Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Wa Nípa Jésù Kristi

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Wa Nípa Jésù Kristi

Ìdáhùn sí Àwọn Ìbéèrè Wa Nípa Jésù Kristi

“Ta ni àwọn ogunlọ́gọ̀ ń sọ pé mo jẹ́?”—LÚÙKÙ 9:18.

JÉSÙ bi àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìbéèrè yẹn nítorí ó mọ̀ pé oríṣiríṣi èrò tó yàtọ̀ síra ni àwọn èèyàn ní nípa òun. Ṣùgbọ́n, kò sídìí tó fi yẹ kí ẹni tí Jésù jẹ́ rú àwọn èèyàn lójú. Jésù kò ya ara rẹ̀ láṣo, kò sì ṣe àwọn nǹkan rẹ̀ ní ìkọ̀kọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó máa ń wà láàárín àwọn èèyàn ní àwọn abúlé àti ìlú ńlá. Ó ń wàásù, ó sì ń kọ́ àwọn èèyàn ní gbangba nítorí ó fẹ́ kí àwọn èèyàn mọ ẹni tí òun jẹ́ gan-an.—Lúùkù 8:1.

Èèyàn lè mọ ẹni tí Jésù jẹ́ lóòótọ́ látinú ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ìṣe rẹ̀, wọ́n sì wà lákọsílẹ̀ nínú ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin tó wà nínú Bíbélì, ìyẹn Mátíù, Máàkù, Lúùkù àti Jòhánù. Inú àwọn ìwé Ìhìn Rere tí Ọlọ́run mí sí yìí ni a ti máa rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wa nípa Jésù. *Jòhánù 17:17.

ÌBÉÈRÈ: Ǹjẹ́ Jésù ti gbé ayé rí lóòótọ́?

ÌDÁHÙN: Bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn òpìtàn bíi Josephus àti Tacitus tó gbé láyé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní dárúkọ Jésù pé ó gbé ayé rí lóòótọ́. Èyí tó tiẹ̀ pabanbarì ni pé àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ ohun tó jẹ́ kó dáni lójú pé ẹni gidi ni Jésù, kì í ṣe ẹ̀dá inú ìtàn àlọ́ kan lásán. Àwọn ìwé Ìhìn Rere náà sọ ìgbà àti àkókó pàtó tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí wọ́n kọ sílẹ̀ wáyé àti ibi tí wọ́n ti wáyé. Bí àpẹẹrẹ, Lúùkù tó kọ ọ̀kan lára ìwé Ìhìn Rere dárúkọ olùṣàkóso méje kan láti fi jẹ́rìí sí ọdún tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, àwọn òpìtàn sì fi hàn pé àwọn olùṣàkóso yẹn wà lóòótọ́.—Lúùkù 3:1, 2, 23.

Ẹ̀rí tó fi hàn pé Jésù ti gbé ayé yìí rí lóòótọ́ pọ̀ gan-an débi pé kò ṣeé já ní koro. Ìwé náà, Evidence for Historical Jesus, sọ pé: “Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ọ̀mọ̀wé ló máa gbà pé ọkùnrin kan tí wọ́n ń pè ní Jésù ará Násárétì gbé ayé ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní lóòótọ́.”

ÌBÉÈRÈ: Ṣé Ọlọ́run ni Jésù jẹ́ lóòótọ́?

ÌDÁHÙN: Rárá o. Jésù kò ka ara rẹ̀ sí ẹni tó bá Ọlọ́run dọ́gba nígbà kankan. Kàkà bẹ́ẹ̀, lemọ́lemọ́ ni Jésù ń fi hàn pé Jèhófà ju òun lọ. * Bí àpẹẹrẹ, Jésù pe Jèhófà ní “Ọlọ́run mi,” ó sì tún pè é ní “Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.” (Mátíù 27:46; Jòhánù 17:3) Ẹni tó bá rẹlẹ̀ sí ẹnì kan ló máa ń lo irú gbólóhùn bẹ́ẹ̀ fún ẹni tó jù ú lọ. Ó dájú pé òṣìṣẹ́ kan tó pe ẹni tó gbà á sí iṣẹ́ ní “ọ̀gá mi” tàbí “ọ̀gá wa” ń fi hàn pé onítọ̀hún ju òun lọ.

Jésù tún fi hàn pé ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni òun àti Ọlọ́run. Nígbà kan, Jésù sọ fún àwọn alátakò kan tó ń béèrè ẹni tó fún un ní àṣẹ pé: “Nínú Òfin ẹ̀yin fúnra yín, a kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Òótọ́ ni ẹ̀rí ènìyàn méjì.’ Ọ̀kan ni èmi tí ń jẹ́rìí nípa ara mi, Baba tí ó rán mi sì ń jẹ́rìí nípa mi.” (Jòhánù 8:17, 18) Dájúdájú, ẹni ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jésù àti Jèhófà jẹ́. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀ báwo ni wọ́n ṣe máa kà wọ́n sí ẹlẹ́rìí méjì? *

ÌBÉÈRÈ: Ṣé èèyàn rere lásán ni Jésù kàn jẹ́?

ÌDÁHÙN: Rárá o. Jésù jù bẹ́ẹ̀ lọ. Ó mọ̀ pé òun ń kó ipa pàtàkì nínú bí ète Ọlọ́run ṣe ń ṣẹ. Díẹ̀ nínú ipa wọ̀nyẹn rèé:

“Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run.” (Jòhánù 3:18) Jésù mọ ibi tí òun ti pilẹ̀ṣẹ̀. Ó ti wà tipẹ́tipẹ́ ṣáájú kí wọ́n tó bí i sí ayé. Jésù sọ pé: “Èmi sọ̀ kalẹ̀ wá láti ọ̀run.” (Jòhánù 6:38) Nínú gbogbo ìṣẹ̀dá Ọlọ́run láyé àti ọ̀run, Jésù ni Ọlọ́run kọ́kọ́ dá, Ọlọ́run sì tún lo Jésù láti dá gbogbo nǹkan yòókù. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé Jésù nìkan ṣoṣo ni Ọlọ́run fúnra rẹ̀ dá, ó tọ́ tí a bá pe Jésù ní “Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run.”—Jòhánù 1:3, 14; Kólósè 1:15, 16.

“Ọmọ ènìyàn.” (Mátíù 8:20) Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Jésù máa ń pe ara rẹ̀ ní “Ọmọ ènìyàn,” gbólóhùn tó sì ń lò fún ara rẹ̀ yìí fara hàn ní nǹkan bí ọgọ́rin [80] ìgbà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere. Gbólóhùn yìí fi hàn pé èèyàn ẹlẹ́ran ara bíi tiwa ni nígbà tó wà láyé, kì í ṣe Ọlọ́run tó kàn para dà di èèyàn. Báwo ni Ọmọ bíbí kan ṣoṣo ti Ọlọ́run ṣe wá dẹni tí a bí ní èèyàn? Ṣe ni Jèhófà lo ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ láti fi mú ìwàláàyè Ọmọ rẹ̀ yìí sínú ilé ọlẹ̀ Màríà wúńdíá tó jẹ́ Júù, tó wá di oyún sínú rẹ̀. Ìyẹn ló jẹ́ kó lè bí Jésù ní ẹni pípé tí kò ní ẹ̀ṣẹ̀ rárá.—Mátíù 1:18; Lúùkù 1:35; Jòhánù 8:46.

“Olùkọ́.” (Jòhánù 13:13) Jésù sọ ọ́ kedere pé iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún òun ni pé kí òun máa “kọ́ni” kí òun sì máa “wàásù ìhìn rere” Ìjọba Ọlọ́run. (Mátíù 4:23; Lúùkù 4:43) Ọ̀nà àrà ọ̀tọ̀ tó ṣe kedere tó sì yéni yékéyéké ni Jésù gbà ṣàlàyé Ìjọba Ọlọ́run àti ohun tí yóò ṣe láti fi mú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ.—Mátíù 6:9, 10.

“Ọ̀rọ̀ náà.” (Jòhánù 1:1) Jésù jẹ́ Agbọ̀rọ̀sọ fún Ọlọ́run, ìyẹn ni pé Ọlọ́run máa ń fi ọ̀rọ̀ àti àwọn ìtọ́ni rẹ̀ rán an pé kó sọ fún àwọn míì. Jèhófà máa ń rán Jésù níṣẹ́ sí àwọn èèyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé.—Jòhánù 7:16, 17.

ÌBÉÈRÈ: Ṣé Jésù ni Mèsáyà tí Ọlọ́run ṣèlérí?

ÌDÁHÙN: Bẹ́ẹ̀ ni. Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ inú Bíbélì ti sọ pé Mèsáyà, tàbí Kristi, èyí tó túmọ̀ sí “Ẹni Àmì Òróró,” ń bọ̀. Ẹni Tí Ọlọ́run Ṣèlérí yìí yóò sì kó ipa pàtàkì nínú bí ète Jèhófà ṣe máa ṣẹ. Nígbà kan, obìnrin ará Samáríà kan sọ fún Jésù pé: “Mo mọ̀ pé Mèsáyà ń bọ̀, ẹni tí a ń pè ní Kristi.” Jésù wá sọ fún obìnrin yẹn kedere pé: “Èmi tí ń bá ọ sọ̀rọ̀ ni ẹni náà.”—Jòhánù 4:25, 26.

Ǹjẹ́ ẹ̀rí kankan wà tó fi hàn pé Jésù ni Mèsáyà yẹn lóòótọ́? Bẹ́ẹ̀ ni. Ẹ̀rí oríṣi mẹ́tà kan wà tó fi hàn bẹ́ẹ̀ lọ́nà tí kò ṣeé já ní koro. Ṣe ló dà bí àwọn ìlà ọwọ́ wa tí tẹnì kan kì í bá tẹnì kejì mu tá a bá tẹ̀ka. Ṣé àwọn ẹ̀rí yẹn sì bá Jésù mu lóòótọ́? Wo àwọn ẹ̀rí náà:

Ìlà ìdílé tí wọ́n ti bí i. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé Mèsáyà náà yóò jẹ́ àtọmọdọ́mọ Ábúráhámù àti ọmọ-ọmọ Dáfídì. (Jẹ́nẹ́sísì 22:18; Sáàmù 132:11, 12) Baba ńlá Jésù sì ni àwọn méjèèjì.—Mátíù 1:1-16; Lúùkù 3:23-38.

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ sí Jésù lára. Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí Mèsáyà ṣe máa gbé ìgbésí ayé rẹ̀ ní ayé, títí kan kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa bí wọ́n ṣe máa bí i àti bó ṣe máa kú. Gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ yìí pátá ló ṣẹ sí Jésù lára. Ara àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ sí Jésù lára ni pé: Wọ́n bí i ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù (Míkà 5:2; Lúùkù 2:4-11), wọ́n pè é wá láti Íjíbítì (Hóséà 11:1; Mátíù 2:15), wọn kò ṣẹ́ ìkankan nínú àwọn egungun rẹ̀ nígbà tí wọ́n pa á. (Sáàmù 34:20; Jòhánù 19:33, 36) Kò sí bí Jésù ṣe lè dọ́gbọ́n darí ìgbésí ayé ara rẹ̀ lọ́nà tí yóò fi mú gbogbo ohun tí àsọtẹ́lẹ̀ ti sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ sí Mèsáyà ṣẹ tán pátápátá. *

Ẹ̀rí ti Ọlọ́run fúnra rẹ̀. Nígbà tí wọ́n bí Jésù, Ọlọ́run rán àwọn áńgẹ́lì kí wọ́n lọ sọ fún àwọn olùṣọ́ àgùntàn kan pé wọ́n ti bí Mèsáyà. (Lúùkù 2:10-14) Nígbà tí Jésù sì ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ọlọ́run fúnra rẹ̀ sọ̀rọ̀ láti ọ̀run, pé òun tẹ́wọ́ gba Jésù. (Mátíù 3:16, 17; 17:1-5) Jèhófà sì tún fún Jésù ní agbára tó fi ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ìyanu, èyí tó jẹ́ ẹ̀rí síwájú sí i pé Jésù ni Mèsáyà.—Ìṣe 10:38.

ÌBÉÈRÈ: Kí nìdí tí Jésù fi ní láti jìyà kó sì kú?

ÌDÁHÙN: Jésù kò dẹ́ṣẹ̀ rárá, nítorí náà kò sídìí tó fi yẹ kó jìyà. Kò sì tọ́ kí wọ́n kàn án mọ́gi kó lè kú ikú ẹ̀sín gẹ́gẹ́ bí ọ̀daràn lásánlàsàn. Síbẹ̀, Jésù retí pé wọ́n á ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí òun, ó sì yọ̀ǹda ara rẹ̀ tinútinú láti jẹ gbogbo ìyà náà.—Mátíù 20:17-19; 1 Pétérù 2:21-23.

Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí Bíbélì sọ nípa Mèsáyà sọ pé Mèsáyà yóò ní láti jìyà kó sì kú láti lè mú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn kúrò. (Aísáyà 53:5; Dáníẹ́lì 9:24, 26) Jésù alára sọ pé òun wá láti “fi ọkàn [òun] fúnni gẹ́gẹ́ bí ìràpadà ní pàṣípààrọ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.” (Mátíù 20:28) Àwọn tó bá ní ìgbàgbọ́ pé ikú ìrúbọ tó kú ní agbára láti ṣe ìràpadà ẹ̀ṣẹ̀, lè dẹni tó rí ìgbàlà kúrò lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú, kí wọ́n sì máa gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé. *Jòhánù 3:16; 1 Jòhánù 4:9, 10.

ÌBÉÈRÈ: Ṣé a lè gbà á gbọ́ pé Ọlọ́run jí Jésù dìde lóòótọ́ nígbà tó kú?

ÌDÁHÙN: Bẹ́ẹ̀ ni. Jésù mọ̀ dájú pé nígbà tí òun bá kú, àjíǹde máa wà fún òun. (Mátíù 16:21) Àmọ́ ṣá, ó ṣe pàtàkì ká fi sọ́kàn pé, Jésù fúnra rẹ̀ àti àwọn tó kọ̀wé inú Bíbélì kò sọ ọ́ níbì kankan pé ṣe ló kàn tún máa fúnra rẹ̀ jí dìde tó bá kú. Irú ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ kò ní ṣeé gbà gbọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, Bíbélì sọ pé: “Ọlọ́run jí i dìde nípa títú àwọn ìroragógó ikú.” (Ìṣe 2:24) Tí a bá gbà pé Ọlọ́run wà àti pé òun ni Ẹlẹ́dàá tó dá ohun gbogbo, kò yẹ kó ṣòro fún wa nígbà náà láti gbà gbọ́ pé ó lè jí Ọmọ rẹ̀ dìde nínú ikú.—Hébérù 3:4.

Ǹjẹ́ ẹ̀rí tó ṣeé gbà gbọ́ tiẹ̀ wà pé Jésù jíǹde lóòótọ́? Ìwọ wo ẹ̀rí wọ̀nyí ná.

Ẹ̀rí látọ̀dọ̀ àwọn tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣojú wọn. Ní nǹkan bí ọdún méjìlélógún lẹ́yìn tí Jésù kú, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] èèyàn lọ tó fojú ara wọn rí Jésù lẹ́yìn tó jíǹde àti pé èyí tó pọ̀ jú lára àwọn tó fojú rí i yẹn ṣì wà láàyè nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ ìwé náà. (1 Kọ́ríńtì 15:6) Ó rọrùn láti sọ pé ẹ̀rí ẹnì kan ṣoṣo tàbí ẹni méjì kì í ṣòótọ́, àmọ́ ta ló máa lè já ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [500] ẹlẹ́rìí tí ọ̀ràn ṣojú wọn ní koro?

Àwọn ẹlẹ́rìí tó ṣeé gbà gbọ́. Àwọn tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù nígbà tó wà ní ayé látijọ́, tó jẹ́ pé kò sí bí wọn kò ṣe ní mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ lóòótọ́, ń fi ìgboyà sọ fáyé gbọ́ pé Ọlọ́run jí Jésù dìde. (Ìṣe 2:29-32; 3:13-15) Kódà, wọ́n gbà pé àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ nígbàgbọ́ pé Kristi jíǹde kí wọ́n tó lè jẹ́ ojúlówó Kristẹni. (1 Kọ́ríńtì 15:12-19) Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ yẹn kò kọ̀ láti kú dípò kí wọ́n jáwọ́ nínú ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Jésù. (Ìṣe 7:51-60; 12:1, 2) Ṣé o rò pé èèyàn kankan máa mọ̀ọ́mọ̀ gbà láti kú torí ohun tó mọ̀ dájú pé ó jẹ́ irọ́ pátápátá?

Wàyí o, a ti ṣàyẹ̀wò ìdáhùn Bíbélì sí àwọn ìbéèrè mẹ́fà tó ṣe kókó nípa Jésù. Àwọn ìdáhùn náà sì sọ ẹni tí Jésù jẹ́ fún wa kedere. Àmọ́, ohun yòówù kí àwọn ìdáhùn náà jẹ́, ǹjẹ́ ó tiẹ̀ ṣe pàtàkì? Tàbí ní kúkúrú, ṣé ohun tó bá ṣáà ti wu èèyàn lèèyàn lè gbà gbọ́ nípa Jésù?

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Àlàyé lórí bí àwọn ìwé Ìhìn Rere inú Bíbélì ṣe yàtọ̀ sí àwọn ayédèrú ìwé kan tí wọ́n kọ nípa Jésù, wà nínú àpilẹ̀kọ kan tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Àwọn Ìwé Ìhìn Rere Ti Àpókírífà, Ǹjẹ́ Ìtàn Jésù Tí Bíbélì Kò Sọ Ni Lóòótọ́?” ní ojú ìwé 18 àti 19.

^ Bíbélì sọ pé Jèhófà ni orúkọ Ọlọ́run.

^ Tó o bá fẹ́ àlàyé kíkún sí i lórí kókó yìí, wo àpilẹ̀kọ tí a pe àkòrí rẹ̀ ní “Ìjíròrò Láàárín Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti Ẹnì Kan—Ṣé Jésù Ni Ọlọ́run?” ní ojú ìwé 20 sí 22.

^ Tó o bá fẹ́ mọ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tó ṣẹ sí Jésù lára, wo ibi tí a to àwọn kan lára rẹ̀ sí ní ojú ìwé 200 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?

^ Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i nípa bí ikú Jésù ṣe rà wá pa dà, ka orí 5 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?