Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Máa Fi Sọ́kàn Pé Iṣẹ́ Ìwàásù Jẹ́ Kánjúkánjú

Máa Fi Sọ́kàn Pé Iṣẹ́ Ìwàásù Jẹ́ Kánjúkánjú

Máa Fi Sọ́kàn Pé Iṣẹ́ Ìwàásù Jẹ́ Kánjúkánjú

“Wàásù ọ̀rọ̀ náà, wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú.”—2 TÍM. 4:2.

ǸJẸ́ O LÈ ṢÀLÀYÉ?

․․․․․

Kí ló mú kí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní wàásù lọ́nà tó fi hàn pé ó jẹ́ kánjúkánjú?

․․․․․

Báwo la ṣe lè máa fi sọ́kàn pé iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ kánjúkánjú?

․․․․․

Kí nìdí tí ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì lásìkò yìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ?

1, 2. Àwọn ìbéèrè wo la máa rí ìdáhùn sí bá a ti ń jíròrò àṣẹ náà pé ‘ká wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní kánjúkánjú’?

 ÀWỌN tí iṣẹ́ wọn gba pé kí wọ́n gba ẹ̀mí àwọn èèyàn là sábà máa ń ṣe iṣẹ́ náà ní kánjúkánjú. Bí àpẹẹrẹ, bí àwọn panápaná bá gba ìpè pàjáwìrì, wọ́n máa ń yára lọ jẹ́ ìpè náà, torí wọ́n mọ̀ pé ẹ̀mí àwọn èèyàn lè wà nínú ewu.

2 Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà náà ń fẹ́ ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè rí ìgbàlà. Torí náà, ọwọ́ pàtàkì la fi mú iṣẹ́ tí Ọlọ́run gbé lé wa lọ́wọ́ pé ká wàásù ìhìn rere Ìjọba rẹ̀. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe pé à ń sáré dìgbàdìgbà bíi tàwọn panápaná o. Kí wá ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó sọ ọ̀rọ̀ ìyànjú náà pé: “Wàásù ọ̀rọ̀ náà, wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú”? (2 Tím. 4:2) Báwo la ṣe lè máa wàásù lọ́nà tó fi hàn pé ó jẹ́ kánjúkánjú? Kí sì nìdí tí iṣẹ́ ìwàásù wa fi jẹ́ kánjúkánjú?

KÍ NÌDÍ TÍ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ WA FI JẸ́ KÁNJÚKÁNJÚ?

3. Kí ló máa yọrí sí bí àwọn èèyàn bá gba ọ̀rọ̀ Ìjọba Ọlọ́run tàbí tí wọ́n kọ̀ ọ́?

3 Tó o bá ronú pé iṣẹ́ ìwàásù wa lè mú kí àwọn èèyàn rí ìgbàlà tàbí kí wọ́n pa run bí a kò bá wàásù fún wọn, wàá rí i pé wíwàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn jẹ́ kánjúkánjú. (Róòmù 10:13, 14) Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Nígbà tí mo bá sì sọ fún ẹni burúkú pé: ‘Dájúdájú ìwọ yóò kú,’ tí ó sì yí padà ní tòótọ́ kúrò nínú ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ó sì ń ṣe ìdájọ́ òdodo àti òdodo, . . . òun yóò máa wà láàyè nìṣó. Òun kì yóò kú. Kò sí ìkankan nínú àwọn ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ tí ó ti ṣẹ̀ tí a óò rántí lòdì sí i.” (Ìsík. 33:14-16) Bíbélì sọ fún àwọn tó ń kọ́ àwọn èèyàn nípa Ìjọba Ọlọ́run pé: “Ìwọ yóò gba ara rẹ àti àwọn tí ń fetí sí ọ là.”—1 Tím. 4:16; Ìsík. 3:17-21.

4. Kí nìdí tí ìpẹ̀yìndà fi mú kí iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ kánjúkánjú ní ọ̀rúndún kìíní?

4 Ká lè mọyì ìdí tí Pọ́ọ̀lù fi gba Tímótì níyànjú pé kó wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní kánjúkánjú, jẹ́ ká wo díẹ̀ lára ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ nínú gbólóhùn tó tẹ̀ lé ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tá a gbé àpilẹ̀kọ yìí kà. Ó kà pé: “Wàásù ọ̀rọ̀ náà, wà lẹ́nu rẹ̀ ní kánjúkánjú ní àsìkò tí ó rọgbọ, ní àsìkò tí ó kún fún ìdààmú, fi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, báni wí kíkankíkan, gbani níyànjú, pẹ̀lú gbogbo ìpamọ́ra àti ọnà ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. Nítorí sáà àkókò kan yóò wà, tí wọn kò ní gba ẹ̀kọ́ afúnni-nílera, ṣùgbọ́n, ní ìbámu pẹ̀lú ìfẹ́-ọkàn ti ara wọn, wọn yóò kó àwọn olùkọ́ jọ fún ara wọn láti máa rìn wọ́n ní etí; wọn yóò sì yí etí wọn kúrò nínú òtítọ́.” (2 Tím. 4:2-4) Jésù ti sọ tẹ́lẹ̀ pé ìpẹ̀yìndà máa wà. (Mát. 13:24, 25, 38) Bí àkókò tí àsọtẹ́lẹ̀ yẹn máa ní ìmúṣẹ ti ń sún mọ́lé, ó jẹ́ kánjúkánjú pé kí Tímótì “wàásù ọ̀rọ̀ náà,” kódà nínú ìjọ, kí àwọn apẹ̀yìndà má bàa ṣi àwọn Kristẹni lọ́nà nípasẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ èké tí ẹ̀tàn inú rẹ̀ máa ń fani mọ́ra. Ó ṣe tán, ìwàláàyè àwọn èèyàn wà nínú ewu. Àmọ́, lóde òní ńkọ́?

5, 6. Èrò tó gbòde kan wo la lè bá pàdé lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wa?

5 Ní báyìí, ìpẹ̀yìndà kúrò nínú ìjọsìn tòótọ́ ti gbilẹ̀. (2 Tẹs. 2:3, 8) Àwọn ẹ̀kọ́ wo ló ń rin àwọn èèyàn létí lóde òní? Lọ́pọ̀ ibi irú ìtara kan náà tí àwọn èèyàn ní fún ẹ̀kọ́ ìsìn ni wọ́n ní fún ẹ̀kọ ẹfolúṣọ̀n. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì ni wọ́n fi ń ṣàlàyé ẹ̀kọ́ ẹfolúṣọ̀n, ó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ di oríṣi ẹ̀sìn kan tí àwọn èèyàn ń ṣe, ó sì ń nípa lórí ojú tí wọ́n fi ń wo Ọlọ́run àtàwọn èèyàn. Ẹ̀kọ́ míì tó tún gbòde kan ni pé Ọlọ́run kò nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn, torí náà, kò yẹ kí àwa náà nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Kí nìdí tí àwọn ẹ̀kọ́ yìí fi ń fa àwọn èèyàn mọ́ra, tó sì ń mú kí ọ̀kẹ́ àìmọye sùn lọ nípa tẹ̀mí? Ẹ̀kọ́ méjèèjì ló mú kí àwọn èèyàn gbà pé àwọn lè ṣe ohunkóhun tí àwọn bá fẹ́ láìsí ẹni tó máa yẹ àwọn lọ́wọ́ wò. Kò sí àní-àní pé irú gbólóhùn yìí ti rin ọ̀pọ̀ èèyàn létí.—Ka Sáàmù 10:4.

6 Àmọ́, àwọn ọ̀nà míì wà tí àwọn èèyàn ń gbà mú kí wọ́n rin àwọn létí. Àwọn kan tó ṣì ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì máa ń fẹ́ láti ní àwọn olùkọ́ tó máa sọ fún wọn pé, ‘Ohun yòówù kó o ṣe, Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ rẹ.’ Àwọn àlùfáà àtàwọn pásítọ̀ máa ń rin àwọn èèyàn létí nípa fífi dá wọn lójú pé àwọn àjọyọ̀, Máàsì, àwọn ayẹyẹ ìsìn àtàwọn ère, máa jẹ́ kí wọ́n rí ìbùkún Ọlọ́run. Àwọn tó ń lọ sì ṣọ́ọ̀ṣì yìí kò sì mọ̀ pé inú ewu làwọn wà. (Sm. 115:4-8) Síbẹ̀, tá a bá lè jí wọn lójú oorun nípa tẹ̀mí tí wọ́n wà, kí wọ́n bàa lè lóye òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni, wọ́n á lè jàǹfààní nínú Ìjọba Ọlọ́run.

KÍ LÓ TÚMỌ̀ SÍ LÁTI MÁA ṢE IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ LỌ́NÀ TÓ FI HÀN PÉ Ó JẸ́ KÁNJÚKÁNJÚ?

7. Báwo la ṣe lè máa ṣe iṣẹ́ ìwàásù lọ́nà tó fi hàn pé ó jẹ́ kánjúkánjú?

7 Oníṣẹ́ abẹ tó bá mọ iṣẹ́ rẹ̀ níṣẹ́ kò ní jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn òun níyà, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó lè fi ẹ̀mí àwọn èèyàn wewu. A lè fi hàn pé iṣẹ́ ìwàásù wa jẹ́ kánjúkánjú tá a bá pọkàn pọ̀ bá a ti ń ṣe iṣẹ́ náà, irú bíi ká máa ronú nípa àwọn kókó ọ̀rọ̀, ìbéèrè, tàbí ìsọfúnni tí àwọn tá à ń bá pàdé lè nífẹ̀ẹ́ sí. Ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù lọ́nà tó fi hàn pé ó jẹ́ kánjúkánjú tún lè mú ká ṣàtúnṣe ìgbòkègbodò wa ká lè wá àwọn èèyàn lọ nígbà tí ara wọn máa balẹ̀ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ wa.—Róòmù 1:15, 16; 1 Tím. 4:16.

8. Kí ló sábà máa ń wé mọ́ ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù lọ́nà tó fi hàn pé ó jẹ́ kánjúkánjú?

8 Ohun mìíràn tó tún wé mọ́ ṣíṣe iṣẹ́ ìwàásù lọ́nà tó fi hàn pé ó jẹ́ kánjúkánjú ni pé ká mọ àwọn ohun tá a máa fi sí ipò àkọ́kọ́. (Ka Jẹ́nẹ́sísì 19:15.) Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé lẹ́yìn tí dókítà rí èsì àyẹ̀wò ìṣègùn tí wọ́n ṣe fún ẹ, ó pè ẹ́ sínú ọ́fíìsì rẹ̀, ó sì fara balẹ̀ sọ fún ẹ pé: “Wò ó! Ńṣe ni àìsàn tó ń ṣe ẹ́ ń le sí i o, o kò sì ní ju oṣù kan lọ láti wá nǹkan ṣe sí i.” Ó dájú pé o kò ní bẹ́ jáde kúrò nínú ọ́fíìsì rẹ̀ bíi panápaná tó gba ìpè pàjáwìrì. Àmọ́, wàá gbọ́ àwọn àbá tó bá fún ẹ, wàá lọ sílé, wàá sì ronú dáadáa lórí àwọn nǹkan tó yẹ kó o kọ́kọ́ mú ṣe.

9. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà ní ìlú Éfésù, kí nìdí tá a fi lè sọ pé ó ṣe iṣẹ́ ìwàásù lọ́nà tó fi hàn pé ó jẹ́ kánjúkánjú?

9 A lè lóye bí Pọ́ọ̀lù ṣe ṣe iṣẹ́ ìwàásù náà lọ́nà tó fi hàn pé ó jẹ́ kánjúkánjú tá a bá ronú lórí ohun tó sọ fún àwọn alàgbà ìjọ Éfésù nípa bó ṣe wàásù ìhìn rere ní àgbègbè Éṣíà. (Ka Ìṣe 20:18-21.) Kò sí àní-àní pé láti ọjọ́ tó ti dé ibẹ̀ ni ọwọ́ rẹ̀ ti dí fún iṣẹ́, tó sì ń wàásù ìhìn rere fún àwọn èèyàn láti ilé dé ilé. Yàtọ̀ sí ìyẹn, ọdún méjì gbáko ló fi ń “sọ àsọyé lójoojúmọ́ nínú gbọ̀ngàn àpéjọ ilé ẹ̀kọ́ Tíránù,” ó sì máa ń ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé. (Ìṣe 19:1, 8-10) Ó ṣe kedere pé, bí Pọ́ọ̀lù ṣe ṣe iṣẹ́ ìwàásù lọ́nà tó fi hàn pé ó jẹ́ kánjúkánjú nípa lórí àwọn ohun tó ń ṣe lójoojúmọ́. Kì í ṣe nítorí kí iṣẹ́ ìwàásù lè wọ̀lọ́rùn la ṣe ké sí wa pé ‘ká wà lẹ́nu iṣẹ́ náà ní kánjúkánjú.’ Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló yẹ ká fi iṣẹ́ ìwàásù sí ipò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé wa.

10. Kí nìdí tó fi yẹ kó dùn mọ́ wa pé àwọn Kristẹni ṣe iṣẹ́ ìwàásù lọ́nà tó fi hàn pé ó jẹ́ kánjúkánjú ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn?

10 Àpẹẹrẹ àwùjọ kéréje ti àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere ṣáájú ọdún 1914 jẹ́ ká mọ ohun tó túmọ̀ sí láti máa fi sọ́kàn pé iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ kánjúkánjú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò ju ẹgbẹ̀rún mélòó kan lọ, wọ́n mọyì bí àkókò tí wọ́n wà ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó, wọ́n sì fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Wọ́n ń gbé ìwàásù jáde nínú ọgọ́rọ̀ọ̀rún ìwé ìròyìn, wọ́n sì tún ń ṣàfihàn sinimá aláwọ̀ mèremère kan tí wọ́n pè ní “Photo-Drama of Creation” [Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá]. Wọ́n tipa bẹ́ẹ̀ mú kí ọ̀pọ̀ mílíọ̀nù èèyàn gbọ́ ìhìn rere. Ká ní kì í ṣe pé wọ́n ṣe iṣẹ́ ìwàásù lọ́nà tó fi hàn pé ó jẹ́ kánjúkánjú ni, mélòó nínú wa ni ì bá gbọ́ ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run?—Ka Sáàmù 119:60.

MÁA ṢE DẸWỌ́ LẸ́NU IṢẸ́ TÓ JẸ́ KÁNJÚKÁNJÚ YÌÍ

11. Kí ló fà á tí àwọn kan fi dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tó jẹ́ kánjúkánjú yìí?

11 Ìpínyà ọkàn lè mú kí ẹnì kan má ṣe ronú nípa bí iṣẹ́ ìwàásù ti ṣe pàtàkì tó mọ́. Sátánì ń lo ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí láti mú kí ọwọ́ wá dí lẹ́nu lílépa àwọn nǹkan tara àti àwọn nǹkan tí kò fi bẹ́ẹ̀ ṣe pàtàkì. (1 Pét. 5:8; 1 Jòh. 2:15-17) Àwọn kan tí wọ́n ti fi iṣẹ́ ìsìn Jèhófà sí ipò àkọ́kọ́ tẹ́lẹ̀ ti dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tó jẹ́ kánjúkánjú yìí. Bí àpẹẹrẹ, ní ọ̀rúndún kìíní, Kristẹni kan wà tó ń jẹ́ Démásì, ó ti jẹ́ “alábàáṣiṣẹ́pọ̀” pẹ̀lú Pọ́ọ̀lù tẹ́lẹ̀, àmọ́ ó jẹ́ kí ètò àwọn nǹkan táwọn èèyàn kò ti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run pín ọkàn òun níyà. Dípò tí ì bá fi máa bá a nìṣó láti fún Pọ́ọ̀lù lókun nígbà ìṣòro, ńṣe ló pa á tì.—Fílém. 23, 24; 2 Tím. 4:10.

12. Àǹfààní wo la ní báyìí, àwọn àǹfààní wo la sì máa gbádùn títí láé?

12 Tí a kò bá fẹ́ dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tó jẹ́ kánjúkánjú yìí, a gbọ́dọ̀ sapá láti má ṣe fàyè gba ohun tó bá máa pín ọkàn wa níyà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. A gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ kára ká bàa lè “di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.” (1 Tím. 6:18, 19) Ó ṣeé ṣe kó dá ẹ lójú pé ìyè àìnípẹ̀kun lábẹ Ìjọba Ọlọ́run máa jẹ́ kó o ní àǹfààní láti gbádùn àwọn ìgbòkègbodò tó gbámúṣé títí láé. Àmọ́ àkókò wa yìí nìkan la ní àǹfààní láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè la ogun Amágẹ́dọ́nì já.

13. Ní báyìí tí a ti di Kristẹni, kí ni kò ní jẹ́ ká dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tó jẹ́ kánjúkánjú yìí?

13 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn èèyàn nínú ayé ló ń sùn nípa tẹ̀mí, kí ni kò ní jẹ́ ká dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ tó jẹ́ kánjúkánjú yìí? Ẹ jẹ́ ká máa rántí pé ojú oorun nínú òkùnkùn biribiri ni àwa náà wà nígbà kan. Àmọ́, a jí wa lójú oorun, Kristi sì ti tàn sórí wa, bí Pọ́ọ̀lù ṣe ṣàlàyé. Ní báyìí, a ní àǹfààní láti máa tan ìmọ́lẹ̀. (Ka Éfésù 5:14.) Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ti sọ èyí tán, ó wá kọ̀wé pé: “Ẹ máa ṣọ́ra lójú méjèèjì pé bí  ṣe ń rìn kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí aláìlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, ní ríra àkókò tí ó rọgbọ padà fún ara yín, nítorí pé àwọn ọjọ́ burú.” (Éfé. 5:15, 16) Nínú àwọn ọjọ́ búburú tá à ń gbé yìí, ẹ jẹ́ ká máa ‘ra àkókò padà’ láti máa fi bójú tó àwọn ohun tó lè mú ká wà lójúfò nípa tẹ̀mí.

ÀKÓKÒ TÓ ṢE PÀTÀKÌ JÙ LỌ LÀ Ń GBÉ YÌÍ

14-16. Kí ló mú kí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run jẹ́ kánjúkánjú báyìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ?

14 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sígbà tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni kò gba kánjúkánjú, ó tún wá gba kánjúkánjú lákòókò yìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Láti ọdún 1914 ni àwọn àmì ọjọ́ ìkẹyìn tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣàpèjúwe ti wá ṣe kedere. (Mát. 24:3-51) Ẹ̀mí àwọn èèyàn wà nínú ewu ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Láìka ti àwọn àdéhùn tí àwọn ìjọba alágbára nínú ayé bá ara wọn ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí sí, wọ́n ṣì ní àwọn ohun ìjà runlérùnnà tó jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] tó ti wà ní sẹpẹ́ láti ṣọṣẹ́. Àwọn aláṣẹ ròyìn pé àwọn “kò rí” ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ohun ìjà runlérùnnà mọ́. Ṣé kì í ṣe pé ọwọ́ àwọn apániláyà ni àwọn ohun ìjà náà bọ́ sí? Àwọn tó ń kíyè sí bí nǹkan ṣe ń lọ sí nínú ayé sọ pé, bí apániláyà kan bá dá ogun sílẹ̀ pẹ́nrẹ́n, ó lè pa gbogbo aráyé run. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe ogun nìkan ló mú kí ẹ̀mí àwọn èèyàn wà nínú ewu.

15 Ohun tí ìwé ìròyìn The Lancet àti ilé ẹ̀kọ́ gíga University College London sọ lọ́dún 2009 ni pé, “ojú ọjọ́ tó ń yí pa dà ni ohun tó ń wu ìlera èèyàn léwu jù lọ lágbàáyé ní ọ̀rúndún kọkànlélógún yìí.” Ó tún sọ pé: “Ipa tí ojú ọjọ́ tó ń yí pa dà máa ní lórí ìlera wa máa ṣàkóbá fún àwọn èèyàn tó pọ̀ jù lọ ní ọ̀pọ̀ ọdún sí àkókò tá a wà yìí, á sì fi ẹ̀mí àti ìlera ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn sínú ewu.” Lára ohun tí èyí lè fà ni àkúnya omi òkun, ọ̀dá, omíyalé, àjàkálẹ̀ àrùn, ìjì líle àti ogun látàrí bí àwọn ohun àmúṣọrọ̀ ṣe ń dín kù, èyí sì lè ṣàkóbá fún ọ̀pọ̀ ibi lágbàáyé. Kò sí àní-àní pé ogun àti àjálù kò jẹ́ kí aráyé rójú ráyè.

16 Àwọn èèyàn kan lè ronú pé bí wọ́n bá lo àwọn ohun ìjà ogun runlérùnnà, ó ṣeé ṣe kí ìyẹn yọrí sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó máa jẹ́ ìmúṣẹ “àmì” àwọn ọjọ́ ìkẹyìn. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ni kò mọ ohun tí àmì náà túmọ̀ sí gan-an. Àmì náà ti hàn gbangba láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, èyí tó fi hàn pé Kristi ti wà níhìn-ín àti pé òpin ètò àwọn nǹkan yìí ń yára sún mọ́lé. (Mát. 24:3) Àsìkò wa yìí gan-an ni ọ̀pọ̀ lára àwọn àmì náà túbọ̀ ń hàn kedere ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Ó ti tó àkókò báyìí fún àwọn èèyàn láti jí lójú oorun tẹ̀mí. Iṣẹ́ ìwàásù wa lè ràn wọ́n lọ́wọ́ láti jí lójú oorun.

17, 18. (a) Báwo ni “àsìkò” ṣe ń ní ipa lórí wa? (b) Kí ló lè mú kí àwọn èèyàn yí ojú tí wọ́n fi ń wo ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run pa dà?

17 Àkókò díẹ̀ ló kù fún wa láti fi hàn pé a nífẹ̀ẹ́ Jèhófà ká sì fi parí iṣẹ́ ìwàásù tó yàn fún wa láti ṣe ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí. Ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní ìlú Róòmù ní ọ̀rúndún kìíní túbọ̀ kan àwa náà gbọ̀ngbọ̀n lónìí, ó sọ pé: “Ẹ mọ àsìkò, pé wákàtí ti tó nísinsìnyí fún yín láti jí lójú oorun, nítorí ìgbàlà wa sún mọ́lé nísinsìnyí ju ìgbà tí a di onígbàgbọ́.”—Róòmù 13:11.

18 Àwọn ohun tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn lè mú kí àwọn èèyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n túbọ̀ ní àjọṣe tó dára pẹ̀lú Ọlọ́run. Àwọn míì gbà pé aráyé nílò ìrànlọ́wọ́ nígbà tí wọ́n ronú nípa bí ìjọba èèyàn ṣe kùnà láti yanjú ìṣòro ọrọ̀ ajé tó dẹnu kọlẹ̀, ìbẹ̀rù ohun ìjà ogun runlérùnnà, ìwà ọ̀daràn tó burú jáì tàbí bíba àyíká jẹ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ìdílé àwọn kan, irú bí àìsàn, ìkọ̀sílẹ̀ tàbí ikú ìbátan wọn, ló jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ó yẹ kí àwọn gbọ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run. Bá a ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù ń jẹ́ ká lè ran irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́.

WỌ́N FẸ́ LÁTI ṢÈRÀNWỌ́ TORÍ PÉ IṢẸ́ NÁÀ JẸ́ KÁNJÚKÁNJÚ

19, 20. Báwo ni bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe jẹ́ kánjúkánjú ṣe mú kí ọ̀pọ̀ Kristẹni yí ọ̀nà tí wọ́n ń gba gbé ìgbé ayé wọn pa dà?

19 Bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe jẹ́ kánjúkánjú ti mú kí ọ̀pọ̀ Kristẹni mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i. Bí àpẹẹrẹ, tọkọtaya kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó tí wọ́n sì jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Ecuador pinnu láti dín ohun ìní wọn kù, lẹ́yìn tí wọ́n gbọ́ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ àkànṣe ti ọdún 2006 tí ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́, “Ẹ Jẹ́ Kí Ojú Yín Mú Ọ̀nà Kan.” Wọ́n ṣe àkọsílẹ̀ àwọn ohun tí wọn kò nílò, láàárín oṣù mẹ́ta wọ́n kó kúrò nínú ilé oníyàrá mẹ́ta tí wọ́n ń gbé, wọ́n sì lọ gba yàrá kan, wọ́n ta díẹ̀ lára àwọn ẹrù wọn, wọ́n sì fi san gbogbo gbèsè tó wà lọ́rùn wọn. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí wọ́n fi di aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́, nígbà tó yá wọ́n tẹ̀ lé àbá tí alábòójútó àyíká fún wọn pé kí wọ́n lọ sìn ní ìjọ kan tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i.

20 Arákùnrin kan tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà ti Àríwá kọ̀wé pé: “Ó ti pé ọgbọ̀n [30] ọdún tí èmi àti ìyàwó mi ti ṣe ìrìbọmi. A lọ sí àpéjọ kan lọ́dún 2006. Nígbà tí a ń pa dà bọ̀ nílé lẹ́yìn àpéjọ náà, a jíròrò bá a ṣe lè dín àwọn ohun ìní wa kù. (Mát. 6:19-22) A ní ilé mẹ́ta, ilẹ̀, àwọn ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, ọkọ̀ ojú omi kan àti ọkọ̀ àfiṣelé kan. Ó ṣe wá bíi pé ńṣe la dà bí àwọn Kristẹni tí kò lọ́gbọ́n nínú, a sì pinnu láti fi iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ṣe àfojúsùn wa. Lọ́dún 2008, a di aṣáájú-ọ̀nà déédéé bíi ti ọmọ wa obìnrin. Inú wa dùn gan-an láti túbọ̀ máa ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn ará. Ó ṣeé ṣe fún wa láti lọ sìn níbi tí wọ́n ti nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i. Bákan náà, bá a ṣe ń ní púpọ̀ sí i láti ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà ti jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. Ohun tó tún mú inú wa dùn ni bí ojú àwọn èèyàn ṣe ń tàn yanran bí wọ́n bá gbọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì lóye rẹ̀.”

21. Ìmọ̀ wo la ní tó ń sún wa ṣiṣẹ́?

21 A mọ̀ pé “ọjọ́ ìdájọ́ àti ti ìparun àwọn ènìyàn aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run” máa tó wá sórí ètò àwọn nǹkan búburú yìí. (2 Pét. 3:7) Ìmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá a ní ń mú ká máa fi ìtara kéde ìpọ́njú ńlá tó ń bọ̀ àti ayé tuntun tó máa tẹ̀ lé e. A túbọ̀ ń rí i pé ó jẹ́ kánjúkánjú láti mú kí àwọn èèyàn ní ìrètí tòótọ́. Tá a bá ń lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ ìwàásù tó jẹ́ kánjúkánjú yìí dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́, ńṣe là ń fi hàn pé ìfẹ́ àìṣẹ̀tàn la ní fún Ọlọ́run àtàwọn èèyàn bíi tiwa.

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]