kọ́kọ́ gbìn sọ́kàn kò jẹ́ kí wọ́n gbà pé Jésù ni Mèsáyà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Ǹjẹ́ ojú tó o fi ń wo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà dá lórí ohun tó o kàn rò nípa wọn àbí ó dá lórí ohun tó jóòótọ́?