Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Jọ̀wọ́ Jẹ́ Ká Pa Dà Wá Sílé”

“Jọ̀wọ́ Jẹ́ Ká Pa Dà Wá Sílé”

Sún Mọ́ Ọlọ́run

“Jọ̀wọ́ Jẹ́ Ká Pa Dà Wá Sílé”

Ǹjẹ́ o ti ń sin Jèhófà nígbà kan rí? Ṣé o ti wá ronú pé o fẹ́ pa dà máa sìn ín báyìí, àmọ́ tí ò ń rò ó pé ǹjẹ́ Jèhófà máa fẹ́ gbà ọ́ pa dà? Jọ̀wọ́ fara balẹ̀ ka àpilẹ̀kọ yìí àti èyí tó tẹ̀ lé e. Torí tìẹ ni a ṣe kọ àpilẹ̀kọ méjèèjì.

OBÌNRIN kan tó ṣe ohun tó lòdì pátápátá sí ìlànà Kristẹni tí wọ́n fi tọ́ ọ dàgbà sọ pé: “Mo bẹ Jèhófà pé kó jọ̀ọ́, kó jẹ́ kí n pa dà wá sílé, [ìyẹn sínú ètò rẹ̀] kó sì dárí jì mí nítorí mo ṣe ohun tó dùn ún.” Ǹjẹ́ àánú obìnrin yìí kò ṣe ọ́? Ṣé ìwọ náà tiẹ̀ máa ń rò ó pé, ‘Báwo lọ̀rọ̀ àwọn tó ti ń sin Ọlọ́run nígbà kan rí àmọ́ tí wọn kò sìn ín mọ́ ṣe máa ń rí lára Ọlọ́run? Ǹjẹ́ ó máa ń rántí wọn? Ṣé Ọlọ́run tiẹ̀ fẹ́ kí wọ́n “pa dà wá sílé,” ìyẹn ni pé kí wọ́n tún pa dà máa sin òun?’ Ká lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ tí wòlíì Jeremáyà sọ yẹ̀ wò. Ó dájú pé àwọn ìdáhùn náà yóò tù ọ́ nínú.—Ka Jeremáyà 31:18-20.

Wo ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jeremáyà kọ ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yẹn. Lọ́dún 740 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ìyẹn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún ṣáájú ìgbà ayé Jeremáyà, Jèhófà jẹ́ kí àwọn ará Ásíríà kó àwọn ẹ̀yà mẹ́wàá tó jẹ́ ìjọba Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn. * Ọlọ́run jẹ́ kí èyí ṣẹlẹ̀ sí àwọn èèyàn rẹ̀ torí pé wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì, wọ́n sì ń kọ etí ikún sí gbogbo ìkìlọ̀ tí àwọn wòlíì rẹ̀ ń kéde fún wọn lemọ́lemọ́. (2 Àwọn Ọba 17:5-18) Ǹjẹ́ àwọn èèyàn náà yí pa dà nígbà tí Ọlọ́run fi wọ́n sílẹ̀, tí ọwọ́ ìyà sì bà wọ́n nígbèkùn tí wọ́n wà, lọ́nà jíjìn rere sí ilẹ̀ wọn? Ṣé Jèhófà pa wọ́n tì, tó sì gbàgbé wọn síbẹ̀? Ǹjẹ́ ó mú wọn pa dà wá sí ilẹ̀ wọn, kí wọ́n lè pa dà máa sìn ín?

“Mo Kábàámọ̀”

Nígbà tí àwọn èèyàn náà wà nígbèkùn wọ́n rí i pé àwọn ti ṣẹ̀, wọ́n sì ronú pìwà dà. Jèhófà sì kíyè sí ẹ̀mí ìrònúpìwàdà wọn. Gbọ́ bí Jèhófà ṣe ṣàpèjúwe ẹ̀dùn ọkàn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wà nígbèkùn yẹn lápapọ̀, èyí tó pè ní Éfúráímù.

Jèhófà sọ pé: “Àní mo ti gbọ́ tí Éfúráímù ń kédàárò nípa ara rẹ̀.” (Ẹsẹ 18) Ó gbọ́ bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe ń kẹ́dùn nítorí ohun tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn yọrí sí. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé gbólóhùn yẹn “kédàárò nípa ara rẹ̀” lè túmọ̀ sí kéèyàn “mi nǹkan síwá-sẹ́yìn tàbí sọ́tùn-ún-sósì.” Ńṣe ni ọ̀rọ̀ wọn dà bí ọmọ aláìgbọràn tó ń mi orí tìrònú-tìrònú bó ṣe ń ro wàhálà tó kó ara sí, tí ọkàn rẹ̀ sì ń fà sílé. (Lúùkù 15:11-17) Kí ni ohun tí àwọn èèyàn náà ń sọ?

“Ìwọ ti tọ́ mi sọ́nà . . . bí ọmọ màlúù tí a kò kọ́.” (Ẹsẹ 18) Àwọn èèyàn yẹn gbà pé ìyà yẹn tọ́ sí àwọn. Ó ṣe tán, ṣe ni wọ́n dà bí ọmọ màlúù tí a kò kọ́. Ìwé ìwádìí kan jẹ́ ká mọ̀ pé àfiwé yìí lè túmọ̀ sí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn dà bí ọmọ màlúù kan “tí wọn ì bá máà gún ní kẹ́ṣẹ́, ká ní ó ṣe ara rẹ̀ jẹ́jẹ́ lábẹ́ àjàgà rẹ̀.”

“Mú mi yí padà. Èmi yóò sì yí padà wéréwéré, nítorí ìwọ ni Jèhófà Ọlọ́run mi.” (Ẹsẹ 18) Àwọn èèyàn náà rẹ ara wọn sílẹ̀, wọ́n sì ké pe Ọlọ́run. Ipa ọ̀nà ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ń tọ̀ tí mú kí wọ́n ṣìnà, àmọ́ ní báyìí, wọ́n ń bẹ̀bẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, kí wọ́n tún lè pa dà rí ojú rere rẹ̀. Bí ìtumọ̀ Bíbélì kan ṣe sọ ọ́ ni pé: “Ìwọ ni Ọlọ́run wa, jọ̀wọ́ jẹ́ ká pa dà wá sílé.”—Bíbélì Contemporary English Version.

“Mo kábàámọ̀. . . . Ìtìjú bá mi, a sì tún tẹ́ mi lógo.” (Ẹsẹ 19) Ìbànújẹ́ bá àwọn èèyàn náà nítorí pé wọ́n dẹ́ṣẹ̀. Wọ́n gba ẹ̀bi wọn lẹ́bi, wọ́n sì mọ ẹ̀ṣẹ̀ wọn lẹ́ṣẹ̀. Wọ́n rí i pé àwọn di ẹni ẹ̀tẹ́, wọ́n sì ń fọwọ́ gbá àyà bí ẹni tí ìrònú bá.—Lúùkù 15:18, 19, 21.

Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yẹn ronú pìwà dà. Wọ́n kẹ́dùn gidigidi, wọ́n jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn fún Ọlọ́run, wọ́n sì yí pa dà kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn. Ǹjẹ́ ẹ̀mí ìrònú pìwà dà tí wọ́n ní yìí máa mú kí wọ́n rí ìyọ́nú Ọlọ́run? Ṣé ó máa jẹ́ kí wọ́n pa dà wá sílé?

“Dájúdájú, Èmi Yóò Ṣe Ojú Àánú sí I”

Jèhófà fẹ́ràn àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́nà àrà ọ̀tọ̀. Ó ní: “Mo ti di Baba fún Ísírẹ́lì; ní ti Éfúráímù, òun ni àkọ́bí mi.” (Jeremáyà 31:9) Ǹjẹ́ bàbá kan tó jẹ́ onífẹ̀ẹ́ kò ní tẹ́wọ́ gba ọmọ rẹ̀ tó ronú pìwà dà tọkàntọkàn pa dà? Wo bí Jèhófà ṣe sọ ìyọ́nú tó ní sí àwọn èèyàn rẹ̀ bí bàbá ṣe ń yọ́nú sí ọmọ.

“Ọmọ àtàtà ha ni Éfúráímù jẹ́ sí mi, tàbí ọmọ tí a hùwà sí lọ́nà ìfẹ́ni? Nítorí dé àyè tí mo sọ̀rọ̀ lòdì sí i dé, láìkùnà, èmi yóò rántí rẹ̀ síwájú sí i.” (Ẹsẹ 20) Ọ̀rọ̀ ìyọ́nú tó ga mà lọ̀rọ̀ yìí o! Gẹ́gẹ́ bí òbí onífẹ̀ẹ́ kan tí kò gbàgbàkugbà, Ọlọ́run rí i pé òun ní láti sọ̀rọ̀ “lòdì sí” àwọn ọmọ òun yìí, ó sì kìlọ̀ fún wọn lemọ́lemọ́ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn. Nígbà tí wọ́n sì kọ etí ikún sí i, ó jẹ́ kí wọ́n kó wọn lọ sí ìgbèkùn, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí wọ́n kúrò nílé. Àmọ́ bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó jẹ wọ́n níyà, kò gbàgbé wọn. Kò lè gbàgbé wọn láéláé. Bàbá onífẹ̀ẹ́ kan kì í gbàgbé àwọn ọmọ rẹ̀. Àmọ́ báwo ló ṣe rí lára Jèhófà nígbà tó rí i pé àwọn ọmọ rẹ̀ yìí ronú pìwà dà tọkàntọkàn?

“Ìfun mi . . . di èyí tí ó ru gùdù fún un. * Dájúdájú, èmi yóò ṣe ojú àánú sí i.” (Ẹsẹ 20) Ọkàn Jèhófà fà sí àwọn ọmọ rẹ̀ gidigidi. Bí wọ́n ṣe ronú pìwà dà tọkàntọkàn dùn mọ́ Jèhófà gan-an, ó sì ń wù ú gan-an pé kí wọ́n pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀. Bí àánú ti ṣe bàbá tí Jésù sọ̀rọ̀ rẹ̀ nínú àkàwé ọmọ onínàákúnàá yẹn náà ni ‘àánú ṣe’ Jèhófà, ó sì ń hára gàgà láti gba àwọn ọmọ rẹ̀ pa dà sílé.—Lúùkù 15:20.

“Jèhófà, Jọ̀wọ́ Jẹ́ Kí N Pa Dà Wá Sílé”

Ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jeremáyà 31:18-20 jẹ́ ká túbọ̀ lóye ìyọ́nú oníjẹ̀lẹ́ńkẹ́ àti àánú Jèhófà. Ọlọ́run kò gbàgbé àwọn tó ti ń sìn ín nígbà kan rí. Tí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ bá fẹ́ láti pa dà wá sọ́dọ̀ rẹ̀ ńkọ́? Ọlọ́run “ṣe tán láti dárí jini.” (Sáàmù 86:5) Ọlọ́run kò ní ṣàì tẹ́wọ́ gba àwọn tí wọ́n ronú pìwà dà tọkàntọkàn tí wọ́n sì pa dà sọ́dọ̀ rẹ̀. (Sáàmù 51:17) Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni inú rẹ̀ máa ń dùn láti gbà wọ́n pa dà sílé, ìyẹn inú ètò rẹ̀.—Lúùkù 15:22-24.

Obìnrin tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí lo ìdánúṣe láti pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà, ó lọ sí ọkàn lára ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní àdúgbò rẹ̀. Ó kọ́kọ́ sapá díẹ̀ ṣá o, kó tó borí ìbànújẹ́ ọkàn rẹ̀. Obìnrin náà sọ pé nígbà yẹn, “àánú ara mi ṣe mí.” Ṣùgbọ́n àwọn alàgbà ìjọ fún un ní ìṣírí, wọ́n sì ràn án lọ́wọ́ tó fi di ẹni tó tún pa dà ń fi ayọ̀ sin Ọlọ́run. Tìdùnnú-tìdùnnú ni obìnrin náà fi sọ pé: “Mo mà dúpẹ́ gan-an o pé Jèhófà jẹ́ kí n tún pa dà wá sílé lọ́dọ̀ rẹ̀!”

Tó bá jẹ́ pé ìwọ náà ti ń sin Jèhófà nígbà kan rí, tí o sì wá ń ronú pé o tún fẹ́ pa dà máa sìn ín, a rọ̀ ọ́ pé kí o lọ sí ọkàn nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó bá wà ní àdúgbò rẹ. Rántí pé Jèhófà máa ń fi ìyọ́nú àti àánú tẹ́wọ́ gba àwọn tó bá ronú pìwà dà tí wọ́n sì bẹ̀ ẹ́ pé, “jọ̀wọ́ jẹ́ ká pa dà wá sílé,” ìyẹn inú ètò rẹ̀.

Bíbélì Kíkà Tá A Dábàá Fún April:

Jeremáyà 17-31

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

^ Ọ̀pọ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún ṣáájú ìgbà náà, ìyẹn ní ọdún 997 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti pín sí ìjọba méjì. Ọ̀kan ni ìjọba Júdà tó jẹ́ ẹ̀yà méjì tó wà níhà gúúsù. Ìkejì ni ìjọba Ísírẹ́lì tó jẹ́ ẹ̀yà mẹ́wàá tó wà níhà àríwá, èyí tí wọ́n tún ń pè ní Éfúráímù torí pé ẹ̀yà náà ló gba iwájú láàárín wọn.

^ Nígbà tí ìwé kan tó jẹ́ ìwé atọ́nà fún àwọn atúmọ̀ Bíbélì ń ṣàlàyé àpèjúwe ìfun tó ru gùdù yìí, ó ní: “Àwọn Júù gbà pé inú èèyàn lọ́hùn-ún ni èèyàn ti máa ń mọ nǹkan lára jù.”