Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ó Ṣe Pàtàkì Kí Á Mọ Ìdáhùn Tó Tọ̀nà?

Ǹjẹ́ Ó Ṣe Pàtàkì Kí Á Mọ Ìdáhùn Tó Tọ̀nà?

Ǹjẹ́ Ó Ṣe Pàtàkì Kí Á Mọ Ìdáhùn Tó Tọ̀nà?

“Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.”—JÒHÁNÙ 8:32.

ÒTÍTỌ́ tó lè mú kí á bọ́ lọ́wọ́ onírúurú èrò tó ń rúni lójú nípa Jésù tàbí èrò tó tiẹ̀ lòdì nípa rẹ̀, wà nínú Bíbélì. Àmọ́, ohun yòówù kéèyàn gbà gbọ́ nípa Jésù, ǹjẹ́ ìyẹn tiẹ̀ ṣe pàtàkì? Bẹ́ẹ̀ ni, ó ṣe pàtàkì. Ó ṣe pàtàkì lójú Jèhófà. Ó ṣe pàtàkì lójú Jésù. Ó sì yẹ kó ṣe pàtàkì lójú àwa náà.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì lójú Jèhófà? Ní kúkúrú, ìdí ni pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Ṣe ni Jèhófà fẹ́ ká wà láàyè títí láé, ká sì máa láyọ̀. Jésù sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé [aráyé] tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ . . . lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ wá sí ayé kó wá rà wá pa dà, kó sì mú kí ó lè ṣeé ṣe fún wa láti máa gbé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé títí láé bí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kó rí ní ìpilẹ̀ṣẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 1:28) Ó ń wu Ọlọ́run láti fi ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun fún àwọn tó bá mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa Ọmọ rẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ lórí ohun tí wọ́n mọ̀ yẹn.—Róòmù 6:23.

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì lójú Jésù? Jésù náà fẹ́ràn aráyé. Ìfẹ́ àrà-ọ̀tọ̀ tó ní yìí ló mú kó fínnúfíndọ̀ fi ẹ̀mí rẹ̀ lélẹ̀ nítorí wa. (Jòhánù 15:13) Ó mọ̀ pé ohun tí òun ṣe yẹn ló máa jẹ́ kí ọ̀nà kan ṣoṣo tí aráyé lè gbà rí ìgbàlà ṣí sílẹ̀. (Jòhánù 14:6) Ǹjẹ́ ó yẹ kó yà wá lẹ́nu pé Jésù fẹ́ kí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ èèyàn jàǹfààní ẹbọ ìràpadà òun? Ó tì o. Ìyẹn ló fi sọ pé kí àwọn ojúlówó ọmọlẹ́yìn òun lọ máa kọ́ àwọn èèyàn kárí ayé nípa ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run àti gbogbo ète rẹ̀.—Mátíù 24:14; 28:19, 20.

Kí nìdí tó fi yẹ kó ṣe pàtàkì lójú tiwa? Ronú ná nípa àwọn nǹkan tó dájú pé ó jẹ ọ́ lógún gan-an, ìyẹn ìlera rẹ àti ti ìdílé rẹ. Ǹjẹ́ ó máa ń wù ọ́ gan-an pé kí ara ìwọ àti àwọn èèyàn rẹ le koko kí ẹ sì máa gbádùn ayé yín? Jèhófà tipasẹ̀ Jésù nawọ́ àǹfààní ńlá kan sí ìwọ àti àwọn èèyàn rẹ, ìyẹn àǹfààní láti ní ìlera pípé, kí ẹ sì máa gbé nínú ayé tuntun títí láé, níbi tí kò ti ní sí ìrora àti ìyà mọ́. (Sáàmù 37:11, 29; Ìṣípayá 21:3, 4) Ṣé wàá fẹ́ láti máa gbé nínú irú ayé bẹ́ẹ̀? Tó o bá fẹ́ bẹ́ẹ̀, ohun kan wà tí o ní láti ṣe.

Tún pa dà wo ẹsẹ Bíbélì tí a kọ sí ìsàlẹ̀ àkòrí àpilẹ̀kọ yìí lókè, èyí tó sọ pé: “Ẹ ó sì mọ òtítọ́, òtítọ́ yóò sì dá yín sílẹ̀ lómìnira.” Tí a bá mọ òtítọ́ nípa Jésù àti ipa tí ó ń kó nínú bí ète Ọlọ́run ṣe ń ṣẹ, èyí lè dá wa nídè kúrò nínú ìsìnrú tó burú jù lọ, ìyẹn kúrò nínú oko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Àmọ́ ṣá o, kí o tó lè rí ìdáǹdè yẹn gbà, o ní láti “mọ òtítọ́.” Nítorí náà, o ò ṣe túbọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa òtítọ́ yìí àti bí ìwọ àti àwọn èèyàn rẹ ṣe lè jàǹfààní nínú rẹ̀? Inú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti ràn ọ́ lọ́wọ́.