Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jẹ́ Kí Ìrètí Tá A Ní Máa Fún Ẹ Láyọ̀

Jẹ́ Kí Ìrètí Tá A Ní Máa Fún Ẹ Láyọ̀

Jẹ́ Kí Ìrètí Tá A Ní Máa Fún Ẹ Láyọ̀

“[A ní] ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí kò lè purọ́, ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́.”—TÍTÙ 1:2.

ÀTÚNYẸ̀WÒ

․․․․․

Báwo la ṣe mọ̀ pé ìdùnnú máa ń wà ní ọ̀run bí ọ̀kan lára àwọn ẹni àmì òróró bá pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ dójú ikú?

․․․․․

Báwo ni ìmúṣẹ ìrètí àwọn àgùntàn mìíràn ṣe kan ti àwọn ẹni àmì òróró?

․․․․․

Kí ọwọ́ wa lè tẹ ohun tí à ń retí, “ìṣe ìwà mímọ́” àti “àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run” wo la gbọ́dọ̀ máa fi hàn?

1. Báwo ni ìrètí tí Jèhófà fún wa ṣe lè jẹ́ ká máa fara dà á?

 ÀPỌ́SÍTÉLÌ PỌ́Ọ̀LÙ sọ pé Jèhófà ni “Ọlọ́run tí ń fúnni ní ìrètí.” Ó wá fi kún un pé Jèhófà lè ‘fi ìdùnnú àti àlàáfíà gbogbo kún inú wa nípa gbígbàgbọ́ wa, kí a lè ní ìrètí púpọ̀ gidigidi pẹ̀lú agbára ẹ̀mí mímọ́.’ (Róòmù 15:13) Bí a bá ní ìrètí púpọ̀ gidigidi, ó máa ṣeé ṣe fún wa láti fara da ipò èyíkéyìí tó bá yọjú, ìdùnnú àti àlàáfíà á sì kún inú ọkàn wa. Bíi ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, irú ìrètí bẹ́ẹ̀ máa jẹ́ “ìdákọ̀ró fún ọkàn, [tí] ó dájú, [tí] ó fìdí múlẹ̀ gbọn-in,” fún àwọn Kristẹni yòókù pẹ̀lú. (Héb. 6:18, 19) A lè rọ̀ mọ́ ìrètí tá a ní yìí nígbà tá a bá dojú kọ ìṣòro nígbèésí ayé, kò sì ní jẹ́ ká máa ṣiyè méjì tàbí ká di ẹni tí kò ní ìgbàgbọ́.—Ka Hébérù 2:1; 6:11.

2. Ìrètí ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ méjì wo ni àwọn Kristẹni ní lóde òní, kí sì nìdí tí “àwọn àgùntàn mìíràn” fi ka ìrètí tí àwọn ẹni àmì òróró ní sí pàtàkì?

2 Oríṣi ìrètí méjì ló wà, àwọn Kristẹni tó ń gbé ní àkókò òpin yìí sì lè ní èyíkéyìí nínú méjèèjì. Àwọn tó ṣẹ́ kù lára “agbo kékeré” ti àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní ìrètí ìyè àìleèkú lókè ọ̀run, níbi tí wọ́n á ti jẹ́ ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Kristi nínú Ìjọba rẹ̀. (Lúùkù 12:32; Ìṣí. 5:9, 10) “Ogunlọ́gọ̀ ńlá” ti “àwọn àgùntàn mìíràn” tí wọ́n pọ̀ lọ súà, ní ìrètí láti wà láàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé gẹ́gẹ́ bí ọmọ abẹ́ Ìjọba Mèsáyà. (Ìṣí. 7:9, 10; Jòh. 10:16) Àwọn àgùntàn mìíràn kò gbọ́dọ̀ gbàgbé pé kí wọ́n tó lè ní ìgbàlà, wọ́n ní láti máa ṣètìlẹ́yìn fún àwọn ẹni àmì òróró “arákùnrin” Kristi tí wọ́n ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé. (Mát. 25:34-40) Àwọn ẹni àmì òróró á gba èrè wọn, kò sì sí àní-àní pé àwọn àgùntàn mìíràn náà máa rí ìmúṣẹ ìrètí tiwọn náà gbà. (Ka Hébérù 11:39, 40.) Ẹ jẹ́ ká kọ́kọ́ ṣàgbéyẹ̀wò ìrètí tí Ọlọ́run gbé ka iwájú àwọn ẹni àmì òróró.

“ÌRÈTÍ TÍ Ó WÀ LÁÀYÈ” TÍ ÀWỌN KRISTẸNI ẸNI ÀMÌ ÒRÓRÓ NÍ

3, 4. Báwo ni àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ṣe ní “ìbí tuntun sí ìrètí tí ó wà láàyè,” kí sì ni ìrètí náà?

3 Àpọ́sítélì Pétérù kọ lẹ́tà méjì sí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró, ó pè wọ́n ní “àwọn ẹni tí a yàn.” (1 Pét. 1:1) Ó ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa ìrètí àgbàyanu tí Ọlọ́run fún agbo kékeré náà. Nínú lẹ́tà àkọ́kọ́, Pétérù sọ pé: “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi, nítorí ní ìbámu pẹ̀lú àánú ńlá rẹ̀, ó fún wa ní ìbí tuntun sí ìrètí tí ó wà láàyè nípasẹ̀ àjíǹde Jésù Kristi kúrò nínú òkú, sí ogún tí ó jẹ́ aláìlè-díbàjẹ́ àti aláìlẹ́gbin àti aláìlèṣá. A fi í pa mọ́ ní ọ̀run de ẹ̀yin, tí agbára Ọlọ́run ń fi ìṣọ́ ṣọ́ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ fún ìgbàlà kan tí a múra tán láti ṣí payá ní sáà àkókò ìkẹyìn. Nínú òtítọ́ yìí ni ẹ̀yin ń yọ̀ gidigidi.”—1 Pét. 1:3-6.

4 Àwọn Kristẹni kéréje tí Jèhófà yàn láti bá Kristi jọba nínú Ìjọba ọ̀run máa ní “ìbí tuntun,” ìyẹn ni pé wọ́n máa di ọmọ Ọlọ́run tí a fi ẹ̀mí bí. Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ yàn wọ́n kí wọ́n lè di ọba àti àlùfáà pẹ̀lú Kristi. (Ìṣí. 20:6) Pétérù sọ pé “ìbí tuntun” yìí ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún wọn láti ní “ìrètí tí ó wà láàyè,” ó sì pe ìrètí yìí ní “ogún tí ó jẹ́ aláìlè-díbàjẹ́ àti aláìlẹ́gbin àti aláìlèṣá” tá a fi pa mọ́ dè wọ́n “ní ọ̀run.” Abájọ tí àwọn ẹni àmì òróró fi ń “yọ̀ gidigidi” nínú ìrètí tí ó wà láàyè tí wọ́n ní! Àmọ́ kí ọwọ́ wọn tó lè tẹ ohun tí wọ́n ń retí yìí, wọ́n gbọ́dọ̀ jẹ́ olóòótọ́.

5, 6. Kí nìdí tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró fi gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wọn láti mú kí pípè tí a pè wọ́n sí ọ̀run dájú?

5 Nínú lẹ́tà kejì tí Pétérù kọ, ó gba àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró níyànjú pé kí wọ́n ‘sa gbogbo ipá wọn láti mú pípè àti yíyàn wọn dájú fún ara wọn.’ (2 Pét. 1:10) Wọ́n gbọ́dọ̀ sa gbogbo ipá wọn kí wọ́n lè ní àwọn ànímọ́ Kristẹni bí ìgbàgbọ́, ìfọkànsin Ọlọ́run, ìfẹ́ ará àti ìfẹ́. Pétérù sọ pé: “Bí nǹkan wọ̀nyí bá wà nínú yín, tí wọ́n sì kún àkúnwọ́sílẹ̀, wọn kì yóò jẹ́ kí ẹ di aláìṣiṣẹ́ tàbí aláìléso.”—Ka 2 Pétérù 1:5-8.

6 Nínú iṣẹ́ tí Kristi tá a ti jí dìde rán sí àwọn alàgbà tí a fi ẹ̀mí bí ní ọ̀rúndún kìíní, tí wọ́n wà ní ìjọ Filadẹ́fíà ní Éṣíà Kékeré, ó sọ pé: “Nítorí pé ìwọ pa ọ̀rọ̀ nípa ìfaradà mi mọ́, ṣe ni èmi pẹ̀lú yóò pa ọ́ mọ́ kúrò nínú wákàtí ìdánwò, èyí tí yóò dé bá gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti dán àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé wò. Mo ń bọ̀ kíákíá. Máa bá a nìṣó ní dídi ohun tí ìwọ ní mú ṣinṣin, kí ẹnì kankan má bàa gba adé rẹ.” (Ìṣí. 3:10, 11) Bí Kristẹni ẹni àmì òróró kan bá di aláìṣòótọ́, kò ní gba “adé ògo tí kì í ṣá” èyí tí Ọlọ́run ṣèlérí láti fún àwọn tí a yàn tí wọ́n sì jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú.—1 Pét. 5:4; Ìṣí. 2:10.

ÌWỌLÉ SÍNÚ ÌJỌBA NÁÀ

7. Ìrètí àgbàyanu wo ni Júúdà mẹ́nu kàn nínú lẹ́tà rẹ̀?

7 Ní nǹkan bí ọdún 65 Sànmánì Kristẹni, Júúdà iyèkan Jésù kọ lẹ́tà kan sí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró bíi tirẹ̀, ó pè wọ́n ní “àwọn tí a pè.” (Júúdà 1; fi wé Hébérù 3:1) Ohun tó kọ́kọ́ fẹ́ kọ sí wọn nínú lẹ́tà rẹ̀ dá lórí ìrètí ológo ti ìgbàlà tí àwọn Kristẹni tí Ọlọ́run pè sí Ìjọba ọ̀run “jọ dì mú.” (Júúdà 3) Àmọ́ bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní àwọn ọ̀ràn pàtàkì míì tó fẹ́ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀, ní ìparí lẹ́tà kúkúrú tó kọ, ó tọ́ka sí ìrètí àgbàyanu tí gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní, ó sọ pé: “Wàyí o, ẹni tí ó lè ṣọ́ yín kúrò nínú kíkọsẹ̀, tí ó sì lè mú yín dúró láìní àbààwọ́n níwájú ògo rẹ̀ pẹ̀lú ìdùnnú ńláǹlà, Ọlọ́run kan ṣoṣo tí ó jẹ́ Olùgbàlà wa nípasẹ̀ Jésù Kristi Olúwa wa, ni kí ògo, ọlá ọba, agbára ńlá àti ọlá àṣẹ jẹ́ tirẹ̀ fún gbogbo ayérayé tí ó ti kọjá àti nísinsìnyí àti títí lọ dé gbogbo ayérayé.”—Júúdà 24, 25.

8. Ní ìbámu pẹ̀lú Júúdà ẹsẹ 24, kí ló fi hàn pé ìdùnnú máa ń wà ní ọ̀run nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ẹni àmì òróró bá pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ dójú ikú?

8 Ó ṣe kedere pé ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó jẹ́ olóòótọ́ máa fẹ́ kí Ọlọ́run dáàbò bo òun nínú ohunkóhun tó lè sọ òun di aláìṣòótọ́ tó sì máa yọrí sí ìparun. Ìrètí wọn tó dá lórí Bíbélì ni pé Jésù Kristi máa jí àwọn dìde kúrò nínú ikú, ó sì máa jẹ́ kí wọ́n fara hàn nínú ìjẹ́pípé ti ẹ̀mí níwájú Ọlọ́run pẹ̀lú ìdùnnú ńláǹlà. Bí ọ̀kan lára àwọn ẹni àmì òróró bá jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú, ó ní ìdánilójú pé a máa “gbé [òun] dìde ní ara ti ẹ̀mí,” a máa jí i dìde “ní àìdíbàjẹ́ . . . , ní ògo.” (1 Kọ́r. 15:42-44) Bí ‘ìdùnnú púpọ̀ bá ń wà ní ọ̀run lórí ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tí ó ronú pìwà dà,’ wo bí ìdùnnú náà á ṣe pọ̀ tó ní ọ̀run nígbà tí ọ̀kan lára àwọn arákùnrin Kristi tí a fi ẹ̀mí bí bá pa ìwà títọ́ rẹ̀ mọ́ lórí ilẹ̀ ayé títí dójú ikú. (Lúùkù 15:7) Jèhófà àti àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ máa bá ẹni àmì òróró náà yọ̀ nígbà tó bá ń gba èrè rẹ̀ “pẹ̀lú ìdùnnú ńláǹlà.”—Ka 1 Jòhánù 3:2.

9. Báwo ni Ọlọ́run ṣe pèsè ìwọlé sínú Ìjọba náà “lọ́pọ̀ jaburata” fún àwọn ẹni àmì òróró tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́, ipa wo sì ni ìrètí yìí ní lórí àwọn tó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé lára wọn?

9 Lọ́nà kan náà, Pétérù kọ̀wé sí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró pé bí wọ́n bá mú pípè wọn dájú nípa jíjẹ́ olùṣòtítọ́, “a ó pèsè ìwọlé fún [wọn] lọ́pọ̀ jaburata sínú ìjọba àìnípẹ̀kun ti Olúwa àti Olùgbàlà wa Jésù Kristi.” (2 Pét. 1:10, 11) Ọlọ́run máa pèsè ìwọlé sí Ìjọba ọ̀run fún wọn “lọ́pọ̀ jaburata” ní ti pé àwọn ànímọ́ Kristẹni tí wọ́n ní á máa tàn yanran. Ti pé a pèsè rẹ̀ fún wọn “lọ́pọ̀ jaburata” tún lè túmọ̀ sí pé wọ́n máa gbádùn ìbùkún yanturu torí pé wọ́n lo gbogbo okun wọn nínú eré ìje ìyè. Bí wọ́n bá ronú nípa bí wọ́n ṣe jẹ́ olóòótọ́ nígbà ayé wọn, ọkàn wọn á kún fún ayọ̀ ńláǹlà àti ọpẹ́. Kò sí àní-àní pé ìrètí tí àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tó ṣì wà lórí ilẹ̀ ayé ní yìí ń fún wọn lókun láti ‘mú èrò inú wọn gbára dì fún ìgbòkègbodò tí kò dáwọ́ dúró.’—1 Pét. 1:13.

“ÌRÈTÍ” TÍ ÀWỌN ÀGÙNTÀN MÌÍRÀN NÍ

10, 11. (a) Ìrètí wo ni àwọn àgùntàn mìíràn ní? (b) Báwo ni ìmúṣẹ ìrètí ìwàláàyè lórí ilẹ̀ ayé ṣe kan Kristi àti “ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run”?

10 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé nípa ìrètí ológo ti “àwọn ọmọ Ọlọ́run” tá a fi ẹ̀mí bí láti jẹ́ “ajùmọ̀jogún” pẹ̀lú Kristi. Lẹ́yìn náà ló wá mẹ́nu ba ìrètí àgbàyanu tí Jèhófà nawọ́ rẹ̀ sí àìlóǹkà àwọn àgùntàn mìíràn. Ó ní: “Ìfojúsọ́nà oníhàáragàgà ìṣẹ̀dá [àwọn èèyàn] ń dúró de ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run [àwọn ẹni àmì òróró]. Nítorí a tẹ ìṣẹ̀dá lórí ba fún ìmúlẹ̀mófo, kì í ṣe nípasẹ̀ ìfẹ́ òun fúnra rẹ̀, ṣùgbọ́n nípasẹ̀ ẹni tí ó tẹ̀ ẹ́ lórí ba, nítorí ìrètí pé a óò dá ìṣẹ̀dá tìkára rẹ̀ pẹ̀lú sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́, yóò sì ní òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.”—Róòmù 8:14-21.

11 Jèhófà ló fún ìran èèyàn ní “ìrètí” nígbà tó ṣèlérí pé òun máa gbà wọ́n sílẹ̀ lọ́wọ́ “ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà,” Sátánì Èṣù, nípasẹ̀ “irú-ọmọ” tá a ṣèlérí. (Ìṣí. 12:9; Jẹ́n. 3:15) Jésù Kristi ni àkọ́kọ́ lára “irú-ọmọ” náà. (Gál. 3:16) Nípasẹ̀ ikú àti àjíǹde Jésù, ó pèsè ẹ̀rí tó fìdí múlẹ̀ fún ìrètí tí aráyé ní, pé a óò dá wọn sílẹ̀ kúrò nínú jíjẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Ìmúṣẹ ìrètí yìí ní í ṣe pẹ̀lú “ìṣípayá àwọn ọmọ Ọlọ́run.” Àwọn ẹni àmì òróró tá a ti ṣe lógo ni apá kejì lára “irú-ọmọ” náà. A máa ‘ṣí wọn payá’ nígbà tí wọ́n bá dara pọ̀ mọ́ Kristi láti pa ètò àwọn nǹkan búburú Sátánì run. (Ìṣí. 2:26, 27) Èyí máa jẹ́ ìgbàlà fún àwọn àgùntàn mìíràn, tí wọ́n jáde wá látinú ìpọ́njú ńlá náà.—Ìṣí. 7:9, 10, 14.

12. Àǹfààní àgbàyanu wo ni ìṣípayá àwọn ẹni àmì òróró máa ṣe fún aráyé?

12 Ìtura ńlá mà ni “ìṣẹ̀dá,” ìyẹn ẹ̀dá èèyàn, máa ní nígbà Ẹgbẹ̀rún Ọdún Ìṣàkóso Kristi o! Ní ìgbà yẹn, a máa túbọ̀ ‘ṣí’ “àwọn ọmọ Ọlọ́run” tá a ti ṣe lógo ‘payá’ nígbà tí wọ́n bá ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà pẹ̀lú Kristi, tí wọ́n sì ń jẹ́ kí aráyé jàǹfààní látinú ẹbọ ìràpadà Jésù. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ abẹ́ Ìjọba ọ̀run náà, àwọn èèyàn tó jẹ́ “ìṣẹ̀dá” máa bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìdáǹdè lọ́wọ́ ipa tí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ti ní lórí wọn. Ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, a ó “dá” àwọn èèyàn tí wọ́n jẹ́ onígbọràn “sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìsọdẹrú fún ìdíbàjẹ́.” Bí wọ́n bá jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà jálẹ̀ Ẹgbẹ̀rún ọdún náà àti nígbà ìdánwò ìkẹyìn tó máa tẹ̀ lé e, a óò kọ orúkọ wọn sínú “àkájọ ìwé ìyè” títí láé. Wọ́n á wá wọnú “òmìnira ológo ti àwọn ọmọ Ọlọ́run.” (Ìṣí. 20:7, 8, 11, 12) Ìrètí ológo lèyí jẹ́ lóòótọ́!

BÍ A ṢE LÈ MÚ ÌRÈTÍ WA WÀ LÁÀYÈ

13. Orí kí ni ìrètí wa dá lé, ìgbà wo la sì máa ṣí Kristi payá?

13 Lẹ́tà méjèèjì tí Ọlọ́run mí sí Pétérù láti kọ ní ọ̀pọ̀ nǹkan tó lè ran àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn lọ́wọ́ láti mú kí ìrètí tí olúkúlùkù wọn ní wà láàyè. Ó ṣàlàyé pé ìrètí wọn kò dá lórí iṣẹ́ tí wọ́n ṣe, bí kò ṣe lórí inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí Jèhófà. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ wà ní ìwọ̀ntúnwọ̀nsì, kẹ́ ẹ sì gbé gbogbo ìrètí yín ka inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí, èyí tí a óò mú wá fún yín nígbà ìṣípayá Jésù Kristi.” (1 Pét. 1:13; àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) A máa ṣí Kristi payá nígbà tó bá wá láti san àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ olóòótọ́ lẹ́san àti láti mú ìdájọ́ Jèhófà wá sórí àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.—Ka 2 Tẹsalóníkà 1:6-10.

14, 15. (a) Ká lè mú kí ìrètí wa wà láàyè, kí la gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn? (b) Ìmọ̀ràn wo ni Pétérù fún wa?

14 Ká lè mú kí ìrètí wa wà láàyè, a gbọ́dọ̀ máa fi sọ́kàn pé “ọjọ́ Jèhófà” ń bọ̀ láìpẹ́, ká sì máa gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó fi hàn pé a mọ̀ bẹ́ẹ̀. Ọjọ́ Jèhófà ni ìparun máa wá sórí “àwọn ọ̀run” tó wà nísinsìnyí, ìyẹn ìṣàkóso ẹ̀dá èèyàn àti “ayé” to dúró fún àwùjọ ẹ̀dá èèyàn burúkú àti “àwọn ohun ìpìlẹ̀” rẹ̀. Pétérù kọ̀wé pé: “Irú ènìyàn wo ni ó yẹ kí ẹ jẹ́ . . . , ní dídúró de wíwàníhìn-ín ọjọ́ Jèhófà àti fífi í sọ́kàn pẹ́kípẹ́kí, nípasẹ̀ èyí tí àwọn ọ̀run tí wọ́n ti gbiná yóò di yíyọ́, tí àwọn ohun ìpìlẹ̀ tí ó ti gbóná janjan yóò sì yọ́!”—2 Pét. 3:10-12.

15 A óò fi “ọ̀run tuntun [ìṣàkóso Ìjọba Kristi] àti ilẹ̀ ayé tuntun [àwùjọ àwọn èèyàn tuntun tó máa wà lórí ilẹ̀ ayé]” rọ́pò “àwọn ọ̀run” àti “ayé” tí ó wà nísinsìnyí. (2 Pét. 3:13) Lẹ́yìn náà Pétérù wá fún wa ní ìmọ̀ràn tó sojú abẹ níkòó, èyí tó dá lórí “dídúró” wa tàbí bí a ṣe lè mú kí ìrètí wa wà láàyè ká sì máa retí ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí yìí. Ó sọ pé: “Nítorí bẹ́ẹ̀, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, níwọ̀n bí ẹ ti ń dúró de nǹkan wọ̀nyí, ẹ sa gbogbo ipá yín kí òun lè bá yín nígbẹ̀yìn-gbẹ́yín ní àìléèérí àti ní àìlábààwọ́n àti ní àlàáfíà.”—2 Pét. 3:14.

BÍ A ṢE LÈ MÁA ṢE OHUN TÓ BÁ ÌRÈTÍ WA MU

16, 17. (a) “Ìṣe ìwà mímọ́” àti “àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run” wo la gbọ́dọ̀ máa fi hàn? (b) Báwo ni ọwọ́ wa ṣe máa tẹ ohun tá a ti ń retí?

16 A gbọ́dọ̀ mú kí ìrètí wa wà láàyè, àmọ́ kì í ṣe ìyẹn nìkan, a tún gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó bá ìrètí wa mu. A gbọ́dọ̀ fún irú ẹni tá a jẹ́ nípa tẹ̀mí ní àfiyèsí. “Ìṣe ìwà mímọ́” gba pé kí a ‘tọ́jú ìwà wa kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè,’ nípa híhu ìwà tó bójú mu. (2 Pét. 3:11; 1 Pét. 2:12) A gbọ́dọ̀ ní “ìfẹ́ láàárín ara wa.” Ìyẹn kan ṣíṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti máa pa ìṣọ̀kan ẹgbẹ́ ará kárí ayé mọ́, títí kan nínú ìjọ wa pàápàá. (Jòh. 13:35) “Àwọn iṣẹ́ ìfọkànsin Ọlọ́run” ni àwọn nǹkan tó fi hàn pé a ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà. Èyí ní í ṣe pẹ̀lú bí àdúrà wa ti jẹ́ ojúlówó tó, títí kan bá a ṣe ń ka Bíbélì lójoojúmọ́, ìdákẹ́kọ̀ọ́ tó jinlẹ̀, Ìjọsìn Ìdílé àti kíkópa déédéé nínú wíwàásù “ìhìn rere ìjọba” Ọlọ́run.—Mát. 24:14.

17 Ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ló fẹ́ jẹ́ irú ẹni tí Jèhófà fẹ́ ká jẹ́, tó sì máa gbà là nígbà tí ètò àwọn nǹkan búburú ìsinsìnyí bá di “yíyọ́.” Ọwọ́ wa á sì tipa bẹ́ẹ̀ tẹ ohun tá a ti ń retí, ìyẹn “ìrètí ìyè àìnípẹ̀kun, èyí tí Ọlọ́run, ẹni tí kò lè purọ́, ti ṣèlérí tipẹ́tipẹ́.”—Títù 1:2.

[Àwọn Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ní “ìbí tuntun sí ìrètí tí ó wà láàyè”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]

Jẹ́ kí ìrètí náà máa wà láàyè nínú ìdílé rẹ