Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó ní kéèyàn dé ibùsọ̀ kejì?

Nígbà tí Jésù ń ṣe Ìwàásù Lórí Òkè, èyí tí àwọn èèyàn mọ̀ bí ẹni mowó, ó sọ pé: ‘Bí ẹnì kan tí ó wà ní ipò ọlá àṣẹ bá fi tipátipá gbéṣẹ́ fún ọ fún ibùsọ̀ kan, bá a dé ibùsọ̀ méjì.’ (Mátíù 5:41) Ó jọ pé àwùjọ tí Jésù ń sọ̀rọ̀ yìí fún nígbà yẹn mọ̀ pé ọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ tí àwọn aláṣẹ lè fipá mú àwọn aráàlú ṣe ni Jésù ń sọ.

Ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni, àwọn ará ilẹ̀ Róòmù ló jẹ gàba lé ilẹ̀ Ísírẹ́lì lórí, tí wọ́n ń ṣàkóso wọn. Wọ́n máa ń fipá mú èèyàn tàbí kí wọ́n kàn mú ẹranko èyíkéyìí láti fi ṣe iṣẹ́ fún wọn tàbí kí wọ́n fipá gba ohunkóhun tí wọ́n bá rí pé àwọn nílò láti fi ṣe iṣẹ́ ìjọba parí kíákíá. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ọmọ ogun Róòmù fipá mú kí Símónì ará Kírénè gbé òpó igi oró Jésù lọ sí ibi tí wọ́n ti fẹ́ pa Jésù. (Mátíù 27:32) Irú ìmúnisìn bẹ́ẹ̀ jẹ́ ìwà aninilára, àwọn èèyàn kà á sí ìwà ìkà, àwọn Júù sì kórìíra rẹ̀ gan-an.

A kò mọ ìwọ̀n ibi tí wọ́n lè ní kí àwọn aráàlú báwọn gbé ẹrù dé. Àmọ́, ó dájú pé àwọn aráàlú kò ní fẹ́ gbé ẹrù náà kọjá ibi tí wọ́n bá ti sọ fún wọn tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa gbé e dé. Torí náà, nígbà tí Jésù sọ fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé kí wọ́n dé ibùsọ̀ kejì, tó túmọ̀ sí pé kí wọ́n tiẹ̀ ṣe jù bẹ́ẹ̀ lọ, ohun tó ń sọ ni pé kí wọ́n ṣe iṣẹ́ tí àwọn aláṣẹ bá pín fún wọn láìjanpata, tí iṣẹ́ yẹn kò bá ti lòdì sí òfin Ọlọ́run.—Máàkù 12:17.

Ta ni Ánásì tí ìwé Ìhìn Rere mẹ́nu kàn?

Nígbà tí wọ́n ń gbọ́ ẹjọ́ Jésù, “olórí àlùfáà” ni wọ́n pe Ánásì (Ánánúsì). (Lúùkù 3:2; Jòhánù 18:13; Ìṣe 4:6) Ánásì jẹ́ àna Káyáfà tó jẹ́ àlùfáà àgbà ní Ísírẹ́lì, Ánásì fúnra rẹ̀ sì ti jẹ́ àlùfáà àgbà rí, ìyẹn láàárín ọdún kẹfà tàbí ìkeje Sànmánì Kristẹni sí ọdún kẹẹ̀ẹ́dógún Sànmánì Kristẹni. Gómìnà Valerius Gratus tó jẹ́ ará Róòmù ló yọ ọ́ kúrò nípò. Síbẹ̀, torí pé Ánásì ti jẹ́ àlùfáà àgbà rí, ó ṣì ní agbára tó pọ̀ gan-an lórí àwọn èèyàn ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Márùn-ún nínú àwọn ọmọ rẹ̀ àti àna rẹ̀ ló dé ipò àlùfáà àgbà.

Láyé ìgbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ṣì ń ṣàkóso ara wọn, ṣe ni àlùfáà àgbà máa ń wà nípò yẹn títí tá a fi kú. (Númérì 35:25) Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ará ilẹ̀ Róòmù jẹ gàba lé ilẹ̀ Ísírẹ́lì lórí, bí àwọn gómìnà àti ọba tí ilẹ̀ Róòmù yàn síbẹ̀ bá ṣe fẹ́ ni àlùfáà àgbà ṣe máa ń pẹ́ tó lórí oyè, wọ́n sì lè rọ̀ ọ́ lóyè. Òpìtàn tó ń jẹ́ Flavius Josephus sọ pé Kúírínọ́sì, tí ilẹ̀ Róòmù fi jẹ́ gómìnà Síríà, yọ ẹnì kan tó ń jẹ́ Joazar kúrò nípò àlùfáà àgbà ní nǹkan bí ọdún kẹfà tàbí ìkeje Sànmánì Kristẹni, ó sì wá yan Ánásì sí ipò yẹn. Àmọ́ ó jọ pé àwọn alákòóso tó jẹ́ abọ̀rìṣà wọ̀nyí máa ń rí i dájú pé àárín àwọn àlùfáà náà ni wọ́n ti máa ń mú ẹni tí wọ́n bá tún fẹ́ yàn sípò.

Ìdílé Ánásì jẹ́ èyí táwọn èèyàn mọ̀ sí ìdílé oníwọra paraku, wọ́n sì lówó lọ́wọ́ bíi ṣẹ̀kẹ̀rẹ̀. Ó dà bíi pé ohun tó sọ wọ́n di ọlọ́rọ̀ ni pé àwọn nìkan ló ràgà bo òwò títa àwọn ohun kòṣeémánìí tí àwọn èèyàn máa ń fi rúbọ ní gbogbo àyíká tẹ́ńpìlì, irú bí àdàbà, àgùntàn, òróró àti wáìnì. Òpìtàn náà Josephus sọ pé Ánánúsì (Ananíà), ìyẹn Ánásì, ní “àwọn ìránṣẹ́ tó jẹ́ ọmọọ̀ta paraku tí wọ́n máa ń fipá gba ìdámẹ́wàá tó jẹ́ ti àwọn àlùfáà àti pé wọ́n máa ń na àwọn tí kò bá fún wọn ní ìnàkunà.”